Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Fà á Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Fi Ń Bẹ̀rù?

Kí Ló Fà á Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Fi Ń Bẹ̀rù?

Kí Ló Fà á Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Fi Ń Bẹ̀rù?

ÌBẸ̀RÙ ti gbayé kan. Ìbẹ̀rù ò ṣeé fojú rí, àmọ́ ó máa ń hàn lójú èèyàn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ẹni tí ẹ̀rù kì í bà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé èèyàn lè má tètè fura. Kí ló fà á táwọn èèyàn fi ń bẹ̀rù níbi gbogbo? Kí ló fà á tọ́kàn àwọn kan fi máa ń pami bí wọ́n bá ti fẹ́ jáde kúrò nínú ilé? Kí ló dé tẹ́rù fi máa ń ba ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́nu iṣẹ́? Kí ló dé tí ọ̀pọ̀ òbí fi ń bẹ̀rù pé kí nǹkan má ṣe ọmọ àwọn? Àwọn ewu wo ló ń mú kẹ́rù máa ba àwọn èèyàn nínú ilé wọn?

Onírúurú nǹkan ló máa ń fa ìbẹ̀rù o, àmọ́ a óò jíròrò mẹ́rin lára àwọn ewu tó máa ń wu àwọn èèyàn lemọ́lemọ́. Ìyẹn ni àwọn ewu bí ìwà ipá láwọn ìlú ńlá, fífi ọ̀ranyàn báni tage, ìfipá-báni-lòpọ̀ àti ìjà lọ́ọ̀dẹ̀. Ẹ jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ látorí ìwà ipá tó ń wáyé láwọn ìlú ńlá. Ibi tó sì yẹ ká ti bẹ̀rẹ̀ gan-an nìyẹn nítorí pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìdajì lára àwọn èèyàn tó wà láyé ló ń gbé nínú ìlú ńláńlá.

Ewu Nílùú Ńláńlá

Àfàìmọ̀ ni kì í ṣe ọ̀ràn ààbò ló mú káwọn èèyàn tẹ àwọn ìlú ńláńlá dó láyé àtijọ́, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti bẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn ìlú ńlá síbi tó léwu láti gbé. Ohun tí wọ́n ti fìgbà kan kà sí ibi ààbò ti wá di ohun tó ń mú wọn láyà pami. Ibi térò ti ń rọ́ gìrọ́gìrọ́ láàárín ìlú làwọn jáwójáwó ti máa ń ṣiṣẹ́ ibi wọn. Láwọn ìlú kan sì rèé, ó léwu láti máa lọ sáwọn àdúgbò tí ò rí ìtọ́jú, tí iná ò fi bẹ́ẹ̀ sí lójú pópó, táwọn ọlọ́pàá ò sì tó nǹkan.

Gbogbo ìgbà kọ́ ni ìbẹ̀rù tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí máa ń jẹ́ ọ̀ràn àsọdùn o, àgbọ́-ṣe-hà niye èèyàn tó ń kú ikú gbígbóná. Ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Àjọ Ìlera Àgbáyé fi tóni létí pé, lórígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé, mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́fà èèyàn ló ń kú lọ́dọọdún nítorí ìwà ipá. Ní Áfíríkà, bá a bá kó ọ̀kẹ́ márùn-ún èèyàn jọ, nǹkan bí ọgọ́ta ó lé kan lára wọn ló ń kú ikú gbígbóná lọ́dọọdún.

