Ìbẹ̀rù Gbayé Kan
Ìbẹ̀rù Gbayé Kan
Ẹ̀RÙ ń ba Roxana a láti sọ fún ọkọ ẹ̀ pé òun fẹ́ máa wá nǹkan pawọ́ dà. Nígbà tó sì ní kó fóun lówó tóun á fi wọkọ̀ lọ sọ́dọ̀ ìyá òun, ó gbá Roxana lẹ́ṣẹ̀ẹ́ débi pé wọ́n ní láti gbé e lọ sí ọsibítù. Gbogbo ìgbà lẹ̀rù máa ń bà á.
Ìgbà kan wà tí Rolando máa ń jẹ́ kí aya rẹ̀ wọ ọkọ̀ èrò wálé lálẹ́, ṣùgbọ́n ó ti ń lọ fi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ gbé e wálé báyìí. Ìròyìn ìwà ipá tó ń gbọ́ ládùúgbò pọ̀ gan-an débi tí ẹ̀rù fi ń bà á kí nǹkan má lọ ṣẹlẹ̀ sí ìyàwó rẹ̀.
Àárín gbùngbùn olú ìlú orílẹ̀-èdè kan ni Haidé ti ń ṣiṣẹ́. Nígbà kan báyìí tó ń lọ sílé, ó já sáàárín ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó ń wọ́de, tí wọ́n sì ń fẹ̀hónú hàn. Látìgbà yẹn, bó bá ti ráwọn èèyàn tó ń rọ́ kọjá lọ báyìí, ara rẹ̀ ò ní balẹ̀ mọ́. Ó sọ pé: “Àyà mi kàn máa ń já ni. Mi ò fẹ́ ṣiṣẹ́ níbí yìí mọ́ o jàre. Iṣẹ́ ni ò sì ṣeé fi sílẹ̀ yìí.”
Ìbẹ̀rù ló ń da Roxana, Rolando àti Haidé láàmú, àmọ́, kì í ṣe ìgbà tí ọ̀ràn pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀ nìkan ló máa ń rí bẹ́ẹ̀ o. Gbogbo ìgbà lẹ̀rù máa ń bà wọ́n. Bó bá jẹ́ gbogbo ìgbà làwọn èèyàn ń rí ohun tó ń bá wọ́n lẹ́rù, ó lè yọ ayé lẹ́mìí wọn. Ìbẹ̀rù ò ní jẹ́ kí wọ́n láyọ̀ mọ́, nítorí pé kò ní jẹ́ kí wọ́n lè ṣe ohun tó bá wù wọ́n. Ìbẹ̀rù lè gba èèyàn lọ́kàn pátá, kò sì ní jẹ́ kéèyàn lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan míì.
Bíbẹ̀rù nígbà gbogbo máa ń kó èèyàn sí pákáǹleke. Ó sábà máa ń mú kéèyàn sorí kọ́, ó sì lè di àárẹ̀ séèyàn lára. Ìwé ìròyìn kan tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìlera ṣàlàyé pé: “Àníyàn kì í jẹ́ kára lágbára láti gbogun tàrùn, ó sì máa ń fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìsàn. Ara á bẹ̀rẹ̀ sí dogbó, pàápàá jù lọ ẹ̀yà ara tí àìsàn náà bá ń bá jà. Oríṣiríṣi àìsàn á bẹ̀rẹ̀ sí yọjú, irú bí ẹ̀jẹ̀ ríru, àrùn ọkàn, àrùn kíndìnrín, ìṣòro tó jẹ mọ́ ikùn àti ìfun, ọgbẹ́ inú, ẹ̀fọ́rí, àìróorunsùntó, ìdààmú ọkàn àti àníyàn. Bó bá ti pẹ́ tẹ́nì kan ti ń bá àwọn àìsàn yìí yí, agara á dá a.”
Láyé òde òní, ó wọ́pọ̀ kẹ́rù máa ba àwọn èèyàn nígbà gbogbo. Ǹjẹ́ ìgbà kan ń bọ̀ táwọn èèyàn á lè máa gbádùn ìgbésí ayé wọn láìsí ìbẹ̀rù?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.