Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Wo Báwọn Èèyàn Ṣe Ta Ẹ̀jẹ̀ Sílẹ̀ Lórúkọ Kristi

Ẹ Wo Báwọn Èèyàn Ṣe Ta Ẹ̀jẹ̀ Sílẹ̀ Lórúkọ Kristi

Ẹ Wo Báwọn Èèyàn Ṣe Ta Ẹ̀jẹ̀ Sílẹ̀ Lórúkọ Kristi

Látọwọ́ òǹkọ̀wé Jí! ní Mẹ́síkò

“Nígbà tí ìsìn Máàsì bá ń lọ lọ́wọ́, àwọn àlùfáà á pariwo látorí àga ìwàásù pé: ‘Gídígbò, gídígbò, ẹ̀yin ọmọ Ìjọ mímọ́! Ìjọba fẹ́ gba Ṣọ́ọ̀ṣì mọ́ wa lọ́wọ́ o!’”—Pedro Rosales Vargas, ẹnì kan tọ́rọ̀ ṣojú ẹ̀ ló sọ̀rọ̀ yìí.

KÍ LÓ lè mú káwọn onísìn dira ogun láti jà fẹ́sìn wọn? Kí láá wá tìdí ẹ̀ yọ báwọn èèyàn bá dá rògbòdìyàn sílẹ̀ nítorí àtigbèjà ẹ̀sìn wọn? Láti lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà Ọ̀tẹ̀ Cristero Lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Wọ́n pe ọ̀tẹ̀ yìí ní Cristeros, nítorí pé orúkọ táwọn tó kópa nínú ọ̀tẹ̀ náà ń jẹ́ nìyẹn.

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Enciclopedia Hispánica sọ pé: “Cristeros lorúkọ tí wọ́n ń pe àwọn ọmọ ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ará Mẹ́síkò tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ Ààrẹ Plutarco Elías Calles lọ́dún 1926 nítorí àwọn ìgbésẹ̀ tó gbé lòdì sí ṣọ́ọ̀ṣì náà. Lára ìgbésẹ̀ wọ̀nyẹn ni bó ṣe ti àwọn ilé wọn àtàwọn ibi tí wọ́n ti ń ṣe ìsìn pa.” Ìjọba ló kọ́kọ́ pe àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn ní Cristeros nítorí bí wọ́n ṣe ń pariwo bó lè dogun kó dogun nípa sísọ pé: “Kí Kristi Ọba pẹ́!” Àmọ́, ibẹ̀ yẹn kọ́ ni rògbòdìyàn náà ti bẹ̀rẹ̀.

Ibi Tí Rògbòdìyàn Ti Bẹ̀rẹ̀

Wọ́n gbé òfin Àtúntò kalẹ̀ lọ́dún 1850, wọ́n sì fọwọ́ sí i lọ́dún 1917. Gẹ́gẹ́ bí ìwé Historia de México ṣe sọ, lára ohun tó mú kí wọ́n gbé òfin náà kalẹ̀ ni “láti sọ àwọn dúkìá tó jẹ́ ti ṣọ́ọ̀ṣì di ti ìjọba.” Ìdí tí ìjọba fi ṣe òfin yìí ni láti dín bí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ṣe ń kó ọrọ̀ jọ rẹpẹtẹ àti bí wọ́n ṣe ń gbalẹ̀ lọ rabidun kù. Kí wọ́n máà tíì fọwọ́ sí òfin ọ̀hún tán ni, ṣe làwọn àlùfáà bẹ̀rẹ̀ sí fẹ̀hónú hàn. Bó ṣe di pé Ìjọba fi òfin gbé àwọn àlùfáà mélòó kan nìyẹn o.

