Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwọn Èèyàn Ṣe Ń Dá Kún Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀

Báwọn Èèyàn Ṣe Ń Dá Kún Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀

Báwọn Èèyàn Ṣe Ń Dá Kún Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀

TÉÈYÀN bá ń tọ́jú mọ́tò bó ṣe yẹ, á máa rí i lò láìséwu. Ṣùgbọ́n mọ́tò náà á di elẹ́kẹ̀ẹ́ẹ̀dẹ téèyàn bá ń lò ó nílòkulò tí kò sì tọ́jú rẹ̀. Ọ̀rọ̀ ilé ayé wa yìí rí bẹ́ẹ̀ lọ́nà kan.

Èrò àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan ni pé báwọn èèyàn ṣe ń tọwọ́ bọ ohun tí Ẹlẹ́dàá dá sínú afẹ́fẹ́ àtèyí tó dá sínú òkun lójú ti sọ ilé ayé wa di eléwu nítorí pé ó ń pa kún bí àjálù tó burú gan-an ṣe túbọ̀ ń ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́. Ohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú ò sì yé èèyàn. Nínú èrò olóòtú ìwé ìròyìn Science lórí ọ̀rọ̀ nípa bí ojú ọjọ́ ṣe rí, ó sọ pé: “A ò tíì mọ ibi tá a máa bá ọ̀rọ̀ já látàrí ọ̀nà tá à ń gbà lo ilé ayé wa yìí, bẹ́ẹ̀ sì rèé, a ò ní ilé míì ju ayé yìí lọ.”

Ó yẹ ká mọ báwọn ohun ìpìlẹ̀ tó so ilé ayé ró ṣe ń yí padà, ká bàa lè mọ bí ìgbòkègbodò àwọn èèyàn ṣe ń pa kún bí àjálù ṣe ń ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́ tó àti bó ṣe ń ṣọṣẹ́ tó. Bí àpẹẹrẹ, kí ló ń fa ìjì líle?

Àwọn Nǹkan Tó Ń Pín Ooru Káàkiri Ayé

Àwọn tó ń kíyè sí bójú ọjọ́ àtàwọn nǹkan tó so ilé ayé ró ṣe ń yí padà sọ pé ṣe ló dà bíi pé ẹ̀rọ kan wà tó ń yí ooru àti ìmọ́lẹ̀ tó ń wá láti inú oòrùn padà tó sì ń pín in káàkiri. Nítorí pé ooru máa ń mú jù ní ìhà àríwá ayé, èyí máa ń jẹ́ kí apá ibì kan móoru ju apá ibòmíì lọ ó sì máa ń mú kí afẹ́fẹ́ máa káàkiri. a Bí ayé ṣe ń yí lójoojúmọ́ ló ń gbé ògìdìgbó afẹ́fẹ́ tútù rinrin kiri, afẹ́fẹ́ yìí á wá di ohun tó ń rọ́ yìì bó ṣe ń kóra jọ. Afẹ́fẹ́ tó ti kóra jọ tó ń fẹ́ náà láá wá di ìjì líle.

Tó o bá kíyè sí bí ìjì ṣe máa ń jà láwọn ilẹ̀ olóoru, wàá rí i pé ó sábà máa ń wá láti apá àárín gbùngbùn ayé lọ sí àríwá tàbí gúúsù, ìyẹn àwọn ibi tó tutù. Ìdí tá a fi lè sọ pé ìjì líle ń pín ooru káàkiri nìyẹn, ó sì ń bá wa so ojú ọjọ́ ró bó ṣe yẹ kó wà. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bó ti jẹ́ pé láwọn ilẹ̀ olóoru, ooru tó bá kóra jọ sórí agbami òkun látàrí oòrùn tó ń ràn sórí ẹ̀ máa ń kọjá lọ sínú afẹ́fẹ́, tóoru náà bá ti mú jù, ìjì líle á jà, á sì fẹ́ afẹ́fẹ́ gbígbóná janjan.

Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa iye ẹ̀mí tó ti ṣòfò, a ó rí i pé ìjábá líle tó burú jù tó tíì jà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni èyí tó ṣẹlẹ̀ ní ìlú Galveston, tó jẹ́ erúkùṣù kan ní ìpínlẹ̀ Texas ní September 8, ọdún 1900. Ìgbì òkun rọ́ wọnú ìlú náà, ó sì pa tó ẹgbẹ̀rún mẹ́fà sí ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ èèyàn. Ó tún pa tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin èèyàn míì láwọn ìlú tó múlé gbe erékùṣù yìí, ó sì ba ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ilé jẹ́. Kódà, kò ṣẹ́ ku ilé kan ṣoṣo tọ́wọ́jà ìjì yìí ò bà.

Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, àwọn ìjì lílágbára jà púpọ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ń ṣèwádìí lórí bóyá mímóoru táyé ń móoru wà lára àwọn nǹkan tó ń fà á, torí ó lè jẹ́ pé báyé ṣe ń móoru ló túbọ̀ ń fún ìjì lágbára. Àmọ́, ọ̀kan péré ni ìyípadà ojú ọjọ́ á jẹ́ lára àwọn nǹkan tí mímóoru táyé ń móoru ń fà. Ó tún lè máa fa ohun mìíràn táá máa ṣèpalára tó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Bí Omi Òkun Ṣe Ń Kún Sí I àti Pípagbórun

Gẹ́gẹ́ bí èrò olóòtú nínú ìwé ìròyìn Science, “omi inú àwọn òkun ti fi bíi sẹ̀ǹtímítà mẹ́wàá sí ogún [èyí lè mu èèyàn dé kókósẹ̀ tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ sókè] kún sí i láti ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn. A sì ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni.” Àmọ́ báwo ni mímóoru táyé ń móoru ṣe lè fa èyí? Àwọn olùṣèwádìí sọ pé ọ̀nà méjì ló lè gbà rí bẹ́ẹ̀. Ọ̀kan ni pé báwọn yìnyín tó máa ń dì sáwọn ìkangun ayé àtèyí tó dì sórí àwọn òkè tó tò bẹẹrẹbẹ bá ṣe ń yọ́, inú àwọn òkun ni wọ́n á máa ṣàn lọ tómi inú wọn á sì máa pọ̀ sí i. Òmíràn ni pé bí omi òkun bá ṣe ń gbóná sí i láá máa pọ̀ sí i.

Bóyá ni kì í ṣe pé kíkún tí omi òkun ń kún sí i ló ń da erékùṣù kékeré kan tó ń jẹ́ Tuvalu tó wà lágbègbè Pàsífíìkì láàmú. Ìwé ìròyìn Smithsonian sọ pé àwọn ìsọfúnni kan tí wọ́n kó jọ ní erékùṣù Funafuti fi hàn pé omi òkun ń pọ̀ sí i ‘níwọ̀n tó tó ìlàjì mìlímítà, ìyẹn bíi gígùn àtàǹpàkò, lọ́dọọdún láàárín ọdún mẹ́wàá tó kọjá.’

Ní ọ̀pọ̀ ibi káàkiri àgbáyé, báwọn èèyàn ṣe ń pọ̀ sí i láwọn ìlú ńláńlá, ńṣe ni wọ́n ń ya lọ sáwọn ilé tí wọ́n figi kọ́ sítòsí irú àwọn ìlú bẹ́ẹ̀, èyí sì túbọ̀ ń fa ìbàyíkájẹ́. Ó ṣeé ṣe kéyìí pa kún báwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ á ṣe máa burú tó. Wo àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀.

Erékùṣù kan térò pọ̀ sí ni orílẹ̀-èdè Haiti, wọ́n sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gé gbogbo igi tó wà níbẹ̀ tán. Ìròyìn kan sọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí nǹkan ṣe ń lọ sí nínú ètò ọrọ̀ ajé, ètò ìṣèlú àti ní àwùjọ lórílẹ̀-èdè Haiti, kò bójú mu, kò sì ohun tó ń wu orílẹ̀-èdè náà léwu tó pípagbórun. Ọdún 2004 ni ewu náà fojú léde dáadáa nígbà tí àgbáàràgbá òjò wọ́ ọ̀gbàrá ẹrọ̀fọ̀ wọbẹ̀, tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn sì bá a rìn.

