Béèyàn Ṣe Lè Gba Ara Ẹ̀ Lọ́wọ́ Àmujù Ọtí
Béèyàn Ṣe Lè Gba Ara Ẹ̀ Lọ́wọ́ Àmujù Ọtí
“Ọ̀mùtí gbàgbé ìṣẹ́ ni baba mi, ọwọ́ ẹ̀ lèmi náà sì gbé. Ìgbà tí mo fi máa pé ọmọ ọdún méjìlá, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí mutí. Ìgbà tí mo fi máa gbéyàwó, àmuyíràá ni ràì lójoojúmọ́. Mo wá ya ẹhànnà kalẹ̀; ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọlọ́pàá máa wá ń gba ìdílé mi kalẹ̀. Àìlera wá dé. Ọtí líle sọ mi di alárùn ọgbẹ́ inú àgbẹ̀du, ẹ̀mí mi sì fẹ́rẹ̀ẹ́ lọ sí i. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni àìsàn ìsúnkì ẹ̀dọ̀ àti àìtó ẹ̀jẹ̀ tún yọjú. Mo wọnú ẹgbẹ́ kan tó ń ran èèyàn lọ́wọ́ láti fi ọtí sílẹ̀, bóyá ìyẹn á lè jẹ́ kí n ṣíwọ́ mímutí, síbẹ̀ ibi pẹlẹbẹ ni ọ̀bẹ mi fi ń lélẹ̀. Lójú mi kò yàtọ̀ sígbà tí mo wà nígbèkùn tí mi ò sì lè lómìnira láé.”—VÍCTOR, a LÁTI AJẸNTÍNÀ LÓ SỌ BẸ́Ẹ̀.
LÓÒRÈKÓÒRÈ làwọn tó ti kó sínú ìdẹkùn ọtí líle ń sọ ìrírí ara wọn bí irú èyí. Bíi ti Víctor, lójú irú wọn, inú okùn ni wọ́n wà, kò sì lè sọ́nà àbáyọ láé. Ǹjẹ́ èèyàn lè borí àwọn ìṣòro tí àmujù ọtí líle ń fà tàbí kéèyàn má tiẹ̀ mu ún mọ́? Bó bá ṣeé ṣe, lọ́nà wo?
Mọ Ohun Tó Fà Á
Lákọ̀ọ́kọ́, ó ṣe pàtàkì pé kẹ́ni tó ń mutí náà àtàwọn tó sún mọ́ ọn gbà pé mímu tó ń mutí lámujù ti di ìṣòro. Ọ̀kan péré ni kí ọtí di bárakú fún ẹnì kan jẹ́ lára ìṣòro ńlá tí ọtí líle máa ń fà. Díẹ̀díẹ̀ téèyàn ń mutí ló máa ń di bárakú tónítọ̀hún á sì máa rò pé ìwọ̀ntúnwọ̀nsì lòun ṣì ń mu. Kàyéfì ọ̀rọ̀ ọ̀hún ni pé, kì í ṣàwọn tí ọtí ti di bárakú fún ló wà nídìí gbogbo bí ọtí ṣe ń fa èyí tó pọ̀ jù lára jàǹbá ọkọ̀ tó ń wáyé, bó ṣe ń sọ àwọn èèyàn di ìpáǹle, àti bó ṣe ń dá wàhálà sílẹ̀ láwùjọ. Gbọ́ ohun tí Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé: “Ọ̀nà tó dáa jù lọ tá a lè fi dín àwọn ìṣòro tí àmujù ọtí ń fà láwùjọ kù ni pé ká tètè mójú tó àwọn tó ń sọ pé ìwọ̀ntúnwọ̀nsì làwọn ń mutí dípò àwọn tó ń mu àmuyíràá.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Ṣé o kì í mu ju ìwọ̀n tí ètò ìlera fọwọ́ sí lọ? Ṣé o kì í mutí lásìkò tó bá yẹ kó o pọkàn pọ̀ kó o sì gbé ìgbésẹ̀ lọ́gán? Ṣé ọtí tó ò ń mu kì í mú kó o máa dá ìṣòro sílẹ̀ nílé tàbí níbi iṣẹ́? “Ọ̀nà tó dáa jù lọ” téèyàn lè gbà dènà ìṣòro tó lè jẹ yọ lọ́jọ́ iwájú ni pé kéèyàn mọ ìwọ̀n tó máa ń yọ òun lẹ́nu, kó má sì mu kọjá ìwọ̀n yẹn. Bó bá ti di bárakú tán, kì í rọrùn rárá láti jáwọ́ nínú ẹ̀ mọ́.
