Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣó Yẹ Kó o Máa Gbàdúrà Sí Màríà Wúńdíá?

Ṣó Yẹ Kó o Máa Gbàdúrà Sí Màríà Wúńdíá?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣó Yẹ Kó o Máa Gbàdúrà Sí Màríà Wúńdíá?

Ọ̀PỌ̀ ẹni tí ẹsìn Kristẹni ò bá ṣàjèjì sí ló máa mọ ẹni tó ń jẹ́ Màríà. Ìwé Mímọ́ sọ pé ìbùkún àrà ọ̀tọ̀ ni ọ̀dọ́mọbìnrin yìí rí gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run Olódùmarè nítorí pé ó yàn án láti jẹ́ ìyá Jésù. Ọ̀nà àrà ni Jésù gbà wáyé nítorí pé wúńdíá ni Màríà nígbà tó lóyún rẹ̀. Ọjọ́ ti pẹ́ táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kan ti ń jọ́sìn Màríà lọ́nà àkànṣe. Lọ́dún 431 Sànmánì Kristẹni, Ìgbìmọ̀ Éfésù polongo pé Màríà ni “Ìyá Ọlọ́run,” lóde tòní, wọ́n sì ń kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn láti máa gbàdúrà sí i. a

Àwọn tó ń fòótọ́ inú sin Ọlọ́run mọ̀ pé ẹni tó tọ́ làwọn gbọ́dọ̀ máa darí àdúrà àwọn sí. Kí ni Bíbélì sọ nípa èyí? Ṣó yẹ káwọn Kristẹni máa gbàdúrà sí Màríà Wúńdíá?

“Kọ́ Wa Bí A Ṣe Ń Gbàdúrà”

Àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere Lúùkù sọ pé ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bẹ̀ ẹ́ pé: “Olúwa, kọ́ wa bí a ṣe ń gbàdúrà.” Nínú èsì tí Jésù fún un, ó sọ pé: “Nígbàkigbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ wí pé, ‘Baba, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.’” Nígbà Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè, Jésù tún fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni pé kí wọ́n máa gbàdúrà báyìí: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.”—Lúùkù 11:1, 2; Mátíù 6:9.

Nítorí náà, ohun àkọ́kọ́ tá a rí kọ́ ni pé Jèhófà tí í ṣe Bàbá Jésù la gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà, tàbí darí ọ̀rọ̀ tá a fi ń jọ́sìn Ọlọ́run sí. Kò sí ibòmíì tí Bíbélì ti sọ fún wa pé ká máa gbàdúrà sí ẹlòmíì. Bó sì ṣe yẹ kí ọ̀ràn rí nìyẹn, nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti sọ fún Mósè nígbà tó ń gba Òfin Mẹ́wàá, Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.”—Ẹ́kísódù 20:5.

Àdúrà Tí Wọ́n Ń Fi Ìlẹ̀kẹ̀ Gbà Ńkọ́?

Ohun tí wọ́n fi kọ́ ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbàdúrà sí Màríà ni pé wọ́n á rí ìbùkún gbà bí wọ́n bá ń gba àwọn àdúrà kan ní àgbàtúngbà, ìyẹn àwọn bí, Ẹ Yin Màríà Mímọ́, Àdúrà Olúwa àtàwọn míì bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ní tàwọn Kátólíìkì, ìwé Symbols of Catholicism sọ pé, “kò sí àníàní pé fífi ìlẹ̀kẹ̀ gbàdúrà ni ọ̀nà tó wọ́pọ̀ jù lọ tí wọ́n fi ń jọ́sìn Màríà.” Ara nǹkan tí wọ́n máa ń ṣe nínú ìjọsìn wọn ni fífi ìlẹ̀kẹ̀ gbàdúrà sí Màríà Wúńdíá. Wọ́n máa ń pe okùn tẹ́ẹ́rẹ́ tí wọ́n sín ìlẹ̀kẹ̀ sí tí wọ́n sì máa ń fà bí wọ́n bá ń gbàdúrà ní ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà. Ìwé kan náà yẹn ṣàlàyé pé: “Ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà tó ní àádọ́ta ìlẹ̀kẹ̀ tí wọ́n pín sọ́nà márùn-ún jẹ́ àmì pé kẹ́ni tó ń lo ìlẹ̀kẹ̀ náà máa ka ‘Ẹ Yin Màríà Mímọ́’ nígbà àádọ́ta, kó ka ‘Àdúrà Olúwa’ nígbà márùn-ún, kó sì ka ‘Ògo ni fún Baba’ nígbà márùn-ún.” Ǹjẹ́ inú Ọlọ́run máa ń dùn sí àdúrà téèyàn á ti máa fa ìlẹ̀kẹ̀ táá sì máa sọ àsọtúnsọ?

Àfi ká tún wonú ìtọ́ni tí Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ká tó lè rí ìdáhùn Bíbélì. Jésù sọ fún wọn pé: “Tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè ti ń ṣe, nítorí wọ́n lérò pé a óò gbọ́ tiwọn nítorí lílò tí wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ púpọ̀.” (Mátíù 6:7) Nítorí náà, Jésù sọ ní pàtó fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe máa sọ ọ̀rọ̀ kan náà ní àsọtúnsọ bí wọ́n bá ń gbàdúrà.

