Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Dé Tó Máa Ń Wù Mí Láti Máa Bá Ẹni Tí Kò Yẹ Rìn?

Kí Ló Dé Tó Máa Ń Wù Mí Láti Máa Bá Ẹni Tí Kò Yẹ Rìn?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Kí Ló Dé Tó Máa Ń Wù Mí Láti Máa Bá Ẹni Tí Kò Yẹ Rìn?

“Mo mọ̀ pé kò yẹ kémi àti ẹ̀ sún mọ́ra tó bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n èmi ni mo fàyè gbà á. Ìdí ni pé mi ò rò pé ọkùnrin kankan lè sọ pé òun á máa bá mi rìn.”—Nancy. a

“Ṣe ni mo máa ń dá lọ síbi tí wọ́n ti máa ń fi bàtà onítáyà sáré, kò pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn tá a jọ ń ‘ṣọ̀rẹ́’ níbẹ̀ jáde wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́. Ká tó wí ká tó fọ̀, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣèṣekúṣe.”—Dan.

LÁTI kékeré ni Dan àti Nancy ti jẹ́ ọmọ dáadáa tó gbẹ̀kọ́ Bíbélì. Inú ilé tí wọ́n ti ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run ni wọ́n ti bí Nancy, ọmọ ọdún mẹ́sàn-án sì ni tó ti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù fáwọn èèyàn. Dan ní tiẹ̀ ò tíì pé ọmọ ogún ọdún tó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Síbẹ̀, àwọn méjèèjì jó àjórẹ̀yìn nínú ìjọsìn wọn sí Ọlọ́run. Kí ló fà á? Wọ́n kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́ ni.

Àbí ìwọ náà ti rí i pé ó ṣàdédé ń wù ẹ́ kó o máa bá ẹnì kan tó o mọ̀ lọ́kàn ara ẹ pé ipa burúkú ló máa ní lórí rẹ kẹ́gbẹ́? Ẹni yẹn lè jẹ́ ọmọ kíláàsì rẹ térò ìwọ àti ẹ̀ sábà máa ń jọra, tàbí kó tiẹ̀ jẹ́ ẹnì kan tó wù ẹ́ kẹ́ ẹ jọ máa fẹ́ra.

Ó ṣeé ṣe kó o níran ìkìlọ̀ Bíbélì pé: “Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Àmọ́ ṣé gbogbo ẹni tí kò bá ti sin Jèhófà ni ẹgbẹ́ búburú? Tí wọ́n bá láwọn ìwà kan tó wu èèyàn, kódà tó ń dá èèyàn lọ́rùn ńkọ́? Ká tiẹ̀ ní Kristẹni bíi tìẹ lẹni náà, àmọ́ tí kì í ṣe àpẹẹrẹ tó dáa nínú ìjọ ńkọ́? Ká tó dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, jẹ́ ká wo bí irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ ṣe máa ń wá séèyàn lọ́kàn àti ohun tó ń fà á.

Kí Ló Fà Á Tí Irú Ìfẹ́ Bẹ́ẹ̀ Fi Máa Ń Wá Séèyàn Lọ́kàn?

Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti dá gbogbo èèyàn ni àwòrán ara rẹ̀, a ò ní ṣaláì ráwọn èèyàn tí ò mọ Jèhófà síbẹ̀ tí wọ́n ń hùwà tó ń dáni lọ́rùn. Torí náà, o lè ráwọn èèyàn kan bí ẹni iyì, kódà bí adùn-únbárìn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́. Ṣó yẹ kó o pa irú àwọn bẹ́ẹ̀ tì pátápátá nítorí pé wọn ò mọ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Kò yẹ bẹ́ẹ̀ rárá. Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa “ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn,” lára gbogbo ènìyàn yìí náà sì làwọn tí kò fara mọ́ ohun tó o gbà gbọ́ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. (Gálátíà 6:10) Torí náà, pé ò ń ṣọ́ra nípa irú ẹni tó o máa yàn lọ́rẹ̀ẹ́ ò sọ pé kó o máa ṣe bíi pé o mọ̀ ju àwọn tó kù lọ. (Òwe 8:13; Gálátíà 6:3) Irú ìwà bẹ́ẹ̀ á mú káwọn nǹkan tó o gbà gbọ́ bíi Kristẹni máa rí wọn lára.

