Àmujù Ọtí Lè Kó Bá Ìlera Rẹ
Àmujù Ọtí Lè Kó Bá Ìlera Rẹ
“Santé!” “Salute!” “Za vashe zdorovye!” “Chuc suc khoe!” Yálà kó jẹ́ lórílẹ̀-èdè Faransé, Ítálì, Rọ́ṣíà tàbí Vietnam, wọ́n á kọ́kọ́ kí ara wọn báyẹn ná, kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí já nǹkan sára, wàá gbọ́: “Ẹ jẹ́ á máa bá fàájì bọ̀!” Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, fàájì tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn káàkiri àgbáyé láwọn ń ṣe yìí náà ló ń rán wọn lọ sínú sàréè.
Ọ̀PỌ̀ ọ̀nà ni ọtí àmujù pín sí, lára wọn ni mímutí débi tó fi lè ṣàkóbá, mímutí débi tó lè wu èèyàn léwu, àti sísọ ọtí mímu di bárakú. Àjọ Ìlera Àgbáyé túmọ̀ mímutí débi tó fi lè ṣàkóbá sí, “mímutí lọ́nà tó lè ṣe èèyàn léṣe,” nínú ara, nínú ọpọlọ tàbí kó kó tẹbí tọ̀rẹ́ àtará àdúgbò sí ìyọnu. Ó tún
túmọ̀ sí mímutí kọjá ìwọ̀n táwọn àjọ ètò ìlera fọwọ́ sí tàbí kọjá èyí tí òfin gbà láàyè. Ọtí àmujù tún máa ń sún èèyàn dédìí mímutí débi tó fi lè wu èèyàn léwu, ìyẹn ni àmujù ọtí tó ti ń ṣàkóbá fún ara tàbí ọpọlọ àmọ́ tí kò tíì di bárakú. Ó ti di bárakú nígbà tó bá di pé èèyàn “ò lè ṣe kó má mutí.” Ńṣe ni ọkàn ẹni tí ọtí ti di bárakú fún máa ń fà sí i ṣáá débi tí kò fi ní ka onírúurú ìṣòro tó wà nídìí ẹ̀ sí mọ́, kódà, irú wọn kì í gbádùn ara wọn bí wọ́n bá tiẹ̀ fẹ́ ṣíwọ́.Ò báà jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà, ọkùnrin tàbí obìnrin kódà ọmọ orílẹ̀-èdè yòówù kó o jẹ́, kò ní kó o má di alámuyíràá. Ọ̀nà wo ni ọtí gbà ń ṣèèyàn ní jàǹbá? Àwọn ewu wo ló wà nínú àmujù ọtí? Ní gbogbo gbòò, ìwọ̀n wo ló jẹ́ ìwọ̀ntúnwọ̀nsì tó yẹ kéèyàn mu?
Ó Léwu fún Ọpọlọ
Kẹ́míkà kan wà nínú ọ̀pọ̀ ọtí líle tó ń jẹ́ ẹ́tánọ́ọ̀lù. Ó lè kó bá ètò ìṣiṣẹ́ ọpọlọ tàbí kó tiẹ̀ bà á jẹ́ pàápàá. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé bí ẹní jẹ oríṣi kẹ́míkà kan mọ́ oúnjẹ lọ̀rọ̀ ẹni tó bá mu ọtí líle lámuyó. Bí kẹ́míkà yẹn bá pọ̀ jù lára èèyàn, ó lè mú kéèyàn dákú lọ gbári tàbí kónítọ̀hún tiẹ̀ kú fin-ín fin-ín. Bí àpẹẹrẹ, kò sí ọdún tí àṣà tí wọ́n ń pè ní ikkinomi, ìyẹn ṣíṣí ọtí líle dà sọ́fun láìdánudúró, kì í ṣekú pa àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ lórílẹ̀-èdè Japan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara wa lè yí kẹ́míkà yẹn padà sì èròjà tí kò lè pa wá lára, síbẹ̀ kì í ṣe lójú ẹsẹ̀. Béèyàn bá mu ọtí tó pọ̀ ju èyí tó lè tètè dà nínú ara ṣe ni kẹ́míkà yẹn, á tọró sínú ara, táá sì mú kí ọpọlọ bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lódìlódì. Lọ́nà wo?
