Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mi Ò Fi Ní Máa Bá Àwọn Èèyàn Tí Kò Yẹ Rìn?

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mi Ò Fi Ní Máa Bá Àwọn Èèyàn Tí Kò Yẹ Rìn?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mi Ò Fi Ní Máa Bá Àwọn Èèyàn Tí Kò Yẹ Rìn?

“Ọmọbìnrin kan wà ti èmi àti ẹ̀ kì í ya ara wa nílé ẹ̀kọ́. . . . Kì í lo oògùn olóró, kì í fọjọ́ gbogbo ròde àríyá, kì í sì í ṣèṣekúṣe. Kì í ṣépè, orí rẹ̀ sì pé síwèé. Ṣùgbọ́n kí n má tàn yín, kì í ṣẹni tó yẹ kéèyàn máa bá rìn.”—Beverly. a

K Í LÓ mú kí Beverly sọ ohun tó sọ lókè yìí? Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ yé e ni pé ọmọbìnrin yẹn ti mú kó tọwọ́ bọ ohun tó burú jáì. Ó sọ pé: “Ìgbà tọ́wọ́ wa wọwọ́ tán, èmi náà bẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn ìwé ìbẹ́mìílò àní mo tiẹ̀ tún máa ń kọ ìtàn lórí ìbẹ́mìílò.”

Ẹnì kan tó pera ẹ̀ ní Kristẹni ló tan ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Melanie sínú ìṣekúṣe! Báwo lo ṣe wá lè mọ̀ bẹ́nì kan kì í bá ṣe ọ̀rẹ́ gidi? Ṣé kò sẹ́nì kankan téèyàn lè bá rìn láàárín àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹrìí ni? Àtipé ṣé gbogbo Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ló ṣeé yàn lọ́rẹ̀ẹ́ tí kò sì ní séwu?

Ká tiẹ̀ sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kí ló burú nínú kéèyàn máa bá ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tẹni ṣọ̀rẹ́? Béèyàn bá lẹ́nì kan lọ́kàn láti fẹ́, báwo lèèyàn ṣe lè mọ̀ bóyá ọmọlúwàbí ni onítọ̀hún? Ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.

Àwọn Wo Gan-an Ló Yẹ Kéèyàn Bá Ṣọ̀rẹ́?

Ǹjẹ́ ó yẹ kí Beverly tìtorí pé ọmọléèwé ẹ̀ kì í sin Ọlọ́run tòótọ́, kó máà fẹ́ bá a rìn? Òótọ́ ni pé àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í ka ẹnì kan sẹ́ni tí kò yẹ láti bá rìn tàbí oníṣekúṣe kìkì nítorí pé onítọ̀hún kì í ṣe Kristẹni bíi tiwọn. Ṣùgbọ́n bó bá di pé ká yan ọ̀rẹ́ kòríkòsùn, èèyàn gbọ́dọ̀ fẹ̀sọ̀ ṣe. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fáwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tó wà nínú ìjọ Kọ́ríńtì pé: “Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Kí ló ní lọ́kàn?

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe làwọn kan lára àwọn Kristẹni tó wà nínú ìjọ Kọ́ríńtì yẹn ń bá àwọn Epikúréì ṣe wọléwọ̀de, ìyẹn àwọn ọmọlẹ́yìn Epicurus, ọlọ́gbọ́n èrò orí Gíríìkì nì. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, ẹ̀kọ́ tí Epicurus ń kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni pé kí wọ́n máa lo làákàyè, kí wọ́n ní ìgboyà, kí wọ́n máa kó ara wọn níjàánu kí wọ́n má sì máa ṣe èrú. Ó tiẹ̀ tún gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n ṣọ́ra fún yíyọ́ búburú ṣe nísinsìyí. Kí ló wá lè mú kí Pọ́ọ̀lù tún máa ka àwọn Epikúréì títí kan àwọn ará kan tó nírú ìwà yẹn sí “ẹgbẹ́ búburú”?

