Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìjẹ́rìí Tó Fa Kíki Látẹnu Àwọn Ọ̀dọ́

Ìjẹ́rìí Tó Fa Kíki Látẹnu Àwọn Ọ̀dọ́

Ìjẹ́rìí Tó Fa Kíki Látẹnu Àwọn Ọ̀dọ́

Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń fìgboyà wàásù ohun tí wọ́n gbà gbọ́ nílé ẹ̀kọ́ àti lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni, wọ́n sì ti ṣàṣeyọrí lọ́pọ̀lọpọ̀. Ẹ jẹ́ ká yẹ àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ wò. a

Kristina sọ pé: “Nígbà tí mo ṣì wà ní kíláàsì kẹta nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, tíṣà wa fún èmi àtàwọn tá a jọ wà ní kíláàsì ní ìwé kan, ó sì ní ká máa kọ àwọn nǹkan tá a bá ń ṣe lójoojúmọ́ síbẹ̀. Olùkọ́ náà á ka ohun tá a kọ, á kọ ọ̀rọ̀ tiẹ̀ sí i, á sì dá a padà fún wa. Mo pinnu láti kọ nǹkan nípa iṣẹ́ tí mo ní ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run sínú ìwé náà. Ó dà bíi pé ohun tí mo kọ náà dùn mọ́ tíṣà wa nínú gan-an, mo bá kúkú ní kó wá gbọ́ bí màá ṣe ṣiṣẹ́ náà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Òun nìkan kọ́ ló wá, tíṣà tó kọ́ mi ní kíláàsì àkọ́kọ́ náà wá. Nígbà tá a padà délé ẹ̀kọ́, tíṣà wa sọ́ fáwọn tá a jọ wà ní kíláàsì pé òun gbádùn iṣẹ́ mi gan-an ni. Inú mi dùn jọjọ. Àmọ́, ibẹ̀ kọ́ lọ̀rọ̀ parí sí o. Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, mo láǹfààní láti sọ ìrírí mi ní àpéjọ àyíká táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe, tíṣà mi yẹn náà sì wá síbẹ̀. Nígbà tó ṣe, èmi àtọ̀rẹ́ mi kan tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà lọ bẹ̀ ẹ́ wò a sì fún un ní ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Kódà, ó ti bá wa ṣe àpéjọ àgbègbè kan rí!”

Látìgbà tí Sydnee ti wà lọ́mọ ọdún mẹ́fà ló ti mọ bó ṣe máa ń fìgboyà bá àwọn tí wọ́n jọ wà ní kíláàsì jíròrò òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bí ipò táwọn òkú wà, àti bí Jésù ṣe jẹ́ sí Ọlọ́run. Màmá rẹ̀ sọ pé: “Ọmọbìnrin wa máa ń fìgboyà wàásù, ó sì nítara púpọ̀.” Nígbà tó kù díẹ̀ kí Sydnee jáde kíláàsì àkọ́kọ́ nílé ẹ̀kọ́, ó sọ ohun kan tó ń dùn ún pé: “Ọ̀rọ̀ àwọn tá a jọ wà ní kíláàsì ń dùn mí. Báwo ni wọ́n á ṣe mọ Jèhófà báyìí o?” Ohun kan wá sọ sí Sydnee lọ́kàn. Lọ́jọ́ tí kíláàsì àkọ́kọ́ parí gan-an, ó fún akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀bùn kan tó fi nǹkan wé. Iwe Itan Bibeli Mi ló wà níbẹ̀. Àpapọ̀ èyí tó fún wọn jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, ó sì sọ fún wọn pé bí wọ́n bá délé, àwọn àtàwọn òbí wọn ni kí wọ́n jọ já ẹ̀bùn náà. Ńṣe ni Sydnee ń wo àwọn tí wọ́n jọ wà ní kíláàsì bíi pé ìpínlẹ̀ ìwàásù òun ni wọ́n wà. Kódà, ó máa ń pè wọ́n lórí fóònù láti béèrè bí wọ́n ṣe ń gbádùn kíka ìwé náà sí. Ọmọdébìnrin kan sọ fún un pé òun àti màmá òun làwọn jọ máa ń ka tòun lálaalẹ́.

Nígbà tí Ellen wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ó fún tíṣà tó ń kọ́ ọ ní ìtàn ní ìwé ìròyìn Jí! mélòó kan. Ellen sọ pé: “Ó fẹ́ràn àwọn ìwé ìròyìn náà gan-an, ó sì ti pé ọdún méjì báyìí tó ti ń ka Jí!” Ellen ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Láìpẹ́ yìí, mo fún un ní Iwe Itan Bibeli Mi, ó sì sọ fún mi pé àwọn ọmọbìnrin òun méjì ń gbádùn kíka ìwé náà gidigidi. Nítorí náà, mo fún un ní ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Lẹ́yìn náà, ó fún mi ní káàdì ìkíni. Ó sọ nínú káàdì náà pé: ‘O ṣeun gan-an, mo mọrírì àwọn ìwé tó o fún wa. Èmi àtàwọn ọmọ mi ò lè ṣe ká má kà wọ́n. Inú mi dùn láti mọ ọ̀dọ́mọbìnrin bíi tìẹ, orí ẹ pé o sì fọkàn sí ohun tó ò ń ṣe. Kò sí ẹ̀bùn tá a lè fi wé ẹ̀bùn ìgbàgbọ́ tó o rí gbà. Ohun tó o ti kọ́ mi tiẹ̀ ti wá pọ̀ ju ohun tí mi ò bá kọ́ ẹ lọ!’ Ìrírí yìí jẹ́ kí n rí báwọn èèyàn ṣe máa ń mọrírì òtítọ́ Bíbélì tó, nígbà tá a bá sapá láti fi hàn wọ́n.”