Àmọ́, àwọn ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ Kristẹni ò fọ̀rọ̀ yìí mọ sórí híhùwà dáadáa sí gbogbo èèyàn, wọ́n ti bá a dórí ṣíṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí nǹkan tẹ̀mí. Dan, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, gbóná gan-an nínú eré ìdárayá tí wọ́n ń fi bàtà onítáyà ṣe. Àwọn èèyàn tó máa ń bá pàdé níbi tí wọn ti máa ń ṣeré ìdárayá yìí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tó yá, Dan bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn tó mú lọ́rẹ̀ẹ́ yìí lọ́wọ́ sí ìṣekúṣe, wọ́n sì jọ ń fi oògùn olóró dánra wò. Nígbà tó rí i pé ìwà òun ò bá ti Kristẹni mu mọ́, ó ṣíwọ́ lílọ sóde ẹ̀rí, kò sì lọ sípàdé mọ́. Ọdún mélòó kan gùn ún kó tó lè lókun láti tún ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe láti lè padà sínú ìjọsìn tòótọ́.

Ó wu ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Melanie pé kó máa bá ẹnì kan tó jẹ́ Kristẹni bíi tiẹ̀, àmọ́ tí kò ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí rìn. Ó ní: “Wọ́n sọ fún mi pé ó nílò ẹni táá máa fún un níṣìírí ni o, òun ló jẹ́ kí n máa bá a rìn.” Lóòótọ́, Bíbélì rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n “máa ṣètìlẹyìn fún àwọn aláìlera.” (1 Tẹsalóníkà 5:14) Àmọ́, Melanie bá tiẹ̀ débi kó máa bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ sílé ọtí, bí àwọn míì tó pàdé níbẹ̀ ṣe tì í débi tó ti lọ́wọ́ nínú ìwà tó ń tini lójú nìyẹn o.

Bí Ìdílé Ṣe Rí Máa Ń Fà Á

Nígbà míì, irú ìdílé tó o ti jáde lè pinnu irú ẹni tó máa wù ẹ́ láti bá rìn. Kò yé ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Michelle bó ṣe dà bíi pé àwọn ọmọkùnrin tí kò rí tiẹ̀ rò tí wọn kì í sì í ṣaájò rẹ̀ ló ń wù ú láti máa bá rìn. Ó sọ pé àwọn ọmọkùnrin náà máa ń mú kóun rántí bàbá òun, tí nǹkan kan kì í da òun àti ẹ̀ pọ̀, ẹni tí kò tiẹ̀ ráàyè tòun. Ó lóun gbà pé ó ti mọ́ òun lára láti máa ti ara òun mọ́ ọkùnrin tí ò gba tòun lọ́rùn débi tóun kì í fi í mọ̀gbà tóun máa bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ wọn.

Kẹ́ ẹ sì wá máa wò ó o, ọ̀dọ́ míì táwọn òbí ẹ̀ jẹ́ Kristẹni lè fẹ́ mọ báwọn míì ṣe ń gbé ìgbé ayé wọn, torí lójú tiẹ̀, àwọn òbí rẹ̀ ò jẹ́ kó rọ́ọ̀ọ́kán. Bóyá ọ̀dọ́ kan rò pé àwọn òbí òun ò jẹ́ kóun rọ́ọ̀ọ́kán tàbí kò rò bẹ́ẹ̀, ṣó dìgbà tó bá sọ àwọn “ọ̀rẹ́ ayé” di kòríkòsùn kó tó mọ ohun tó ń lọ níta ni? (Jákọ́bù 4:4) Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Bill.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyá Bill ti kọ́ ọ ní Ìwé Mímọ́ láti kékeré, síbẹ̀ kò fẹ́ ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, nítorí ó rò pé tóun bá ti ṣèrìbọmi, òmìnira òun á dín kù. Ó fẹ́ mọ bóun á ṣe gbádùn ayé tó tóun kì í bá ṣe Kristẹni tòótọ́, bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí bá ẹgbẹ́ búburú rìn nìyẹn, ó ń bá wọn lo oògùn olóró, ó sì tún ń bá wọn hùwà ipá àti ìwà ọ̀daràn. Lọ́jọ́ kan, níbi táwọn ọlọ́pàá ti ń lé e lọ pẹ̀lú eré burúkú, ó ṣèṣe, ọ̀pọ̀ oṣù ló sì lò níbi tó sùn gbalaja sí láìmọ nǹkan kan. Àwọn dókítà sọ pé bóyá ló lè yè é. Ọpẹ́ ni pé Bill yè é. Àmọ́ ojú rẹ̀ lọ sí i, ó sì di aláàbọ̀ ara. Nígbà tójú rẹ̀ já a ló tó kẹ́kọ̀ọ́ tipátipá, ó sì ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni báyìí. Ṣùgbọ́n ó tún rí i pé téèyàn bá kẹ́kọ̀ọ́ tipátipá, títí ayé láá máa rán ohun tó bá fara gbá.