Ọlọ́run tòótọ kọ́ làwọn Epikúréì ń sìn. Níwọ̀n bí wọn ò sì ti gba àjíǹde òkú gbọ́, ohun tí wọ́n gbájú mọ́ kò ju bí wọ́n á ṣe máa jayé orí wọn lọ. (Ìṣe 17:18, 19, 32) Ìyẹn ni ò ṣe lè yà wá lẹ́nu pé látàrí bíbá táwọn kan nínú ìjọ Kọ́ríńtì ń bá àwọn Epikúréì rìn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyè méjì nípa ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde àwọn òkú. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi ṣàlàyé lọ́nà tó yè kooro nípa bí àjíǹde ṣe dájú tó nínú 1 Kọ́ríńtì orí 15, níbi tó ti ṣèkìlọ̀ nípa ẹgbẹ́ búburú, kó bàa lè yí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ yẹn lérò padà lẹ́ẹ̀kan sí i.

Kí ni gbogbo èyí ń kọ́ wa? Ó kọ́ wa pé àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́ pàápàá lè láwọn ìwà ọmọlúwàbí kan. Ṣùgbọ́n bó bá jẹ́ pé àwọn lo yàn bí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn, kò sí ni kí ọ̀nà tó o gbà ń ronú, ohun tó o gbà gbọ́ àti ìwà tó ò ń hù máà yí padà. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi sọ nínú lẹ́tà kejì tó kọ sáwọn ará Kọ́ríńtì pé: “Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.”—2 Kọ́ríńtì 6:14-18.

Fred, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún rí i pé ọgbọ́n wà nínú ọ̀rọ̀ Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ó ti kọ́kọ́ gbà láti bá wọn rìnrìn-àjò lọ sí orílẹ̀-èdè kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà láti lọ kọ́ àwọn ògowẹẹrẹ lẹ́kọ̀ọ́, èyí tí kì í ṣe ara iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ ní tààràtà. Àmọ́, bóun àtàwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ kan ṣe ń palẹ̀ mọ́ fún ìrìn àjò náà, èrò Fred yí padà. Ó ní: “Mo ronú pé iṣẹ́ yẹn á gba àkókò tó pọ̀ lọ́wọ́ mi, ìyẹn sì máa kó bá mi nípa tẹ̀mí.” Nítorí èyí, Fred pinnu láti má lọ mọ́, ó sì lo àkókò yẹn láti máa ran àwọn tó kù díẹ̀ káàtó fún lọ́wọ́.

Bá A Ṣe Lè Wá Ọ̀rẹ́ Sáàárín Àwọn Kristẹni Bíi Tiwa

Béèyàn bá kúkú wẹ́ni bá ṣọ̀rẹ́ nínú ìjọ Kristẹni ńkọ́? Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sí ọ̀dọ́mọkùnrin náà, Tímótì, ó kìlọ̀ fún un pé: “Nínú ilé ńlá, kì í ṣe àwọn ohun èlò wúrà àti fàdákà nìkan ni ó wà ṣùgbọ́n ti igi àti ohun èlò amọ̀ pẹ̀lú, àwọn kan sì wà fún ète ọlọ́lá ṣùgbọ́n àwọn mìíràn fún ète tí kò ní ọlá. Nítorí náà, bí ẹnikẹ́ni bá yẹra fún àwọn ti ìkẹyìn yìí, òun yóò jẹ́ ohun èlò fún ète ọlọ́lá, tí a sọ di mímọ́, tí ó wúlò fún ẹni tí ó ni ín, tí a múra sílẹ̀ fún gbogbo iṣẹ́ rere.” (2 Tímótì 2:20, 21) Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù sojú abẹ níkòó pé àwọn kan wà, kódà nínú ìjọ, tí wọ́n ń hùwà bí ohun èlò tí kò ní ọlá. Ìyẹn ló kúkú ṣe là á mọ́lẹ̀ fún Tímótì pé kó yẹra fún irú wọn.