Ńṣe ni àwọn ẹ̀yà ara tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ sísọ, ìríran, ìséraró, ìrònú àti ìṣesí so kọ́ra lónírúurú ọ̀nà dídíjú tí àwọn iṣan tó ń gbé ìsọfúnni kiri nínú ọpọlọ gbà ń ṣiṣẹ́. Bí kẹ́míkà yẹn bá tún wá wọra, ṣe ló máa dín agbára àwọn kan nínú àwọn iṣan náà kù tàbí kó mú kí wọ́n ṣiṣẹ́ kọjá bó ṣe yẹ. Ọpọlọ á wá máa tàtaré ìsọfúnni ségesège, kò sì ní lè ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé bí ẹnì kan bá mutí yó, àwọn nǹkan téèyàn á fi mọ̀ ni pé kò ní
lè sọ̀rọ̀ dáadáa, òòyì á máa kọ́ ọ, á máa ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́, tàbí kó má lè ṣàkóso ara ẹ̀ mọ́.Ọpọlọ ẹni tó bá ti jingíri sínú ọtí líle máa ń ṣiṣẹ́ lọ́nà tí oró kẹ́míkà tó wà nínú ọtí líle ò fi ní lè dà á láàmú táwọn iṣan ara rẹ̀ á sì lè máa ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, á di mọ́líkì sírú ẹni bẹ́ẹ̀ lára, tó túmọ̀ sí pé ìwọ̀n tó ń yọ ọ́ lẹ́nu tẹ́lẹ̀ ò ní máa fi bẹ́ẹ̀ yọ ọ́ lẹ́nu mọ́. Ó máa ń di bárakú nígbà tó bá ti wọnú ọpọlọ débi tó jẹ́ pé bí ẹni yẹn ò bá tíì mu ọtí líle, kò ní lè ṣe nǹkan bó ṣe yẹ. Á wá di pé kónítọ̀hún máa yán hànhàn fún ọtí líle kí ọpọlọ rẹ̀ bàa lè ṣiṣẹ́ dáadáa. Bí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ó bá rí ọtí líle, ṣe ni ọpọlọ wọn á kọṣẹ́ pátápátá tí wọ́n á sì máa ṣàníyàn, ara wọn á máa gbọ̀n rìrì, tàbí kí wọ́n máa ṣàdédé dákú lọ gbári.
Yàtọ̀ sí pé ọtí líle ń yí ọ̀nà tí ọpọlọ gbà ń ṣiṣẹ́ padà, ó tún lè mú káwọn sẹ́ẹ̀lì inú ọpọlọ dẹwọ́ iṣẹ́ tàbí kó bà wọ́n jẹ́, èyí tó máa ń mú kí ọ̀nà tí ọpọlọ gbà ń ṣiṣẹ́ yí padà pátápàtá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìsúnmọ́ ọtí mọ́ lè ṣe díẹ̀ níbẹ̀, síbẹ̀ ó dàbí pé àwọn ìpalára kan tó bá ti ṣe kì í ṣeé ṣàtúnṣe sí, ó tún lè ra èèyàn níyè, èèyàn ò sì ní lè lo làákàyè níbi tó bá yẹ. Ó ṣe tán, kò pọn dandan kó pẹ́ téèyàn ti ń múti líle kó tó lè ṣàkóbá fún ọpọlọ. Ìwádìí ń jẹ́ ká mọ̀ pé kódà tí ò bá tiẹ̀ tíì pẹ́ téèyàn ti ń mutí, ó lè pààyàn lára.
Àrùn Ẹ̀dọ̀ àti Àrùn Jẹjẹrẹ
Ipa kékeré kọ́ ni ẹ̀dọ̀ ń kó nínú yíyí oúnjẹ padà sí èròjà tó máa ṣara lóore, nínú gbígbógun ti àrùn, nínú mímú kí ẹ̀jẹ̀ inú ara máa ṣàn bó ṣe yẹ àti nínú mímú oró kẹ́míkà, irú èyí tó máa ń wà nínú ọtí líle kúrò nínú ara. Ìpele mẹ́ta ni àkóbá tí ọtí àmujù ń ṣe fún ẹ̀dọ̀ pín sí. Ìpele àkọ́kọ́, tí wọ́n ń pè ní steatohepatitis, ni ìpele tí ara ti máa ń fọ́ kẹ́míkà ọtí líle sí wẹ́wẹ́, èyí sì máa ń mú kí ọ̀rá pẹ́ gan-an kó tó dà nínú ara, bó bá sì ti ń pẹ́ jù, ńṣe làwọn ọ̀rá yẹn á gbára jọ síbi tí ẹ̀dọ̀ wà tí wọ́n á fi bò ó mọ́lẹ̀. Nígbà tó bá ṣe, àrùn mẹ́dọ̀wú lílekoko á yọjú. Yàtọ̀ sí pé ọtí líle lè fa àrùn mẹ́dọ̀wú ní tààràtà, ó ṣeé ṣe kó tún máa dín agbára tí ara ní láti dènà kòkòrò àrùn mẹ́dọ̀wú oríṣi kejì àti oríṣi kẹta kù. a Béèyàn ò bá múra sí i, àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ara á wú, bí àwọn sẹ́ẹ̀lì náà bá sì ti bẹ́, wọ́n parí iṣẹ́ nìyẹn. Láfikún sí jàǹbá yìí, ó ṣeé ṣe kí ọtí líle túbọ̀ tanná ran ohun tó ń ṣekú pa sẹ́ẹ̀lì tí apilẹ̀ àbùdá wa ń darí.
