“Ẹ Wo Bí A Ṣe Rántí . . . Aáyù!”
“Ẹ Wo Bí A Ṣe Rántí . . . Aáyù!”
Látọwọ́ òǹkọ̀wé Jí! ní Dominican Republic
TÓ O bá wà níbi tó jìnnà sílé tébi sì ń pa ọ́, irú oúnjẹ wo ló máa wù ọ́ kó o rí jẹ? Ó ṣeé ṣe káwọn èso àti ẹ̀fọ́ tí wọ́n ń gbìn ní ìlú ẹ wá sí ọ lọ́kàn, ó sì lè jẹ́ ọbẹ̀ aládùn tí màmá ẹ máa ń fi ẹran tàbí ẹja sè láá máa dá ọ lọ́rùn. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ aáyù lè máa dá ẹ lọ́fun tòótòó?
Ní nǹkan bí ẹgbàá méjìdínlógún ó dín ọgọ́rùn-ún ọdún [3,500] sẹ́yìn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹsẹ̀ rìn gba aginjù Sínáì kọjá, bí wọ́n ṣe ń lọ wọ́n ń sọ pé: “Ẹ wo bí a ṣe rántí ẹja tí a máa ń jẹ ní Íjíbítì lọ́fẹ̀ẹ́, àwọn apálá àti bàrà olómi àti ewébẹ̀ líìkì àti àlùbọ́sà àti aáyù!” (Númérì 11:4, 5) Ẹ ò rí nǹkan, aáyù ń dá wọn lọ́rùn! Àwọn Júù fẹ́ràn aáyù débi pé ìtàn àtẹnudẹ́nu wọn kan sọ pé wọ́n máa ń pe ara wọn ní ajẹ-aáyù.
Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe kúndùn aáyù tó bẹ́ẹ̀? Nígbà tí wọ́n fi wà ní Íjíbítì fún igba àti mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ọdún [215] gbáko, ohun táwa kà sí egbòogi yìí wà lára oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ. Ẹ̀rí táwọn awalẹ̀pìtàn hú jáde fi hàn pé kó tiẹ̀ tó di pé Jékọ́bù àti ìdílé rẹ̀ lálàá pé àwọn á dé sí Íjíbítì làwọn ará ibẹ̀ ti ń ṣọ̀gbìn aáyù. Herodotus, òpìtàn tó jẹ́ Gíríìkì ròyìn pé àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Íjíbítì máa ń ra ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlùbọ́sà, ewé radish, àti aáyù láti lè máa fáwọn ẹrú tó ń bá wọn kọ́ ilé aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ onígun mẹ́rin. Ó dà bíi pé bí aáyù ṣe pọ̀ nínú oúnjẹ àwọn òṣìṣẹ́ yẹn ń fi kún okun àti agbára wọn. Nígbà táwọn ará Íjíbítì ń sìnkú Fáráò Tutankhamen, wọ́n kó ọ̀pọ̀ nǹkan ṣíṣeyebíye, tó fi mọ́ aáyù sínú ibojì rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aáyù kò wúlò fáwọn òkú, àmọ́ ó wúlò gan-an fáwọn alààyè.