Ọ̀pọ̀ èèyàn tí kì í ṣe oníwàhálà tẹ́lẹ̀ ló ti di oníjàgídíjàgan. Bákan náà, ọ̀pọ̀ ibi tí kò léwu látijọ́ àti ọ̀pọ̀ àjọ àti iléeṣẹ́ tó fọkàn ẹni balẹ̀ tẹ́lẹ̀, làwọn èèyàn ti ń kà sí èyí tó léwu báyìí. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ibi ìṣeré, ilé ẹ̀kọ́ àti ilé ìtajà làwọn èèyàn ti ń kà sí ibi tí ìwà ọ̀daràn tó légbá kan ti ń ṣẹlẹ̀ báyìí. A tiẹ̀ ti ríbi tó jẹ́ pé àwọn tó yẹ kí wọ́n máa dáàbò boni gan-an bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn, àwọn òṣìṣẹ́ ìlú, àtàwọn olùkọ́, ló ń já àwọn èèyàn tó gbára lé wọn kulẹ̀. Nítorí pé àwọn òbí ti gbọ́ pé àwọn kan lára wọn máa ń báwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe, kì í fi bẹ́ẹ̀ yá wọn lára láti ní kí ẹlòmíì wo ọmọ de àwọn. Ńṣe ló yẹ káwọn ọlọ́pàá máa dáàbò bo àwọn èèyàn, àmọ́ láwọn ìlú kan, àwọn gan-an ló pọ̀ jù nídìí ìwà ìbàjẹ́ àti àṣìlò agbára. Àwọn orílẹ̀-èdè kan sì wà táwọn èèyàn ò ti jẹ́ gbàgbé báwọn “aláàbò ìlú” ṣe kó tẹbí tọ̀rẹ́ wọn lọ nígbà ogún abẹ́lé, tí wọn ò sì rí àbọ̀ wọn mọ́. Nítorí náà, ní onírúurú ibi lágbàáyé, dípò káwọn ọlọ́pàá àtàwọn ológun máa dín ìbẹ̀rù tó gbòde kù, ńṣe ni wọ́n ń dá kún un.

Ìwé Citizens of Fear—Urban Violence in Latin America sọ pé: “Ìgbà gbogbo lẹ̀rù máa ń ba àwọn tó ń gbé láwọn olú ìlú Látìn Amẹ́ríkà, inú ipò tó léwu jù lọ láyé yìí ni wọ́n sì ń gbé. Ní ẹkùn ilẹ̀ gbígbòòrò yẹn, nǹkan bí ọ̀kẹ́ méje èèyàn ló ń kú ikú gbígbóná lọ́dọọdún, ìdá mẹ́ta lára àwọn tó ń gbé níbẹ̀ ló sì ti rí fìrífìrí ìwà ipá rí, yálà lọ́nà tó ṣe tààràtà tàbí lọ́nà tí kò ṣe tààràtà.” Láwọn apá ibòmíì nínú ayé sì rèé, ìjà òṣèlú máa ń ṣẹlẹ̀ nínú àwọn ìlú ńláńlá. Báwọn ìjà náà bá wá dèyí tápá ò ká mọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn á fi tìjà náà bojú, wọ́n á sì máa jí ọjà ọlọ́jà kó, gbogbo nǹkan á túbọ̀ wá lọ́jú pọ̀. Ìgbàkigbà làwọn tó ń fẹ̀hónú hàn sì lè ya bo àwọn oníṣòwò tó wà láàárín ìlú.

Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ló wà láàárín àwọn olówó tí wọ́n wà ní yọ̀tọ̀mì àtàwọn òtòṣì tí wọ́n ń ráágó, inú fu, àyà fu ni wọ́n sì fi ń bára wọn gbé. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn tí wọn ò rí já jẹ máa ń rọ́ lọ sí àdúgbò àwọn ọ̀tọ̀kùlú, wọ́n á sì máa jí ẹrù wọn kó. Irú ẹ̀ ò tíì ṣẹlẹ̀ láwọn ìlú kan o, àmọ́ ṣe lọ̀ràn náà dà bíi dùgbẹ̀dùgbẹ̀ tó ń fì lókè, tó máa já bó bá yá, ìgbà tó máa já sí lẹnikẹ́ni ò lè sọ.

Ewu ti pé olè lè jani àti pé rúkèrúdò lè ṣẹlẹ̀ ti tó ohun tí í ba èèyàn lẹ́rù lóòótọ́, àmọ́ àwọn nǹkan míì wà tó máa ń fa àníyàn tó sì máa ń pa kún ẹ̀rù tó ń ba àwọn èèyàn nígbà gbogbo.

