Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ti Rí Ohun Tó Sàn Jù

Àwa Ti Rí Ohun Tó Sàn Jù

Àwa Ti Rí Ohun Tó Sàn Jù

GẸ́GẸ́ BÍ FRANCIS DEL ROSARIO DE PÁEZ ṢE SỌ Ọ́

Lọ́dún 1988, èmi àtàwọn bùrọ̀dá mi pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ akọrin mìíràn kọrin níwájú ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ní gbàgede ìwòran kan tí wọ́n ń pè ní Madison Square Garden nílùú New York City. Ijó tí mo jó lọ́jọ́ náà mú kí ẹgbẹ́ wa gbayì gan-an. Látìgbà tá a ti wà ní kékeré ni Baba wa ti ṣètò bọ́wọ́ wa ṣe máa tẹ́nu fún wa.

NÍWỌ̀N bí bàbá wa fúnra ẹ̀ ti jẹ́ olórin, ó ti ṣàkíyèsí pé àwọn bùrọ̀dá mi méjèèje lẹ́bùn orín. Nítorí náà, ó ta ilé wa, ó sì ra àwọn ohun èèlò ìkọrin àtàwọn irin iṣẹ́ tí wọ́n á nílò láti lè dá ẹgbẹ́ tiwọn sílẹ̀. Lásìkò tí mò ń sọ yìí, mo kéré gan-an, torí kò tíì pẹ́ tí wọ́n bí mi, ìyẹn níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1966. Ìlú Higüey lórílẹ̀-èdè Dominican Republic là ń gbé nígbà yẹn.

Inú gbọ̀ngàn ìlú Higüey làwọn bùrọ̀dá mi ti kọ́kọ́ kọrin lọ́dún 1978. Nígbà tó yá, wọ́n ṣí lọ sí Santo Domingo tó jẹ́ olú ìlú Higüey, ibẹ̀ ni wọ́n ń gbé, ibẹ̀ náà ni wọ́n sì ti máa ń kọrin. Àrà ọ̀tọ̀ lorin merengue tiwọn, ìyẹn sì mú kí wọ́n gbajúmọ̀ nílé lóko. a Bó ṣe di pé àwọn èèyàn ń pè wọ́n ní Los Hermanos Rosario, ìyẹn Ẹgbẹ́ Akọrin Àwọn Ọmọ Rosario, nìyẹn o.

Níwọ̀n bó ti wù mí kí n di alájòótà táyé mọ̀, mo fẹ́ dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ akọrin táwọn ẹ̀gbọ́n mi dá sílẹ̀. Lóde àríyá kan, bùrọ̀dá mi Pepe, tó jẹ́ aṣáájú ẹgbẹ́ náà ní kí ń wá jó, ó ní: “Ṣẹ́ ẹ rí sisí tẹ́ ẹ̀ ń wò yìí, kòkòrò ni, Francis lorúkọ ẹ̀, òun sì ni àbíkẹ́yìn àwọn òbí wa.” Gbogbo èèyàn tó wá wòran ijó yẹn ló gbádùn mi. Ìyẹn ló jẹ́ kí n sọ fún bùrọ̀dá mi Pepe pé kó kúkú jẹ́ kí n máa jó níwájú Ẹgbẹ́ Akọrin Àwọn Ọmọ Rosario. Nítorí náà, lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún mo bẹ̀rẹ̀ sí jó fún wọn ní gbogbo òde eré tá a bá lọ.

Bá A Ṣe Mókè Nídìí Iṣẹ́ Orin

Ṣáájú ìgbà tí mò ń sọ yìí làwọn obìnrin tó ń kọrin merengue ti wà, àmọ́ kò tíì sí obìnrin èyíkéyìí tó ń jó níwájú èrò ìwòran tó jẹ́ kìkì dá ọkùnrin. Ó ní bí mo ṣe máa ń gbẹ́sẹ̀ ijó orin kọ̀ọ̀kan, ijó tuntun tí mo gbé dóde yìí ni mo sì máa ń jó sí orin wa. Ìgbà táwọn èèyàn wá mọ ọ̀nà tí mò ń gbà jó yìí dunjú, ni wọ́n bá fún un lórúkọ, wọ́n pè é ní a lo Francis Rosario, ìyẹn ni ijó Francis Rosario.