Àwọn Nǹkan Míì Tó Máa Ń Fà Á

Nígbà míì ohun tó ń wá láti àwọn ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń gbé eré jáde kì í jẹ́ káwọn ọ̀dọ́ mọ irú ẹni tó yẹ kí wọ́n mú lọ́rẹ̀ẹ́. Bí àpẹẹrẹ, a sábà máa ń rí irú àwọn tí wọ́n máa ń gbé jáde bí akọni nínú ìwé, nínú ètò orí tẹlifíṣọ̀n, nínú fíìmù, tàbí nínú fídíò orin. Irú àwọn bẹ́ẹ̀ sábà máa ń kọ́kọ́ dà bí ẹni tó le tàbí ẹni téèyàn ò jọ lójú, àmọ́ lẹ́yìn náà wọ́n á wá fi wọ́n hàn bí ẹlẹ́yinjú àánú. Ohun tí wọ́n ń fìyẹn kọ́ àwọn èèyàn ni pé àwọn tó kọ́kọ́ dà bí ọ̀dájú tí wọn kì í sì í ro tẹlòmíì mọ́ tiwọn lè jẹ́ ẹni tó mọ èèyàn tọ́jú tó sì láájò èèyàn. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún lè máa dọ́gbọ́n sọ pé ọ̀rẹ́ rẹ kan tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ lẹni tó o lè máa bá rìn tó o bá ń fẹ́ ẹni tó nírú àwọn ànímọ́ dáadáa yìí. Lóòótọ́, irú àwọn ìtàn báyìí ló máa ń dùn mọ́ àwọn èèyàn. Àmọ́, bó bá dojú ayé, ǹjẹ́ o rò pé òótọ́ ni àwọn ìtàn ìfẹ́ tí wọ́n ń jẹ́ káwọn èèyàn gbé sọ́kàn yìí? Ó mà ṣe o, àwọn ọ̀dọ́ kan ti gba àwọn èròkerò orí afẹ́fẹ́ yìí gbọ́, wọ́n sì ti lọ ń fẹ́ ẹni tó jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan àti oníjàgídíjàgan èèyàn tí wọ́n sì ń retí kó yí padà di aláàánú àti ẹni tó ń gba tẹlòmíràn rò. Àwọn míì tiẹ̀ ti bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣègbéyàwó, àmọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ ò yí padà.

Tún wo ìdí kan sí i lára àwọn ohun tó ń mú kó máa wu àwọn kan láti máa bá ẹni tí kò yẹ rìn: Wọ́n ti ka ara wọn sẹ́ni tí kò lè rẹ́ni bá rìn, torí náà ẹnikẹ́ni tó bá dà bíi pé ó wojú wọn ni wọ́n ń bá lọ. Nancy, tá a mẹ́nu ba ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣáájú, mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa gbígbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 7:39) Síbẹ̀, ó gbà pé ẹnikẹ́ni ò lè gba tòun, torí náà nígbà tẹ́nì kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ dẹnu ìfẹ́ kọ ọ́, ṣe lorí ẹ̀ wú, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó kọnu sí i yìí kì í ṣe onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀. Bó ṣe di pé wọ́n jọ ń jáde nìyẹn, ṣíún báyìí ló sì kù kí wọ́n ṣàgbèrè.

