Àjálù Ojoojúmọ́ Yìí Ò Wa Pọ̀ Jù?
Àjálù Ojoojúmọ́ Yìí Ò Wa Pọ̀ Jù?
“Ó yẹ ká máa retí pé ìyípadà ojú ọjọ́ á fa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì lọ́jọ́ iwájú. Láburú tírú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ sì máa fà kò ní ṣeé sọ. Èyí túmọ̀ sí pé ó yẹ ká máa fiyè sí bójú ọjọ́ ṣe ń yí padà báyìí, ká sì máa múra sílẹ̀ de ìṣòro tó lè mú wá àti àdánù ńláǹlà míì tó lè tẹ̀yìn rẹ̀ yọ. . . . Tá a bá sì tẹ̀ lé ìlànà tó wà lórí dídáàbò bo ara wa nígbà tírú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ bá wáyé, irú àjálù bẹ́ẹ̀ ò ní máa bá wa lẹ́jafùú.”—Ìwé Ìròyìn Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì Náà,“Topics Geo—Annual Review: Natural Catastrophes 2003.”
NÍGBÀ ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 2003, ojú ọjọ́ gbóná janjan láwọn apá ibì kan nílẹ̀ Yúróòpù. Ooru gbígbóná yìí wà lára ohun tó fa ikú nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n èèyàn láwọn orílẹ̀-èdè bíi Belgium, Ítálì, Netherlands, Potogí, Sípéènì tó fi mọ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ilẹ̀ Faransé. Afẹ́fẹ́ gbígbóná tó máa ń fẹ́ kí òjò oníjì tó rọ̀ bú jáde láwọn orílẹ̀-èdè Bangladesh, Íńdíà, àti Pakistan, ó sì pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] èèyàn. Bákan náà, lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà, ọ̀dá àti ooru gbígbóná janjan yìí mú kí iná ṣẹ́ yọ nínú igbó tó fẹ̀ tó mílíọ̀nù mẹ́ta hẹ́kítà.
Gẹ́gẹ́ bí àjọ àgbáyé kan tó ń kíyè sí bójú ọjọ́ ṣe rí lábẹ́ àsíá Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe sọ, “láti nǹkan bí ọdún 1995, ìjì lílágbára tó ń jà lọ́dọọdún túbọ̀ ń pọ̀ sí i ni. Àmọ́, èyí tó fẹ́ wá láti orí òkun Àtìláńtíìkì, lékenkà nítorí pé ìjì lílágbára mẹ́rìndínlógún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló jà lọ́dún náà. Kódà, tá a bá ro iye irú ìjì yìí tó jà láàárín ọdún 1944 sí 1996 pọ̀, a ó rí i pé iye ìjì líle tó ń jà lọ́dọọdún nígbà yẹn kò tó mẹ́wàá.” Tọdún 2004 tún pọ̀ jù. Lọ́dún yìí, ìjì lílágbára mìíràn jà lágbègbè Caribbean àti lágbègbè ibi tí omi ti ya wọ ilẹ̀ Mẹ́síkò, èyí mú ẹ̀mí nǹkan bí ẹgbàá èèyàn lọ́wọ́, jìnnìjìnnì rẹ̀ ò sì tíì kúrò nílẹ̀.
Irú ìjì líle míì jà lórílẹ̀-èdè Sri Lanka lọ́dún
2003, ó sì di omíyalé tó pa àwọn èèyàn tí kò dín ní àádọ́talérúgba [250]. Ìjì líle tó jà ní ìwọ̀ oòrùn Pàsífíìkì lọ́dún 2004 kò dín ní mẹ́tàlélógún. Mẹ́wàá irú rẹ̀ jà ní orílẹ̀-èdè Japan ó sì gbẹ̀mí àwọn èèyàn tó ju àádọ́sàn-án [170] lọ. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgbọ̀n mílíọ̀nù èèyàn tó fara gbá omíyalé tí òjò alátẹ́gùn fà lágbègbè Gúúsù Éṣíà, pàápàá jù lọ lórílẹ̀-èdè Bangladesh. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló sọ di aláìnílélórí, èèyàn bíi mílíọ̀nù mẹ́ta ló sá kúrò nílé torí ẹ̀mí wọn, nígbà tí ẹ̀ẹ́dégbèje [1,300] èèyàn sì kú.Ọ̀pọ̀ ìsẹ̀lẹ̀ ló wáyé lọ́dún 2003. Ọ̀kan lára wọn ni èyí tó ṣẹlẹ̀ ní May 21, ní ìpínlẹ̀ Algiers lórílẹ̀-èdè Algeria, èyí tó ṣe ẹgbàárùn-ún [10,000] èèyàn léṣe tó sì sọ ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [200,000] di aláìnílélórí. Ní nǹkan bí aago márùn-ún ààbọ̀ ìdájí ní December 26, ọdún kan náà yẹn, ilẹ̀ mì tìtì ní nǹkan bíi kìlómítà mẹ́jọ sí apá gúúsù ìlú Bam lórílẹ̀-èdè Iran. Ìsẹ̀lẹ̀ náà lágbára débi pé ó ba ìdá méje nínú mẹ́wàá ìlú náà jẹ́, ó gbẹ̀mí ọ̀kẹ́ méjì [40,000] èèyàn, ó sì sọ ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] èèyàn di aláìnílélórí. Òun ló ṣọṣẹ́ jù lọ nínú àwọn àjálù tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún náà. Àní, ó sọ ilé aláruru tó jẹ́ àmúṣagbára ìlú yẹn, ìyẹn ilé kan tí wọ́n pè ní Arg-e-Bam di àlàpà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ba ibi àbẹ̀wò tó máa ń mówó wọlé fáwọn ará ibẹ̀ jẹ́.
