Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Aráyé Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Ohun Tó Ń Fa Ìbẹ̀rù?

Ṣé Aráyé Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Ohun Tó Ń Fa Ìbẹ̀rù?

Ṣé Aráyé Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Ohun Tó Ń Fa Ìbẹ̀rù?

ǸJẸ́ ẹnikẹ́ni wà láyé eléwu yìí tó lè fi gbogbo ẹnu sọ pé kò sóhun tó ń ba òun lẹ́rù? Kò dájú. Àwọn èèyàn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run pàápàá ń dojú kọ ewu tó ń mú kí wọ́n bẹ̀rù. Bí àpẹẹrẹ, ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó rìnrìn-àjò débi tó pọ̀ sọ pé ọkọ̀ ojú omi tóun wọ̀ rì, ó tún sọ nípa ewu odò, ewu àwọn dánàdánà, àti ewu nínú ìlú. (2 Kọ́ríńtì 11:25-28) Bákan náà lọ̀ràn rí lónìí, ọ̀pọ̀ nínú wa lewu máa ń wu.

Àmọ́ ṣá o, a lè máa wá ọ̀nà láti dáàbò bo ara wa. Bá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ó máa dín ewu tó ń wu wá kù, a ó sì lè dín ẹ̀rù tó ń bà wá kù. Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.” (Òwe 22:3) Kí làwọn nǹkan díẹ̀ tó lè ràn wá lọ́wọ́ tá a lè ṣe?

Bá A Ó Ṣe Máa Ṣọ́ra Wa

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ ti pẹ́ tí wọ́n ti kọ Bíbélì, ọpẹ́ ni pé lọ́jọ́ tòní, ọ̀pọ̀ ìlànà tá a lè mú lò tá a ò fi ní kó séwu, ṣì wà nínú ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé: “Ní ti ọlọ́gbọ́n, ojú rẹ̀ wà ní orí rẹ̀; ṣùgbọ́n arìndìn ń rìn lọ nínú ògédé òkùnkùn.” (Oníwàásù 2:14) Ó bọ́gbọ́n mu kó o mọ̀ béèyàn bá wà ní sàkáání rẹ, bó bá sì ṣeé ṣe, má máa rìn ní àyíká ibi tó ṣókùnkùn. Bó bá ṣeé ṣe, o lè máa gba àdúgbò tí iná ti pọ̀ lójú pópó, bó bá tiẹ̀ máa mú kí ìrìn ẹ gùn sí i. Bíbélì tún sọ pé: “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan . . . Bí ẹnì kan bá sì lè borí ẹni tí ó dá wà, ẹni méjì tí ó wà pa pọ̀ lè mú ìdúró wọn láti dojú kọ ọ́.” (Oníwàásù 4:9, 12) Bó o bá ń gbé níbi tó léwu, o ò ṣe kúkú máa wá ẹni tẹ́ ẹ ó jọ máa rìn lọ sílé?

Bó o bá bọ́ sọ́wọ́ dánàdánà, ó máa dára kó o rántí pé ẹ̀mí ẹ ṣe pàtàkì púpọ̀ ju ohun ìní lọ. (Mátíù 16:26) Ó tún dáa kó o rántí pé báwọn èèyàn bá kóra jọ láti fẹ̀hónú hàn, wọn ò ṣeé kò lójú, wọ́n sì lè dán mẹ́wàá wò.—Ẹ́kísódù 23:2.

Bí ẹnì kan bá ń yọ ọ́ lẹ́nu nípa fífi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ ẹ́, tàbí nípa fífi ọ̀rọ̀ rírùn ṣẹ̀fẹ̀, tàbí nípa gbígbìyànjú láti fọwọ́ kàn ọ́ níbi tí kò yẹ, òun tó dára jù ni pé kó o kọ̀ fún un jálẹ̀. O tiẹ̀ lè fibẹ̀ sílẹ̀ bí Jósẹ́fù ṣe ṣe nígbà tí obìnrin oníwà pálapàla kan di ẹ̀wù rẹ̀ mú. Ó “fẹsẹ̀ fẹ, ó sì bọ́ síta.” (Jẹ́nẹ́sísì 39:12) Bí kò bá ṣeé ṣe láti fẹsẹ̀ fẹ, o lè sọ pé: “Mi ò gbarú ẹ̀ rárá!” tàbí “Má fọwọ́ ẹ kàn mí mọ́ láé!” tàbí “Mi ò fẹ́ kéèyàn máa sọ irú ọ̀rọ̀ rírùn yẹn sí mi.” Bó bá ṣeé ṣe, má máa lọ síbi táwọn èèyàn ti lè máa yọ ẹ́ lẹ́nu.

