Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àpilẹ̀kọ Kan Tọ́jọ́ Ẹ̀ Ti Pẹ́ Wọ Àwọn Èèyàn Lọ́kàn

Àpilẹ̀kọ Kan Tọ́jọ́ Ẹ̀ Ti Pẹ́ Wọ Àwọn Èèyàn Lọ́kàn

Àpilẹ̀kọ Kan Tọ́jọ́ Ẹ̀ Ti Pẹ́ Wọ Àwọn Èèyàn Lọ́kàn

NÍ ÌLÚ Suwałki tó wà lápá ìlà oòrùn àríwá ilẹ̀ Poland, obìnrin kan tó jẹ́ olùkọ́ sọ pé káwọn akẹ́kọ̀ọ́ múra sílẹ̀ fún ìjíròrò lórí ìṣẹ́yún. Justyna, tóun náà jẹ́ ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́rìndínlógún, ṣa àwọn ìsọfúnni díẹ̀ jọ látinú ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lọ́jọ́ tí ìjíròrò náà wáyé, olùkọ́ náà ní kí akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan wá máa sọ ohun tó bá rí sí ọ̀rọ̀ náà.

Justyna sọ pé: “Mo tọ olùkọ́ náà lọ, mo sì ni kó wo àpilẹ̀kọ tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní, ‘Akọsilẹ Ohun Ti O Ṣẹlẹ Si Ọmọ Kan Ti A Kò Bí,’ èyí tó jáde nínú Jí! August 8, 1981.” Ó wá sọ fún olùkọ́ rẹ̀ pé: “Ẹ jọ̀wọ́ mà, ẹ kíyè sí i pé wọ́n kọ ọ́ bíi pé ọmọ jòjòló kan tí wọn ò tíì bí, tí wọ́n sì fẹ́ ṣẹ́ oyún ẹ̀ dà nù ló ń sọ̀rọ̀. Mo rò pé ohun tó yẹ kí gbogbo èèyàn kà ni.” Bí olùkọ́ rẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ka àkọsílẹ̀ náà sókè nìyẹn o. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pa rọ́rọ́, gbogbo wọn sì tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́.

Kó tó di pé olùkọ́ náà kà á dé ìdajì, ẹkún ti bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n ọ́n, ló bá ní kí akẹ́kọ̀ọ́ kan ka èyí tó kù. Bó ṣe fìdí kalẹ̀ nìyẹn, ló bá mẹ́kún sun. Lẹ́yìn tí akẹ́kọ̀ọ́ ka àkọsílẹ̀ náà tán, ìjíròrò tó lárinrin tẹ̀ lé e, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan sì béèrè fún ẹ̀dà àpilẹ̀kọ náà. Justyna sọ pé: “Èrò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti bẹ̀rẹ̀ sí yàtọ̀ lórí ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ojú tí ò dáa ni wọ́n fi ń wo àwọn ìwé náà tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí, wọ́n fẹ́ràn wọn gan-an ni. Ọmọkùnrin kan tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ka Jí! déédéé.”

Bí Justyna ṣe kẹ́sẹ járí nígbà tó lo àpilẹ̀kọ kan tó rí nínú Jí! tí wọ́n ti tẹ̀ láti ohun tó lé lógún ọdún sẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ nìwọ náà ṣe lè rí “ẹ̀kún àpò ọgbọ́n” nínú àwọn ìwé ìròyìn tọ́jọ́ wọn ti pẹ́ yìí. (Jóòbù 28:18) Bó o bá lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ, o lè yẹ àwọn ìdìpọ̀ ìwé ìròyìn Jí! tó bá wà níbi tí wọ́n ń kówèé sí wò. Wàá rí i pé kíka àwọn àpilẹ̀kọ tó wúlò gidigidi, tí ọ̀rọ̀ inú wọn kì í ṣá náà, á gbádùn mọ́ ẹ. O sì tún lè rí ẹ̀dà ìwé ìròyìn Jí! tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde gbà lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Justyna rèé nígbà tó wà nílé ẹ̀kọ́