‘Ó Yẹ Kínú Ẹ Dùn sí Nǹkan Tó O Ṣe Yìí’
‘Ó Yẹ Kínú Ẹ Dùn sí Nǹkan Tó O Ṣe Yìí’
ÀWỌN ojúlówó ìránṣẹ́ Ọlọ́run mọ̀ pé kò sí ohun tó dà bíi kéèyàn jẹ́ olóòótọ́. Ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Ẹlẹ́dàá wọn ló sì fà á tí wọ́n fi jẹ́ olóòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká gbé ọ̀ràn Lázaro yẹ̀ wò. Nígbà kan tó ṣì ń ṣiṣẹ́ ní òtẹ́ẹ̀lì ìlú Huatulco lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, ó rí àádọ́rin dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà tí ẹnì kan gbàgbé síbi tó jókòó sí. Lójú ẹsẹ̀ ló ti mú owó náà lọ sọ́dọ̀ ọ̀gá tó wà lẹ́nu iṣẹ́ lọ́jọ́ náà. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ló tún rí pọ́ọ̀sì kan nílé ìwẹ̀. Ó mú ìyẹn náà lọ síbi tí wọ́n ti ń gbàlejò wọlé, ìyàlẹ́nu ló sì jẹ́ fún ẹni tí pọ́ọ̀sì náà sọ nù lọ́wọ́ rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ẹ̀ dùn.
Nígbà tí ọ̀rọ̀ náà dé etígbọ̀ọ́ ọ̀gá pátápátá, ó bi Lázaro léèrè ohun tó sún un tó fi dá owó àti pọ́ọ̀sì náà padà. Lázaro sọ pé ìlànà rere tóun ti kọ́ nínú Bíbélì ni kò jẹ́ kóun tẹ nǹkan tí kì í ṣe tòun rì. Nínú lẹ́tà tí ọ̀gá pátápátá náà fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Lázaro, ó sọ pé: “Lóde òní, ó ṣòro láti rí àwọn èèyàn tó ń hùwà rere. A dúpẹ́ gidigidi fún ohun tó o ṣe yìí. O ti fi hàn pé ọmọlúwàbí èèyàn ni ọ́, àpẹẹrẹ rere lo sì jẹ́ fáwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́. Ó yẹ kínú ìwọ àtàwọn ará ilé rẹ dùn sí nǹkan tó o ṣe yìí.” Bí wọ́n ṣe dá Lázaro lọ́lá gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ tó ṣe dáadáa jù lóṣù yẹn nìyẹn o.
Àwọn òṣìṣẹ́ kan níbi iṣẹ́ Lázaro rò pé àṣìṣe ni dídá tó dá owó àti pọ́ọ̀sì yẹn padà. Àmọ́, lẹ́yìn tí wọ́n rí bó ṣe gbayì gbẹ̀yẹ lọ́wọ́ ọ̀gá pátápátá, wọ́n bá Lázaro yọ̀ pé ó hùwà rere.
Bíbélì gba àwọn olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn Jésù níyànjú pé kí wọ́n máa “ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn” kí wọ́n sì máa “hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Gálátíà 6:10; Hébérù 13:18) Láìsí iyèméjì, bí àwa Kristẹni bá ń hùwà láìṣàbòsí, ìyẹn á máa fìyìn fún Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tí Bíbélì sọ pé ó jẹ́ “olódodo àti adúróṣánṣán.”—Diutarónómì 32:4.