Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó Wàásù Lọ́nà Tó Múná Dóko Nílé Ìwé

Ó Wàásù Lọ́nà Tó Múná Dóko Nílé Ìwé

Ó Wàásù Lọ́nà Tó Múná Dóko Nílé Ìwé

Látọwọ́ òǹkọ̀wé Jí! ní Mẹ́síkò

NÍ ÌBẸ̀RẸ̀ ọdún tuntun nílé ìwé àwọn Daniel tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, ó pinnu pé òun á jẹ́ káwọn ọmọ kíláàsì òun mọ òun gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀nà wá ṣí sílẹ̀ fún un wàyí nígbà tí ọ̀gá tó ń kọ́ wọn ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ní káwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹnì kan tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè míì, tí èdè Gẹ̀ẹ́sì sì jẹ́ èdè ìbílẹ̀ rẹ̀. Ohun tó ní kí wọ́n ṣe ni pé kí wọ́n lọ síbi táwọn àrìnrìn-àjò afẹ́ máa ń ṣèbẹ̀wò sí nílùú Mexico City, kí wọ́n fọ̀rọ̀ wá ẹnì kan lẹ́nu wò, kí wọ́n sì wá fi bí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ọ̀hún bá ṣe lọ sí han àwọn tó kù ní kíláàsì lórí fídíò.

Ohun tí Daniel ṣe ni pé ó lọ fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu míṣọ́nnárì kan tó jẹ́ elédè Gẹ̀ẹ́sì, ẹni tó ń ṣiṣẹ́ ní iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tá à ń pè ní Bẹ́tẹ́lì, lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Ó fi fídíò ya Bẹ́tẹ́lì yẹn, ó sì fi èdè Gẹ̀ẹ́sì sàlàyé ohun tó yà náà sínú ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó pàtẹ oríṣiríṣi ìwé pẹlẹbẹ tí wọ́n tẹ̀ láwọn onírúurú èdè tí wọ́n ń sọ ní Mẹ́síkò, àtàwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tí wọ́n tẹ̀ ní onírúurú èdè. Daniel wá bẹ olùkọ́ tó ń kọ́ ọ lédè Gẹ̀ẹ́sì pé kó jẹ́ kóun fi fídíò àtàwọn ìwé náà han àwọn ọmọ kíláàsì òun.

Ẹnu ya àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀, àti olùkọ́ náà pàápàá, nígbà tí wọ́n rí iṣẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ní Mẹ́síkò. Inú gbogbo wọn dùn sí iṣẹ́ ribiribi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe láti mú ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè náà.

Ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ló gba Daniel láti fi fídíò àtàwọn ìwé náà hàn wọ́n, òun ló sì gba máàkì tó pọ̀ jù nínú àfihàn yìí. Nígbà tí wọ́n parí rẹ̀, Daniel fún gbogbo wọn ní ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, tó fi mọ́ ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè-Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́. Ọ̀pọ̀ wọn ló gba àwọn ìwé yìí, èyí sì yorí sí ọ̀pọ̀ ìjíròrò síwájú sí i láti inú Bibélì. Daniel sọ pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ kí n lè fi iṣẹ́ àṣetiléwá ráńpẹ́ tá a ṣe nílé ìwé yẹn mú ọlá bá orúkọ rẹ̀.”