A kọ orin merengue kan tá a pè ní “Cumandé,” díẹ̀ lára ọ̀rọ̀ orin ọ̀hún rèé: “Y ahora todo el mundo como Francis Rosario,” èyí tó túmọ̀ sí pé káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ kí wọ́n mújó Rosario. Àwọn èèyàn á wá bẹ̀rẹ̀ sí jó bí mo ṣe ń jó gẹ́lẹ́. Nígbà míì, ṣe ni wọ́n á kàn jókòó sílẹ̀ tí wọ́n á sì máa wò mí dípò káwọn fúnra wọn máa jó. Nígbà tó tiẹ̀ yá, fọ́tò mi nìkan lẹgbẹ́ wa fi ń kéde ọjọ́ tá a máa kọrin. Báwọn èèyàn bá sì ti rí fọ́tò náà báyìí, wọ́n ti mọ̀ pé Ẹgbẹ́ Akọrin Àwọn Ọmọ Rosario fẹ́ ṣeré nìyẹn.

Ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí jó fún ẹgbẹ́ akọrin yìí làwọn akọrin mìíràn tún dara pọ̀ mọ́ wa. Lára wọn ni àwọn mẹ́ta tó jẹ́ ọmọ ìyá kan náà tórúkọ baba wọn ń jẹ́ Páez. Ọ̀kan nínú wọn tó ń jẹ́ Roberto máa ń fun kàkàkí, òun sì ni mo pàpà fẹ́. Báwọn ọmọ Páez náà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí jọlá ẹgbẹ́ wa nìyẹn o. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fìwé pè wá pé kẹ́gbẹ́ wa wá kọrin lórí tẹlifíṣọ̀n tó wà nílùú Santo Domingo, bákan náà ni wọ́n ń pè wá láti kọrin láwọn orílẹ̀-èdè míì káàkiri.

Lọ́dún 1988, a gbé orin wa lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti Kánádà. Ọ̀kan lára irú òde eré bẹ́ẹ̀ lèyí tí mo sọ níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ yìí pé a ṣe ní gbàgede Madison Square Garden. Ọ̀pọ̀ àwọn gbajúmọ̀ olórin merengue ló kọrin lọ́jọ́ náà, àmọ́ ẹgbẹ́ tiwa ló gbégbá orókè. Lẹ́yìn àríyá ọjọ́ yẹn, àwa làwọn tó ń ṣètò àríyá máa ń fẹ́ ká kọrin kẹ́yìn. Òkìkí ijó mi ṣáà ń kàn sí i ni ṣáá, bẹ́ẹ̀ làwọn tó ń fẹ́ ti Ẹgbẹ́ Akọrin Àwọn Ọmọ Rosario náà ń pọ̀ sí i. Bákan náà làwọn rẹ́kọ́ọ̀dù orin wa túbọ̀ ń tà wàràwàrà.

A tún gbé orin wa lọ sáwọn orílẹ̀-èdè bíi Kòlóńbíà, Ecuador, Panama, Puerto Rico, Curaçao, Sípéènì, Jámánì àtàwọn orílẹ̀-èdè míì. Kò pẹ́ tá a fi di ọ̀kan lára ẹgbẹ́ akọrin tó gbajúmọ̀ jù lọ ní gbogbo agbègbè Latin Amẹ́ríkà. Kò wá sí nǹkan míì tí mò ń fi orí mi rò nígbà yẹn ju ijó, orí ìtàgé, bí màá ṣe máa múra àti bí màá ṣe ṣara mi lóge.

Ohun tí mo sábà máa ń sọ nígbà tí mo ṣì wà ní sisí ni pé ọkùnrin tó bá máa fẹ́ mi gbọ́dọ̀ múra àtifẹ́ mi pẹ̀lú ijó mi, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó tẹ́ mi lọ́rùn kí n wà láìlọ́kọ ju pé kí n ṣíwọ́ ijó jíjó lọ. Àmọ́ kò ní pẹ́ tí ohun tó ṣe pàtàkì nínú ìgbésí ayé mi á fi yí padà.

Ojú Mi Là sí Nǹkan Tẹ̀mí

Ọdún 1991 ni àyípadà yìí wáyé nígbà tá a gbé eré wa lọ sí àgbáríjọ erékùṣù kan tí wọ́n ń pè ní Canary Islands. Èmi àti ọkọ mi ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó ni. Àṣé ẹ̀gbọ́n ọkọ mi tó ń jẹ́ Freddy, tóun náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wa, ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìwé wọn kì í sì í wọ́n lọ́dọ̀ rẹ̀.

Lọ́jọ́ kan, mo rí ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye nínú yàrá ẹ̀gbọ́n ọkọ mi yìí, ni mo bá bẹ̀rẹ̀ sí kà á. Àkòrí kan tó sọ pé “Iru Ibo Ni Hell Jẹ?” fà mí mọ́ra gan-an. Mo fara balẹ̀ ka àkòrí yẹn torí Màmá ti sọ fún mi pé inú hẹ́ẹ̀lì ni wọ́n ti máa ń dáná sun èèyàn burúkú tó bá kú. Àtìgbà yẹn lẹ̀rù ti ń bà mí torí èmi ò fẹ́ lọ síbẹ̀.

