Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Pankéèkì Ẹlẹ́gẹ̀ẹ́ Oúnjẹ Aládùn Ilẹ̀ Brazil

Pankéèkì Ẹlẹ́gẹ̀ẹ́ Oúnjẹ Aládùn Ilẹ̀ Brazil

Pankéèkì Ẹlẹ́gẹ̀ẹ́ Oúnjẹ Aládùn Ilẹ̀ Brazil

Látọwọ́ òǹkọ̀wé Jí! ní Brazil

ORÍṢIRÍṢI nǹkan tí wọ́n fi ẹ̀gẹ́ ṣe làwọn ará Brazil ń pè ní tapioca. Ọ̀kan lára wọn ni búrẹ́dì pẹlẹbẹ kan báyìí tí kò ní èròjà púpọ̀ nínú. Irú àwọn búrẹ́dì pẹlẹbẹ yìí jọ pankéèkì, ìdí sì nìyẹn tí wọ́n fi sábà máa ń pè wọ́n ní pankéèkì ẹlẹ́gẹ̀ẹ́. Irú tááṣì kan báyìí tí wọ́n ń pè ní polvilho doce tàbí goma, ni wọ́n máa ń fi ṣe é, ara ẹ̀gẹ́ ni wọ́n sì ti máa ń rí i.

Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti wa ẹ̀gẹ́, tí wọ́n bẹ ẹ́, wọ́n á rin ín, wọ́n á sì tẹ̀ ẹ́ kí omi tó funfun bíi mílíìkì lè ro jáde lára rẹ̀. Wọ́n á wá jẹ́ kí omi yìí silẹ̀ kí tááṣì inú rẹ̀ bàa lè rogún sísàlẹ̀. Lẹ́yìn èyí ni wọ́n á yọ́ omi orí rẹ̀ dànù, wọ́n á sì na tááṣì kíki tó wà nísàlẹ̀ sá sínú oòrùn kó lè gbẹ.

Àwọn ẹ̀ya Íńdíà tó ń gbé ní Brazil ló máa ń jẹ oúnjẹ tí wọ́n ń pè ní tapioca yìí nígbà kan. Nígbà tó yá, àwọn Potogí tó ń gbé ní Brazil wá rí i pé àwọn lè máa jẹ oúnjẹ yìí dípò búrẹ́dì. Kò tíì ju ọdún bíi mélòó kan báyìí tí tapioca di oúnjẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí gbayì lọ́wọ́ àwọn tó ń fi oúnjẹ gbígbọ́ ṣiṣẹ́ ṣe lórílẹ̀-èdè Brazil. Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí fi gbọ́únjẹ táyé ń fẹ́ nílé oúnjẹ wọn báyìí nìyẹn o.

Kó bàa lè tẹ́ àwọn èèyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ oúnjẹ tó ṣàrà-ọ̀tọ̀ lọ́rùn, àwọn agbọ́únjẹ náà bẹ̀rẹ̀ sí fi pankéèkì ẹlẹ́gẹ̀ẹ́ dá oríṣiríṣi àrà, wọ́n ń fi ọgbọ́n míì ṣe irú èyí tí wọ́n ti mọ̀ ọ́n ṣe tẹ́lẹ̀. Pankéèkì ẹlẹ́gẹ̀ẹ́ ti pọ̀ nígboro orílẹ̀-èdè Brazil báyìí, àwọn ará ibẹ̀ sì gba tiẹ̀ gan-an. Ọ̀pọ̀ ilé oúnjẹ ló wà níbẹ̀ táwọn èèyàn ti mọ̀ síbi tí wọ́n ti lè rí pankéèkì yìí jẹ.

Ìwọ náà ò ṣe gbìyànjú láti ṣe pankéèkì yìí wò ná? Wàá rí i pé àjẹpọ́nnulá ló máa jẹ́ fún tẹbí tọ̀rẹ́.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Bó O Ṣe Lè Ṣe Pankéèkì Ẹlẹ́gẹ̀ẹ́

Èròjà tó o lè fi ṣe pankéèkì mẹ́jọ:

Bu ṣíbí ìmùkọ mẹ́rìnlélógún tááṣì polvilho doce àti ife omi kan àtààbọ̀, kó o wá fi iyọ̀ díẹ̀ sí i.

Bó o ṣe máa ṣe é: Da tááṣì náà sínú abọ́ àdému kékeré kan, wọ́n iyọ̀ sí i, wọ́n omi díẹ̀ lé e lórí, kó o wá fi ika rò ó pọ̀. Lẹ́yìn náà kó o wá máa tami sí i díẹ̀díẹ̀ kó o sì máa fọwọ́ pò ó pọ̀ títí tá á fi rọ́ tí ò sì ní máa lẹ̀ mọ́ ẹ lọ́wọ́ bó o bá ń ra á róbóróbó. Ohun tó kàn ni pé kó fajọ̀ jọ̀ ọ́. Ó ti ṣeé fi ṣe pankéèkì nìyẹn.

Gbé páànù tí wọ́n fi ń dín nǹkan kaná, àmọ́ kí iná má pọ̀ nídìí ẹ̀ o. Wá pín ìyẹ̀fun tó o ti pò sí mẹ́jọ, kó o ju ọ̀kan lara rẹ̀ sínú páànù tó wà lórí iná, kó o sì fi ẹ̀yìn ṣíbí tẹ̀ ẹ́ pẹlẹbẹ. Jẹ́ kó lo ìṣẹ́jú méjì sí mẹ́rin lórí iná, tàbí kó wà lórí iná títí tí ìyẹ̀fun náà fi máa dà bíi kéèkì pẹlẹbẹ tí eteetí ẹ̀ á sì máa ta kúrò lára páànù. Ṣíbi oníke tí ẹnu rẹ̀ rí pẹrẹsẹ ló dáa láti fi yí i padà, sì jẹ́ kí apá kejì náà lo ìṣẹ́jú kan lorí iná. Ṣe àwọn méje tó kù náà bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn èyí, kó o tò wọ́n léra, wọ́n ti di jíjẹ nìyẹn.

Tó o bá tún fẹ́ kí pankéèkì ẹlẹ́gẹ̀ẹ́ yìí jojú ní gbèsè, o lè fàwọn nǹkan míì kún un. Tó o bá fẹ́ fi ṣe oúnjẹ àárọ̀, o lè fi bọ́tà pa á lórí nígbà tó ṣì ń gbóná, kó o tún wá fi ṣíbí ìmùkọ méjì lára àgbọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gé sí wẹ́wẹ́ kún un. Ohun tó o sì tún lè ṣe ni pé kó o tú mílíìkì kíki tó dùn sórí àwọn pankéèkì tó wà nílẹ̀ yíká, kó o fi àgbọn sí i, kó o sì ṣẹ́ pankéèkì náà po, ó ti di jíjẹ nìyẹn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ẹ̀gẹ́ rèé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Pankéèkì ẹlẹ́gẹ̀ẹ́ tí wọ́n fi àgbọn àti mílíìkì kíki tó dùn sí