Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Àwọn “Oníjàngbọ̀n” Ọmọ Lè Yí Padà

Ìwé ìròyìn The Sydney Morning Herald sọ pé: “Ọ̀pọ̀ oníjàngbọ̀n ọmọ tí wọn ò tíì dàgbà ju ọmọ aláábíídí lọ lè yí padà. Wọ́n lè dàgbà dẹni tó mọ̀wàá hù.” Àjọ Tó Ń Rí sí Ìwádìí Nípa Ìdílé Nílẹ̀ Ọsirélíà ṣe ìwádìí kan tó dá lórí àwọn ọmọ méjìdínlọ́gọ́sàn-án. Nígbà táwọn ọmọ náà pé ọmọ ọdún mọ́kànlá sí méjìlá ni wọ́n ti rí i pé wọ́n ń hu mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ìwà bíi “jàgídíjàgan, kìígbọ́-kìígbà, wérewère, àìlèpọkànpọ̀, araàbalẹ̀, inú fùfù àti kí ìṣesí wọn máa yí padà.” Lẹ́yìn ọdún mẹ́fà, ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọ̀dọ́ yìí ti ń hùwà “tó fẹ́rẹ̀ẹ́ bá ti àwọn ọ̀dọ́ tí kò lágbaja mu.” Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yíwà padà? Ìròyìn náà sọ pé: “Àwọn ọmọ tí kì í báwọn ẹgbẹ́ wọn tó ṣónú ṣọ̀rẹ́, tó sì ṣeé ṣe kí wọ́n rí òbí bójú tó wọn dáadáa, ni wọ́n sábà máa ń di ọ̀dọ́ tó láyọ̀.”

Àwọn Abo Béárì Kì Í Sá Fáwọn Arìnrìn-Àjò Afẹ́

Ìwé ìròyìn New Scientist ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ròyìn pé: “Àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ sí àjọṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti àyíká lè má mọ̀ pé oore ńlá làwọn ń ṣe àwọn béárì aláwọ̀ ilẹ̀ tó ń gbé nígbó.” Àwọn tó máa ń ṣèbẹ̀wò síbi àdádó táwọn ẹranko ń gbé sábà máa ń dáyà já àwọn ẹranko náà, wọ́n sì máa ń pa wọ́n lára nígbà míì. Àmọ́ ṣá o, àwọn olùṣèwádìí láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà tí wọ́n ń kọ́ nípa àwọn béárì níbi àdádó kan báyìí táwọn ẹja aláràn-án ti máa ń pamọ ní ìwọ̀ oòrùn Kánádà ti “rí i pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn akọ béárì tó ti dàgbà máa ń sá fáwọn arìnrìn-àjò afẹ́, . . . àwọn abo béárì àtàwọn béárì kéékèèké kì í sá fún wọn, kàkà bẹ́ẹ̀ bí wọ́n bá ti gbọ́ ariwo bọ́ọ̀sì àwọn arìnrìn àjò náà ni wọ́n ti máa ń mọ̀ pé àwọn akọ tó lè ṣe wọ́n léṣe á ti kúrò nínú omi,” bí ìròyìn náà ṣe sọ. “Kódà, bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn akọ ti kúrò lágbègbè náà tẹ́lẹ̀, àwọn abo kì í yọjú àfi táwọn arìnrìn-àjò afẹ́ bá dé.” Ó dájú pé ńṣe làwọn abo béárì yìí ń jọlá àwọn arìnrìn-àjò afẹ́, ni wọ́n fi ń wá oúnjẹ wá síbi tó dáa jù lọ tàwọn akọ béárì ò ti ni gbéjà ko àwọn ọmọ wọn yìí.

Fífi Àárẹ̀ Ara Ṣiṣẹ́

Ìwé ìròyìn orí Íńtánẹ́ẹ̀tì náà, Telegraph ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ròyìn pé: “Àwọn tí ara wọn ò yá, síbẹ̀ tí wọ́n ń lọ fàárẹ̀ ara ṣiṣẹ́” ń rìn ní bèbè àìsàn ọkàn ni. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga University College nílùú London ṣe ìwádìí nípa àkọsílẹ̀ ìlera àti àkọsílẹ̀ nípa báwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tó tó ẹgbàárùn-ún [10,000] nílùú London, ṣe ń wá síbi iṣẹ́ sí, láàárín ohun tó lé lọ́dún mẹ́wàá. Ọ̀jọ̀gbọ́n Michael Marmot tó bójú tó ìwádìí náà sọ pé ìdá mẹ́ta sí mẹ́rin nínú mẹ́wàá lára àwọn òṣìṣẹ́ náà, “ni ìṣòro àìsàn ọkàn tí wọ́n ní láwọn ọdún tó tẹ̀ lé e fi ìlọ́po méjì pọ̀ sí i.” Ìdí ni pé wọn kì í sinmi nílé bí ara wọn kò bá yá, ì báà tiẹ̀ ṣe ọ̀fìnkìn lásán ló ń yọ wọ́n lẹ́nu.