Kò ju ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sígbà yẹn, nígbà tá a ṣì wà ní erékùṣù Canary Islands, oyún inú mi wálẹ̀. Nígbà tí mo ṣì wà ní ọsibítù mo ní kí ọkọ mi bá mi yá ìwé tí mo rí nínú yàrá ẹ̀gbọ́n rẹ̀ wá. Mo fẹ́ máa kà á bí ara mi bá ṣe ń mókun sí i. Mo gbádùn ìwé náà gan-an ni. Lára àwọn nǹkan tí mo rí kọ́ nínú ìwé náà ni pé ohun tó ń jẹ́ hẹ́ẹ̀lì kò ju ipò òkú àti pé Ọlọ́run kò fìgbà kan rí ronú àtimáa dá àwọn èèyàn lóró nínú iná. (Jeremáyà 7:31) Mi ò lè sọ bó ṣe dùn mọ́ mi tó nígbà tí mo kà á nínú Bíbélì pé àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá.—Oníwàásù 9:5, 10.

Nígbà tá a padà sí orílẹ̀-èdè Dominican Republic, ẹ̀gbọ́n ọkọ mi yẹn ní kí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wá bẹ̀ wá wò. Ó ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé, èyí sì mú kí ọkọ mi fẹ́ mọ̀ sí i. (Sáàmù 37:29; Lúùkù 23:43) A ní kí wọ́n wá máa kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Bí Ohun Tó Ṣe Pàtàkì sí Mi Ṣe Yí Padà.

Bí mo ṣe ń ní ìmọ̀ kún ìmọ̀ nínú Bíbélì ni èrò mi nípa iṣẹ́ tí mo fẹ́ràn jù lọ yẹn bẹ̀rẹ̀ sí yí padà. Ìlànà Bíbélì wá mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí ṣàtúnṣe ọ̀nà tí mo gbà ń ronú. (Róòmù 12:2) Mo máa ń bi ara mi pé: ‘Ǹjẹ́ ó yẹ káwọn èèyàn tún máa rí mi nídìí irú ijó yìí ṣáá? Kò tọ́ sí mi.’ Mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé, “Dákun gbà mí lọ́wọ́ ìgbésí ayé rádaràda yìí o.” Mo sọ bó ṣe ń ṣe mí fọ́kọ mi láìmọ̀ pé bó ṣe ń ṣe òun náà nìyẹn. Ó pè mí, ó ní “Olólùfẹ́, ṣó o mọ̀ pé ohun a fẹ̀sọ̀ mú kì í bàjẹ́, ìwọ ni kó o kọ́kọ́ sọ pé o ò ṣẹgbẹ́ mọ́, èmi náà á sì kúrò.”

Mo tún finú ṣoyún, níwọ̀n bí ìyẹn sì ti máa mú kí n dín ijó tí mò ń jó kù, ó wá jẹ́ kí n túbọ̀ máa rí àyè lọ sí ìpàdé Kristẹni ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Èyí mú kí èmi àti ọkọ mi lókun nípa tẹ̀mí ká sì mọyì àǹfààní ńlá tó wà nínú kéèyàn máa péjọ déédéé pẹ̀lú àwọn èèyàn Jèhófà. Ó wá yé wa pé ká tó lè máa tẹ̀ síwájú lójú ọ̀nà òtítọ́, a nílò ìtọ́ni àti ìṣírí tá à ń rí gbà láwọn ìpàdé Kristẹni. (Hébérù 10:24, 25) Kódà nígbà tí iṣẹ́ bá gbé wa kúrò ní orílẹ̀-èdè Dominican Republic, èmi àti ọkọ mi máa ń rí i pé a wá Gbọ̀ngàn Ìjọba kàn, a sì máa ń lọ sí ìpàdé.

Mo padà sẹ́nu iṣẹ́ lẹ́yìn tí mo bímọ ṣùgbọ́n iṣẹ́ ọ̀hún ti yọ kúrò lọ́kàn mi. Àwọn èèyàn mọ̀ pé ìṣesí mi ti yàtọ̀. Àwọn akọ̀ròyìn sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ oríṣiríṣi nǹkan nípa mi. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń bi mí pé, “O ò fara jó bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, ṣé kò sí?” Mo kàn ṣáà ń gbàdúrà sí Jèhófà ni pé kó dákun kọ́ mi mọ̀ọ́ṣe torí mi ò fẹ́ kí wàhálà bẹ́ sílẹ̀ láàárín èmi àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi. Lásìkò yẹn, èmi náà ti di ọ̀kan lára àwọn tó ni ẹgbẹ́ náà, mi ò sí fẹ́ nǹkan tó máa dá ìjà sílẹ̀ láàárín wa.

