Ṣé Káwọn Obìnrin Máa Bo Ẹwà Wọn Mọ́ra Ni?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ṣé Káwọn Obìnrin Máa Bo Ẹwà Wọn Mọ́ra Ni?
ARÁNṢỌ àsìkò kan tó ń jẹ́ George Simonton, tó tún jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nílé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ nípa oge ṣíṣe, ìyẹn New York’s Fashion Institute of Technology, sọ pé: “Àwọn obìnrin fẹ́ràn oge ṣíṣe, wọ́n á múra nigínnigín bíi pé kò sírú wọn, wọ́n fẹ́ràn àtimáa ṣe ohunkóhun tó lè fi kún ẹwà wọn . . . Mo rò pé ìyẹn ń buyì kún yín, ó sì ń pọ́n àwọn tó mọ̀ yín lé.” Ọ̀rọ̀ ni ọ̀jọ̀gbọ́n George kúkú sọ torí pé kì í ṣèní kì í ṣàná tá a ti mọ àwọn obìnrin mọ ohun ọ̀ṣọ́, èyí tó máa ń ṣàlékún ẹwà wọn tó sì máa ń jẹ́ káwọn náà wuyì láwùjọ.
Àmọ́, àwọn kan ti ń fi ìsìn bojú láti bẹnu àtẹ́ lu báwọn obìnrin ṣe ń lo ohun ọ̀ṣọ́. Ní ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Kristẹni, Tertullian kọ̀wé kan, apá kan lára ìwé náà kà pé: ‘Àwọn obìnrin mímọ́ tí wọ́n jẹ́ òrékelẹ́wà kò gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun láti ṣàlékún ẹwà yẹn kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ kí wọ́n gbìyànjú láti bo ẹwà náà mọ́ra.’ Ó tún sọ nípa ohun ìṣaralóge pé: “Ńṣe làwọn obìnrin ń dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run bí wọ́n ṣe ń lo ìpara, tí wọ́n ń kun àtíkè pupa tàbí bí wọ́n ṣe ń lé tìróò.” Ó tiẹ̀ tún sọ pé “ohun tó ń súnni dẹ́ṣẹ̀” làwọn góòlù àti fàdákà tí wọ́n fi ń “ṣe ọ̀ṣọ́.”
Lójúmọ́ tòní, ọ̀pọ̀ ṣì ń wo ohun ọ̀ṣọ́ táwọn obìnrin ń lò bí nǹkan tó burú jáì. Àwọn ẹ̀sìn kan tiẹ̀ ti kà á léèwọ̀ pé káwọn ọmọ ìjọ má máa lo ohun ọ̀ṣọ́ èyíkéyìí, ohun ìṣaralóge, tàbí aṣọ aláwọ̀ mèremère. Èwo wá ni ṣíṣe o, ṣé kí obìnrin Kristẹni náà máa bo ẹwà rẹ̀ mọ́ra ni àbí kó máa túnra ṣe?
Ojú Ìwòye Ọlọ́run
Bíbélì ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ lórí lílo ohun ọ̀ṣọ́ àti ohun ìṣaralóge. Síbẹ̀
àwọn ẹ̀rí tó pọ̀ tó wà láti fi hàn pé Ọlọ́run ò ka àwọn nǹkan yẹn tàbí ohun ọ̀ṣọ́ míì léèwọ̀.Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ọlọ́run ń ṣàlàyé nípa ọ̀nà tó gbà bù kún Jerúsálẹ́mù, Ó sọ̀rọ̀ bíi pé obìnrin ni ìlú yẹn, ó ní: “Mo sì tẹ̀ síwájú láti fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́ . . . , ìwọ sì di ẹni tí ó lẹ́wà gidigidi ní ìrísí.” (Ìsíkíẹ́lì 16:11-13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àpẹẹrẹ ló fi ọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun ọ̀ṣọ́ bẹ́ẹ̀ ṣe, àmọ́ ó dárúkọ júfù, ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn àti yẹtí. Bákan náà, Ìwé Mímọ́ fi wúrà wé “ọlọ́gbọ́n olùfi ìbáwí tọ́ni sọ́nà,” èyí táwọn tó gbọ́ràn ń fetí sí. (Òwe 25:1, 12) Níwọ̀n bí àfiwé tí Ìwé Mímọ́ ṣe yìí ti fi hàn pé kò sóhun tó burú nínú lílo ohun ọ̀ṣọ́, ó bọ́gbọ́n mu pé Ọlọ́run ò ní kà á bì ẹ̀ṣẹ̀ sáwọn obìnrin lọ́rùn bí wọ́n bá lo àwọn nǹkan tó jojú nígbèsè bẹ́ẹ̀ láti fi ṣàlékún ẹwà wọn.
Àwọn Kristẹni Obìnrin Máa Ń Lo Ohun Ọ̀ṣọ́
Àwọn ẹsẹ Bíbélì kan wà tó sọ ní tààràtà nípa ọ̀ṣọ́ àwọn obìnrin. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Mo ní ìfẹ́-ọkàn pé kí àwọn obìnrin máa fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́.” Bí wọ́n bá ń ṣèyẹn pẹ̀lú “ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú,” ó lè fi wọ́n hàn bí àwọn obìnrin tó ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run. (1 Tímótì 2:9, 10) Báwọn Kristẹni obìnrin bá ń fi irú àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ lélẹ̀, á máa fi hàn pé ẹ̀kọ́ gidi ni ẹ̀kọ́ Ọlọ́run kò sì ní tàbùkù sí orúkọ ìjọ.