Ọ̀kan lára ìdí tí wọ́n fi ṣe ìyípadà tipátipá lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò láàárín ọdún 1910 sí 1920 ni láti mú káwọn tálákà máa rí ilẹ̀ lò. Nítorí náà, àbá tó wà nínú òfin tuntun tí wọ́n ṣe yìí ni láti máa fipá gbalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ní ilẹ̀ púpọ̀ kí wọ́n sì máa pín in fáwọn aláìní, òun sì ni wọ́n pè ní àtúntò iṣẹ́ àgbẹ̀. Àwọn àlùfáà lápapọ̀ ń wá bí wọ́n ṣe máa dá sọ́ràn náà. Ìdí ni pé òfin tuntun náà kan àwọn àlùfáà tó lẹ́nu láwùjọ tí wọ́n sì ní ilẹ̀ tó pọ̀. Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì sọ pé àwọn ò lòdì sí bí ìjọba ṣe fẹ́ tún ilẹ̀ pín ṣùgbọ́n, wọ́n dábàá ọ̀nà míì tó yàtọ̀ sí ti ìjọba.

Àmọ́ ṣá, àwọn kan gbà pé ìjàdù àwọn tó ní ilẹ̀ ńláńlá, tó fi mọ́ àwọn àlùfáà tó lọ́rọ̀, làwọn ṣọ́ọ̀ṣì ń jà. Síbẹ̀, àwọn àlùfáà kan wà tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ àgbẹ̀, àwọn wọ̀nyí fara mọ́ pínpín ilẹ̀ fáwọn aláìní. Bó ṣe wá di pé ẹnu àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì ò kò yìí, ńṣe ló mú kí wàhálà tí ìjọba ń bá ṣọ́ọ̀ṣì fà lágbára sí i.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1925, Ààrẹ Plutarco Elías Calles, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dórí àlééfà lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò nígbà yẹn, bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ lé apá ibi tó sọ̀rọ̀ nípa ṣọ́ọ̀ṣì nínú òfin tuntun, kò sì gba gbẹ̀rẹ́ lórí ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó lé ọ̀pọ̀ àlùfáà Kátólíìkì tó jẹ́ àlejò kúrò nílẹ̀ Mẹ́síkò. Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí bíṣọ́ọ̀bù àgbà fún ilẹ̀ Mẹ́síkò sọ pé àwọn àlùfáà kò ní fara mọ́ apá ibi tó lòdì sáwọn àlùfáà nínú òfin orílẹ̀-èdè náà, ìjọba fòfin gbé e. Wọ́n tún gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ilé kan tó jẹ́ ti ṣọ́ọ̀ṣì. Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ìdí tí ìjọba fi ṣe gbogbo èyí ni láti rí i pé àwọn Kátólíìkì ò rí owó ribiribi kó láti ilẹ̀ Mẹ́síkò lọ sí ìlú Róòmù.

Lóṣù July ọdún 1926, àwọn bíṣọ́ọ̀bù ilẹ̀ Mẹ́síkò fúnra wọn pàṣẹ pé kí wọ́n má ṣe ìsìn mọ́ nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì. Ìjọba mọ̀ pé òṣèlú làwọn bíṣọ́ọ̀bù kì bọ ọ̀rọ̀ ọ̀hún torí kí wọ́n lè forí ìjọba àtàwọn aráàlú gbára. Lọ́rọ̀ kan ṣá, ohun tó tapo sí iná wàhálà ńlá tó di Ọ̀tẹ̀ Cristero ni dídá tí wọ́n dá ìsìn dúró láwọn ṣọ́ọ̀ṣì.

Ogun Bẹ̀rẹ̀

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, táwọn àlùfáà ti kó sí lórí ló jagun láti gbèjà ẹ̀sìn wọn. Wọ́n ń gbé ère Wúńdíá Guadalupe káàkiri gbogbo ibi tí wọ́n ń lọ gẹ́gẹ́ bí àmì ẹgbẹ́ ológun wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lára àwọn Cristero retí pé káwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì wá gbèjà ṣọ́ọ̀ṣì, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn bíṣọ́ọ̀bù àtàwọn àlùfáà ni kò dá sógun náà nítorí wọ́n ń bẹ̀rù pé ìjọba á yaró rẹ̀ lára àwọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe lọ̀pọ̀ jù lọ wọn ń wá ilé olówó ba sí, wọn ò dá sí ìjà tó ń lọ, bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn mẹ̀kúnnù ń ja ìjà àjàkú akátá nìṣó lórúkọ ẹ̀sìn.