Fífi Ọ̀ranyàn Báni Tage Tó Ohun Tí Í Bani Lẹ́rù

Àyà àìmọye obìnrin máa ń já lójoojúmọ́ báwọn èèyàn ṣe ń fi ìfé pè wọ́n, tí wọ́n ń fín wọn níràn, tí wọ́n sì ń fojú bá wọn sọ̀rọ̀. Ìwé ìròyìn Asia Week sọ pé: “Ìwádìí káàkiri fi hàn pé nínú obìnrin ará Japan mẹ́rin, wọ́n ti fi ọ̀ranyàn bá ẹnì kan tage rí ní gbangba, inú ọkọ̀ ojú irin lèyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ọ̀ràn náà sì ti máa ń wáyé. . . . Ìdá méjì nínú ọgọ́rùn-ún péré lára àwọn tọ́ràn kàn ló kọ ìwọ̀sí náà. Èyí tó pọ̀ jù lára wọn sọ pé ẹ̀rù ohun tí ẹni tó fìwọ̀sí lọ àwọn máa fáwọn ṣe ló ba àwọn táwọn fi dákẹ́ mẹ́rẹ́n.”

Káwọn èèyàn máa fi ọ̀ranyàn báni tage ti pọ̀ sí i gan-an nílẹ̀ Íńdíà. Akọ̀ròyìn kan tó ń gbé níbẹ̀ sọ pé: “Nígbàkigbà tí obìnrin kan bá ti jáde nílé báyìí, ó di pé kẹ́rù máa bà á nìyẹn. Gbogbo ibi tó bá lọ làwọn èèyàn á ti máa sọ̀rọ̀ àlùfààṣá sí i tí wọ́n á sì máa fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ ọ́.” Ibì kan wà nílùú Íńdíà tí inú àwọn tó ń gbé níbẹ̀ ti máa ń dùn pé kò séwu ní òpópónà àwọn. A rí i gbọ́ látinú ìròyìn tó ti ibẹ̀ wá pé: ‘Ìṣòro [ìlú yìí] ò sí lójú pópó, láwọn ilé iṣẹ́ ìlú náà ló wà. . . . nǹkan bí ìdámẹ́ta àwọn obìnrin tí wọ́n ṣèwádìí nípa wọn sọ pé wọ́n ti fi ọ̀ranyàn bá àwọn tage rí níbi táwọn ti ń ṣiṣẹ́. . . . Ó sì tó ìdajì nínú wọn tó sọ pé ìbẹ̀rù pé wọ́n á máa fi ọ̀ranyàn bá àwọn tage níbi iṣẹ́ ló jẹ́ káwọn máa ṣiṣẹ́ olówó pọ́ọ́kú . . . níbi tó jẹ́ pé [kìkì] obìnrin bíi táwọn làwọn á jọ máa ṣe wọlé wọ̀de.’

Ìfipábánilòpọ̀ Ń Dẹ́rù Bani

Ohun tó ń ba àwọn obìnrin lẹ́rù ò mọ sórí pé wọ́n lè sọ̀rọ̀ àrífín sí wọn. Ìgbà míì wà tó jẹ́ pé bí wọ́n bá ti ń fi ọ̀ranyàn bá wọn tage báyìí, wọ́n ń dọ́gbọ́n àtifipá bá wọn lò pọ̀ nìyẹn. Kò sírọ́ ńbẹ̀, ọ̀pọ̀ obìnrin bẹ̀rù ìfipábánilòpọ̀ ju ikú lọ. Obìnrin kan lè ṣàdédé bá ara ẹ̀ lóun nìkan níbi àdádó tí ẹ̀rù á ti máa bà á pé wọ́n lè fipá bá òun lò pọ̀. Ó lè rí ọkùnrin kan tí kò mọ̀ rí tàbí ọkùnrin kan tí kò lè gbẹ̀rí ẹ̀ jẹ́. Àyà rẹ̀ á bẹ̀rẹ̀ sí lù kìkì bó ṣe ń hára gàgà láti wá nǹkan ṣe sí ipò tó bá ara rẹ̀ yìí. ‘Kí lọkùnrin náà á ṣe? Níbo ni mo lè sá gbà? Àbí kí n lọgun ni?’ Ìbẹ̀rù ìgbà gbogbo bí irú èyí máa ń dá àìsàn sáwọn obìnrin lára ni. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò tiẹ̀ fẹ́ láti máa gbé láwọn ìlú ńlá tàbí kí wọ́n tiẹ̀ rẹ́sẹ̀ àwọn láwọn ìlú ńlá, kí ẹ̀rù má bàa máa bà wọ́n bẹ́ẹ̀ yẹn.