Àwọn kan máa ń jiyàn pé ṣebí àwọn ẹsẹ kan náà yẹn ló sọ pé kí ọ̀ṣọ́ wa má ṣe jẹ́ “pẹ̀lú àwọn àrà irun dídì àti wúrà tàbí péálì tàbí aṣọ àrà olówó ńlá gan-an, ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó yẹ àwọn obìnrin tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé wọn ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run, èyíinì ni, nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rere.” Ṣéyẹn wá ní pé káwọn obìnrin má ṣe irun wọn mọ́ àbí kí wọ́n má lo ohun ọ̀ṣọ́ mọ́ ni?
Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá o, Bíbélì sọ ohun tó dáa nípa lílo ohun ọ̀ṣọ́. Nítorí náà, dípò kí Pọ́ọ̀lù ka lílo àwọn ohun ọ̀ṣọ́ kan léèwọ̀, ṣe ló ń sọ pé káwọn obìnrin gbájú mọ́ fífi àwọn ànímọ́ Kristẹni àtàwọn iṣẹ́ rere ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́.
Ohun Tó Ń Mú Kẹ́nì Kan Lo Ohun Ọ̀ṣọ́ Ṣe Pàtàkì
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí a má ṣe máa dá ara wa lẹ́jọ́ mọ́ lẹ́nì kìíní-kejì, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ fi èyí ṣe ìpinnu yín, láti má ṣe fi ohun ìkọ̀sẹ̀ tàbí okùnfà fún ìgbéniṣubú sí iwájú arákùnrin.” (Róòmù 14:13) Báwo lèyí ṣe kan ohun ọ̀ṣọ́ tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa bá fẹ́ lò?
Lákọ̀ọ́kọ́, Pọ́ọ̀lù sọ fún wa pé ká má ṣe máa ‘dá ara wa lẹ́jọ́ lẹ́nì kìíní-kejì.’ A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ‘ká má ṣe fi ohun ìkọ̀sẹ̀ síwájú arákùnrin wa.’ Nǹkan tó bójú mu lórílẹ̀-èdè kan lè máà bójú mu lórílẹ̀-èdè míì, bákan náà ló ṣe jẹ́ pé báyìí là ń ṣe nílùú wa èèwọ̀ ìbomíì ni. Ohun tó yẹ ọmọlúwàbí lásìkò kan àti níbì kan lè máà rí bẹ́ẹ̀ níbòmíì. A ò gbọ́dọ̀ lo ohun ọ̀ṣọ́ tí kò bá àṣà ibi tá à ń gbé mu ká má bàa mú àwọn èèyàn kọsẹ̀. Á dáa táwọn obìnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run bá lè bi ara wọn pé: Ojú wo làwọn aládùúgbò mi á fi wo ohun ọ̀ṣọ́ tí mo lò yìí? Ṣé ohun ọ̀ṣọ́ tí mò ń lò kò ní máa kó àbùkù bá àwọn tá a jọ wà nínú ìjọ, ṣé kò ní jẹ́ kí wọ́n máa wò mí bí ẹni tó yàtọ̀ tàbí kó tiẹ̀ máa mú ojú tì wọ́n? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Kristẹni obìnrin kan ní ẹ̀tọ́ láti múra bó bá ṣe wù ú, síbẹ̀ ó yẹ kó gbà láti yááfì irú ẹ̀tọ́ bẹ́ẹ̀ bí ìmúra rẹ̀ ò bá bójú mu ládùúgbò yẹn.—1 Kọ́ríńtì 10:23, 24.
Bákan náà, bó bá jẹ́ pé béèyàn ṣe máa múra ló jẹ ẹ́ lógún jù, ó lè ti onítọ̀hún dédìí ìwà tí ò dáa. Lóde òní, lọ́pọ̀ ilẹ̀, àwọn obìnrin kan máa ń fi ìmúra polówó ara wọn. Àmọ́, Kristẹni obìnrin èyíkéyìí ò gbọ́dọ̀ fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, dípò ìyẹn, ṣe ni wọ́n gbọ́dọ̀ sapá láti yè kooro ní èrò inú kí wọ́n sì jẹ́ oníwà mímọ́ nínú ohun tí wọ́n bá ń ṣe, kí “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run má bàa di èyí tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ tèébútèébú.”—Títù 2:4, 5.
Bí àwọn Kristẹni obìnrin bá tiẹ̀ máa lo ohun ọ̀ṣọ́, wọ́n mọ̀ pé ojúlówó ẹwà àwọn sinmi lórí jíjẹ́ “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà,” ìyẹn á sì hàn nínú ìwà àti ìṣesí wọn sáwọn èèyàn. (1 Pétérù 3:3, 4) Àwọn èèyàn á fojú iyì wo obìnrin tó bá fọgbọ́n yan irú aṣọ, ohun ìṣaralóge àti ohun ọ̀ṣọ́ tó ń lò, ìyẹn á sì fi ìyìn fún Ẹlẹ́dàá rẹ̀.