Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Bílíọ̀nù Kan Èèyàn á Ṣe Máa Róúnjẹ Jẹ

Bí Bílíọ̀nù Kan Èèyàn á Ṣe Máa Róúnjẹ Jẹ

Bí Bílíọ̀nù Kan Èèyàn á Ṣe Máa Róúnjẹ Jẹ

BÍLÍỌ̀NÙ kan èèyàn ló ń sùn lójoojúmọ́ láìrí oúnjẹ jẹ kánú. Síbẹ̀, àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè sọ pé kò yẹ kọ́rọ̀ burú tó báyìí.

Àjọ náà pe ìpàdé àpérò kan ní September 8 ọdún 2000. Àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn tó lágbára jù lágbàáyé, lọ́kùnrin lóbìnrin, ló wà nípàdé àpérò yẹn. Ọ̀gbẹ́ni Kofi Annan tó jẹ́ ọ̀gá àgbà àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè sọ fáwọn tó wà níbi ìpàdé náà pé: “Ẹ ti sọ pé olórí ohun tó wà lọ́kàn yín ni bẹ́ ẹ ṣe máa yọ àwọn èèyàn kúrò nínú òṣì robo.” Nínú ìpàdé tí wọ́n ti jíròrò ohun tí Ìparapọ̀ Orílẹ̀-èdè mú ní ọ̀kúnkúndùn ní sáà tuntun yìí, díẹ̀ nínú àwọn olórí orílẹ̀-èdè náà sọ ojú abẹ níkòó lórí ìṣòro tó ń kojú àwọn tálákà. Igbá kejì ààrẹ orílẹ̀-èdè Brazil sọ pé: “Ó bu ìran èèyàn kù pé a ṣì ń ráwọn tí òṣì ń ta tó báyìí.” Olórí ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tiẹ̀ fi kún un pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà lágbàáyé ti kùnà pátápátá lórí bọ́rọ̀ ṣe rí nílẹ̀ Áfíríkà báyìí, ìtìjú gbáà ló sì jẹ́, níbi tá a lajú dé yìí.”

Ohun táwọn méjèèjì tó sọ̀rọ̀ yẹn sọ fi hàn pé àwọn orílẹ̀-èdè ti dójú ti ara wọn nípa bí wọ́n ṣe kùnà láti ṣe ohun tó wà níkàáwọ́ wọn kí gbogbo èèyàn lè róúnjẹ jẹ. Láti lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé lóòótọ́ ni wọ́n fẹ́ mú kára túbọ̀ tu kóówá, àwọn tó lọ síbi ìpàdé àpérò náà ṣèlérí pé àwọn á wá nǹkan ṣe sí i. Wọ́n ṣèpinnu tó pín sí apá mẹ́jọ, lára ohun tó sì wà nínú ẹ̀ ni pé: “Gbogbo ohun tó bá gbà la máa fún un láti lè gba àwọn èèyàn bíi tiwa, lọ́kùnrin lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà lọ́wọ́ ìṣẹ́, kí wọ́n lè yé ráre nínú òṣì, tó ń ta àwọn tó ju bílíọ̀nù kan èèyàn báyìí. . . . A tún pinnu pé: Tó bá fi máa di ọdún 2015, àwọn tówó tó ń wọlé fún wọn lójúmọ́ kò tó dọ́là kan yóò ti dín kù sí ìlàjì iye tí wọ́n jẹ́ báyìí, bákan náà ni iye àwọn tébi ń hàn léèmọ̀ á ti dín kù sí ìlàjì.”

Látìgbà tí wọ́n ti ṣèlérí láti ṣe ohun dáadáa yìí ní September ọdún 2000, itú wo ni wọ́n ti pa?

Ẹnu Dùn-ún Ròfọ́?