Ìgbà tí mo tún lóyún , mo sọ fún Bùrọ̀dá Rafa, tó di alákòóso ẹgbẹ́ wa lẹ́yìn tí Bùrọ̀dá Pepe kú, pé mo fẹ́ máa lo àkókò púpọ̀ sí i pẹ̀lú àwọn ọmọ mi nílé àti pé mi ò ní lè máa wá síbi iṣẹ́ mọ́. Kò tiẹ̀ bá mi janpata, tinútinú ló fi yọ̀ǹda mi. Kò sẹ́ni tó tako ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mò ń kọ́ nínú àwọn ẹ̀gbọ́n mi. Mo dúpẹ́ gidigidi fún ìyẹn.

Ìgbésí Ayé Ọ̀tun Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà

Lọ́dún 1993, lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí mo ti wà nínú ẹgbẹ́ yẹn, mo fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀, mo sì ya ara mi sí mímọ́ pátápátá fún Jèhófà. Mo di akéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, èmi àti ọkọ mi sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1994 lẹ́yìn tó ti kúrò nínú ẹgbẹ́ náà. (Mátíù 24:14) Àwọn ẹ̀gbọ́n ọkọ mi méjì, Bùrọ̀dá Freddy àti Bùrọ̀dá Julio, náà di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, bákan náà sì ni ọmọ ẹgbẹ́ wa kan tó ń jẹ́ Manuel Pérez. Gbogbo wọn ló ṣì ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà títí dòní.

Ọ̀pọ̀ ló ṣì ń rú lójú bí mo ṣe ní láti fi iṣẹ́ tí mo gbádùn tóyẹn sílẹ̀. Àwọn kan, tó fi mọ́ olóòtú ètò orí tẹlifíṣọ̀n kan táwọn èèyàn mọ́ bí ẹní mowó lórílẹ̀-èdè wa, tiẹ̀ sọ pé mo máa tó o yí i dá, pé ó ṣì ń ṣe mí bẹ́ẹ̀ ni. Ó sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé: “Bí gbogbo àwọn òṣèré yẹn ṣe máa ń ṣe nìyẹn, ó máa tó padà sídìí iṣẹ́ ẹ̀.” Ṣùgbọ́n ibi tó fojú sí, ọ̀nà ò gbabẹ̀. Mo ti pinnu pé Jèhófà ni màá sìn pẹ̀lú gbogbo agbára mi.

Ọmọ mẹ́ta ni Ọlọ́run fi ta wá lọ́rẹ, àwọn ni Katty, Roberto àti Obed. À ń sapá láti kọ́ wọn pé àwọn nǹkan tẹ̀mí ṣe pàtàkì nígbèésí ayé ju tara lọ. Ìrírí wa ti jẹ́ ká lè tọ́ wọn lọ́nà tí wọn ò fi ní jẹ́ kí ohun tó wà nínú ayé ṣì wọ́n lọ́nà. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ìdílé wa máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ti ràn wá lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀, ó ti jẹ́ ká lè máa ṣe àwọn nǹkan pa pọ̀ láìka báwọn ìdílé ṣe túbọ̀ ń pínyà láyé tá a wà yìí sí.

A ti sapá láti kọ́ àwọn ọmọ wa pé Jèhófà lẹnì kan ṣoṣo tí wọ́n lè fọkàn tán. (Òwe 3:5, 6; Hébérù 11:27) A tún ti kọ́ wọn bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n máa pésẹ̀ sí gbogbo ìpàdé Kristẹni kí wọ́n sì máa lóhùn sí i. Àǹfààní tí ò ṣeé díye lé ló jẹ́ fún wa bá a ṣe ń rí i táwọn ọmọ wa ń tẹ̀ síwájú nínú òtítọ́. Látọdún méjì sẹ́yìn ni mo ti ń sìn bí aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, ìyẹn orúkọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pe ẹni tó ń fi àádọ́ta wákàtí tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lóṣù wàásù òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Ọkọ mi sì ti ń sìn bí alàgbà nínú Ìjọ fún bí ọdún mélòó kan báyìí.