Ọ̀rọ̀ Tó Ṣòro Túmọ̀ Jù Lọ Láyé

Ilé iṣẹ́ ìròyìn BBC ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé, “ọ̀rọ̀ tó ṣòro túmọ̀ jù lọ láyé ni ‘ilunga’ tó wá látinú èdè Tshiluba,” tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè Kóńgò. Ọ̀rọ̀ náà làwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ mú nínú ìwádìí tí wọ́n ṣe káàkiri láàárín ẹgbẹ̀rún kan èèyàn tí wọ́n mọ̀ nípa èdè púpọ̀. Ilunga túmọ̀ sí “ẹnì kan tó múra tán láti dárí jini nígbà àkọ́kọ́ téèyàn bá ṣẹ̀ ẹ́, tó ṣe tán láti fara mọ́ ọn nígbà kejì, ṣùgbọ́n táá yarí kanlẹ̀ bó bá dìgbà kẹta.” Ọ̀rọ̀ míì tọ́pọ̀ èèyàn tún gbà pó ṣòro láti túmọ̀ ni naa, inú èdè àwọn ará Japan ló wà. Wọ́n máa ń lò ó “ní àgbègbè Kansai lórílẹ̀-èdè Japan láti tẹnu mọ́ gbólóhùn ọ̀rọ̀ tàbí láti jọ́hẹn sí ohun tẹ́nì kan bá sọ.” Olùdarí ilé iṣẹ́ tó ń ṣojú fún títúmọ̀ àti ṣíṣe ògbufọ̀, Jurga Zilinskiene, tó ní kí wọ́n ṣe ìwádìí náà sọ pé, “àwọn èèyàn máa ń gbàgbé nígbà míì pé iṣẹ́ ògbufọ̀ . . . kò mọ sórí gbígba ọ̀rọ̀ sọ láti èdè kan sí òmíràn, ṣùgbọ́n á tún máa fi àṣà tó wà nínú èdè méjì wéra,” àti pé “nígbà míì, ńṣe ni kì í sí èrò tó jọra rárá nínú àṣà méjèèjì.”

O Lè Gba Máàkì Púpọ̀ Bó O Bá Ń Fìwé Kíkà Najú

Ìwé ìròyìn Milenio ti Ìlú Mẹ́síkò ròyìn pé béèyàn bá ń kàwé najú, ó lè mú kó ṣe dáadáa sí i nílé ẹ̀kọ́ ju “ọ̀pọ̀ wákàtí tó bá fi ń kẹ́kọ̀ọ́, tó fi ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ látọ̀dọ̀ òbí, tó fi ń ka ìwé tó ń kọ iṣẹ́ sí nílé ẹ̀kọ́, tàbí èyí tó fi ń lo kọ̀ǹpútà.” Ìwádìí kan tó dá lórí ìdánwò àṣewọlé-ẹ̀kọ́ gíga, táwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ju ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lọ ṣe, fi hàn pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n bá ya àkókò sọ́tọ̀ fún kíka ohun tí wọ́n ń kọ́ wọn nílé ẹ̀kọ́ àti kíkàwé najú ló ṣeé ṣe jù lọ pé kí wọ́n ṣàṣeyọrí nílé ẹ̀kọ́. Kò pọn dandan kí ìwé táwọn akẹ́kọ̀ọ́ bá yàn láti kà dá lórí ohun tí wọ́n ń kọ́ wọn nílé ìwé nìkan, àmọ́ ó tún lè dá lórí àwọn nǹkan téèyàn lè kà ní àkàgbádùn, bí ìtàn ìgbésí ayé, àwọn ìwé ewì, àtàwọn ìwé nípa ìmọ̀ ìjìnlẹ̀. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ìròyìn náà sọ pé ó dà bíi pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n bá ń fi ọ̀pọ̀ wákàtí wo tẹlifíṣọ̀n lóòjọ́ dípò kí wọ́n máa kàwé kì í fi bẹ́ẹ̀ gba máàkì tó pọ̀.