Ìwé The Female Fear sọ pé: “Ìbẹ̀rù, àníyàn àti ìdààmú ọkàn yìí wà lára nǹkan táwọn obìnrin tó ń gbé nígboro ń dojú kọ lójoojúmọ́. Ńṣe ni ìbẹ̀rù pé wọ́n lè fipá bá àwọn obìnrin lò pọ̀ máa ń mú kí wọ́n gbára dì nígbà gbogbo, kí wọ́n máa wà lójú fò, kí wọ́n sì máa tẹ́tí léko, àwọn ohun táwọn obìnrin ń kó lé ọkàn yìí máa ń mú kí ara wọn gbẹ̀kan bí ẹnì kan bá ń rìn sún mọ́ wọn jù, pàápàá lọ́wọ́ alẹ́. Kò sì sí . . . bí wọn ò ṣe ní máa ronú lọ́nà yẹn.”

Ọ̀pọ̀ obìnrin ni wọn máa ń hùwà ìwà ipá bíburú jáì sí. Àmọ́ ṣá, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí obìnrin náà tí kì í bẹ̀rù ìwà ipá. Ìwé The State of World Population 2000, tí Àjọ Ìparapọ Orílẹ̀-Èdè ṣe jáde, sọ pé: “Lórígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, kò dín ní ìdámẹ́ta àwọn obìnrin tí wọ́n ti lù rí tàbí tí wọ́n fi agídí bá lò pọ̀ rí, tàbí tí wọ́n fìyà jẹ lọ́nà kan tàbí òmíràn, àwọn tó mọ irú obìnrin bẹ́ẹ̀ ló sì sábà máa ń wà nídìí ọ̀ràn náà.” Ṣé ohun tó ń múni bẹ̀rù máa ń ṣẹlẹ̀ láwọn ibòmíì yàtọ̀ sí ojú pópó àti ibi iṣẹ́? Báwo ló ṣe wọ́pọ̀ tó pé káwọn èèyàn máa bẹ̀rù nínú ilé wọn?

Àwọn Èèyàn Ń Bẹ̀rù Ìwà Ipá Lọ́ọ̀dẹ̀ Wọn

Kárí ayé làwọn èèyàn ti máa ń fi lílù ṣe ti ìyàwó wọn kó bàa lè gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu, ìwà ìkà tó burú jáì sì nìyẹn jẹ́. Ẹnu àìpẹ́ yìí ni wọ́n sì tó kà á sí ìwà ọ̀daràn níbi púpọ̀. Ní Íńdíà, ìròyìn kan sọ pé “ó kéré tán, nǹkan bí ìdajì àwọn obìnrin tó ń gbé nílẹ̀ Íńdíà làwọn ọkọ wọn máa ń gbá létí, tàbí kí wọ́n da ẹ̀ṣẹ́ bò, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ fi lílù ṣe tiwọn.” Ìṣòro tó kárí ayé ni káwọn ọkùnrin máa lu ìyàwó wọn ni àlùbami. Ní tàwọn obìnrin tí wọ́n wà láàárín ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí mẹ́rìnlélógójì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ilé iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà tó ń tọpinpin ìwà ọ̀daràn, Federal Bureau of Investigation, ròyìn pé bá a bá ṣe àròpọ̀ iye àwọn obìnrin tó ń ṣèṣe nítorí ìjàǹbá ọkọ̀, ìgbéjakoni, àti ìfipábánilòpọ̀, wọn ò tíì tó àwọn tó ń ṣèṣe nítorí ìjà tó ń wáyé láàárín tọkọtaya. Nítorí èyí, ìjà tó ń wáyé láàárín tọkọtaya kọjá iyàn jíjà tó ń wáyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, tó lè mú kí wọ́n gbára wọn létí. Ọ̀pọ̀ obìnrin lẹ̀rù jàǹbá àti ikú ń bà nínú ilé. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe jákèjádò orílẹ̀-èdè Kánádà fi hàn pé ìdá mẹ́ta lára àwọn obìnrin tí wọ́n ti lù lálùbami rí, lẹ̀rù bà pé ó ṣeé ṣe káwọn kú. Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ibi táwọn olùṣèwádìí méjì kan fẹnu ọ̀rọ̀ jóná sí ni pé: “Ilé nibi tó léwu jù lọ fáwọn obìnrin, ibẹ̀ náà sì ni wọ́n ti sábà máa ń jẹ wọ́n níyà tí wọ́n sì ń dá wọn lóró.”

