Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣó o Ti Ṣe Gbogbo Nǹkan Tó Yẹ Láti Lè Wà Ńbẹ̀?

Ṣó o Ti Ṣe Gbogbo Nǹkan Tó Yẹ Láti Lè Wà Ńbẹ̀?

Ṣó o Ti Ṣe Gbogbo Nǹkan Tó Yẹ Láti Lè Wà Ńbẹ̀?

Wà níbo? Àpéjọ Àgbègbè “Ìgbọràn sí Ọlọ́run” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni! Ọ̀wọ́ àpéjọ ọlọ́jọ́ mẹ́tà yìí ti bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lópin ọ̀sẹ̀ tó kẹ́yìn lóṣù May, a ó sì ṣe é wọ ọdún tó ń bọ̀ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìlú káàkiri àgbáyé. Ó ṣeé ṣe kí ọ̀kan wáyé ní ìlú kan tó sún mọ́ ibi tí ò ń gbé.

Láwọn ibi tó pọ̀ jù lọ, a ó bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ohun orin tí a ó fi ṣí ìpàdé ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ní agogo mẹ́sàn-án àbọ̀ òwúrọ̀. Ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ Friday ni “Ẹ Ṣègbọràn sí Ohùn Mi, Èmi Yóò sì Di Ọlọ́run Yín.” (Jeremáyà 7:23) Lẹ́yìn àwọn àsọyé òwúrọ̀ tí àkòrí wọn jẹ́ “Ọlọ́run ‘Ṣẹ̀dá Wa Tìyanu-tìyanu’” àti “Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Gbà Pé Àjíǹde Ń Bọ̀ Lóòótọ́,” a óò wá gbọ́ lájorí ọ̀rọ̀ àsọyé tá ó fi kádìí ìjókòó àárọ̀, àkòrí rẹ̀ ni,“Máa Ṣe Ìgbọràn sí Ọlọ́run Nípa Títẹ̀lé Àpẹẹrẹ Jésù.”

Àwọn àsọyé tá a máa gbádùn lọ́sàn-án Friday ni “Ẹ Jẹ́ Ká Máa ‘Gbé Èrò Inú Wa Ka Ohun Tẹ̀mí,’ Ká Lè Jèrè Ìyè,” “Ẹ Máa Ṣọ́ra fún Gbogbo Onírúurú Ojúkòkòrò,” àti “Má Ṣe Tẹ̀ Lé ‘Àwọn Ìtàn Èké.’” Lẹ́yìn ìyẹn ni àpínsọ àsọyé alápá méjì náà, tó máa fa kókó yọ látinú àsọtẹ́lẹ̀ Hágáì àti Sekaráyà nínú Bíbélì, máa wáyé. Àsọyé tí yòó kádìí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ náà nílẹ̀ ni “Gbogbo Ìpọ́njú Máa Dópin Láìpẹ́!”

Ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ Saturday ni “Ìgbọràn Láti Inú Ọkàn Wá” “Nínú Ohun Gbogbo,” tá a gbé ka Róòmù 6:17 àti 2 Kọ́ríńtì 2:9. Lára àwọn àsọyé tá a máa gbádùn lákòókò ìjókòó àárọ̀ ni àpínsọ àsọyé alápá-mẹ́ta náà “Aláyọ̀ Ni Àwọn Ìdílé Tí Ń Pa Ìlànà Ọlọ́run Mọ́.” Ó láwọn àṣefihàn àti ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò nínú, ó sì tún tẹnu mọ́ bí àwọn tó wà nínú ìdílé, ìyẹn ọkọ, aya àtàwọn ọmọ ṣe lè ṣe ipa tiwọn kí ìdílé bàa lè láyọ̀. Àsọyé kan tó ní àkòrí náà “Jẹ́ Kí Bẹ́ẹ̀ Ni Rẹ Jẹ́ Bẹ́ẹ̀ Ni,” la ó fi kádìí ìtòlẹ̀sẹẹsẹ àárọ̀ ọjọ́ náà, lẹ́yìn náà lààyè yòó wà fáwọn tó tóótun láti ṣèrìbọmi.

Lára àwọn àsọyé tá a óò gbọ́ lọ́sàn-án Saturday ni “Kọjá Lọ Láìrí Ohun Tí Kò Ní Láárí” àti “Ẹ Padà Sọ́dọ̀ Olùṣọ́ Àgùntàn Ọkàn.” Àpínsọ àsọyé alápá-méjì náà “Ẹ Jẹ́ Onígbọràn sí Àwọn Tí Ń Mú Ipò Iwájú” ni yòó tẹ̀lé e. Àkòrí àsọyé tá o fi kádìí ìjókòó ọ̀sán ọjọ́ náà ni “Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, òun ni yòó sì jẹ́ kókó pàtàkì àpéjọ náà.

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àárọ̀ Sunday yòó jíròrò ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ náà “Ṣègbọràn sí Gbogbo Ọ̀rọ̀ Wọ̀nyí Kí Nǹkan Lè Máa Lọ Dáadáa fún Ọ,” èyí tá a gbé ka Diutarónómì 12:28. Àpínsọ àsọyé alápá-mẹ́ta tó ní àkòrí náà “Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Máa Ṣe Ohun Tí Bíbélì Fi Kọ́ni” ṣàlàyé àwọn ọ̀nà tó ṣeé múlò láti lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí yóò máa tẹ̀ síwájú, ká sì máa dárí rẹ̀.

A óò kádìí ìjókòó àárọ̀ pẹ̀lú àwòkẹ́kọ̀ọ́ kan tí wọ́n ti máa múra bí àwọn ará ìgbàanì, èyí tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ẹ Máa Lépa Ohun Tó Máa Gbórúkọ Ọlọ́run Ga.” A óò kọ́kọ́ gbọ́ àsọyé kan tó ní àkòrí náà “Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ǹjẹ́ Àwọn Ohun Tẹ̀mí Tó Máa Jẹ́ Kẹ́ Ẹ Ṣe Ojúlówó Àṣeyọrí Lẹ̀ Ń Lépa?” Àsọyé yìí ló máa ṣàlàyé àwọn nǹkan tá a ní láti mọ̀ ṣáájú nípa àwòkẹ́kọ̀ọ́ inú Bíbélì náà èyí tó dá lórí ọ̀dọ́kùnrin Tímótì, ẹni tó jẹ́ àpẹẹrẹ tó yááyì bó bá dọ̀rọ̀ ká ṣiṣẹ́ ìsìn àfọkànṣe, tó sì yẹ káwọn ọ̀dọ́ fara wé. Àkòrí àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí yòó kádìí àpéjọ náà lọ́sàn-án ọjọ́ Sunday ni, “Ta Ló Yẹ Ká Máa Ṣègbọràn Sí?”

Tètè bẹ̀rẹ̀ sí múra sílẹ̀ kó o lè wà ńbẹ̀. Tó o bá fẹ́ mọ èyí tó sún mọ́ ilé rẹ jù lára ibi tá a ó ti ṣe àpéjọ yìí, o lè lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kó o kọ̀wé béèrè lọ́wọ́ àwọn tó ń tẹ ìwé ìròyìn yìí.