Lọ́dún 2003, àjọ kan tó ń rí sí ètò ọrọ̀ ajé lágbàáyé, tó sì ń rí sí i pé àwọn àbá fún ìrànlọ́wọ́ di mímú lò, ìyẹn Global Governance Initiative of the World Economic Forum, bẹ̀rẹ̀ sí ṣàyẹ̀wò ibi táwọn orílẹ̀-èdè báṣẹ́ dé lórí ohun tí wọ́n láwọn máa ṣe nígbà tí wọ́n ṣèpàdé àpérò ní September ọdún 2000. Àtẹ̀jáde tí wọ́n fi síta ní January 15, ọdún 2004 sọ pé: “Aráyé kò tíì ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe láti lè mú ìpinnu pàtàkì yìí ṣẹ.” Lórí ọ̀rọ̀ ebi, ìròyìn náà sọ pé: “Kì í kúkú ṣe pé oúnjẹ ló wọ́n láyé tó bẹ́ẹ̀, oúnjẹ tó wà láyé tó gbogbo ẹni tó wà láyé jẹ lájẹyó. Ìṣòro ibẹ̀ ni pé oúnjẹ tó wà láyé àtohun tó ń ṣara lóore kì í dé ọ̀dọ̀ àwọn tí kò lówó lọ́wọ́.”

Ìròyìn náà pa gbogbo ọ̀ràn pọ̀ lórí ọ̀ràn òṣì pé: “Àwọn ìjọba, láwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ àtàwọn tí kò lọ́rọ̀ ló yẹ ká dẹ́bi rù lórí bọ́rọ̀ títán ìṣẹ́ ṣe di àléèbá. Àmọ́ ṣá, báwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ ṣe ṣètò ọrọ̀ ajé lágbàáyé gan-an máa ń sábà mú kí nǹkan nira fáwọn tí kò lọ́rọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọlọ́rọ̀ ń ṣe kùkùfẹ̀fẹ̀ bíi pé wọ́n ní nǹkan ṣe, ìṣe wọn kò fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ṣíṣàtúntò ètò ọrọ̀ ajé, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ṣe nǹkan láti fi kún ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ń ṣe fáwọn orílẹ̀-èdè tí òṣì ń bá fínra.” Pẹ̀lú bí wọ́n ṣe fi ìròyìn yìí nà wọ́n lẹ́gba ọ̀rọ̀ báyìí, ńṣe làwọn olóṣèlú kan ń rojọ́ lọ kùlà láwọn ìpàdé àpérò dípò kí wọ́n wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá. Bákan náà, ṣe làwọn ìjọba kan ń pa oríṣiríṣi ète torí ohun tí orílẹ̀-èdè wọn á rí jẹ. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ebi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ yọjú àwọn tálákà tó wà láyé lé wọn lọ́wọ́.

Àtẹ̀jáde kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ọ̀tọ̀ Ni Rírò Ọ̀tọ̀ Ni Ṣíṣe,” èyí tí àjọ tó ń rí sí ètò ọrọ̀ ajé lágbàáyé fi síta, kìlọ̀ pé “ebi á fẹ́ lu ọ̀pọ̀ èèyàn pa láyé tí wọn ò bá ṣàtúnṣe sí ètò ọrọ̀ ajé láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, káwọn orílẹ̀-èdè sì ṣàtúnṣe ètò tí wọ́n ń ṣe láti ṣẹ́gun ebi, kí wọ́n sì làlùyọ lórí ètò tí wọ́n ń ṣe ní abẹ́lé láti gbá ebi wọlẹ̀.” Ta wá ló yẹ kó ṣètò gidi “ní abẹ́lé láti gbá ebi wọlẹ̀” o? Kì í ṣe ẹlòmíì bí kò ṣàwọn ìjọba tí wọ́n kéde lọ́dún 2000 pé àwọn máa tó sayé dẹ̀rọ̀ fún mùtúmùwà.

Ìjákulẹ̀ ló máa ń jẹ́ tẹ́nì kan bá ṣèlérí lẹ́ẹ̀kan tí kò bá mú un ṣẹ; tó bá wá ti wá di wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́, kò sẹ́ni táá gbọ̀rọ̀ olúwa rẹ̀ gbọ́ mọ́. Nígbà táwọn ìjọba kì í ti í mú ìlérí tí wọ́n ṣe láti tọ́jú àwọn tálákà ṣẹ, àwọn èèyàn ò fẹ́ máa gbà wọ́n gbọ́ mọ́. Bí àpẹẹrẹ, oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan lóòjọ́ ni obìnrin kan tó ń gbé ní ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lágbègbè Caribbean àtàwọn ọmọ rẹ̀ márùn-ún máa ń lè jẹ. Ó sọ pé: “Ohun tá a máa jẹ ló kàn mí. Kò sóhun tó kàn mí pẹ̀lú ẹni tó wà lórí àlééfà. Ẹnikẹ́ni ò tíì ṣe nǹkan kan fún wa rí lára àwọn tó ti ń ṣèjọba.”

Jeremáyà, ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì, sọ pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) A ó rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ yìí tá a bá wo báwọn èèyàn ti ṣe ń kùnà láti tán ìṣòro àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́.

Àmọ́ Alákòóso kan wà tó ní agbára láti yanjú àwọn ìṣòro tó ń dojú kọ ìran ènìyàn tó sì fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, Bíbélì sì jẹ́ ká mọ onítọ̀hún. Nígbà tí Alákòóso náà bá gbàjọba, kò sẹ́ni táá sùn lébi mọ́.

Ìdí Tá A Fi Lè Ní Ìrètí

“Ìwọ ni ojú gbogbo gbòò ń wò tìrètí-tìrètí, ìwọ sì ń fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àsìkò rẹ̀.” (Sáàmù 145:15) Ta ni Ẹni tí Bíbélì sọ níbí yìí pé yóò máa fún àwọn èèyàn ní oúnjẹ ní àkókò tó yẹ? Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá wa ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn ni ìyàn àtàwọn ìṣòro míì ti ń da aráyé láàmú, gbogbo ìgbà lọ̀rọ̀ àwa èèyàn máa ń wà lọ́kàn Jèhófà. Ó ti rí i báwọn ìjọba èèyàn ti ṣe ń kùnà, Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí kì í kùnà sì fi hàn wá pé kò ní pẹ́ mọ́ tó fi máa fi ìjọba tiẹ̀ rọ́pò wọn.

Jèhófà sọ pé: “Èmi, àní èmi, ti fi ọba mi jẹ lórí Síónì, òkè ńlá mímọ́ mi.” (Sáàmù 2:6) Ìkéde tí aláṣẹ gíga jù lọ láyé àti lọ́run ṣe yìí tó ohun tó ń fún èèyàn ní ìrètí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso èèyàn kì í sábàá ṣèrànlọ́wọ́ fáwọn tí wọ́n ń ṣàkóso lé lórí, Jésù Kristi tí Ọlọ́run ti fi jẹ Ọba yóò mú ọ̀pọ̀ àǹfààní táwọn tó kúṣẹ̀ẹ́ jù lọ láyé ó tíì rí rí wá.

Jèhófà yóò tipasẹ̀ Ọba yìí bọ́ gbogbo àwọn tébi ń pa. Aísáyà 25:6 nínú Bíbélì Mímọ́ sọ pé: “Oluwa awọn ọmọ-ogun yío sè asè ohun abọ́pa fún gbogbo orilẹ-ède.” Lábẹ́ ìjọba Ọlọ́run tí Kristi yóò máa ṣàkóso, àwọn èèyàn kò ní lálàṣí oúnjẹ tó dáa, tó ń ṣara lóore, ibi yòówù tí wọn ì báà máa gbé. Jèhófà ni Bíbélì ń bá wí nígbà tó sọ pé: “Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ, ìwọ sì ń tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.”—Sáàmù 145:16.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]

“Àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà lágbàáyé ti kùnà pátápátá lórí bọ́rọ̀ ṣe rí nílẹ̀ Áfíríkà báyìí, ìtìjú gbáà ló sì jẹ́, níbi tá a lajú dé yìí.”—Olórí Ìjọba Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Tony Blair

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

ETIÓPÍÀ: Lórílẹ̀-èdè yìí, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́tàlá èèyàn ló ń dúró de oúnjẹ tí wọ́n fi ń ṣèrànwọ́ kí wọ́n tó lè jẹun. Ọmọ tó wà lókè yìí wà lára wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

ÍŃDÍÀ: Ilé ìwé làwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí ti ń róúnjẹ tí wọ́n ń jẹ

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 10]

Tòkè: © Àwòrán tí Sven Torfinn/Panos yà; tìsàlẹ̀: © Àwòrán tí Sean Sprague/Panos yà