Kí ló fà á tọ́pọ̀ obìnrin fi bára wọn nínú irú ilé onílàásìgbò bẹ́ẹ̀? Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń ṣe kàyééfì tiẹ̀ máa ń sọ pé: ‘Wọn ò ṣe wẹ́ni ràn wọ́n lọ́wọ́? Wọn ò ṣe wá ibòmíì gbà lọ?’ Ìdáhùn tá a sábà máa ń rí sí ìbéèrè náà ni pé, ẹ̀rù ló ń bà wọ́n. Ìbẹ̀rù ló sábà máa ń wà nídìí ìjà tó ń wáyé lábẹ́ ọ̀ọ̀dẹ̀. Ìjà làwọn ọkùnrin tó ń fipá darí àwọn ìyàwó wọn sábà máa ń gbé kò wọ́n lójú, bí wọ́n bá sì janpata, wọ́n á fikú halẹ̀ mọ́ wọn. Ká tiẹ̀ wá ní ìyàwó tí wọ́n ń lù bí ẹni lu bàrà náà nígboyà láti wẹ́ni ran òun lọ́wọ́, ó lè má máa rẹ́ni ràn án lọ́wọ́ ní gbogbo ìgbà. A tiẹ̀ ráwọn èèyàn kan tí wọ́n kórìíra oríṣi ìwà ipá míì, àmọ́ bó bá di tàwọn ọkọ tó ń fìyà jẹ ìyàwó wọn, ojú kò-tó-nǹkan ni wọ́n fi ń wò ó, wọ́n tiẹ̀ lè fetí palàbà ẹ̀, tàbí kí wọ́n kà á sí ohun tí kò burú. Òmíràn sì tún ni pé, ọkùnrin tó ń fìyà jẹ aya rẹ̀ lè jẹ ẹni tí wọ́n gba tiẹ̀ ládùúgbò. Àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ kì í sì í sábà gbà pé ó ń lu ìyàwó rẹ̀. Bí ọ̀pọ̀ àya tí wọ́n ń fìyà jẹ bá sì wá rí i pé kò sẹ́ni tó gba àwọn gbọ́, tí wọn ò sì ríbi sá sí, kò sí méjì ju pé kí wọ́n máa bo ẹ̀rù tó ń bà wọ́n nígbà gbogbo mọ́ra.

Nígbà míì sì rèé, báwọn obìnrin tí wọ́n ń lù ni àlùbami bá yàn láti kó kúrò lọ́dọ̀ irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa ń kàgbákò irú ìfìtínà míì, ìyẹn ni pé kí ọkùnrin náà máa dọdẹ wọn kiri. Ní Àríwá Amẹ́ríkà, nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nípa àwọn obìnrin tó lé lẹ́gbẹ̀rún ní ìpínlẹ̀ Louisiana, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó ju àádọ́jọ lọ lára wọn tó sọ pé wọ́n ti dọdẹ àwọn rí. Kékeré kọ́ lẹ̀rù táá máa bà wọ́n. Kẹ́nì kan tó ti fikú halẹ̀ mọ́ ẹ ṣàdédé máa yọ sí ẹ níbikíbi tó o bá lọ. Bó ṣe ń ké sí ọ lórí tẹlifóònù, ló ń tẹ̀ lé ọ káàkiri, bẹ́ẹ̀ ló ń ṣọ́ ẹ lójú méjèèjì, tó sì ń dènà dè ọ́. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó pa ẹran ọ̀sìn rẹ. Gbogbo ẹ̀ ó ṣáà ju pé kó lè máa kó ìpayà bá ọ lọ!