Ohun Tó O Lè Ṣe Nípa Ìbẹ̀rù Nínú Ilé

Kí lo lè ṣe bí ẹ̀rù ọkọ rẹ tó ń fìyà jẹ ọ́ bá ń bà ọ́? Ì bá dáa bó o bá ní ibi tí wàá sá gbà lọ́kàn bí ọkọ rẹ bá ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí hùwà tó lè pa ìwọ tàbí àwọn ọmọ rẹ lára, tàbí tó tiẹ̀ lè gbẹ̀mí yín. a Bíbélì sọ bí Jékọ́bù ṣe fara balẹ̀ ronú nípa ohun tó máa ṣe bó bá ṣẹlẹ̀ pé Ísọ̀ fẹ́ ta á ní jàǹbá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ò wá rí bó ṣe rò, ọgbọ́n wà nínú bó ṣe lo ìṣọ́ra. (Jẹ́nẹ́sísì 32:6-8) Lára ọ̀nà tó o lè gbà dọ́gbọ́n ara ẹ ni pé kó o wá ẹnì kan tó lè gbà ọ́ sílé bí ọ̀ràn pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀. O ti lè ṣàlàyé àwọn ọ̀nà tí onítọ̀hún lè gbà ràn ọ́ lọ́wọ́ fún un kó tó di pé o sá tọ̀ ọ́ lọ. Á sì tún dáa káwọn ìwé ẹ̀rí àtàwọn nǹkan pàtàkì míì wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ.

Lára ohun tó o tún lè ṣe ni pé kó o jẹ́ káwọn agbófinró mọ̀ nípa lílù tí ọkọ rẹ máa ń lù ọ́, kó o sì máa wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ wọn. b Bíbélì kọ́ni pé olúkúlùkù ló máa dáhùn fún gbogbo ìwà tó bá hù. (Gálátíà 6:7) Bíbélì sọ nípa àwọn agbófinró pé: “Òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni ó jẹ́ sí ọ fún ire rẹ. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń ṣe ohun tí ó burú, kí o máa bẹ̀rù.” (Róòmù 13:4) Ìwà ọ̀daràn ni gbígbéjàkoni lójú pópó, ìwà ọ̀daràn náà sì ni nínú ilé. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè, ìwà ọ̀daràn tún ni kéèyàn máa dọdẹ ẹlòmíì.

Bó o bá ń ṣe àwọn ohun tá a sọ yìí, ó lè dín ìbẹ̀rù kù débì kan. Ṣùgbọ́n ohun tí Bíbélì ń ṣe ò mọ sórí fífúnni ní ìmọ̀ràn tó wúlò o. Kì í ṣe ìwé abánigbọ́ṣòro kan lásán. Ìwé táwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú rẹ̀ kì í kùnà, tó ń jẹ́ ká mọ ohun tí Ọlọ́run ń ṣe báyìí àti ohun tó ń bọ̀ wá ṣe lọ́jọ́ iwájú ló jẹ́. Ìròyìn ayọ̀ wo ló wà nínú Bíbélì fáwọn tí ìbẹ̀rù ò tíì kúrò lọ́rọ̀ wọn?

Ohun Tó Fà Á Tí Ìbẹ̀rù Fi Gbòde Kan

Ní pàtàkì jù lọ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, . . . aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere.” (2 Tímótì 3:1-3) Ọ̀rọ̀ kàbìtì mà nìyẹn jẹ́ nípa bí àkókò wa ṣe máa kún fún ìbẹ̀rù tó o!

Nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa “ìparí ètò àwọn nǹkan,” ó ní: “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba; ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà yóò sì wà, àti àwọn àjàkálẹ̀ àrùn àti àìtó oúnjẹ láti ibì kan dé ibòmíràn; àwọn ìran bíbanilẹ́rù yóò sì wà àti àwọn àmì ńláǹlà láti ọ̀run.” (Mátíù 24:3, 7, 8; Lúùkù 21:10, 11) Nítorí náà, “àwọn ìran bíbanilẹ́rù” tá a ti rí, tí wọ́n sì wà lára àwọn nǹkan tó jẹ́ kí ìbẹ̀rù gbayé kan, kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ìyàlẹ́nu fún wa. Àmọ́, kí ló fà á tí wọ́n fi ń ṣẹlẹ̀ gan-an?