Egbòogi Tó Lágbára Ni
Láyé àtijọ́, àwọn dókítà máa ń fi aáyù tọ́jú àwọn aláìsàn wọn. Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn, àwọn Gíríìkì méjì tí wọ́n jẹ́ oníṣègùn, ìyẹn Hippocrates àti Dioscorides dá a lábàá pé aáyù ṣeé lò bí oògùn fún ẹni tí oúnjẹ kò bá dà nínú ẹ̀, adẹ́tẹ̀, alárùn jẹjẹrẹ, ẹni tó ní egbò, ẹni tó kárùn àtẹni tó lárùn ọkàn. Nígbà kan láàárín ọdún 1801 sí 1900, oníṣègùn ọmọ ilẹ̀ Faransé náà, Louis Pasteur ṣèwádìí nípa aáyù ó sì sọ pé oògùn apakòkòrò wà nínú ẹ̀. Nílẹ̀ Áfíríkà láàárín ọdún 1901 sí ọdún 2000, dókítà kan tó tún jẹ́ míṣọ́nnárì, Albert Schweitzer, tí gbogbo èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó, lo aáyù láti tọ́jú ìgbẹ́ ọ̀rìn tí kòkòrò amoeba ń fà. Nígbà tí oògùn ìgbàlódé tán lọ́wọ́ àwọn dókítà tó ń tọ́jú àwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi aáyù tọ́jú ojú ọgbẹ́ àwọn sójà tó fara pa. Ohun tó mú kí wọ́n máa pe aáyù ní penicillin, ìyẹn oògùn apakòkòrò àwọn Rọ́ṣíà nìyẹn. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣèwádìí nípa bí aáyù ṣe lè mú ẹ̀jẹ̀ máa ṣàn bó ṣe yẹn.
Tá a bá wò ó lọ, wò ó bọ̀, a ó rí i pé aáyù yàtọ̀ lóúnjẹ, egbòogi bíi tiẹ̀ ṣọ̀wọ́n, òórùn rẹ̀ ò sì lẹ́gbẹ́. Ibo ni wọ́n ti kọ́kọ́ gbin aáyù gan-an? Èrò àwọn kan tó mọ̀ nípa igi àti ewéko ni pé àárín gbùngbùn ilẹ̀ Éṣíà ni aáyù ti ṣẹ̀ wá, àtibẹ̀ ló sì ti tàn kárí ayé. Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀kan lára ibi tí aáyù ti tàn dé.
Bí Wọ́n Ṣe Ń Gbin Aáyù ní Àfonífojì Constanza
Ojú ọjọ́ kì í gbónà jù, kì í sì í tutù jù ní Àfonífojì Constanza tó wà lórílẹ̀-èdè Dominican Republic. Ilẹ̀ ọlọ́ràá ló wà ní àfonífojì tó wà láàárín òkè yìí, òjò sì máa ń rọ̀ níbẹ̀ dáadáa. Aáyù tí wọ́n bá gbìn ní Constanza máa ń dára gan-an ni.
Lóṣù kẹ́sàn-án tàbí ìkẹwàá ọdún làwọn àgbẹ̀ máa ń túlẹ̀ nínú oko wọn, lẹ́yìn ìtúlẹ̀ náà láá dà bí ìgbà tí wọ́n bá kọ ebè tó fẹ̀ tó nǹkan bíi mítà kan tàbí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ta. Wọ́n á gbìn ín sọ́nà mẹ́ta tàbí mẹ́rin lórí àwọn èbè náà. Ṣáájú èyí, àwọn òṣìṣẹ́ tó fẹ́ gbìn ín á kọ́kọ́ ya odidi aáyù kan sí tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́, wọ́n á wá kó o sínú omi fún bí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, wọ́n á
sì bẹ̀rẹ̀ sí gbìn ín sórí àwọn ebè tí wọ́n fẹ́ gbìn wọ́n sí. Ìgbà tí òtútù bá rọra mú lórílẹ̀-èdè Dominican Republic ni aáyù máa ń hù jù.Oṣù kẹta tàbí ìkẹrin ni wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí kórè. Àwọn tó ń kórè lóko náà á bẹ̀rẹ̀ sí hú aáyù tó ti gbó jáde látinú ilẹ̀, wọ́n á sì fi wọ́n sílẹ̀ sínú oko fún bí ọjọ́ márùn-ún sí mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, wọ́n á kó aáyù náà, wọ́n á gé orí àti ìdí rẹ̀ kúrò, wọ́n á sì kó aáyù tó ti mọ́ tónítóní sínú cribas, iyẹn ike tí kò ní ìdérí. Wọ́n á sá cribas tí aáyù kún inú rẹ̀ sínú oòrùn fún odidi ọjọ́ kan kó lè gbẹ dáadáa. Lẹ́yìn ìyẹn, ó di títà.