Ìwé ìròyìn Time ti Éṣíà sọ pé “gbígbóná táyé ń gbóná, ìsédò, ìpagbórun àti báwọn àgbẹ̀ ṣe ń dáná sungbó” wà lára ohun tó ń mú kí àjálù tó ń wáyé lápá Gúúsù Éṣíà túbọ̀ lágbára. Ibi tí ìpagbórun tún wá burú sí jù ni pé ó lè fa ọ̀dá nítorí pé ó máa ń mú kí ilẹ̀ yára gbẹ táútáú. Láti bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn báyìí, ọ̀dá tó dá láwọn orílẹ̀-èdè Indonesia àti Brazil ló fà á tíná fi ń ṣẹ́ yọ nínú igbó tí wọ́n máa ń sọ tẹ́lẹ̀ pé ó tutù kọjá kó lè jó. Àmọ́ ṣá o, ojú ọjọ́ tó ń gbóná janjan nìkan kọ́ ló ń fa àjálù o. Àwọn ohun tó ń fa àjálù láwọn orílẹ̀-èdè kan jẹ́ àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ilẹ̀.

Ohun Tó Máa Ń Ṣẹlẹ̀ tí Ilẹ̀ Fi Máa Ń Mì Tìtì

Ìpele ìpele ni abẹ́ ilẹ tá a dúró lé yìí pín sí, ìpele kọ̀ọ̀kan sì nípọn ju ara wọn lọ. Àìmọye ìgbà làwọn ìpele abẹ́ ilẹ̀ yìí máa ń túnra wọn tò, tí ìyẹn sì lè fa ọ̀kẹ́ àìmọye ìsẹ̀lẹ̀ lọ́dọọdún. Àmọ́ ṣá, àìmọye àtúntò yìí ló ń ṣẹlẹ̀ tá ò sì ní mọ̀.

Wọ́n sọ pé nínú ìsẹ̀lẹ̀ mẹ́wàá, ìdá mẹ́sàn-án ló ń wáyé níbi tí àpáta abẹ́ ilẹ̀ bá ti sán. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lẹ́ẹ̀kanlọ́gbọ̀n ni, àwọn ìsẹ̀lẹ̀ tó ń ṣọṣẹ́ lílágbára lè wáyé lápá ibi tí ilẹ̀ ò ti sán. Bí ìṣirò ṣe fi hàn, ìsẹ̀lẹ̀ tó tíì ṣọṣẹ́ jù lọ tó wà lákọọ́lẹ̀ lèyí tó wáyé ní ẹkùn ilẹ̀ mẹ́ta lórílẹ̀-èdè Ṣáínà, lọ́dún 1556. Àfàìmọ̀ ni kò ní pa tó ọ̀kẹ́ méjìlélógójì ó dín ẹgbàárùn-ún [830,000] èèyàn!

Àtúbọ̀tán ìsẹ̀lẹ̀ kì í rọgbọ. Bí àpẹẹrẹ, ní November 1, ọdún 1755, ìsẹ̀lẹ̀ kan wáyé ní ìlú Lisbon, lórílẹ̀-èdè Potogí, ìyẹn ìlú táwọn tó ń gbébẹ̀ pọ̀ tó ọ̀kẹ́ mẹ́tàlá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [275,000]. Ṣùgbọ́n ibẹ̀ kọ́ ni jìnnìjìnnì tọ́rọ̀ náà dá sílẹ̀ mọ sí o. Ìsẹ̀lẹ̀ yìí fa iná àti ìrugùdù láti abẹ́ omi débi tí omi fi ru sókè tó mítà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ìyẹn àádọ́ta ẹsẹ̀ bàtà, tó sì ya wọbẹ̀ wá láti Òkun Àtìláńtíìkì tó wà nítòsí ibẹ̀. Lápapọ̀ ṣá, àwọn tó kú sí ìsẹ̀lẹ̀ náà ní ìlú yẹn ju ọ̀kẹ́ mẹta [60,000] lọ.

Bíi tàwọn ìsẹ̀lẹ̀ tó kù, bí ìsẹ̀lẹ̀ yìí ṣe lágbára tó sinmi lórí ìgbòkègbodò àwọn ọmọ èèyàn. Ara nǹkan tó lè fún irú ìsẹ̀lẹ̀ yẹn lágbára láti ṣe ọṣẹ́ tó tóyẹn ni iye èrò tó ń gbé láwọn ibi tó ṣeé ṣe kí ilẹ̀ ti sẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni Andrew Robinson tó jẹ́ òǹkọ̀wé, sọ pé: “Ní báyìí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlàjì àwọn ìlú ńláńlá tí wọ́n wà níbi tó ti ṣeé ṣe kí ilẹ̀ ti sẹ̀.” Yàtọ̀ sí ti èrò tó pọ̀, irú ilé táwọn èèyàn ń kọ́ gan-an ń pa kún ohun tó ń ṣẹlẹ̀, pàápàá bí wọ́n ṣe ń fi àwọn ohun èlò tí kò lágbára kọ́lé àti bí wọ́n ṣe ń kọ́lé tí kò dúró dáadáa. Òótọ́ pọ́ńbélé ni òwe kan tí wọ́n máa ń pa pé: “Ìsẹ̀lẹ̀ kì í pààyàn, ilé tó wó ló ń pani.” Àmọ́ kí làwọn tí wọn ò lówó lọ́wọ́ láti kọ́ irú ilé tí ò ní wó lákòókò ìsẹ̀lẹ̀ lè ṣe?

Ohun Tó Ń Bú Jáde Látinú Ilẹ̀ Máa Ń Ṣàǹfààní Ó sì Tún Ń Fa Ìparun

Àjọ Smithsonian Institute, tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Bó o ṣe ń ka ọ̀rọ̀ yìí lọ́wọ́, bíi ká máà rí ibi tó tó ogún tí ilẹ̀ á ti máa bú jáde kọ́.” A lè rí i gbá mú nínú ọ̀rọ̀ àwọn tó mọ̀ nípa bí ilẹ̀ ṣe tò ní ìpele ìpele pé ìsẹ̀lẹ̀ àti ìbújáde látinú ilẹ̀ sábà máa ń wáyé láwọn apá ibì kan náà. Àwọn ibi tó ti lè wáyé ni ibi tí ilẹ̀ bá ti là pẹ̀rẹ́ táwọn àpáta tó wà níbẹ̀ sì ru wá sókè àti ibi tí ìpele ilẹ̀ kan bá ti ri lábẹ́ òmíràn.

Ìsẹ̀lẹ̀ tó bá wáyé níbi tí ilẹ̀ bá ti ri báyìí ló léwu jù fáwọn èèyàn nítorí pé ó sábà máa ń pọ̀ gan-an ó sì máa ń ṣẹlẹ̀ nítòsí ibi térò bá pọ̀ sí. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún irú ìbújáde bẹ́ẹ̀ ló ti wáyé láwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Pacific Rim tí wọ́n ń pè ní Òrùka Iná. Ìwọ̀nba irú èyí tún ṣẹlẹ̀ láwọn ibi tó léwu, tí ilẹ̀ ti ní ìpele tó ń ri lábẹ́ ara wọn. Ó dà bíi pé irú ríri ilẹ̀ lọ́nà yìí ló jẹ́ káwọn àgbájọ Erúkùṣù Hawaii, ti Azores, ti Galápagos, tó fi mọ́ ti Erékùṣù Society yọrí jáde.

Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kékeré kọ́ ni ipa tí ilẹ̀ tó ń bú jáde yìí ń kó látọdúnmọdún lórí bí oríṣiríṣi nǹkan mèremère ṣe wà láyé. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n kọ sí ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì Yunifásítì kan ṣe sọ, “ó tó ìdá mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá àwọn àlà ilẹ̀ àti ipadò tó jẹ́ pé ìbújáde ilẹ̀ ló mú kí wọ́n wà.” Ṣùgbọ́n kí ló máa ń mú káwọn ìbújáde ilẹ̀ míì burú gan-an?