Ìpele tó kẹ́yìn ni àrùn ìsúnkì ẹ̀dọ̀. Bí ẹ̀dọ̀ ò bá yé wú, sẹ́ẹ̀lì inú ara á bà jẹ́ kọjá àtúnṣe. Nígbà tó bá yá, ẹ̀dọ̀ á dì gbagidi dípò kó rí múlọ́múlọ́. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, bó ṣe dì yẹn ò ní jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ lè máa ṣàn dáadáa káàkiri ara, á wá di pé kí ẹ̀dọ̀ dáwọ́ iṣẹ́ dúró kẹ́ni náà sì gbẹ́mìí mì.
Ọṣẹ́ mìíràn wà tí ọtí líle máa ń yọ́ kẹ́lẹ́ ṣe fún ẹ̀dọ̀, ìyẹn ni bó ṣe máa ń mú kí ẹ̀dọ̀ má lè lágbára láti dènà kòkòrò tó ń fa àrùn jẹjẹrẹ. Yàtọ̀ sí pé ọtí líle máa ń dá kún bí àrùn jẹjẹrẹ inú ẹ̀dọ̀ ṣe ń bẹ̀rẹ̀, ó tún máa ń mú kí àrùn jẹjẹrẹ ẹnu, ti ọ̀nà ọ̀fun, ti gògóńgò àti ti ihò ọ̀fun tètè ṣe èèyàn. Síwájú sí i, ọtí líle máa ń jẹ́ kí èròjà kan tó wà nínú sìgá, tó ń fa àrùn jẹjẹrẹ, tètè ráàyè wọnú itọ́, èyí tó túbọ̀ fi àwọn tó ń mu sìgá sínú ewu tó légbá kan. Àwọn obìnrin tí wọn ò lè ṣe kí wọ́n má mutí lóòjọ́ ni àrùn jẹjẹrẹ ọmú tètè máa ń ṣe. Ìwádìí kan tiẹ̀ sọ pé àwọn tó ń mutí tó ní kẹ́míkà ọtí líle ìwọ̀n ṣíbí ìmùkọ mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lóòjọ́ ni wọ́n lè tètè ní àrùn jẹjẹrẹ ọmú ju àwọn tí kì í mutí rárá.
Bí Àwọn Ọmọ Inú Ọlẹ̀ Ṣe Ń Jẹ Májèlé
Èyí tó burú jù lára àtúbọ̀tán àmujù ọtí ni bó ṣe ń kó bá oyún inú. Ìwé ìròyìn àgbáyé, International Herald Tribune sọ pé: “Lára àwọn oògùn olóró tó wà, ọtí líle ló ń kó bá oyún inú jù lọ.” Ní gbogbo ìgbà tí aboyún bá mutí, ọmọ inú ẹ̀ náà ti mutí nìyẹn, àkóbá tí ọtí líle sì máa ń ṣe fún oyún inú lásìkò táwọn ẹ̀yà ara ń dàgbà yẹn burú jáì. Ọtí líle máa ń ba ibi tó dà bí ilé agbára tó ń mú kí ọpọlọ ṣiṣẹ́ jẹ́ kọjá àtúnṣe. Kì í jẹ́ káwọn iṣan inú ọpọlọ lè dàgbà débi tó yẹ. Ó máa ń ba àwọn sẹ́ẹ̀lì ara ọmọ inú jẹ́. Àwọn sẹ́ẹ̀lì kan tiẹ̀ máa ń dàgbà sí àyè tó yẹ kí sẹ́ẹ̀lì mìíràn wà.
