Béèyàn Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run
Béèyàn Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run
◼ Ohun tí ìwé pẹlẹbẹ olójú-ewé 32 náà, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! fi kọ́ wa nìyẹn. Lára àwọn ẹ̀kọ́ fífanimọ́ra tó wà nínú ẹ̀ ni, “Ọlọ́run Ń Pè Ọ́ Pé Kí O Wá Di Ọ̀rẹ́ Òun” àti “Ọlọ́run Lọ̀rẹ́ Tó Dára Jù Lọ Tóo Lè Ní.” A ṣe ìwé pẹlẹbẹ náà kí ẹni tó bá kà á lè mọ àwọn àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì.
Lábẹ́ àkòrí náà, “Àwọn Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Yóò Gbé Inú Párádísè,” ìwé pẹlẹbẹ náà ṣàlàyé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún ilẹ̀ ayé lọ́nà tó ṣe kedere. Síbẹ̀, ká bàa lè gbádùn Párádísè tí Bíbélì ṣèlérí, a gbọ́dọ̀ mọ bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ ká máa sin òun. Àwọn àkòrí tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run kó o sì gbádùn ojú rere rẹ̀ ni àwọn bíi, “Bí O Ṣe Lè Rí Ẹ̀sìn Tòótọ́” àti “Kọ Ẹ̀sìn Èké Sílẹ̀!” Ó dá wa lójú pé wàá rí àǹfààní púpọ̀ nínú kíka ìwé pẹlẹbẹ náà.
Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà lójú ewé yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.