Ohun tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ọ̀mùtípara ni sísẹ́ tí wọ́n máa ń sẹ́ pé àwọn kì í ṣe ọ̀mùtí. Ohun tí wọ́n máa ń sọ ni pé: “Èmi nìkan ṣáà kọ́ ni mò ń mutí” tàbí “Mo lè fi sílẹ̀ tí n bá ṣe tán àtifi sílẹ̀ kẹ̀.” Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Konstantin lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà sọ pé: “Ó burú débi pé díẹ̀ ló kù kí ẹ̀mí mi bọ́, síbẹ̀ mi ò fi ọjọ́ kan rò ó rí pé mo ti di ọ̀mùtípara, nítorí náà kò wá sí mi lọ́kàn rí pé ó yẹ kí n yé mutí.” Marek láti orílẹ̀-èdè Poland sọ ìrírí ara rẹ̀, ó ní: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo gbìyànjú kí n lè ṣíwọ́ mímutí
síbẹ̀ mo ṣì ń ṣiyè méjì lórí bóyá lóòótọ́ ni mò ń mutí para. Mi ò ka bí àmujù ọtí ṣe lè ṣe mí ní jàǹbá sí nǹkan bàbàrà.”Báwo la ṣe lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti mọ̀ pé ìṣòro ni àmujù ọtí jẹ́ fóun kó bàa lè ṣe àtúnṣe? Ẹni náà gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ̀ pé àmujù ọtí ló ṣokùnfà ìṣòro òun àti pé ayé òun á túbọ̀ nítumọ̀ bóun bá lè yé mutí. Ìwé ìmọ̀ ìṣègùn kan, La Revue du Praticien—Médecine Générale, sọ pé, ó gbọ́dọ̀ gbà pé ṣe ni “ìyàwó òun kọ òun sílẹ̀ tí iṣẹ́ sì bọ́ lọ́wọ́ òun torí àmupara tóun ń mu” dípò kó máa ronú pé “ṣe lòun ń mutí láti fi pàrònú ìyàwó tó kọ òun sílẹ̀ àti iṣẹ́ tó bọ́ lọ́wọ́ òun rẹ́.”
Bó o bá fẹ́ ran ẹni tí ọtí líle ti di bárakú fún lọ́wọ́ láti tún ìrònú ẹ̀ ṣe, àwọn àbá tó tẹ̀ lé e yìí lè wúlò fún ọ: Máa fetí sílẹ̀ dáadáa, àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtó ni kó o máa bi í kó lè rọrùn fún un láti sọ èrò ọ̀kan rẹ̀ fún ọ, bá a kẹ́dùn lọ́nà tó fi máa mọ̀ pé o mọ bó ṣe ń ṣe òun, yìn ín bí ìtẹ̀síwájú ọ̀hún ò bá tiẹ̀ jọ èèyàn lójú, ṣọ́ra láti má máa ṣe ohun tó lè mú kó o dà bí ẹni tó ń rin kinkin jù tàbí ohun tó lè mú kó má finú hàn ẹ́ mọ́ àti ohun tó lè mú kó má gba ìmọ̀ràn ẹ mọ́. O tún lè ràn án lọ́wọ́ tó o bá sọ pé kó kọ gbogbo ìdáhùn tó mọ̀ sáwọn ìbéèrè méjì yìí sínú ìwé kan Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tí n bá ṣì ń mutí? àti Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tí n bá ṣíwọ́ ọtí mímu?