Kéèyàn máa mutí bó bá lóyún ló sábà máa ń fa àrùn kan tó máa ń jẹ́ kí ọmọ ìkókó rìndìn. Lára ìṣòro tó máa ń dojú kọ irú àwọn ọmọ yẹn ni àìjáfáfá, àìlè-tètè gbédè, kọ́mọ má tètè gbọ́n, híhùwà lódìlódì, kí ọmọ rán, kára má balẹ̀, àìlè gbọ́ràn dáadáa àti àìríran dáadáa. Àléébù máa ń wà lójú àwọn ọmọ tí wọ́n bá bí pẹ̀lú irú àrùn yẹn.
Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọmọ táwọn òbí wọn tiẹ̀ mutí níwọ̀nba nígbà tí wọ́n lóyún wọn pàápàá máa ń láwọn àbùkù ara kan irú bíi kí wọ́n máa ṣe wọ́nran-wọ̀nran àti kí wọ́n má lè kẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀jọ̀gbọ́n Ann Streissguth, tóun náà jẹ́ obìnrin, ní ẹ̀ka tó ń rí sọ́rọ̀ àwọn aboyún tó ń mutí, ní ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Washington, sọ pé “kò dìgbà tó o bá ń mu àmujù ọtí kó o tó kó bá ọmọ inú ẹ, tó o bá ti ń fẹnu kàn án báyìí, o ti ń kó bá ọmọ náà nìyẹn.” Ìròyìn kan tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní Alcool—Effets sur la santé, wá láti iléeṣẹ́ ètò ìlera àti ìwádìí ìṣègùn nílẹ̀ Faransé, ìyẹn National Institute b
of Health and Medical Research. Ìròyìn tó dá lórí àìlera tí ọtí líle ń fà yìí, sọ pé: “Ó léwu fún aboyún láti fẹnu kan ọtí líle nígbàkigbà tí oyún bá fi wà nínú ẹ̀, kódà títí di bá a ṣe ń wí yìí, kò tíì sí ìwọ̀n tí aboyún lè mu tí ò ní ṣèpalára.” Fún ìdí èyí, ohun tó dáa jù ni pé kí aboyún tàbí ẹni tó bá ń gbèrò àtilóyún rí i pé òun ò fẹnu kan ọtí líle èyíkéyìí rárá.Ìwọ̀n Téèyàn Lè Mu Tí Ò Ní Ṣèpalára
Ìpalára tí ọtí líle ń ṣe ṣì pọ̀ jáǹrẹrẹ ju èyí tá a sọ lókè yìí. Lọ́dún 2004, àpilẹ̀kọ kan tó jáde nínú ìwé ìròyìn Nature fa kókó ọ̀rọ̀ yọ, ó ní: “Ìwọ̀n ọtí líle tó kéré gan-an téèyàn bá mu á jẹ́ kéèyàn sún mọ́ bèbè àtiko jàǹbá, á sì túbọ̀ mú kó rọrùn gan-an láti kó àrùn tó tó ọgọ́ta.” Níbi tí ọ̀rọ̀ dé yìí, ìwọ̀n wo lèèyàn lè mu tí ò ní ṣèpalára? Lónìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn kárí ayé ló ń mutí lọ́nà tí ò lè pa wọ́n lára nígbà tí wọ́n bá ń ṣe fàájì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àṣírí bí ò ṣe ní pààyàn lára ni pé kéèyàn máa mu ún níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Ìwọ̀n wo gan-an ni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ìwọ̀n táwọn ń mu wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Wọ́n lè máa ronú pé báwọn ò bá ṣáà ti yó bìnàkò tí kò sì tíì di pé báwọn ò bá rí ọtí àwọn ò lè jẹun, a jẹ́ pé àbùṣebùṣe. Síbẹ̀, ẹnì kan nínú ọkùnrin mẹ́rin nílẹ̀ Yúróòpù ló ń mu ìwọ̀n ọtí líle tó lè ṣe é léṣe.
Onírúurú ìsọfúnni ló fi hàn pé kẹ́míkà ọtí líle tó yẹ kò wà nínú ìwọ̀n ọtí téèyàn lè mu lóòjọ́ kò gbọ́dọ̀ ju ṣíbí ìmùkọ kan àti díẹ̀ lọ fáwọn ọkùnrin àti nǹkan bíi ṣíbí ìmùkọ kan fáwọn obìnrin tàbí lédè míì, ìwọ̀n méjì fáwọn ọkùnrin àti ìwọ̀n kan fáwọn obìnrin. Àjọ ètò ìlera nílẹ̀ Faransé àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì dábàá pé “ìwọ̀n tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì” fáwọn ọkùnrin lóòjọ́ ni ṣíbí ìmùkọ méjì, tí tàwọn obìnrin sì jẹ́ ṣíbí ìmùkọ kan ó lé díẹ̀. Ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀ràn àmujù ọtí lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìyẹn U.S. National Institute on Alcohol Abuse and Alcoholism, fi kún un pé, “káwọn tó bá ti tó ọmọ ọdún márùnlélọ́gọ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ dín ìwọ̀n ọtí líle tí wọ́n ń mu kù sí nǹkan bíi ṣíbí ìmùkọ kan lóòjọ́.” c Ó kàn jẹ́ pé ara yàtọ̀ sára lórí ọ̀ràn ọtí mímu. Fáwọn kan, ìwọ̀n tá a pè ní èyí tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì yìí gan-an lè ti pọ̀ jù fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, Ìròyìn Pàtàkì Ẹlẹ́ẹ̀kẹwàá Tí Wọ́n Fi Ránṣẹ́ sí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilẹ̀ Amẹ́ríkà Lórí Ọ̀rọ̀ Ọtí Líle àti Ìlera, kà pé: “Ìwọ̀n ọtí líle tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì lè ṣèpalára fáwọn tó ní àrùn tó ń mú ìṣesí ẹni yàtọ̀ àti àníyàn.” Ọjọ́ orí, àkọsílẹ̀ àtẹ̀yìnwá lórí àìsàn tó ti ṣèèyàn rí àti oògùn téèyàn lò sí i, àti bí èèyàn ṣe tóbi tó, wà lára ohun tó yẹ kéèyàn gbé yẹ̀ wò kó tó o mutí.—Wo àpótí náà, “Bó O Ṣe Lè Dín Ìpalára Tó Lè Ṣe Kù.”
Ìrànlọ́wọ́ wo ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó fáwọn tó ń mutí para? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e á dáhùn ìbéèrè yìí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní ilẹ̀ Faransé ṣe fi hàn, àwọn ọ̀mùtí tó bá ní kòkòrò àrùn mẹ́dọ̀wú oríṣi kẹta lè tètè kàgbákò àrùn ìsúnkì ẹ̀dọ̀ nígbà méjì ju ẹni tó ní kòkòrò àrùn mẹ́dọ̀wú kan náà àmọ́ tó ń mutí níwọ̀nba lọ. Wọ́n wá dábàá pé kí ẹni tó bá ní kòkòrò àrùn mẹ́dọ̀wú náà máa mutí níwọ̀nba tàbí kó má tiẹ̀ mu ún rárá.
b Ó yẹ káwọn tó ń fọ́mọ lọ́mú mọ̀ pé ṣe ni ọtí líle táwọn bá mu máa dà pọ̀ mọ́ omi ọyàn àwọn. Kódà, tá a bá wọ̀n ọ́n, ìwọ̀n ọtí líle tó máa ń dà pọ̀ mọ́ omi ọyàn ẹni tó ń tọ́ ọmọ lọ́wọ́ sábà máa ń pọ̀ ju èyí tó máa ń dà pọ̀ mọ́ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ. Ohun tó fà á ni pé omi ọyàn pọ̀ ju omi tó wà nínú ẹ̀jẹ̀ lọ, èyí ló máa ń mú kí ọtí líle yára dà pọ̀ mọ́ omi ọyàn ju bó ṣe máa dà pọ̀ mọ́ ẹ̀jẹ̀ lọ.
c Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìwọ̀n “ọtí” líle téèyàn lè mu lẹ́ẹ̀kan yàtọ̀ síra láti ibì kan sí òmíràn, ìwọ̀n téèyàn bá máa mu lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo yẹ kó jẹ́ èyí tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì ládùúgbò yẹn, èèyàn sì gbọ́dọ̀ rí i pé kì í ṣe ìwọ̀n tó lè ṣèpalára fóun.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
KÉÈYÀN GBÉ DÍẸ̀ LURA KÓ TÓ WAKỌ̀ KẸ̀?
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ọjọ́ tí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kọ́kọ́ rìn lọ́nà láyé ni wọ́n ti ṣòfin pé kéèyàn má mutí tó bá ń wakọ̀. Orílẹ̀-èdè Denmark ni wọ́n ti kọ́kọ́ gbé òfin yẹn jáde lọ́dún 1903.
Bó o bá fi ọtí tẹ́lẹ̀ inú láìjẹun, kẹ́míkà ọtí líle tó wà nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ á yára pọ̀ sí i láàárín ọgbọ̀n ìṣẹ́jú tó o mu ún. Àwọn kan tiẹ̀ máa ń sọ pé ọtí máa tètè dá lójú ẹ bó o bá lè mu kọfí, tó o mí sínú dáadáa tàbí tó o ṣeré ìmárale. Àmọ́, ilẹ̀ á ta sí i kí ọtí tó o mu tó lè ṣiṣẹ́ tán lára. Má gbàgbé pé “ọtí ni ọtí ń jẹ́ o.” Ò báà mu ìwọ̀n wáìnì, bíà tàbí ògógóró téèyàn lè mu lẹ́ẹ̀kan, ìwọ̀n kẹ́míkà kan náà ló wà nínú wọn. d
Kódà, ìwọ̀n ọtí líle tó o bá ta sọ́fun téré lè mú kó o wakọ̀ níwàkuwà. Kò ní jẹ́ kó o ríran dáadáa. Àwọn àmì òfin ìrìnnà á wá kéré gan-an lójú ẹ. Ojú kò ní lè rí ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún àti ẹ̀gbẹ́ òsì nígbà tó o bá ń wo ọ̀kánkán, o ò ní lè mọ bó o ti ṣe jìnnà tàbí bó o ti ṣe sún mọ́ nǹkan tó àti pé o ò ní lè rí ohun tó bá wà níwájú ẹ dáadáa. Ọpọlọ ò ní lè tètè ronú dáadáa, o ò sì ní lè tètè mọ ohun yẹ kó o ṣe lásìkò tó bá yẹ.
Bí jàǹbá bá ṣẹlẹ̀ lásìkò tó o ti mutí yó, ó ṣeé ṣe kó o fara pa gan-an jù ìgbà tó ò bá mutí lọ. Síwájú sí i, bí wọ́n bá ní láti ṣiṣẹ́ abẹ fún ọ, ó ṣeé ṣe kó o má lè yè é nítorí jàǹbá tí ọtí á ti ṣe fún ọkàn rẹ àti báá ṣe máa dí ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́ láti máa lọ káàkiri ara. Ìyẹn ni ẹ̀ka ètò ìlera àti ìwádìí ìṣègùn nílẹ̀ Faransé ṣe sọ pé: “Àwọn tó ń mutí wakọ̀ ló sábà máa ń kú jù tí jàǹbá ọkọ̀ bá ṣẹlẹ̀, èyí sì yàtọ̀ sí èrò ọ̀pọ̀ èèyàn.” Nítorí bí ewu ibẹ̀ ṣe pọ̀ tó, àbá tó wà nínú ìròyìn náà ni pé:
◼ Má ṣe wakọ̀ tó o bá ti mutí.
◼ Má ṣe gbà kí awakọ̀ tó ti mutí wà ọ́.
◼ Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀rẹ́ ẹ tàbí àwọn òbí ẹ wakọ̀ bí wọ́n bá mutí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
d Ní gbogbo gbòò, kìkì nǹkan bí ìdajì ṣíbí ìmùkọ kan kẹ́míkà inú ọtí líle ni òòlọ̀ tó ń mu oúnjẹ dà nínú ara lè mú kó dà láàárín wákàtí kan. Ìwọ̀n ọtí tó jẹ́ ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ní orílẹ̀-èdè kan yàtọ̀ sí ti orílẹ̀-èdè mìíràn. Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé ìwọ̀n kẹ́míkà inú ọtí líle tó yẹ kó wà nínú ọtí téèyàn lè mu lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ò gbọ́dọ̀ ju ṣíbí ìmùkọ kan lọ. Èyí jẹ́ déédéé ìwọ̀n ṣíbí ìmùkọ bíà mẹ́rìndínlógún, ìwọ̀n ṣíbí ìmùkọ wáìnì méje, tàbí ìwọ̀n ṣíbí ìmùkọ họ́ọ̀tì méjì.
[Àwọn àwòrán]
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìwọ̀n kẹ́míkà inú ọtí líle kan náà ló wà nínú ìwọ̀n ọtí wọ̀nyí
Bíà ìlàjì ìgò (Ó ní nǹkan bí ṣíbí ìmùkọ kan kẹ́míkà inú ọtí líle)
Gàásì họ́ọ̀tì kan (wisikí, jíìnì, vodka) (Ó ní kẹ́míkà ọtí líle tó lé díẹ̀ ní ṣíbí ìmùkọ kan ààbọ̀)
Ife wáìnì kan (Ó ní ìwọ̀n kẹ́míkà inú ọtí líle tó lè díẹ̀ ní ṣíbí ìmùkọ kan)
Tọ́ńbìlà burandí ẹlẹ́rìndòdò kékeré kan (Ó ní kẹ́míkà ọtí líle tó lé díẹ̀ ní ṣíbí ìmùkọ kan)
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
ṢÉ APILẸ̀ ÀBÙDÁ LÓ Ń JẸ́ KÍ ỌTÍ DI BÁRAKÚ?
Ìsapá táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń ṣe kí wọ́n lè mọ bí wọ́n á ṣe máa tọ́jú àwọn tí ọtí àmupara ti di bárakú fún ti jẹ́ kí wọ́n lóye ipa tí apilẹ̀ àbùdá ń kó nínú báwọn èèyàn ṣe ń nífẹ̀ẹ́ sí ọtí àti bó ṣe ń wọ̀ wọ́n lára. Ó ti tó apilẹ̀ àbùdá bíi mélòó kan táwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ yẹn ti rí tó dà bíi pé ó ń jẹ́ káwọn èèyàn fẹ́ láti mutí. Síbẹ̀, kì í ṣe apilẹ̀ àbùdá nìkan ló ń fa ìmutípara. Kódà, àwọn tí wọ́n tiẹ̀ jogún irú apilẹ̀ àbùdá bẹ́ẹ̀ ṣì lè rọ́nà gbé e gbà tí ọtí ò fi ní di bárakú fún wọn. Ipò tí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bá ara wọn náà lè ṣe díẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ wọn. Lára àwọn nǹkan tó tún ń ṣokùnfà ìmutípara ni káwọn òbí má máa bójú tó àwọn ọmọ, káwọn òbí, àwọn aráalé tàbí àwọn ojúgbà ẹni máa mu àmujù ọtí, kéèyàn máa ní aáwọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, kí ọkàn èèyàn má balẹ̀, kéèyàn máa ro àròdùn, kéèyàn máa hùwà ìpáǹle, káwọn èèyàn máa fi ọtí dárayá, kí òórùn ọtí líle nìkan ti máa da èèyàn láàmú tàbí káwọn oògùn olóró míì ti mọ́ èèyàn lára. Àwọn nǹkan tá a dárúkọ yìí àtàwọn míì ló máa ń mú kí ọtí di bárakú.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
FARANSÉ:
Ìṣirò fi hàn pé ó tó bíi mílíọ̀nù márùn-ún èèyàn tó ń mutí para lórílẹ̀-èdè náà, àti pé mílíọ̀nù méjì tàbí mẹ́ta ni ọtí líle ti di bárakú fún
NÀÌJÍRÍÀ:
Ìwé ìròyìn Daily Champion tí wọ́n ń tẹ̀ nílùú Èkó, sọ pé: “Ó lé ní mílíọ̀nù márùndínlógún ọmọ Nàìjíríà tó ya ọ̀mùtí,” ìyẹn ni pé ó ju ẹnì kan lọ nínú ọmọ orílẹ̀-èdè yìí mẹ́wàá tó ń mutí para
POTOGÍ:
Ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń mu ọtí líle jù lọ ní gbogbo ayé ni orílẹ̀-èdè yìí. Ìwé ìròyìn Lisbon, Público ròyìn pé, ẹnì kan nínú mẹ́wàá ọmọ orílẹ̀-èdè yìí ló ti di “aláàbọ̀ ara látàrí àmujù ọtí líle”
ILẸ̀ AMẸ́RÍKÀ:
Ìròyìn Pàtàkì Ẹlẹ́ẹ̀kẹwàá Tí Wọ́n Fi Ránṣẹ́ sí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilẹ̀ Amẹ́ríkà Lórí Ọ̀rọ̀ Ọtí Líle àti Ìlera, kà pé: “Ó tó mílíọ̀nù mẹ́rìnlá ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ìyẹn ìdá méje ó lé díẹ̀ lára gbogbo olùgbé ibẹ̀, tí àyẹ̀wò ìṣègùn tí wọ́n ṣe fi hàn pé ọ̀mùtí tàbí ẹni tó ń mu àmuyíràá ni”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
BÓ O ṢE LÈ DÍN ÌPALÁRA TÓ LÈ ṢE KÙ
Ẹ̀ka tó ń rí sí ìlera ọpọlọ àtàwọn ohun tó ń di bárakú lábẹ́ àsíá Àjọ Ìlera Àgbáyé, ìyẹn Department of Mental Health and Substance Dependence of the World Health Organization, ló tẹ àlàyé tó tẹ̀lé e wọ̀nyí jáde nípa ohun tí ìwọ̀n tí kò lè pa èèyàn lára túmọ̀ sí. Pé ewu náà dín kù kò fi hàn pé kò léwu rárá o. Ara yàtọ̀ sára.
◼ Má ṣe mu ju ọtí méjì lóòjọ́ e
◼ Ó kéré tán, má ṣe mutí láàárín ọjọ́ méjì lọ́sẹ̀
Ó ṣeé ṣe kí ọtí tó ní kẹ́míkà inú ọtí líle tó jẹ́ ìwọ̀n ṣíbí ìmùkọ méjì tàbí ẹyọ kan pàápàá pọ̀ jù:
◼ Nígbà tó o bá ń wakọ̀ tàbí tó o bá ń lo ẹ̀rọ̀
◼ Bó o bá ń tọ́mọ lọ́wọ́ tàbí tó o bá lóyún
◼ Bó o bá ṣì ń lo oògùn tí dókítà fún ẹ
◼ Bó o bá ní nǹkan kan tó ń yọ ẹ́ lẹ́nu
◼ Bó ò bá lè mojú kúrò lára ọtí
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
e Ìwọ̀n tí wọ́n ń pè ní ọtí kan ni ọtí tí kẹ́míkà ọtí líle tó wà nínú ẹ̀ kò ju nǹkan bíi ṣíbí ìmùkọ kan lọ.
[Credit Line]
Ibi tá a ti rí ìsọfúnni: Ìwé Brief Intervention for Hazardous and Harmful Drinking
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
ṢÉ ỌTÍ LÍLE NÍ OORE GIDI KAN TÓ Ń ṢE ỌKÀN?
Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ gbà pé àwọn èròjà tó wà nínú wáìnì pupa máa ń ṣèdíwọ́ fún kẹ́míkà tó ń mú kí òpójẹ̀ sún kì.
Síwájú sí i, wọ́n ti sọ pé ọtí líle wà lára ohun tó ń mú kí ọ̀rá mọ níwọ̀n nínú ara. Ó sì tún máa ń dín èròjà tó ń mú kí ẹ̀jẹ̀ dì kù.
Bí oore kan bá wà tí ọtí líle lè ṣe èèyàn, á jẹ́ pé àfi téèyàn bá lè máa mu díẹ̀ díẹ̀ nígbà mélòó kan láàárín ọ̀sẹ̀ dípò mímu púpọ̀ ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo. Mímu ọtí líle tó ju ṣíbí ìmùkọ mẹ́ta lọ lóòjọ́ wà lára ohun tó máa ń mú kí ìfúnpá èèyàn ga sí i, bó bá sì ti di àmujù, ó lè súnná sí àrùn rọpárọsẹ̀, ó tún lè mú kí ọkàn máa wú, èyí tó máa ń mú kéèyàn má lè mí dáadáa. Àwọn àtúbọ̀tán tá a mẹ́nu kàn wọ̀nyí àtàwọn míì tí àmuyíràá ń fà ju oore yòówù tí ọtí lè máa ṣe láti mú kí ọkàn ṣiṣẹ́ lọ. Ká tiẹ̀ ní ọtí dáa lára, bí nǹkan rere bá pọ̀ jù pàápàá, kì í dáa.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
BÍ ỌTÍ LÍLE ṢE LÈ BA AYÉ ÈÈYÀN JẸ́
Ọpọlọ
Sẹ́ẹ̀lì á bàjẹ́, iyè á ra, ìsoríkọ́, títètè bínú
Èèyàn ò ní ríran dáadáa, kò ní lè sọ̀rọ̀ dáadáa kò sì ní lè séra ró
Àrùn jẹjẹrẹ ọ̀fun, ti ẹnu, ti ọmú, ti ẹ̀dọ̀
Ọkàn
Iṣan á máa dẹ̀, ọkàn lè déédéé dáwọ́ iṣẹ́ dúró
Ẹ̀dọ̀
Ọ̀rá máa pọ̀ nínú ẹ̀, lẹ́yìn náà, á tóbi sí i, lẹ́yìn náà, á wá yi (àrùn ìsúnkì ẹ̀dọ̀)
Àwọn jàǹbá míì
Ètò inú ara tó ń dènà àrùn á bà jẹ́, ọgbẹ́ inú, àmọ́ tó wà lórí ẹ̀dọ̀ á wú
Àwọn aboyún
Ọmọ inú rẹ̀ lè ya abirùn tàbí kó ya arìndìn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
“Lára àwọn oògùn olóró tó wà, o fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kẹ́míkà inú ọtí líle ló ń kó bá oyún inú jù”