Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

(Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí. Wàá rí àwọn ìdáhùn níbi tí a tẹ̀ ẹ́ sí lójú ìwé 25. Bó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ìdáhùn yìí, wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀.)

1. Èyí tó dára jù lọ nínú àwọn nǹkan wo ni Jèhófà sọ pé kí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì mú wá fóun, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sọ bó ṣe gbọ́dọ̀ pọ̀ tó? (Ẹ́kísódù 23:19)

2. Nítorí pé àwọn èèyàn Ọlọ́run láásìkí tó sì dà bíi pé wọ́n wà láìláàbò, ta ló máa fẹ́ láti gbéjà kò wọ́n? (Ìsíkíẹ́lì 38:10-12, 14-16)

3. Ìjòyè wo ló ń retí àtigbowó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ Pọ́ọ̀lù, tó wá tìtorí ẹ̀ dá àpọ́sítélì náà dúró sí àtìmọ́lé fọ́dún méjì ní Kesaréà? (Ìṣe 24:26, 27)

4. Igbe wo làwọn adẹ́tẹ̀ tó wà nílẹ̀ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ máa ké, káwọn èèyàn má bàa sún mọ́ ibi tí wọ́n wà kí ẹ̀tẹ̀ sì ràn wọ́n? (Léfítíkù 13:45)

5. Kí ni Jékọ́bù fi sàmì sí ibojì Rákélì? (Jẹ́nẹ́sísì 35:20)

6. Kí nìdí tí Jèhófà fi rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn ju ìgbà kan lọ? (2 Àwọn Ọba 18:11, 12)

7. Dípò kí jíjowú, níní ẹ̀mí asọ̀ àti pípurọ́ lòdì sí òtítọ́ fi ọgbọ́n tó ti òkè wá hàn, kí ni Jákọ́bù sọ pé wọ́n jẹ́? (Jákọ́bù 3:15)

8. Igi wo ni Sólómọ́nì sọ pé kí Hírámù Ọba kó ránṣẹ́ sóun kóun bàa lè fi kọ́ tẹ́ńpìlì, kóun sì tún fi ṣe háàpù àtàwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín? (1 Àwọn Ọba 10:11, 12)

9. Àwọn èèyàn mẹ́ta wo ni Jèhófà pàṣẹ fún Èlíjà pé kó lọ fòróró yàn? (1 Àwọn Ọba 19:15, 16)

10. Ta ni olórí àlùfáà “fún gbogbo ọ̀ràn Jèhófà” nígbà ìṣàkóso Jèhóṣáfátì? (2 Kíróníkà 19:11)

11. Kí ni Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú pé kó fi ṣe àfojúsùn rẹ̀ bó ṣe ń kọ́ ara rẹ̀? (1 Tímótì 4:7)

12. Fáráò ilẹ̀ Íjíbítì wo ni Nebukadinésárì ṣẹ́gun ní Kákémíṣì nígbà ìṣàkóso Jèhóákímù, ọba Júdà? (Jeremáyà 46:2)

13. Nítorí pé olóye èèyàn ni Ábígẹ́lì, ìṣòro wo ni kò jẹ́ kí Dáfídì kó sí? (1 Sámúẹ́lì 25:31)

14. Gbólóhùn wo ni Bíbélì fi pe àwọn ẹyẹ? (Jẹ́nẹ́sísì 1:26)

15. Kí ló dé tí ìwé Òwe fi sọ pé ká má ṣe máa lọ sílé àwọn ẹlòmíràn lemọ́lemọ́ jù? (Òwe 25:17)

16. Bí Pétérù ṣe sọ, dídarí ẹ̀yà ara wo ló ṣe pàtàkì bá a bá fẹ́ jèrè ojú rere Jèhófà? (1 Pétérù 3:10-12)

17. Irú ẹran wo ni wọ́n lò fún ẹbọ ìfinijoyè nígbà tí wọ́n ń yan Áárónì sí ipò àlùfáà? (Léfítíkù 8:22-28)

18. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ fín àmì sí ara wọn? (Léfítíkù 19:28)

19. Orúkọ wo ni Jékọ́bù pe ibi tí òun àti Lábánì ti dá májẹ̀mú àlááfíà? (Jẹ́nẹ́sísì 31:43-53)

20. Iṣẹ́ ìyanu wo ni Jésù kọ́kọ́ ṣe? (Jòhánù 2:7-11)

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè

1. Àkọ́pọ́n àwọn èso ilẹ̀

2. Gọ́ọ̀gù

3. Fẹ́líìsì, ajẹ́lẹ̀ Jùdíà

4. “Aláìmọ́, aláìmọ́!”

5. Ó gbé ọwọ̀n kan dúró sórí rẹ̀

6. Wọn kò pa májẹ̀mú tí wọ́n bá a dá mọ́

7. “Ti ilẹ̀ ayé, ti ẹranko, ti ẹ̀mí èṣù”

8. Álígúmù

9. Kó yan Hásáélì ṣe ọba lórí Síríà, kó yan Jéhù ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì, kó sì yan Èlíṣà ṣe wòlíì dípò ara rẹ̀

10. Amaráyà

11. Kó ní “ìfọkànsin Ọlọ́run”

12. Nékò

13. Jíjẹ̀bi ẹ̀jẹ̀

14. “Àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run”

15. Kí ọ̀rọ̀ wa má bàa sú wọn, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kórìíra wa

16. Ahọ́n

17. Àgbò

18. Kí wọ́n bàa lè yàtọ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, kí wọ́n má sì gbàgbé bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n ní ọ̀wọ̀ tó tọ́ fún ara èèyàn gẹ́gẹ́ bí ohun tí Ọlọ́run dá, kéèyàn lè máa lò ó láti bọlá fún un

19. Gáléédì (tá a wá mọ̀ sí Gíléádì)

20. Ó sọ omi di ọtí wáìnì