Láìpẹ́—Òpin Máa Dé Bá Gbogbo Àjálù
Láìpẹ́—Òpin Máa Dé Bá Gbogbo Àjálù
“Ẹ̀yin ọmọ àtẹ̀yin ọmọ ọmọ ò. Etí yín mélòó? . . . Bópẹ́bóyá, òkè tẹ́ ẹ̀ ń wò yìí á gbiná o. Àmọ́ kó tó gbiná, ẹ óò máa gbúròó ẹ̀ táá máa rọ́ kẹ̀kẹ̀, ẹ ó sì máa gbúròó ìmìtìtì ilẹ̀. Èéfín àti ọwọ́ iná pẹ̀lú mànàmáná á gba ojú ọ̀run, afẹ́fẹ́ á máa rọ́ yìì, á sì máa pariwo. Ẹ sá, ẹ má ṣe dúró nítòsí o. . . Tẹ́ ẹ bá dágunlá, tí dúkìá àti búrùjí tẹ́ ẹ ní bá ká yín lara ju ẹ̀mí yín lọ, òkè yìí á bú jáde, á sì pa yín tẹ̀yìn ti àìgbàkìlọ̀ àti ọ̀kánjúwà yín. Ẹ mọ́kàn kúrò lára ilé yín àtàwọn ohun tẹ́ ẹ ní, ẹ bẹ́sẹ̀ yín sọ̀rọ̀ láìjáfara.”
LẸ́YÌN tí Òkè Vesuvius lórílẹ̀-èdè Ítálì bú jáde lọ́dún 1631 ni wọ́n kọ ọ̀rọ̀ yìí sórí wàláà òkúta ní ìlú Portici tó wà níbi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè. Inú ìwé Earth Shock tí Andrew Robinson kọ ni wọ́n ti fa ọ̀rọ̀ náà yọ. Òkè tó bú jáde yìí pa ẹgbàajì èèyàn. Robinson sọ pé: “Bíbú tí Òkè Vesuvius bú jáde lọ́dún 1631 yìí . . . ló sọ ọ́ di òkè tí gbogbo ayé mọ̀.” Bíi báwo? Nígbà tí wọ́n ń tún ìlú Portici kọ́, wọ́n ṣàwárí ìlú Herculaneum àti Pompeii. Nígbà tí Òkè Vesuvius bú jáde lọ́dún 79 Sànmánì Kristẹni ló ti ya bo ìlú méjèèjì yìí mọ́lẹ̀.
Pliny Kékeré, ará Róòmù tó la ìṣẹ̀lẹ̀ náà já tó tún wá di gómìnà nígbà tó yá, kọ̀wé nípa bí ilẹ̀ ṣe ń mì wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ lọ́nà tó ṣàjèjì, èyí tó yẹ kó ti kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé ìsẹ̀lẹ̀ ń bọ̀. Òun àti ìyá rẹ̀ kúrò nítòsí ibi tí òkè náà ti fẹ́ bú jáde, wọ́n sì yè é.
Àwọn Àmì Ìkìlọ̀ Lákòókò Tiwa
Lákòókò tá a wà yìí, a ti ń sún mọ́ àsìkò tí òpin máa dé bá ètò ọrọ̀ ajé, onírúurú ètò táwọn èèyàn gbé kalẹ̀ àti onírúurú ètò ìjọba jákèjádò ayé. Báwo la ṣe mọ̀? Bá a ṣe mọ̀ ni pé Jésù Kristi sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ táá máa ṣẹlẹ̀ tó máa jẹ́ àmì tá a máa fi mọ̀ pé ọjọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run ti sún mọ́lé. Ṣe ló dà bí ìgbà tí òkè bá fẹ́ bú jáde tó ń hooru yìì, tó ń yèéfín, tó sì tún ń tú eérú gbígbóná jáde. Àwọn àmì tí Jésù fún wa nípa àkókò náà ni àwọn ogun runlérùnnà, ìsẹ̀lẹ̀, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn—gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ tí ò tíì wáyé rí yìí ló ti ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé látọdún 1914 títí di ìsinsìnyí, ṣáájú ọdún yẹn kò tíì ṣẹlẹ̀ báyìí rí.—Mátíù 24:3-8; Lúùkù 21:10, 11; Ìṣípayá 6:1-8.