Wọ́n Ti Ń Ki Èrú Bọ Ìwé Ẹ̀rí Ìtóótun Fúnṣẹ́ O

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó dáa jù lọ lójú àwọn agbanisíṣẹ́ làwọn tó ń wáṣẹ́ sábà máa ń fẹ́ láti ṣe, ńṣe làwọn kan ń ṣèrú lọ ràì ní tiwọn. Nínú ìwádìí kan tí ilé iṣẹ́ Australian Background, tó máa ń fọ̀rọ̀ wá àwọn tó ń wáṣẹ́ lẹ́nu wò ṣe, wọ́n rí i pé nínú ẹgbẹ̀rún kan èèyàn tó ń wáṣẹ́, igba ó lé mẹ́wàá lára wọn ló ti purọ́ nípa bí wọ́n ṣe tóótun sí fáwọn tó fẹ́ gbà wọ́n síṣẹ́, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Sydney Morning Herald ṣe sọ. Ìwé ìròyìn náà tún wá fi kún un pé, “ẹgbẹ̀ta lára àwọn tí wọ́n ti dájọ́ ẹ̀wọ̀n fún rí ni ò jẹ́wọ́, kódà, lẹ́yìn tí wọ́n ti béèrè lọ́wọ́ wọn.” Ọ̀gá kan níbi tí wọ́n ti ń gbani síṣẹ́, Gary Brack, tiẹ̀ sọ pé, “àwọn tó ń wáṣẹ́ náà lè máa fọ́nnu pé kò sí báwọn ò ṣe jẹ́. Ṣùgbọ́n ìwọ kàn wádìí wọn lọ síbi tí wọn ti ṣiṣẹ́ kẹ́yìn, wàá rí i pé àgbá òfìfo tó kàn ń pariwo ni wọ́n.”

Jíjókòó Sójú Kan Tètè Ń Pààyàn Ju Sìgá Mímu Lọ

Ẹgbàá méjìlá [24,000] èèyàn ló kú lórílẹ̀-èdè Hong Kong lọ́dún 1998. Àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe nípa bí wọ́n ṣe máa ń ṣeré ìmárale sí kí wọ́n tó kú fi hàn pé, “kéèyàn máa jókòó sójú kan lè tètè pààyàn ju sìgá mímu lọ.” Ìwádìí náà fi hàn pé kéèyàn má máa fára ṣiṣẹ́ máa ń mú kí ewu ikú àìtọ́jọ́ fi ìpín mọ́kàndínlọ́gọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i láàárín àwọn ọkùnrin, ó sì ń fi ìpín mẹ́tàlélọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i láàárín àwọn obìnrin, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn South China Morning Post ṣe sọ. Lam Tai-hing, tó jẹ́ ọ̀gá ní ẹ̀ka ìmọ̀ nípa ìlera alábọ́dé ní ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Hong Kong sọ pé: “Ó dáa bí o kì í bá mu sìgá. Àmọ́, bí o kì í bá ṣe eré ìmárale, a jẹ́ pé ewu ńlá ṣì wà lórí ẹ.” Kódà, bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Lam ṣe sọ, eré ìmárale níwọ̀n sàn ju kéèyàn má máa ṣe é rárá. Ó dábàá pé ó yẹ kéèyàn yọ ọgbọ̀n ìṣẹ́jú kúrò nínú àkókò tó fi ń jókòó, kó sì máa fi ọgbọ́n ìṣẹ́jú yẹn rìn tàbí kó fi máa tọ́jú ilé.

Àrùn Rẹ́kórẹ́kó Ń Pọ̀ Sí I

Ní Ítálì, ìròyìn tó ń dé sí etígbọ̀ọ́ nípa àìsàn rẹ́kórẹ́kó táwọn èèyàn ń kó látinú ìbálòpọ̀ “ti fi ohun tó ju ìlọ́po méjì pọ̀ sí i lẹ́nu ọdún méjì tó kọjá,” bí ìwé ìròyìn Panorama, ti ilẹ̀ Ítálì, ṣe sọ. Bí Giampiero Carosi, tó darí ìwádìí nípa àwọn àrùn tó máa ń ranni nílẹ̀ olóoru ṣe sọ nílé ẹ̀kọ́ gíga University of Brescia, àwọn ọ̀dọ́ tí èyí sábà máa ń ṣẹlẹ̀ sí làwọn tí ò tíì lọ síbi ètò tó wà fún kíkòòré àrùn éèdì rí, tó sì jẹ́ pé lẹ́yìn tí wọ́n ti tọ́ ìbálòpọ̀ wò fún ìgbà àkọ́kọ́ ni wọ́n tó wá sí ọsibítù. Ìwé ìròyìn Panorama ṣàlàyé pé a rí ìpín ogójì nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tó kó àrùn rẹ́kórẹ́kó tó jẹ́ pé àrùn náà ti burú sí i, ó ti dé ìpele kẹta níbi tí “apá tó bà jẹ́ nínú ara wọn lọ́hùn-ún ti ràn dé ọpọlọ, àyà, inú egungun, oríkèéríkèé ara, ojú àti ẹ̀dọ̀.”