Aáyù Bíńtín Ń Dá Òórùn Palẹ̀
Tó o bá jókòó ti omi ọbẹ̀ tàbí ewébẹ̀ tó dùn, kò ní pẹ́ tí aáyù á fi máa ta sánsán sí ọ nímú, tó bá wà nínú oúnjẹ náà. Kí wá ló dé tí aáyù kì í fi í rùn tí wọn ò bá tíì bó èèpo ẹ̀yìn rẹ̀? Ìdí ni pé àwọn èròjà tó lágbára kan wà nínú aáyù tí wọn kì í fojú kan ara wọn títí dìgbà tí wọ́n bá bó èèpo ẹ̀yin rẹ̀, tí wọ́n bá gé e tàbí tí wọ́n bá lọ̀ ọ́. Téèyàn bá gé tẹ́ẹ́rẹ́ kan lára aáyù, èròjà kan tó ń jẹ́ alliinase àti alliin á pa pọ̀. Lójú ẹsẹ̀ ni àdàpọ̀ èròjà méjèèjì á tún mú èròjà míì tó ń jẹ́ allicin wá, èròjà tí wọ́n mú wá yìí ló máa ń mú kí aáyù ní òórùn tó máa ń ní yẹn, òun ló sì jẹ́ kó rí bó ṣe máa ń rí lẹ́nu.
Tó o bá rọra gé aáyù kékeré kan sẹ́nu, ṣe ló máa dà bíi pé ẹnu rẹ ni gbogbo èròjà allicin ayé yìí tú dà sí. Bóyá ó dùn mọ́ ẹ tàbí kò dùn mọ́ ẹ o, aáyù ò ní pẹ́ máa rùn ní gbogbo ara rẹ. Ǹjẹ́ ohun kan wà tó o lè ṣe láti dín òórùn aáyù tó ń rùn lẹ́nu ẹ kù? O lè jẹ ọ̀mùnú ewé títa sánsán mìíràn tó ń jẹ́ parsley láti lè bo òórùn rẹ̀ mọ́lẹ̀.
Àmọ́, má gbàgbé pé inú ẹ̀dọ̀fóró rẹ lọ́hùn-ún ni aáyù tó ń rùn lẹ́nu rẹ ti wá. Tó o bá jẹ aáyù, tí òòlọ̀ inú ẹ bá lọ̀ ọ́, tó sì dà, inú ẹ̀jẹ̀ rẹ ló máa kọjá sí, á sì gbabẹ̀ dé inú ẹ̀dọ̀fóró ẹ. Bó o bá ṣe ń mí síta báyìí, ṣe ni òórùn ẹ̀ tó máa ń wọni nímú yẹn á máa rùn lẹ́nu ẹ. Nítorí náà, kò sí bó o ṣe lè fọnu tàbí kó o jẹ ewé parsley tó tí aáyù ò ní rùn lẹ́nu ẹ. Ǹjẹ́ ojútùú kankan wà sí ìṣòro yìí báyìí? A ò lè sọ pó wà. Ṣùgbọ́n ká ní gbogbo àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣe wọlé wọ̀de ló ń jẹ aáyù, gẹ́gẹ́ yín ṣe gẹ́gẹ́ nìyẹn, ó lè máà sẹ́ni tó máa fura nínú yín!
Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, tí wọ́n bá gbọ́ pé èèyàn lè gbọ́únjẹ láìlo aáyù, wọ́n á ní irọ́ ni. Níbi tó sì ti jẹ́ pé wọ́n máa ń jẹ ẹ́ níwọ̀nba, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń jẹ aáyù ló gbà pé oore tó ń ṣe fára pọ̀ ju ìṣòro tó ń fà lọ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Aáyù tí wọ́n ń sá lóòrùn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Àfonífojì Constanza
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Kí ló dé tó jẹ́ pé ẹ̀yìn tí wọ́n bá bó aáyù tán ló tó máa ń rùn?