Bí àwọn ìrírí wọ̀nyí ṣe fi hàn, ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ń fà á tí Kristẹni ọ̀dọ́ kan fi lè fẹ́ máa bá àwọn tó lè kó bá a rìn. Ó sì dà bíi pé ọ̀pọ̀ nǹkan lèèyàn lè sọ pé ó mú kóun sọ irú àwọn bẹ́ẹ̀ di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Síbẹ̀, bá a bá wá a lọ wá a bọ̀, ọ̀rẹ́ rẹ́rùnrẹ́rùn nírú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

Bí Ọ̀rẹ́ Ṣe Máa Ń Lágbára Lórí Ẹni

Òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé àwọn tó ò ń bá rìn ni wàá fìwà jọ. Ìdí tó fi jẹ́ pé àwọn tá a bá ń lo àkókò wa lọ́dọ̀ wọn máa ń kọ́ wa ní ìwà wọn tí wọ́n sì máa ń lágbára lórí wa nìyẹn. Òwe 13:20 fi hàn pé agbára tí ọ̀rẹ́ ní lórí ẹni lè yọrí sí rere tàbí búburú, ó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” Àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ dà bí àwọn méjì tí wọ́n jọ wà nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan náà, kò sí àníàní pé ibì kan náà ni wọ́n dorí kọ, ibì kan náà sì ní wọ́n máa já sí. Nítorí náà bi ara rẹ pé: ‘Ṣé ọ̀nà ibi témi fẹ́ lọ ni ọ̀rẹ́ mi dorí kọ yìí? Ṣé ọ̀nà yìí á jẹ́ kọ́wọ́ mi tètè tẹ àwọn nǹkan tẹ̀mí tí mò ń lé?’

A mọ̀ pé ó lè ṣòro fún ẹ láti ṣàyẹ̀wò ara rẹ o. Ó lè jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ ti kó sí ẹ lágbárí. Ṣùgbọ́n ṣé bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ nìkan ti tó láti yan àwọn tí wàá fi ṣọ̀rẹ́? Ó ṣeé ṣe kó o ti máa gbọ́ táwọn kan máa ń fún èèyàn nímọ̀ràn pé, “Ohun tọ́kàn rẹ bá ti ní kó o ṣe ni kó o ṣe.” Ṣùgbọ́n Òwe 28:26 sọ pé: “Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ́ arìndìn.” Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé “ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ.” (Jeremáyà 17:9; Númérì 15:39) Ẹni tó jẹ́ ọ̀dàlẹ̀, èké, tàbí ṣèhín-ṣọ̀hún ni wọ́n ń pè ní aládàkàdekè. Ṣé á wù ẹ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé ẹni tá a mọ̀ sí ẹlẹ̀tàn àti ọ̀dàlẹ̀? Ọkàn wa lè máa ṣe békebèke o. Nítorí náà, pé ìwọ àti ẹnì kan mọwọ́ ara yín kò ní kó o máa bá a rìn.

Ohun tó lè tọ́ ẹ sọ́nà jù tó o sì lè gbẹ́kẹ̀ lé dáadáa ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bíbélì ò dà bí ọkàn aláìpé tó o ní, àwọn ìlànà Bíbélì ò ní kó ẹ ṣìnà láé, kò sì lè já ẹ kulẹ̀ rárá. Báwo làwọn ìlànà inú Bíbélì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá ọ̀rẹ́ gidi lẹnì kan máa jẹ́? Tó o bá fẹ́ yan ọ̀rẹ́ tẹ́ ẹ jọ máa wà títí ayé, ìyẹn ẹni tí wàá fẹ́, báwo lo ṣe lè ṣe é tó ò fi ní yan ẹni tó máa kó bá ẹ? A ó dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ kan tó ń bọ̀ lọ́nà?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Àwọn nǹkan tí ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde ń gbé jáde lè máà jẹ́ ká mọ irú ẹni tó yẹ ká yàn lọ́rẹ̀ẹ́