Àwọn nǹkan tó máa ń bà ọ́ lẹ́rù lè yàtọ̀ sáwọn tá a ti sọ yìí. Ṣùgbọ́n ipa wo ni ìbẹ̀rù ń kó nínú ìgbòkègbodò tìẹ náà lójoojúmọ́?

Ṣé O Máa Ń Fìbẹ̀rù Ṣe Nǹkan?

Nítorí pé ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń múni bẹ̀rù ló yí wa ká, a lè má mọ bí ìpinnu tá à ń ṣe lójoojúmọ́, nítorí ẹ̀rù tó ń bà wá, ṣe pọ̀ tó. Báwo lo ṣe ń fìbẹ̀rù ṣe nǹkan lemọ́lemọ́ tó?

Ṣé ìwọ tàbí ìdílé rẹ kì í fẹ́ kílẹ̀ ṣú kẹ́ ẹ tó délé, nítorí pé ẹ̀ ń bẹ̀rù ìwà ipá? Ṣé ìbẹ̀rù ò fẹ́ jẹ́ kó o wọkọ̀ èrò mọ́? Ṣé ìbẹ̀rù à ń wọkọ̀ lọ, wọkọ̀ bọ̀ ló jẹ́ kó o máa ṣe irú iṣẹ́ tó ò ń ṣe báyìí? Àbí nítorí pé ò ń bẹ̀rù àwọn tẹ́ ẹ ó jọ máa ṣiṣẹ́ tàbí àwọn èèyàn tí wàá máa bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ló ṣe yan irú iṣẹ́ tó ò ń ṣe báyìí? Ṣé ìbẹ̀rù ni ò jẹ́ kó o lé máa báwọn èèyàn ṣe wọléwọ̀de mọ́, àbí kò jẹ́ kó o lè gbádùn eré ìdárayá tó wù ẹ́ mọ́? Bóyá oò tiẹ̀ lè lọ síbi àwọn eré ìdárayá tàbí agbo eré kan mọ́ nítorí pé ẹ̀rù àwọn onímukúmu àti èrò rẹpẹtẹ tó o máa bá pàdé níbẹ̀ ń bà ọ́? Ṣé ìbẹ̀rù lo fi máa ń ṣe nǹkan nílé ìwé? Ọ̀pọ̀ òbí lẹ̀rù ń bà pé káwọn ọmọ wọn má yàyàkuyà, nítorí ẹ̀ ni wọ́n ṣe yan irú ilé ìwé tí wọ́n á máa lọ fún wọn, ẹ̀rù tó ń bà wọ́n ló sì fà á tí ọ̀pọ̀ lára àwọn òbí fi ń lọ fọkọ̀ gbé àwọn ọmọ nílé ìwé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ náà lè fẹsẹ̀ rìn wálé tàbí kí wọ́n wọkọ̀ èrò.

Dájúdájú, ìbẹ̀rù ti gbayé kan. Ṣùgbọ́n ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé látọjọ́ táláyé ti dáyé la ti ń bẹ̀rù ìwà ipá. Ṣé a lè retí pé nǹkan á yí padà ní tòótọ́ ṣá? Ṣé òótọ́ ni pé aráyé máa tó bọ́ lọ́wọ́ ìbẹ̀rù? Àbí ìdí kan tó ṣeé gbára lé wà pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ẹnikẹ́ni ò ní bẹ̀rù ohun búburú èyíkéyìí mọ́?