Ìbújáde ilẹ̀ máa ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ooru gbígbóná tó wà nínú ilẹ̀ bá ń mú káwọn àpáta abẹ́ ilẹ̀ máa gbóná. Nígbà míì tí ilẹ̀ bá bú, ńṣe ni àpáta tó yọ́ á rọ́ra máa ru jáde, kì í sábàá dà gọ̀ọ̀rọ̀gọ̀ débi táá fi bá àwọn èèyàn lójijì. Ṣùgbọ́n ńṣe làwọn míì máa bú jáde pẹ̀lú agbára tó ju ti àgbá runlérùnnà lọ! Ohun tó máa ń fà á tó fi ń rú jáde díẹ̀díẹ̀ tàbí tó fi ń bú gbàù ni báwọn àpáta tó yọ́ yìí ṣe ki tó àti bí gáàsì àtomi gbígbóná janjan tó wà nínú ohun tó yọ́ yìí ṣe pọ̀ tó. Bí àpáta yíyọ́ yìí bá ṣe ń jáde kúrò nínú ilẹ̀ báyìí, omi àti gáàsì tó ti dà pọ̀ mọ́ ọn á máa ru gùdù. Bí èyí tó dà mọ́ omi àti gáàsì lára àpáta tó yọ náà bá pọ̀ tó, ńṣe ni ìbúgbàù rẹ̀ á dà bí ìgbà tí ẹmu tó ń ru pàṣà bá bú jáde láti inú ibi tí wọ́n dé e mọ́.

Ó tiẹ̀ dáa tó jẹ́ pé àwọn òkè ayọ́náyèéfín sábà máa ń fáwọn èèyàn lámì kí wọ́n tó bú jáde. Irú bẹ́ẹ̀ ni ti Òkè Pelée, tó wà ní erékùṣù Martinique ní àgbègbè Caribbean tó bú jáde lọ́dún 1902. Ìbò ń bọ̀ lọ́nà lásìkò yẹn ní ìlú St. Pierre tí kò jìnnà sí erékùṣù náà, àwọn olóṣèlú sì rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n má ṣe sá lọ. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn èèyàn ti rí eérú tó ń wọ́ dà sílẹ̀ látòkè yẹn, jìnnìjìnnì ti bò wọ́n, gbogbo àwọn tó wà nínú ìlú náà ló sì ti ń bẹ̀rù. Kódà, ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀bù ni wọ́n ti tì pa fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́!

Nígbà tó di May 8 lọ́dún yẹn, lọ́jọ́ tí wọ́n ń ṣayẹyẹ ọjọ́ tí Jésù gòkè re ọ̀run, ọ̀pọ̀ èèyàn lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì láti lọ gbàdúrà nítorí òkè tí wọ́n ń bẹ̀rù pé ó lè bú jáde yìí. Láàárọ̀ ọjọ́ yẹn gan-an, nígbà tó kù díẹ̀ kí aago mẹ́jọ lù, Òkè Pelée bú jáde, àwọn nǹkan tó rọ́ jáde sì ni àwọn nǹkan bí eérú gbígbóná, oríṣiríṣi afẹ́fẹ́ olóró àti gáàsì tó fẹ́rẹ̀ẹ́ gbóná tó ìlọ́po márùn-ún omi híhó. Bí afẹ́fẹ́ yẹn ṣe ń balẹ̀ láti orí òkè náà báyìí, ó pa tó ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ [30,000] èèyàn fin-ín fin-ín, ó yọ́ aago ṣọ́ọ̀ṣì, ó sì jó àwọn ọkọ ojú omi ńláńlá tó wà létí omi. Òun ni ìbújáde òkè ayọnáyèéfín tó pààyàn jù lọ láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún tó kọjá. Àmọ́, ká láwọn wọ̀nyẹn ti gba ìkìlọ̀ ni, ì bá tí pààyàn tó bẹ́ẹ̀.