Mo ṣì ka ijó merengue sí ijó tó dáa. Ó kàn jẹ́ pé merengue tí wọ́n ń jó lóde òní ti wá yàtọ̀ sí tìgbà yẹn. Nígbà yẹn, ijó tó dáa fún ọmọlúwàbí ni. Ìyẹn ló ṣe jẹ́ pé ká tó lè fetí sí orin merengue èyíkéyìí lásìkò yìí, a máa ń yẹ̀ ẹ́ wò dáadáa.

Ìjọsìn Jèhófà La Fi Ṣáájú

Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà nínú ayé ṣùgbọ́n èèyàn gbọ́dọ̀ fojú balẹ̀ dáadáa kó tó o dáwọ́ lé ohunkóhun. Pàápàá jù lọ nídìí orin, tó jẹ́ pé ó máa ń fa èèyàn mọ́ra táá sì dà bíi pé kó lè ṣàkóbá kankan. Síbẹ̀, ẹ̀tàn gbáà ni. Ọ̀pọ̀ akọrin ló máa ń lo oògùn olóró tó sì máa ń ṣèṣekúṣe. Béèyàn bá wá ń bá wọn dòwò pọ̀, ṣe lonítọ̀hún náà ń gbé ìgbésí ayé jayé orí ẹ, pẹ̀lú àwọn tí ò ní ẹ̀rí ọkàn kankan.—1 Kọ́ríńtì 15:33.

Ó ti wá yé wa pé kò sóhun míì tó dáa tó kéèyàn sin Jèhófà. Mo rántí ọjọ́ kan tí mo padà sí òtẹ́ẹ̀lì tá a dé sí lẹ́yìn ijó tó tíì yẹ mí jù lọ láyé, tí gbogbo nǹkan sì dédé sú mi wá. Mo wá rí i pé àìfi àwọn ohun tẹ̀mí sí àyè tó yẹ wọ́n ló fà á.—Mátíù 5:3.

Ohun tá a gbájú mọ́ báyìí ni ṣíṣe ohun tí Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ nìṣó pàápàá iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ àwọn èèyàn ní ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 24:14; Ìṣe 20:35) Iṣẹ́ ìwàásù yìí ń mú kí ìdílé wa láyọ̀ ká sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. A dúpẹ́, a tọ́pẹ́ dá, pé a wà láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run àti pé a ní àwọn ojúlówó ọ̀rẹ́, ìyẹn àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nínú ìgbàgbọ́, àwọn tá a jọ ń retí ìyè àìnípẹ̀kun ológo nínú ayé tuntun Ọlọ́run.—Máàkù 10:29, 30; 2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:3, 4.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a rí towó ṣe dáadáa nídìí iṣẹ́ orin, ọrọ̀ tẹ̀mí tá a ní nígbà tá a mọ Ọlọ́run wa, Jèhófà ṣe pàtàkì púpọ̀ lójú wa ju ọrọ̀ yòówù nípa tara lọ. A ò lè sọ bínú wa ṣe dùn tó pé ó ṣeé ṣe fún wa láti sin Ọlọ́run tó fẹ́ wa fẹ́re, Ọlọ́run aláyọ̀ tó jẹ́ pé òun fúnra ẹ̀ ló ní ká gbọ́kàn lé òun! (Sáàmù 37:3) Kò ní pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ ń sọ, a ti rí ohun tó sàn gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ju òkìkí àti ọ̀rọ̀ lọ, ẹ̀bẹ̀ wa kàn ni pé kí Jèhófà má ṣe ṣíwọ́ àánú rẹ̀ lórí àwa àti ìdílé wa ká lè máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ títí ayé.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orin tí wọ́n máa ń jó sí ní merengue. Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ orin merengue náà ni pé àwọn akọrin mélòó kan á máa fi dùùrù tàbí ohun èlò ìkọrin olóhùn agogo kọ orin ọ̀hún tí wọ́n á sì máa lu ìlù tambora sí i (ìyẹn ìlù kékeré olójú méjì kan báyìí). Nígbà tó ṣe, àwọn ẹgbẹ́ akọrin ńláńlá míì (táwọn ará Dominican Republic mọ̀ sí orquestas) bẹ̀rẹ̀ sì dá eré sílẹ̀. Ní báyìí, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń kọ irú orin yìí ló ti ń lo ohun èlò ìkọrin bíi dùrù, fèrè gígùn tó rí kọdọrọ, kàkàkí, oríṣiríṣi ìlù kongá àtàwọn ohun èlò ìkọrin mìíràn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Èmi àtàwọn ọmọ ẹgbẹ́ wa rèé nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn ròde eré

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Nígbà tá à ń kọrin nílùú New York City, ní bí ọdún 1990

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Níwájú Gbọ̀ngàn Ìjọba

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Inú àkámọ́: Nígbà tá à ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé