Àmujù Ọtí Àkóbá Tó Ń Ṣe Fún Àwùjọ
Àmujù Ọtí Àkóbá Tó Ń Ṣe Fún Àwùjọ
NǸKAN méjì lọtí líle ń ṣe féèyàn, ó ń múnú èèyàn dùn, ó sì ń ba èèyàn nínú jẹ́. Bí ọtí bá mọ níwọ̀n, Bíbélì sọ pé ó lè múnú ọkàn ọmọ èèyàn yọ̀. (Sm. 104:15) Síbẹ̀, ó tún kìlọ̀ pé àmujù ọtí lè ṣe èèyàn léṣe tàbí kó tiẹ̀ ṣekú pààyàn, àfi bí ìgbà tí ejò olóró bá buni ṣán. (Òwe 23:31, 32) Ẹ wá jẹ́ ká fojú ṣùnnùkùn wo àdánù tí àmujù ọtí ń fà.
Ìwé ìròyìn Le Monde ròyìn pé: “Awakọ̀ kan tó ti mutí yó kọ lu adélébọ̀ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n àti ọmọkùnrin rẹ̀, ọmọ ọdún méjì lọ́jọ́ Sátidé . . . . Ọjọ́ kejì, ìyẹn ọjọ́ Sunday, ni ìyá yẹn gbẹ́mìí mì tòun ti oyún oṣù mẹ́fà nínú. Ọmọkùnrin ẹ̀ fi orí ṣèṣe, orí bó máa kú bó máa yè ló sì wà.” Ó bani nínú jẹ́ pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ bí èyí pọ̀ káàkiri. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà mọ ẹnì kan tó kàgbákò jàǹbá mọ́tò látàrí àmujù ọtí. Lọ́dọọdún lẹ̀mí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ń ṣòfò tí ọ̀pọ̀ sì ń fara pa nínú jàǹbá ojú pópó nítorí àmujù ọtí.
Iye Ẹ̀mí Tó Ń Ṣòfò
Káàkiri ayé, ká fi sẹ́nu ká dákẹ́ ni jàǹbá tí àmujù ọtí ń ṣe lọ́rọ̀ tẹrú tọmọ. Lórílẹ̀-èdè Faransé, tá a bá yọwọ́ àwọn tí àìsàn jẹjẹrẹ àti àìsàn òpójẹ̀ ń pa, àmujù ọtí ni nǹkan kẹta tó ń ṣekú pa èèyàn jù lọ lórílẹ̀-èdè náà nítorí bó ṣe ń pa nǹkan bí ọ̀kẹ́ méjì àbọ̀ èèyàn ní àpasára tàbí bó ṣe ń pa wọ́n kú fin-ín fin-ín, lọ́dọọdún. Iléeṣẹ́ ìjọba tó ń rí sí ọ̀ràn ìlera nílẹ̀ Faransé, French Health Ministry, sọ pé: “Ṣe ló dà bíi kí ọkọ̀ òfuurufú gbàgbàrà méjì tàbí mẹ́ta tó máa ń kó èrò tó lé nírínwó, máa já lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.”
Àwọn ọ̀dọ́ ló pọ̀ jù lára àwọn tó ń kàgbákò ikú látàrí àmujù ọtí. Ìròyìn kan tí Àjọ Ìlera Àgbáyé tẹ̀ jáde lọ́dún 2001 sọ pé ọtí ló ń ṣekú pa èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó ń kú láàárín àwọn ọ̀dọ́kùnrin ilẹ̀ Yúróòpù tí wọ́n wà láàárín ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí mọ́kàndínlọ́gbọ̀n. Wọ́n fojú dá a pé kò lè pẹ́ mọ́ tí àmujù ọtí á fi bẹ̀rẹ̀ sí pa ọ̀dọ́ kan nínú mẹ́ta láwọn orílẹ̀-èdè kan ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù.
Ó Ń Fa Ìwà Ipá àti Ìfipábánilòpọ̀
Ọtí wà lára ohun tó ń ti àwọn èèyàn hùwà ipá. Bí ọtí bá ti wọni lára tán ó lè mú kéèyàn má lè kó ara rẹ̀ níjàánu mọ́, ó sì lè mú kéèyàn má lè ṣe ohun tó yẹ kó ṣe, ó lè mú kéèyàn máa ṣi àwọn ẹlòmíì lóye kéèyàn sì dẹni tó tètè máa ń gbaná jẹ.
