Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Wá Gbọ́ Àsọyé Fún Gbogbo Ènìyàn “Ta Ló Yẹ Ká Máa Ṣègbọràn Sí?”

Ẹ Wá Gbọ́ Àsọyé Fún Gbogbo Ènìyàn “Ta Ló Yẹ Ká Máa Ṣègbọràn Sí?”

Ẹ Wá Gbọ́ Àsọyé Fún Gbogbo Ènìyàn “Ta Ló Yẹ Ká Máa Ṣègbọràn Sí?”

Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í fẹ́ gbọ́ pó yẹ káwọn máa gbọ́ràn sí ẹlòmíì lẹ́nu. Ohun tó sábà máa ń jẹ́ èrò àwọn èèyàn ni pé ‘gbogbo àrà tó bá wu àwọn láwọn fẹ́ máa dá.’ Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé bá a ṣe ń sùn tá à ń jí, gbogbo wa là ń rí bí ìgbọràn ti ṣe pàtàkì tó. Ní gbogbo ìgbà tó o bá tẹ̀ lé àmì ìkìlọ̀ tàbí ìtọ́ni kan, ò ń ṣègbọràn náà nìyẹn. Ta ni ò sì mọ̀ pé nípa ṣíṣègbọràn sófin àwọn aláṣẹ nìkan ni àlááfíà fi lè jọba, tí ò sì ní sí rúkèrúdò? Àbí, ẹ wo láburú tí ì bá máa ṣẹlẹ̀ bí gbogbo èèyàn bá kọ̀ láti máa pa àwọn òfin ìrìnnà mọ́!

Àmọ́ kan tó wà níbẹ̀ ni pé báwọn èèyàn ṣe ń ṣàkóso ẹ̀dá ẹgbẹ́ wọn, nǹkan kì í fìgbà gbogbo lọ bó ṣe yẹ. Ọjọ́ ti pẹ́ tí Bíbélì ti sọ pé “ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Ǹjẹ́ alákòóso kan tiẹ̀ wà tó yẹ ká gbára lé ká sì máa ṣègbọràn sí? Bó bá wà, báwo la ṣe lè dá a mọ̀? Báwo sì ni ìṣàkóso rẹ̀ ṣe máa rí? A óò dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àsọyé alárinrin kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ , “Ta Ló Yẹ Ká Máa Ṣègbọràn Sí?” Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọyé yìí láwọn àpéjọ àgbègbè wa tí yóò bẹ̀rẹ̀ lóṣù tó ń bọ̀. Ọ̀pọ̀ irú àpéjọ àgbègbè bẹ́ẹ̀ la ó sì tún ṣe káàkiri àgbáyé. Bó o bá fẹ́ mọ èyí tó sún mọ́ ilé rẹ̀ jù lọ lára ibi tá a ó ti ṣe àwọn àpéjọ yìí, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ tàbí kó o lo èyí tó bá yẹ lára àwọn àdírẹ́sì tá a tò sójú ewé 5 láti kọ̀wé béèrè lọ́wọ́ àwọn tó ń tẹ ìwé ìròyìn yìí.