Ṣé Àjálù Á Máa Pọ̀ Sí I Ni?

Àgbáríjọ àwọn ẹgbẹ́ aláàánú lágbàáyé, International Federation of Red Cross and Red Crescent Societies, sọ nínú ìròyìn wọn World Disasters Report 2004 pé láti ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, àjálù tí àwọn ìyípadà tó ń wáyé lábẹ́ ilẹ̀ àti ipò ojú ọjọ́ ń fà ti fi ìdámẹ́ta nínú márùn-ún iye tó jẹ́ tẹ́lẹ̀ pọ̀ sí i. Wọ́n ti gbé ìròyìn náà jáde ṣáájú ìbújáde ilẹ̀ látinú omi, èyí tó wáyé ní December 26, lágbègbè Òkun Íńdíà, wọ́n sì sọ nínú rẹ̀, pé “èyí fi hàn pé ìṣòro ọlọ́jọ́ gbọọrọ ni ìṣòro yìí.” Kò sí iyè méjì níbẹ̀ pé báwọn èèyàn bá ń ṣe báyìí wọ́ lọ sí ibi tó léwu láti máa gbé tí wọ́n ò sì ṣíwọ́ láti máa pa igbó run, kò sígbà tí irú àjálù báyìí ò ní máa wáyé o.

Yàtọ̀ síyẹn, ńṣe làwọn orílẹ̀-èdè tí ilé iṣẹ́ pọ̀ sí ń bá a nìṣó láti máa tú àwọn gáàsì olóró tó ń mú káyé gbóná dà sínú afẹ́fẹ́. Ìdí rèé tí olóòtú ìwé ìròyìn Science fi sọ nígbà kan rí pé tá a bá ń fònídónìí fọ̀ladọ́la lórí bá a ṣe máa dín títú gáàsì olóró sáfẹ́fẹ́ kù, “ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn bá kọ̀ láti lo oògùn sí àrùn kan tó ń ràn nínú ara rẹ̀: Ó dájú pé nígbà tó bá ní kóun bẹ̀rẹ̀ sí tọ́jú àrùn náà lọ́jọ́ iwájú, ohun tó máa ná an á kọjá sísọ.” Nígbà tí ìròyìn kan láti orílẹ̀-èdè Kánádà ń sọ̀rọ̀ nípa dídín àjálù kù, ó sọ pé: “Ìyípadà ojú ọjọ́ ló lágbára jù lọ lára àwọn ìṣòro àyíká táwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé ò tíì lè para pọ̀ yanjú rẹ̀.”

Àní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé ò tíì lè fẹnu kò lórí bóyá ìgbòkègbodò àwọn ẹ̀dá ń pa kún mímóoru táyé ń móoru, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé wọ́n á mọ bí wọ́n ṣe máa bójú tó ìṣòro náà. Èyí á ránni létí òótọ́ kan tó wà nínú Bíbélì, pé: “Kì í ṣe ti ènìyàn . . . àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Síbẹ̀, bá ó ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tó kàn lẹ́yìn èyí, ìrètí ò tíì pin lórí ọ̀ràn yìí o. Kódà, àwọn làlúrí tó ń dààmú ọmọ aráyé lákòókò wa yìí, tó fi mọ́ àwọn ìjì tó ń jà láwùjọ ẹ̀dá, wulẹ̀ ń fi kún ẹ̀rí pé ìtura ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé ni.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bí ooru tó tinú oòrun wá ṣe máa ń mú níbì kan ju ibòmíì lọ yìí ló máa ń mú kí ìgbì okun kóra jọ táá sì máa mú kí ooru fẹ́ lọ sáwọn ibi tó tutù láyé.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Ẹ WÁ WO ÒKÈ TÓ HÙ LÓKO ÀGBÀDO!