Ipa kékeré kọ́ ni ọtí ń kó nínú báwọn èèyàn ṣe ń fa wàhálà lábẹ́ ọ̀ọ̀dẹ̀ àti bí wọ́n ṣe ń fipá báwọn obìnrin ṣèṣekúṣe. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láàárín àwọn ẹlẹ́wọ̀n nílẹ̀ Faransé fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọtí ló fa méjì nínú gbogbo ìfipábánilòpọ̀ mẹ́ta tó bá wáyé àti bí wọ́n ṣe ń hùwà tí kò bójú mu sáwọn èèyàn. Ìwé ìròyìn Polityka gbé àbọ̀ ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nílùú Poland jáde pé nǹkan bíi mẹ́rin nínú márùn-ún lára àwọn aya tí ọkọ wọn jẹ́ ọ̀mùtí ni ìyà ti mọ́ lára tipátipá. Ìgbìmọ̀ kan tó ń rí sọ́ràn sáyẹ́ǹsì lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ oníṣègùn ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ìyẹn American Medical Association, Council on Scientific Affairs, fojú dá a pé: “Ọtí wà lára ohun tó ń mú kí iye ìpànìyàn láàárín tọmọdé tàgbà fi nǹkan bí ìlọ́po méjì lọ sókè sí i àti pé [kódà] ẹni tí kì í mutí àmọ́ tó ń bá ọ̀mùtí gbélé lè tètè rí ikú he látọwọ́ ọ̀mùtí náà.”
Bó Ṣe Kan Kóówá
Bá a bá ṣírò iye tí wọ́n fi ń tọ́jú àwọn tó fara pa nínú ìjàǹbá mọ́tò látàrí àmujù ọtí, iye tí ilé iṣẹ́ ìbánigbófò ń ná lórí ìṣòro táwọn ọ̀mùtí dá sílẹ̀ àti bí àmujù ọtí ṣe ń fawọ́ aago àwọn ilé iṣẹ́ sẹ́yìn, àgbọ́sọgbánù niye owó tó ń ṣègbé. Wọ́n sọ pé lọ́dún, iye tí àmujù ọtí ń gbọ́n lọ lápò mílíọ̀nù mẹ́rin èèyàn tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Ireland kò dín ní bílíọ̀nù kan dọ́là, owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Ìròyìn kan tó wà nínú ìwé ìròyìn The Irish Times ṣàlàyé pé “iye yẹn tó láti kọ́ ọsibítù tuntun kan, pápá eré ìdárayá kan àti láti máa ra ọkọ̀ òfuurufú kọ̀ọ̀kan fún gbogbo Mínísítà tó wà lórílẹ̀-èdè náà lọ́dọọdún.” Lọ́dún 1998, ìwé ìròyìn Mainichi Daily News ròyìn pé iye tí àtúbọ̀tán ìmukúmu ń gbọ́n dànù lápò orílẹ̀-èdè Japan ‘ju bílíọ̀nù márùndínlọ́gọ́ta dọ́là lọ lọ́dún.’ Ìròyìn kan tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilẹ̀ Amẹ́ríkà kà pé: ‘Nǹkan bí ọgọ́sàn-án ó lé márùn ún [185] bílíọ̀nù dọ́là ni àmujù ọtí gbọ́n dànù lápò orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 1998 nìkan, tàbí lédè míì, nǹkan bí òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó dín méjì [638] dọ́là èyí tó yẹ kó lọ sápò tẹrú tọmọ tó ń gbé lórílẹ̀-èdè náà lọ́dún yẹn.’ Èyí tá ò mọye ẹ̀ ńkọ́, ìyẹn ni àníyàn tó máa kún ọkàn ẹni tí àmujù ọtí mú kí òun àtẹni tó fẹ́ kọ́ra wọn sílẹ̀, tàbí ẹ̀dùn ọkàn tó máa bá mọ̀lẹ́bí ẹni tí àmujù ọtí ti sọ dèrò sàréè láìtọ́jọ́ àti àníyàn wọn lórí bí ọ̀mùtí náà ò ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ yege tàbí bí ò ṣe lè ṣàṣeyọrí nídìí ohun tó dáwọ́ lé?
Kò fi bẹ́ẹ̀ ṣòro láti rí i pé àmujù ọtí ń ṣe àkóbá fún àwùjọ. Ǹjẹ́ bó o ṣe ń mutí lè ṣe ọ́ léṣe kó sì tún ṣe àwọn ẹlòmíì náà léṣe? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀lé èyí yóò jíròrò ìbéèrè yìí.