Ẹ̀rí Ọkàn Rere Ń Fògo fún Ọlọ́run
Ẹ̀rí Ọkàn Rere Ń Fògo fún Ọlọ́run
LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ UKRAINE
NÍGBÀ tí Chibisov àti ìdílé rẹ̀ ń darí bọ̀ láti ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n rí pọ́ọ̀sì kan táwọn nǹkan tó ṣeyebíye wà nínú ẹ̀, ìyẹn àwọn nǹkan bí ìwé àṣẹ ìwakọ̀, káàdì ìrajà àti owó tí wọ́n ń ná ní ilẹ̀ wọn tó tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún dọ́là. Nínú ìdílé ẹlẹ́ni márùn-ún yìí, ọkọ nìkan ló níṣẹ́ lọ́wọ́. Owó oṣù rẹ̀ kò sì ju bí àádọ́rin dọ́là lọ. Nítorí náà, ìfà gbáà lówó tí wọ́n rí he yìí ì bá jẹ́ fún wọn. Báwo ni wọ́n ṣe wá ṣowó ọ̀hún?
Màmá àwọn ọmọ náà sọ pé: “Kíá làwọn ọmọbìnrin wa ti ń dábàá bá a ṣe máa dá pọ́ọ̀sì ọ̀hún padà fẹ́ni tó ni ín. Fọ́tò obìnrin tó ní in sì wà nínú ìwé àṣẹ ìwakọ̀ tó wà nínú pọ́ọ̀sì náà. Inú èmi àtọkọ mi dùn pé àwọn ọmọ wa ní irú ẹ̀rí ọkàn rere bẹ́ẹ̀. Lọ́jọ́ kejì, mo tẹ obìnrin tó ni pọ́ọ̀sì náà láago pé a ti bá a rí i. Omijé ayọ̀ wà lójú Olha nígbà tó dé ọ̀dọ̀ wa, ó sọ pé òun àtọkọ òun ní àwọn ṣọ́ọ̀bù kéékèèké bíi mélòó kan nílùú yẹn táwọn ti ń tajà. Ó fi kún un pé owó táwọn fẹ́ fi sanwó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ ló wà nínú pọ́ọ̀sì náà. Àti pé ìwé àkọsílẹ̀ kan tó ṣe pàtàkì fún òwò tí wọ́n ń ṣe wà nínú pọ́ọ̀sì yẹn.
“Ó béèrè ibi tá a ti rí pọ́ọ̀sì náà lọ́wọ́ wa. A sọ ibẹ̀ fún un, a sì jẹ́ kó mọ̀ pé ìgbà tá à ń darí bọ̀ láti ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la gbabẹ̀ kọjá. A fún un láwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀, ó sì gbà á tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.
“Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀, Kristẹni kan tá a jọ wà nínú ìjọ sọ pé nígbà tóun ń fi àwọn ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì lọ àwọn èèyàn ní òpópónà, òun rí obìnrin kan tó sọ fóun pé, ká ní ìgbà kan ni, òun kì í dúró gbọ́ tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣùgbọ́n lọ́wọ́ yìí, òun máa ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, òun sì tún máa ń gbàwé. Ó ní ìdí ni pé, Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló bá ọmọbìnrin òun rí pọ́ọ̀sì rẹ̀ tó sọnù.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ìdílé Chibisov