LỌ́DÚN 1943, àgbẹ̀ alágbàdo kan ní ìlú Mẹ́síkò rí ohun kan tó yàtọ̀ sí àgbàdo tó ń hù lóko ẹ̀. Nígbà tó wà lóko, ó rí ibi tí ilẹ̀ ti sán. Lọ́jọ́ kejì, ó rí i ti ojú ibẹ̀ ti hù jáde bí ebè, ó ti di òkè kékeré ayọnáyèéfín. Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, òkè náà ti ga tó àádọ́jọ mítà, ìyẹn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ẹsẹ̀ bàtà, lọ́dún kan lẹ́yìn náà, ó ti di òkè gàgàrà tó ga tó ọ̀tàlélọ́ọ̀ọ́dúrún [360] mítà, ìyẹn ẹgbẹ̀rún kan àti igba ẹsẹ̀ bàtà. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó ga tó irínwó ó lé ọgbọ̀n mítà, ìyẹn egbèje ẹsẹ̀ bàtà, ó sì ga tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó dín igba àti mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n mítà, ìyẹn ẹsẹ̀ bàtà ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án àti ọgọ́rùn-ún, láti ibi ìtẹ́jú òkun. Nígbà tó di ọdún 1952, òkè yìí ò ga mọ́, kò sì tíì bú jáde látìgbà náà. Òkè yìí ni wọ́n ń pè ní Paricutín.

[Credit Line]

Ilé Iṣẹ́ Tó Ń Yẹ Ilẹ̀ Wò ní Amẹ́ríkà/Fọ́tò tí R. E. Wilcox yà

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

ỌLỌ́RUN GBA ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ LỌ́WỌ́ ÀJÁLÙ

Ọ̀KAN lára àwọn àjálù ni ìyàn jẹ́. Ọ̀kan lára ìyàn tó kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ láyé tó wà lákọọ́lẹ̀ ni èyí tó ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Íjíbítì àtijọ́, láyé Jósẹ́fù ọmọ Jékọ́bù, ẹni tó tún ń jẹ́ Ísírẹ́lì. Ọdún méje gbáko ni ìyàn ọ̀hún fi mú, àwọn orílẹ̀-èdè tó sì fara gbá a ni Íjíbítì, Kénáánì àtàwọn ilẹ̀ míì. Ṣùgbọ́n nítorí pé Jèhófà ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìyàn náà lọ́dún méje ṣáájú ìgbà tó mú, ìyàn náà kò pa wọ́n run. Ó tún ti fi hàn wọ́n pé ọdún méje tó máa ṣáájú ọdún méje ìyàn náà máa jẹ́ ọdún tí ọ̀pọ̀kúyọ̀kú oúnjẹ máa wà ní Íjíbítì. Jósẹ́fù, tó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, ni wọ́n yàn ṣe igbá kejì ọba àti alábòójútó ètò oúnjẹ ní Íjíbítì, torí náà, ó ti ṣètò bí wọ́n á ṣe máa tọ́jú oúnjẹ pa mọ́ débi pé “wọ́n jáwọ́ nínú kíkà á.” Bó ṣe di pé orílẹ̀-èdè Íjíbítì ń rí oúnjẹ jẹ lásìkò ìyàn náà nìyẹn, kódà wọ́n tún pèsè oúnjẹ fún “àwọn ènìyàn gbogbo ilẹ̀” ayé, tó fi mọ́ ìdílé Jósẹ́fù.—Jẹ́nẹ́sísì 41:49, 57; 47:11, 12.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

HAITI 2004 Àwọn ọmọkùnrin tó ń pọnmi mímu, lójú pópó tó kún fún ọ̀gbàrá. Gígé tí wọ́n ń gégi nígèékúgèé wà lára ohun tó jẹ́ kí ẹrọ̀fọ̀ rọ́ wọ̀lú

[Àwọn Credit Line]

Àwòrán apá ẹ̀yìn: Sophia Pris/EPA/Sipa Press ló yà á; tinú àkámọ́: Carl Juste/Miami Herald/Sipa Press ló yà á

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè kàn ń tú gáàsì olóró dà sáfẹ́fẹ́ nìṣó ni

[Credit Line]

© Fọ́tò tí Mark Henley/Panos yà