Àmọ́ ìkìlọ̀ Jésù tún fún wa ní ìrètí. Ó sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Kíyè sí i pé Jésù pe ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run ní “ìhìn rere.” Ìhìn rere ni lóòótọ́ torí pé Ìjọba Ọlọ́run táá máa ṣàkóso láti ọ̀run, táá sì wà níkàáwọ́ Kristi Jésù máa mú gbogbo láburú táwọn ọmọ èèyàn ti fọwọ́ ara wọn fà kúrò. Yàtọ̀ síyẹn, á tún fòpin sí gbogbo àjálù.—Lúùkù 4:43; Ìṣípayá 21:3, 4.
Àní nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí èèyàn, ó lo agbára tó ní lórí ìṣẹ̀dá nígbà tó mú kí ìgbì òkun tó lè gbẹ̀mí èèyàn rọlẹ̀. Ẹ̀rù ba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ débi tí wọ́n fi sọ pé: “Ta nìyí ní ti gidi, nítorí ó ń pa àṣẹ ìtọ́ni fún ẹ̀fúùfù àti omi pàápàá, wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i?” (Lúùkù 8:22-25) Jésù kì í ṣe èèyàn lásán mọ́ báyìí, ẹ̀dá ẹ̀mí tó lágbára ni. Torí náà kò lè ṣòro fún un láti máa darí gbogbo ohun tó wà láyé pátá lọ́nà tí kò fi ní ṣe jàǹbá kankan fáwọn tó bá wà lábẹ́ ìjọba rẹ̀!—Sáàmù 2:6-9; Ìṣípayá 11:15.
Lójú àwọn míì, ọ̀rọ̀ yìí lè dà bí ìgbà téèyàn bá ń dá ara rẹ̀ nínú dùn lásán. Àmọ́, fi sọ́kàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ò dà bí ìlérí àti àsọtẹ́lẹ̀ èèyàn. Gbogbo ohun tí Bíbélì bá sọ pátá ló máa ń ṣẹ, ara rẹ̀ sì làwọn èyí tá à ń rí tó ń ní ìmúṣẹ láti ọdún 1914 wá yìí. (Aísáyà 46:10; 55:10, 11) Bẹ́ẹ̀ ni o, ó dájú pé àlàáfíà ń bọ̀ wá jọba láyé lọ́jọ́ iwájú. Ó sì dájú pé tá a bá fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ́kàn, tá a sì ń tẹ̀ lé ìkìlọ̀ tó ṣe nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ táá gbo ayé jìgìjìgì, èyí tí ò ní pẹ́ ṣẹlẹ̀ báyìí, ọjọ́ iwájú tó mìrìngìndìn á jẹ́ tiwa.—Mátíù 24:42, 44; Jòhánù 17:3.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
ṢÉ ÌRÈTÍ ṢÌ WÀ FÁWỌN ÈÈYÀN WA TÓ TI KÚ?
NÍGBÀ téèyàn wa kan bá kú, ìbànújẹ́ lè dorí wa kodò. Bíbélì sọ fún wa pé Jésù sunkún nígbà tí Lásárù, ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n kú. Síbẹ̀, ní ìṣẹ́jú mélòó kan lẹ́yìn náà, Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu pípabanbarì kan, ìyẹn ni pé ó mú kí Lásárù tún padà wà láàyè! (Jòhánù 11:32-44) Jíjí tí Jésù jí Lásárù dìde jẹ́ ẹ̀rí tí gbogbo èèyàn fi lè gba ìlérí tó kọ́kọ́ ṣe nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ gbọ́, pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù], wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Àdúrà wa ni pé kí ìrètí pé àwọn òkú ṣì máa padà wà láàyè nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé máa tu àwọn téèyàn wọn ti kú nínú.—Ìṣe 24:15.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ṣé ò ń fọkàn sí ìkìlọ̀ pé ayé tá a wà nínú rẹ̀ yìí ti wọ àkókò òpin?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 18]
USGS, David A. Johnston, Cascades Volcano Observatory