Àmọ́ ṣá, àwọn àlùfáà kan dá sí i, ó sì láwọn tí olúkúlùkù wọn gbè sí lẹ́yìn. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, The Cristiada, (Ìdìpọ̀ 1, The War of the Cristeros) ṣe sọ, ó tó ọgọ́rùn-ún àlùfáà Kátólíìkì tó ta ko àwọn Cristero, nígbà tí ogójì lọ́wọ́ sí ìjà náà. Àwọn márùn-ún míì tiẹ̀ bá wọn dójú ogun.

Ohun tó tẹ̀yìn ogun náà wá burú jọjọ. Níbi tó pọ̀ logun náà ti kó gbogbo èèyàn sínú ìṣẹ́. Bákan náà, ọ̀pọ̀ ìròyìn la gbọ́ nípa àwọn ọ̀dọ́kùnrin táwọn Cristero ń fagídí kó lọ sójú ogun. A tún gbọ́ ìròyìn nípa báwọn Cristero àtàwọn ọmọ ogun ìjọba ṣe ń yọ àwọn ìdílé kan lẹ́nu wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ pé kí wọ́n fáwọn lóúnjẹ. A sì tún gbọ́ pé ṣe làwọn ọmọ ogun tọ̀tún tòsì ń fipá bá àwọn èèyàn lò pọ̀ tí wọ́n sì ń pa tẹbí tọ̀rẹ́ àwọn tí wọ́n dojú ìjà kọ.

Àtàwọn ọmọ ogun ìjọba o, àtàwọn Cristero o, gbogbo wọn ló ṣàṣejù. Ara ìwà burúkú gbáà tí wọ́n hù ni kí wọ́n máa pa ọ̀pọ̀ aláìṣẹ̀ tọ́rọ̀ ìjà náà ò kàn lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀. Iye èèyàn tí wọ́n fi ọ̀dájú pa láàárín ọdún mẹ́ta tí wọ́n fi ja ogun náà kò dín ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin [70,000], èyí ló sì fi bógun náà ṣe lágbára tó hàn.

Ogun Parí

Lóṣù June ọdún 1929, Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì àti ìjọba kọwọ́ bọ ìwé àdéhùn, wọ́n dáwọ́ ogun dúró, nígbà tó sì di August ọdún náà, ìjà parí. Àmọ́ wọn ò pe àwọn jagunjagun Cristero nígbà tí wọ́n ń ṣàdéhùn, nítorí náà wọn ò mọ ìdí táwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì á fi gbà fáwọn ọ̀tá tó ń lòdì sí àṣẹ Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dun àwọn Cristero gan-an, síbẹ̀ wọ́n tẹ̀ lé àṣẹ àwọn àlùfáà, wọ́n juwọ́ sílẹ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín, olúkúlùkù wọn sì gbalé ẹ̀ lọ. Àwọn aláṣẹ ìjọba ṣèlérí pé àwọn á dẹwọ́ òfin àwọn díẹ̀, wọ́n sì ní kí wọ́n máa ṣe ìsìn Máàsì lọ. Síbẹ̀, wọn ò yí òfin tó de ẹ̀sìn padà.

Àwọn kan ka Ọ̀tẹ̀ Cristero sí ìgbìyànjú àwọn kan nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì láti dá agbára tó wà lọ́wọ́ ṣọ́ọ̀ṣì kí wọ́n tó ṣe òfin Àtúntò padà fún wọn. Àmọ́, pẹ̀lú gbogbo ogun tí wọ́n jà, òfin tí wọ́n ṣe yẹn ṣì múlẹ̀ ní Mẹ́síkò títí di ọdún 1992, nígbà tí wọ́n ṣe òfin lórí ọ̀ràn ẹ̀sìn. Síbẹ̀ náà, wọn ò fi gbogbo ara gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ẹlẹ́sìn. Àní wọn ò tíì máa gba àwọn àlùfáà àtàwọn òjíṣẹ́ Ṣọ́ọ̀ṣì láàyè láti máa kópa nínú ìṣèlú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn onísìn lè ní ilé àti ilẹ̀, gbogbo ilé àti ilẹ̀ tíjọba gbà lọ́wọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì ṣáájú ọdún 1992 ṣì wà níkàáwọ́ ìjọba. Síbẹ̀, àwọn kan lára àwọn àlùfáà Mẹ́síkò yẹn ò yé yọjú sọ́ràn ìṣèlú láìka òfin tó wà nílẹ̀ sí.