Ṣé ohun tá à ń sọ ni pé kó o bẹ̀rẹ̀ sí fura sáwọn ará? Ó tì o. A ò sì sọ pé kó o wá máa retí pé káwọn ọ̀rẹ́ ẹ má ṣàṣìṣe o. (Oníwàásù 7:16-18) Síbẹ̀, pé ọ̀dọ́ kan ń pésẹ̀ sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé tàbí pé ọ̀dọ́ kan láwọn òbí tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa nínú ìjọ kò tó láti yan irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́ kòríkòsùn.

Òwe 20:11 sọ pé: “Àní nípa àwọn ìṣe rẹ̀, ọmọdékùnrin [tabí ọmọdébìnrin] kan ń mú kí a dá òun mọ̀, ní ti bóyá ìgbòkègbodò rẹ̀ mọ́ gaara tí ó sì dúró ṣánṣán.” Nítorí náà, á dáa kó o bi ara ẹ pé: Ṣé sísún mọ́ Jèhófà ló jẹ ẹni yìí lógún? Àbí, dípò ìyẹn, ṣé ńṣe lọ̀nà tó gbà ń ronú àtàwọn ìṣesí ẹ̀ bá “ẹ̀mí ayé” mu? (1 Kọ́ríńtì 2:12; Éfésù 2:2) Ǹjẹ́ bẹ́ ẹ ṣe jọ máa ń ṣeré ń mú kó o túbọ̀ fẹ́ láti sin Jèhófà?

Bó bá jẹ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dọ́kàn, táwọn nǹkan tẹ̀mí sì jọ lójú lo yàn lọ́rẹ̀ẹ́, yàtọ̀ sí pé o kò ní máa kó sí wàhálà, wàá tún lè máa sin Ọlọ́run nìṣó. Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Máa lépa òdodo, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àlàáfíà, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí ń ké pe Olúwa láti inú ọkàn-àyà tí ó mọ́.”2 Tímótì 2:22.

Yíyan Ẹni Tí Kì Í Ṣe Ọkùnrin Tàbí Obìnrin Bíi Tẹni Lọ́rẹ̀ẹ́

Bó o bá ti dàgbà tó, tó o sì fẹ́ ṣègbéyàwó, ǹjẹ́ o ti fara balẹ̀ ronú lórí bí àwọn ìlànà yìí ṣe kan ọ̀ràn yíyan ẹni tó o máa fẹ́? Ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè mú kó o nífẹ̀ẹ́ àfẹ́sọ́nà rẹ, àmọ́ kò sí èyí to ṣe pàtàkì tó bí onítọ̀hún ṣe sún mọ Jèhófà tó.

Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi kìlọ̀ lemọ́lemọ́ pé ká má ṣe fẹ́ ẹnikẹ́ni tí kò sí “nínú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 7:39; Diutarónómì 7:3, 4; Nehemáyà 13:25) Lóòótọ́ o, àwọn kan tí kì í ṣe onígbàgbọ́ bíi tìẹ lè jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán, tí wọ́n níwà, tí wọ́n sì ń ro tẹlòmíì mọ́ tiwọn. Síbẹ̀, nǹkan kan wà tó lè máa sún ìwọ láti máa lo àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ yẹn nìṣó tí ìgbéyàwó rẹ á fi tọ́jọ́, ṣùgbọ́n àwọn ò ní nǹkan kan tó lè sún wọn ṣe bẹ́ẹ̀.

Àmọ́, ṣe ló máa ń wu ẹni tó ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà tó sì jẹ́ adúróṣinṣin láti máa hùwà tó bá Bíbélì mu, kò sì ní fẹ́ láti ṣe ohun tó yàtọ̀ síyẹn, bó ṣe wù kó rí. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ á mọ̀ pé Bíbélì so ọ̀rọ̀ fífẹ́ràn ọkọ tàbí aya ẹni pọ̀ mọ́ sísún mọ́ Jèhófà. (Éfésù 5:28, 33; 1 Pétérù 3:7) Bí tọkọtaya bá sì wá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ìfẹ́ yẹn ò ní jẹ́ kí wọ́n ya ara wọn.