Jésù sọ pé: “Nígbà tí ẹ bá rí nǹkan wọ̀nyí tí ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìjọba Ọlọ́run sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:31) Lákòókò tá à ń gbé yìí, a lè retí pé kí ìjọba kan láti ọwọ́ Ọlọ́run máa ṣàkóso aráyé látọ̀run wá. (Dáníẹ́lì 2:44) Báwo ni ayé á ṣe rí nígbà yẹn?

Kò Sí Ìbẹ̀rù Mọ́!

Bíbélì ṣàlàyé nípa ọjọ́ iwájú tí àlàáfíà yóò wà, tí kò ní sí ogun mọ́, tí àwọn aṣebi ò ní sí mọ́, tí ayé á sì kún fáwọn èèyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Pétérù, àpọ́sítélì Jésù, kọ̀wé nípa “ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run,” tó ń bọ̀ lọ́nà. Kò ní sí olubi kankan téèyàn á máa bẹ̀rù mọ́ nítorí pé ‘òdodo yóò máa gbé’ lórí ilẹ̀ ayé. (2 Pétérù 3:7, 9, 13) Wo bó ṣe máa tuni lára tó béèyàn bá ń gbé láàárín àwọn tó ṣeé fọkàn tán, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú! Àwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ yìí á ràn wá lọ́wọ́ láti máa fojú tó yàtọ̀ wo ewu tó wà lákòókò wa yìí. Ewu yẹn ò ní máa bá a lọ bẹ́ẹ̀ títí ayé.—Sáàmù 37:9-11.

Nítorí tàwọn tó ń ṣàníyàn, Jèhófà sọ fún wòlíì rẹ̀ pé: “Sọ fún àwọn tí ń ṣàníyàn nínú ọkàn-àyà pé: ‘Ẹ jẹ́ alágbára. Ẹ má fòyà. Ẹ wò ó! Ọlọ́run yín yóò wá tòun ti ẹ̀san, Ọlọ́run yóò wá, àní tòun ti ìsanpadà. Òun fúnra rẹ̀ yóò wá, yóò sì gbà yín là.’” (Aísáyà 35:4) Nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run òtítọ́ lè máa fi ìdánilójú wọ̀nà fún ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. (Fílípì 4:6, 7) Ìtùnú gbáà ló jẹ́ fáwọn tẹ́rù ń bà láti mọ̀ pé Jèhófà ò tíì pa ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe fún aráyé ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ tì, ó ṣì fẹ́ kí ilẹ̀ ayé kún fún àwọn èèyàn tí wọ́n mọ̀ ọ́n tí wọ́n sì ń fi àwọn ànímọ́ onífẹ̀ẹ́ bíi tiẹ̀ hàn.—Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28; Aísáyà 11:9.

A mọ̀ pé kó sóhun tó lè dí Jèhófà lọ́wọ́ láti fìfẹ́ ṣe ohun tó wù ú fún aráyé. (Aísáyà 55:10, 11; Róòmù 8:35-39) Bá a bá mọ̀ bẹ́ẹ̀, ohun tó wà nínú Sáàmù kan, tá a mọ̀ bí-ẹní-mowó nínú Bíbélì á nítumọ̀ gidi sí wa. A kà níbẹ̀ pé: “Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. . . . Ó ń tu ọkàn mi lára. Ó ń ṣamọ̀nà mi ní àwọn òpó ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀. Bí mo tilẹ̀ ń rìn ní àfonífojì ibú òjìji, èmi kò bẹ̀rù ohun búburú kankan, nítorí tí ìwọ wà pẹ̀lú mi.” (Sáàmù 23:1-4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ń mú kẹ́rù bani nínú ayé lè pọ̀ sí i, ó dájú hán-ún hán-ún pé ayé kan tẹ́rù ò ti ní bani mọ́ ti sún mọ́lé.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bó o bá fẹ́ mọ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ lórí àwọn tó lè mú kí tọkọtaya pínyà, wo Jí! February 8, 2002, ojú ìwé 10.

b Bó o bá fẹ́ kà nípa àwọn tí wọ́n ń lù ní àlùbami nínú ilé, wo Jí! November 8, 2001, ojú ìwé 3 sí 12, àti Jí! February 8, 1993, ojú ìwé 3 sí 14.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ọlọ́run máa tó mú ayé tẹ́rù ò ti ní bani mọ́ wá