Kí Ni Wọ́n Bá Bọ̀ Nídìí Ẹ̀ O?

Ǹjẹ́ báwọn Cristero ṣe jagun láti lè gbèjà ẹ̀sìn wọn ṣe wọ́n lóore tó tọ́jọ́? María Valadez, tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú ẹ̀ sọ pé: “Lójú tèmi o, asán ni ìpakúpa tí wọ́n para wọn yẹn já sí. Ìranù pátápátá ni.” Pedro Rosales Vargas, tá a fọ̀rọ̀ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ̀rọ̀ nípa bí àtẹ̀yìnbọ̀ ogun náà ṣe korò tó, ó ní: “Àwọn èèyàn ń pa èèyàn ẹlẹ́ran ara bíi tiwọn, kódà àwọn tí wọ́n jọ ń ṣe ẹ̀sìn kan náà. Bí wọ́n ṣe sọ mí di ọmọ òrukàn nìyẹn, wọ́n pa bàbá mi.”

Ohun tójú rí nígbà Ọ̀tẹ̀ Cristero, kò kọ́ àwọn onísìn pé kí wọ́n yé dá wàhálà sílẹ̀ mọ́. Irú ẹ̀ tún ṣẹlẹ̀ ní Àríwá Ireland àti ní orílẹ̀-èdè Yugoslavia tẹ́lẹ̀. Àfi tí gbogbo ayé bá ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́ tí Kristi fi lélẹ̀ nìkan nírú jàǹbá bẹ́ẹ̀ ò fi ní wáyé mọ́. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máà dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú, ó ní wọn “kì í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:16; 18:36) Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù fẹ́ dà á síjà kí wọ́n máa bàa mú Jésù lọ, Jésù sọ fún un pé: “Dá idà rẹ padà sí àyè rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.”—Mátíù 26:52.

Kí Làwọn Kristẹni Máa Ń Ṣe Tí Wọ́n Bá Ń Fojú Wọn Gbolẹ̀?

Ṣé ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé tí wọ́n bá ń fi òmìnira ẹ̀sìn du àwọn Kristẹni kí wọ́n máa wòran? Rárá o. Nígbà tí wọ́n ń ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n fi àǹfààní tí wọ́n ní lábẹ́ òfin gbèjà ara wọn. Wọ́n pẹjọ́ sí kóòtù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ń jù wọ́n sẹ́wọ̀n, wọn ò pa ìgbàgbọ́ wọn tì, wọn ò sì kúrò lórí ìdúró wọn láti má ṣe dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú.—Ìṣe 5:27-42.

Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ò fìgbà kan rí dira ogun láti jà fún ẹ̀tọ́ ẹ̀sìn wọn. Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í pa àwọn ẹlẹ́sìn míì, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ àwọn tó jẹ́ onígbàgbọ́ bíi tiwọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀kọ́ Ọ̀gá wọn ni wọ́n ń tẹ̀ lé, pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòhánù 13:35.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Àlùfáà kan tó dúró sáàárín àwọn jagunjagun “Cristero” méjì

[Credit Line]

© (Inventory image number: 422036) SINAFO-Fototeca Nacional

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ààrẹ Plutarco E. Calles

[Credit Line]

© (Inventory image number: 66027) SINAFO-Fototeca Nacional

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Díẹ̀ lára àwọn aṣáájú àwọn ọmọ ogun “Cristero”

[Credit Line]

© (Inventory image number: 451110) SINAFO-Fototeca Nacional