Ẹnì kan wá lè béèrè pé, ‘ṣùgbọ́n kí ló wá dé tí Jésù fi kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gba Àdúrà Olúwa,’ tó wà lára ọ̀rọ̀ táwọn tó ń fa ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà máa ń sọ? Lóòótọ́ ni Jésù fúnni ní àpẹẹrẹ bá a ṣeé gbàdúrà, èyí tá a wá mọ̀ sí Bába Wa Tí Ń Bẹ Lọ́run, tàbí Àdúrà Olúwa. Àmọ́, ó yẹ ká mọ̀ pé lẹ́yìn ìkìlọ̀ rẹ̀ pé ká má máa sọ “ohun kan náà ní àsọtúnsọ” ni àdúrà ọ̀hún tó wáyé. A sì tún lè rí i pé àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù lò níbi méjèèjì tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì pé ó ti kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní àdúrà kò jọra. Ẹ̀rí míì nìyẹn jẹ́ pé kò fẹ́ ká máa ka àdúrà àwòkọ́ṣe náà ní àkàsórí. (Mátíù 6:9-15; Lúùkù 11:2-4) Àwọn kókó kan náà ni Jésù ń fà yọ nígbà méjèèjì tó kọ́ wọn ní àdúrà, àmọ́ ọ̀rọ̀ inú àwọn àdúrà náà ò jọra. Èyí lè mú ká parí èrò pé Jésù wulẹ̀ ń fi àwòkọ́ṣe tàbí àpẹẹrẹ lélẹ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni. Èyí á sì mú kí wọ́n lè mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa gbàdúrà àtàwọn ohun tó yẹ kí wọ́n máa gbàdúrà fún. Pabanbarì rẹ̀ wá ni pé, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ ká mọ ẹni tó yẹ ká máa gbàdúrà sí.

Ti Bíbọ̀wọ̀ fún Màríà Ńkọ́?

Ti pé Ìwé Mímọ́ ò kọ́ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa gbàdúrà sí Màríà kò túmọ̀ sí pé a kò mọrírì ipa tó kó nínú mímú àwọn ète Ọlọ́run ṣẹ. Ìbùkún tó máa wà títí ayérayé ni gbogbo aráyé onígbọràn máa rí gbà nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀. Màríà fúnra rẹ̀ sọ pé: “Gbogbo ìran ni yóò máa pè mí ní aláyọ̀.” Èlísábẹ́tì tó jẹ́ ìbátan Màríà náà sọ pé: “Alábùkún ni . . . láàárín àwọn obìnrin.” Alábùkún náà sì ni lóòótọ́. Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ ló jẹ́ fún Màríà pé Ọlọ́run yàn án láti bí Mèsáyà.—Lúùkù 1:42, 48, 49.

Àmọ́ o, kì í ṣe Màríà nìkan ni obìnrin tí Ìwé Mímọ́ pè ní alábùkún o. Nítorí itú tí Jáẹ́lì pa fún àǹfààní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì, Bíbélì sọ pé òun pẹ̀lú jẹ́ “alábùkún jù lọ láàárín àwọn obìnrin.” (Àwọn Onídàájọ́ 5:24) Dájúdájú, ó yẹ ká máa ṣàfarawé Jáẹ́lì, Màríà àti ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin mìíràn tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́, tí Bíbélì sì sọ pé wọ́n ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, àmọ́ kò yẹ ká máa júbà wọn.

Adúróṣinṣin, ọmọlẹ́yìn Jésù ni Màríà. Lọ́pọ̀ ìgbà ló wà pẹ̀lú Jésù nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé àti nígbà ikú rẹ̀. Lẹ́yìn àjíǹde Jésù, òun àti àwọn arákùnrin Jésù ń bá a nìṣó ní ‘títẹpẹlẹ mọ́ àdúrà.’ Èyí ló mú ká gbàgbọ́ pé nígbà tá a fàmì òróró yàn wọ́n ní Pẹ́ńtíkọ́sì, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, òun náà wà pẹ̀lú wọn, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ wà lára àwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ ìyàwó tí yóò bá Kristi ṣàkóso lọ́run.—Mátíù 19:28; Ìṣe 1:14; 2:1-4; Ìṣípayá 21:2, 9.

Síbẹ̀, gbogbo bọ́rọ̀ Màríà ṣe jẹ́ yìí kò ní ká máa gbàdúrà sí i o. Apá pàtàkì ni àdúrà àtọkànwá kó nínú ìjọsìn, Bíbélì sì rọ àwọn Kristẹni láti máa “ní ìforítì nínú àdúrà.” (Róòmù 12:12) Àmọ́, Jèhófà nìkan ṣoṣo ló yẹ ká máa darí àdúrà èyíkéyìí tá a bá gbà nínú ìjọsìn sí, ó sì yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Kristi.—Mátíù 4:10; 1 Tímótì 2:5.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, èyí tó fi Jésù pe Ọlọ́run, ló fà á tí wọ́n fi ń pe Màríà ní ìyá Ọlọ́run.