Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Ó Dùn Mí Pé Mi Ò Tètè Jáwọ́’

‘Ó Dùn Mí Pé Mi Ò Tètè Jáwọ́’

‘Ó Dùn Mí Pé Mi Ò Tètè Jáwọ́’

Àwọn tó pè é ní ohun tó máa ń di bárakú ò ṣì sọ rárá. Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wọ́n rí i pé àwọn ọmọkùnrin ọlọ́dún mẹ́tàlá kan tí wọ́n wà nílé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, ń lo bíi wákàtí mẹ́tàlélógún lọ́sẹ̀ nídìí eré ìdárayá orí fídíò tàbí ti kọ̀ǹpútà. Ó ti wọ ọ̀pọ̀ àwọn tó dàgbà náà lẹ́wù. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ti Kristẹni kan tó ń jẹ́ Charles. a Ó sọ pé: “Ní tèmi o, mo máa ń fi eré ìdárayá orí fídíò tàbí ti kọ̀ǹpútà pàrònú rẹ́ ni, kí n lè ráyè sinmi kí n sì ṣe bí mo ṣe fẹ́. Ṣùgbọ́n ó ti kó sí mi lórí. Báwọn kan ò ṣe lè ṣe kí wọ́n má mu oògùn olóró tàbí ọtí líle, bẹ́ẹ̀ lèmi náà ò ṣe lè ṣe kí n má ṣe eré ìdárayá orí fídíò.”

Charles sọ pé nígbà tóun wà lọ́mọ ọdún mọ́kànlá, “gbogbo ìgbà ṣáá” lòun máa ń ṣe eré náà. Ó ní: “N kì í bá wọn ṣe eré tó la ẹ̀mí èṣù lọ tàbí èyí tí wọ́n ń hùwà ipá nínú ẹ̀ o, àmọ́ àkókò tí mò ń lò nídìí eré ìdárayá orí fídíò ti pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Àwọn ìgbà míì tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé jálẹ̀ ọ̀sẹ̀, n kì í ronú nǹkan míì mọ́ nílé ìwé, nípàdé àti lóde ẹ̀rí, kọjá bí màá ṣe lọ ṣeré ìdárayá orí kọ̀ǹpútà yẹn yanjú.”

Ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tó wà nínú Jí! December 22, 2002, lédè Gẹ̀ẹ́sì, tó ní àkọlé náà, “Electronic Games—Is There a Dark Side?,” ran Charles lọ́wọ́ gidigidi. Ó sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo kà á tán, mo sapá láti dín àkókò tí mò ń lò nídìí ẹ̀ kù. Àmọ́ ṣá, lẹ́yìn àkókò díẹ̀, mo tún padà sídìí eré ìdárayá yìí bí mo ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀.”

Nígbà tí Charles ń fẹ́ ìyàwó rẹ̀ sọ́nà àti fún ìgbà díẹ̀ lẹ́yìn tó ṣègbéyàwó, ó ṣeé ṣe fún un láti dín ṣíṣe eré ìdárayá orí fídíò kù. “Ṣùgbọ́n,” gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, “lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n gbé eré ìdárayá tuntun tí mo ti ń wọ̀nà fún tipẹ́tipẹ́ jáde. Mo kọrùn bọ gbèsè kí n bàa lè ra kọ̀ǹpútà kan tí mo lè máa gbádùn eré náà lórí ẹ̀. Ìyẹn gan-an sì wá leré ìdárayá orí kọ̀ǹpútà tó tíì gbà mí lákòókò jù lọ rí. Gbogbo àkókò tó yẹ kí n lò fún Jèhófà ló gbà mọ́ mi lọ́wọ́. Mi ò sì tún rí tìyàwó mi rò mọ́.” Kò pẹ́ tí Charles fi rí i pé àfi kóun yáa tètè wá nǹkan ṣe sí i. Ó sọ pé: “Mo pinnu pé màá wábi kó gbogbo eré fídíò náà dà sí. Mo pa gbogbo èyí tó ti wà lórí kọ̀ǹpútà mi rẹ́, mo sì kó gbogbo èyí tó kù dà sí ààtàn.”

Ṣé Charles kábàámọ̀ ìpinnu tó ṣe? Kò sóun tó jọ bẹ́ẹ̀! Ó sọ pé: “Ìtura tó bá mi lẹ́yìn tí mo ṣe bẹ́ẹ̀ tán kò ṣeé fẹnu sọ. Ṣe ló dà bíi pé wọ́n gbé ẹrù tó wúwo kúrò léjìká mi. Mo mọ̀ ọ́n lára pé mo túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, látìgbà yẹn ni mi ò sì ti yé gbàdúrà sí i. Mo ti wá ń rí tìyàwó mi rò báyìí. Ẹnu mi ò gbọpẹ́ pé ó ṣeé ṣe fún mi láti borí àṣà tó ti di bárakú yìí. Ohun kan ṣoṣo tó dùn mí ni pé mi ò tètè jáwọ́.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí orúkọ rẹ̀ padà.