Ní ọdún kan géérégé lẹ́yìn ìyẹn, ìsẹ̀lẹ̀ tó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ wáyé nítòsí etíkun tó wà ní àríwá erékùṣù Sumatra, ní ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Indonesia. Òun ni ìrugùdù omi tó wáyé látàrí ìsẹ̀lẹ̀ abẹ́ omi, èyí tó burú jù lọ tá a tíì gbọ́ rí látọjọ́ táláyé ti dáyé. Ìsẹ̀lẹ̀ burúkú yìí pa iye tó ju ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [200,000] èèyàn lọ, ó sì ṣe àwọn tó pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ léṣe tàbí kó sọ wọ́n di aláìnílélórí, ó tiẹ̀ ṣe àwọn kan lọ́ṣẹ́ lọ́nà méjèèjì. Kódà ìsẹ̀lẹ̀ runlérùnnà yìí jà dé etíkun ìlà oòrùn Áfíríkà níbi tó jìnnà tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin àbọ̀ kìlómítà tàbí kó tiẹ̀ jìn jù bẹ́ẹ̀ lọ, lápá ìwọ̀ oòrùn ibi tí ìsẹ̀lẹ̀ náà ti rinlẹ̀ jù.
Ṣé Àwọn Àjálù Tó Burú Jù Bẹ́ẹ̀ Lọ Ṣì Ń Bọ̀?
Ṣé àwọn àjálù wọ̀nyí ń ṣàpẹẹrẹ ohun tó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú ni? Ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ àjálù tó ń bá ojú ọjọ́ rìn ni pé báwọn ọmọ èèyàn ṣe ń lo ilé ayé wà lára ohun tó ń mú kí ojú ọjọ́ yí padà kó sì di èyí tó burú sí i. Bọ́rọ̀ yìí bá lọ jẹ́ òótọ́, nǹkan á le lọ́jọ́ iwájú. Ohun tó tún mú kí ọ̀rọ̀ náà túbọ̀ léwu sí i ni pé àwọn èèyàn tó ń gbé níbi tó ti ṣeé ṣé kí àjálù ṣẹlẹ̀ túbọ̀ ń pọ̀ sí i ni, nítorí pé ibẹ̀ ló wù wọ́n láti máa gbé tàbí kó jẹ́ pé wọn ò ríbòmíì gbé.
Nínú ìwádìí tí wọ́n ṣe, ìṣirò fi hàn pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn tí àjálù ń pa ló wà láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, àjálù kì í sábàá pa wọ́n láwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀, àmọ́ ibẹ̀ ló ti máa ń ṣàkóbá fún ọrọ̀ ajé jù. Ó ti mú káwọn ilé abánigbófò kan máa bẹ̀rù lórí bí wọ́n á ṣe máa rówó ìbánigbófò san nítorí báwọn èèyàn ṣe túbọ̀ ń ṣòfò dúkìá.
Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a ó ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ìjábá tó lè wáyé látàrí báwọn kan lára ohun tí ẹlẹ́dàá dá ṣe ń ṣiṣẹ́. A óò tún sọ nípa báwọn èèyàn ṣe ń dá kún bí ìjábá náà ṣe ń ṣọṣẹ́ tó. A ó sì tún wò ó bóyá aráyé lágbára láti yí àwọn nǹkan padà débi táyé á fi rọrùn gbé fáwọn ìran tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, a ó sì tún wò ó bóyá ó tiẹ̀ wù wọ́n láti ṣe bẹ́ẹ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
FARANSÉ 2003 Ooru ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tó ṣẹlẹ̀ ní Yúróòpù pa ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ èèyàn; ojú ọjọ́ gbóná janjan ní Sípéènì
[Credit Line]
Alfred/EPA/Sipa Press
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]
IRAN 2003 Ìsẹ̀lẹ̀ tó wáyé nílùú Bam pa ọ̀kẹ́ méjì èèyàn; àwọn obìnrin tó ń ṣọ̀fọ̀ àwọn ìbátan wọ́n tó kú níbi tí wọ́n sin wọ́n pa pọ̀ sí
[Credit Line]
Àwòrán apá ẹ̀yìn àtiàwọn obìnrin: © Tim Dirven/Panos Pictures ló yà á