Ọmọ ọdún mẹ́fà ni Daniel nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí dárí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó sọ pé: “Màmá mi ló ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ èmi náà ń wá ẹni tí màá kọ́.” Daniel yàn láti ṣèkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú Ìyáàfin Ratcliff, ìyá arúgbó kan tó fún níwèé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó sọ fún ìyá arúgbó náà pé: “Màá fẹ́ láti fi ìwé tí mo fẹ́ràn hàn yín, Iwe Itan Bibeli Mi lorúkọ rẹ̀.” Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ jẹ́ kí n mọ̀ bẹ́ ẹ bá máa fẹ́ kí n wá máa kà á fún yín lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.” Ìyáàfin Ratcliff gbà pé kí Daniel wá máa kàwé náà fóun. Laura, ìyá Daniel, sọ pé: “Kílẹ̀ ọjọ́ yẹn tó ṣú, a bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ Ìyáàfin Ratcliff lẹ́kọ̀ọ́. Daniel àti Ìyáàfin Ratcliff ni wọ́n jọ máa ń pín àwọn ìpínrọ̀ inú ìwé náà kà, lẹ́yìn náà ni Daniel á ní kó ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n fà yọ ní ìparí ìtàn náà. Mo ti bá Daniel lọ rí, ṣùgbọ́n ó dà bíi pé Ìyáàfin Ratcliff ṣáà ń fẹ́ kó jẹ́ pé òun àti ọmọkùnrin mi làwọn á jọ máa jíròrò ohun tó wà nínú ìwé náà!” Nígbà tó ṣe, Daniel àti Ìyáàfin Ratcliff bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Nígbà tí Daniel àti màmá Ratcliff bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí, Natalie, àbúrò rẹ̀ obìnrin ti mọ ìwé kà, òun náà sì máa ń wà pẹ̀lú wọn bí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà bá ń lọ lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ ìbéèrè ló ń jà gùdù lọ́kàn Ìyáàfin Ratcliff, àwọn kan nínú wọn sì díjú gan-an. Ṣùgbọ́n Daniel àti Natalie máa ń lo ìwé kékeré Awọn Akori Ọrọ Bibeli Fun Ijiroro àti atọ́ka tó wà lẹ́yìn Bíbélì láti dáhùn àwọn ìbéèrè náà lọ́nà tó bá Ìwé Mímọ́ mu. Yùngbà làwọn ẹ̀kọ́ tí Ìyáàfin Ratcliff ń kọ́ máa ń dùn mọ́ ọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ṣe ẹ̀sìn míì rí yàtọ̀ sí ẹ̀sìn Kátólíìkì. Bí wọ́n ṣe kẹ́kọ̀ọ́ tán lọ́jọ́ kan báyìí, ó sọ pé: “Ó dà bíi kó jẹ́ pé ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì!” Ó bani nínú jẹ́ pé láìpẹ́ yìí ni Ìyáàfin Ratcliff ṣaláìsí. Ọmọ ọdún mọ́kànléláàádọ́rùn-ún ni kó tó kú. Àmọ́, ẹ̀kọ́ Bíbélì tó kọ́ ti jẹ́ kó mọ àwọn òtítọ́ ṣíṣeyebíye, tó fi mọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì pé àwọn òkú yóò jíǹde sínú párádísè ilẹ̀ ayé. Ọmọ ọdún mẹ́wàá ni Daniel báyìí, ó sì ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì méjì. Natalie, tóun náà ti pé ọmọ ọdún mẹ́jọ báyìí, ń bá ọmọdébìnrin kan tí wọ́n jọ jẹ́ ẹgbẹ́ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́.

Àwọn ọ̀dọ́ bíi ti Kristina, Sydnee, Ellen, Daniel àti Natalie máa ń múnú àwọn òbí wọn tó jẹ́ Kristẹni dùn. Èyí tó tún wá ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, wọ́n ń múnú Jèhófà dùn, kò sì ní gbàgbé ìfẹ́ tírú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ ń fi hàn fún orúkọ rẹ̀.—Òwe 27:11; Hébérù 6:10.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ gbogbo ìwé tá a tọ́ka sí pátá nínú àpilẹ̀kọ yìí.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Kristina (lókè) àti Sydnee

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Daniel àti Natalie

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ellen