Ṣé ohun tó túmọ̀ sí ni pé béèyàn bá fẹ́ Kristẹni bíi tẹni, ìgbéyàwó náà ò lè tú láéláé? Rárá o. Àpẹẹrẹ kan rèé, bó bá jẹ́ pé ẹni tí kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sáwọn nǹkan tẹ̀mí lo fẹ́, kí lo rò pé ó lè ṣẹlẹ̀? Ó rọrùn fẹ́ni tí kò lágbára nípa tẹ̀mí, tí ò kẹ́kọ̀ọ́ béèyàn ṣe lè gbójú kúrò lára àwọn nǹkan inú ayé yìí láti sú lọ kúrò nínú ìjọ Kristẹni nígbàkigbà. (Fílípì 3:18; 1 Jòhánù 2:19) Àbí, kí ni ká ti wá gbọ́ bí ọkọ tàbi àya rẹ bá dẹni tó kó sínú “àwọn ẹ̀gbin ayé”? Ìrora ọkàn gbáà ló máa jẹ́ fún ọ, gbọ́nmi-si omi-ò-to tá tẹ̀yìn rẹ̀ wá á sì pọ̀.—2 Pétérù 2:20.

Kó o tó bẹ̀rẹ̀ ìfẹ́sọ́nà táá yọrí sí ìgbéyàwó, bi ara ẹ pé: Ǹjẹ́ ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ wà pé ẹni tó dúró sán-ún nípa tẹ̀mí lonítọ̀hún? Ǹjẹ́ ọ̀nà tó gbà ń gbé ìgbésí ayé rẹ̀ fi í hàn bíi Kristẹni téèyàn lè rí ẹ̀kọ́ tó dáa kọ́ lára rẹ̀? Ṣé ẹni yìí ní ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ nínú Bíbélì àbí ó ṣì nílò àkókò díẹ̀ sí i kó lè dàgbà nípa tẹ̀mí? Ṣó dá ẹ lójú pé ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà ló gbapò iwàjú nígbèésí ayé rẹ̀? Ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá wádìí irú ẹni táwọn èèyàn mọ̀ ọ́n sí. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, o gbọ́dọ̀ rí i pé o ṣe gbogbo ohun tó yẹ kó o ṣe láti lè mọ̀ bóyá ẹni tó o fẹ́ fẹ́ yìí gbà pé ti Jèhófà làṣẹ àti pé bóyá ó máa yẹ lẹ́ni téèyàn lè bá tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn ìgbéyàwó.

Rántí pé àwọn tó máa ń kó sínú ìfẹ́ pẹ̀lú “èèyàn tí kò yẹ” kọ́kọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ sáwọn nǹkan tó burú, bí àwọn eré ìnàjú tí ò bójú mu tàbí àwọn nǹkan míì bẹ́ẹ̀. Àwọn ọ̀dọ́ tó bá jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa nínú ìjọ ò ní bá ẹ lọ́wọ́ sáwọn nǹkan tí kò dáa wọ̀nyẹn. Nítorí náà, yẹ ọkàn ara rẹ wò.

Bó o bá rí i pé ọkàn rẹ yẹ fún ìbáwí, má bara jẹ́ jù. Ọkàn ṣeé báwí. (Òwe 23:12) Kókó ibẹ̀ ṣáà ni pé: Kí ni ohun tó ò ń fẹ́ gan an? Ṣé ohun tó dáa ló wù ẹ́, ṣé ẹni tó ń hùwà tó dáa ló sì fẹ́ máa bá rìn? Jèhófà ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ni ohun tó dá a lọ́kàn. (Sáàmù 97:10) Bó o bá sì ń kọ́ agbára ìwòye rẹ láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́, ó máa rọrùn fún ẹ láti yan ọ̀rẹ́ tí kò ní ki ọwọ́ rẹ bọ ìbọ̀kubọ̀, tí kì í sì ṣe ọ̀rẹ́ rẹ́rùnrẹ́rùn.—Hébérù 5:14.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ padà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Bó o bá ń bá ọmọlúwàbí rìn, wàá lágbára nípa tẹ̀mí