Bó O Ṣe Lè Wá Ìrànlọ́wọ́
Torí pé ẹnì kan ti di ọ̀mùtípara kò túmọ̀ sí pé onítọ̀hún ò jámọ́ nǹkan kan mọ́ tàbí pé ó ti tán fónítọ̀hún nìyẹn. Àwọn kan tiẹ̀ máa ń jáwọ́ nínú ọtí mímu fúnra wọn. Àmọ́ ṣá o, àwọn tó ti di bárakú fún lè lọ rí àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣíwọ́ mímutí. b Àwọn míì wà tó jẹ́ pé, ìtọ́jú táwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ń fún wọn nílé ti tó, síbẹ̀ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè dẹni táá gba bẹ́ẹ̀dì ní ọsibítù bí wọ́n bá ṣàkíyèsí pé, àwọn nǹkan tó máa ń ṣèèyàn lẹ́yìn téèyàn bá jáwọ́ nínú mímutí ń yọ àwọn lẹ́nu púpọ̀ jù. Gbàrà táwọn nǹkan tó máa ń ṣèèyàn lẹ́yìn téèyàn bá yé mu ọtí bá ti ṣe é kọjá láàárín ọjọ́ méjì sí márùn-ún, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí lo oògùn tó máa dín bí ọtí ṣe ń dá a lọ́rùn tí ò fi ní mu ún mọ́ rárá kù.
Bó ti wù kó rí, gbogbo ìtọ́jú tá a sọ lókè yìí kò fi hàn pé èèyàn ti ṣàṣeyọrí. Àwọn oògùn téèyàn bá sì ń lò kàn lè ṣèrànwọ́ fúngbà díẹ̀ ni, kò lè mú un kúrò pátápátá. Alain, láti ilẹ̀ Faransé náà ti gba oríṣi bíi mélòó kan lára irú ìtọ́jú wọ̀nyẹn. Ó sọ pé: “Gbàrà tí mo bá ti yísẹ̀ padà kúrò ní ọsibítù báyìí ni màá tún nawọ́ gán ọtí, kò sì sí nǹkan méjì tó ń fà á ju pé mi ò ní ọ̀rẹ́ míì yàtọ̀ sáwọn tá a jọ ń mutí. Olórí àrùn ọ̀hún ni pé mi ò rí nǹkan gidi kan tó lè mú kí n fi sílẹ̀.”
Ohun Tó O Lè Fi Rọ́pò Rẹ̀
Ọ̀pọ̀ ni ò lè ṣàṣeyọrí torí pé bí wọ́n ṣe ṣíwọ́ mímutí ń ṣe wọ́n bíi pé ó ṣì ku nǹkan kan tó yẹ kí wọ́n ṣe, àfi bí ìgbà téèyàn pínyà pẹ̀lú ọ̀rẹ́ téèyàn mọwọ́ ẹ̀. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Vasiliy ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà sọ bó ṣe máa ń rí, ó ní: “Bí mo ṣe máa rí ọtí mu ni mo máa ń fi ayé mi rò. Bí ojúmọ́ kan bá mọ́ tí mi ò rí ọtí mu, a jẹ́ pé ojúmọ́ yẹn kì í ṣe ojúmọ́ọre fún mi.” Kò sí ohun tó ṣe pàtàkì fún ẹni tí ọtí ti di bárakú fún bíi kó ṣáà ti rí ọtí dà sọ́fun. Jerzy tó ń gbé ní Poland sọ pé: “Ohun tó jẹ èmi lógún láyé mi ò ju bí màá ṣe máa rí ọtí mu, tí owó tí màá máa fi rà á ò sì ní wọ́n mi.” Ó wá ṣe kedere pé, bí ọ̀mùtí kan bá ti ń jáwọ́ nínú mímutí, ó ṣe pàtàkì kó wá nǹkan míì tó máa jẹ ẹ́ lógún jù lọ nígbèésí ayé bí àfidípò.
Ìwé kan tí Àjọ Ìlera Àgbáyé tẹ̀ jáde tẹnu mọ́ ọn pé, ó máa ṣe àwọn tó ń gbìyànjú láti ṣíwọ́ mímutí láǹfààní bí wọ́n bá ní ìgbòkègbodò gidi kan tí wọ́n á máa ṣe kí wọ́n má bàa padà sídìí ọtí mímu mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti jáwọ́. Àbá kan tí wọ́n dá ni pé kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa kópa nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn.
Béèyàn bá jẹ́ kọ́wọ́ òun dí lẹ́nu àwọn nǹkan tẹ̀mí, ó lè gba ara rẹ̀ lọ́wọ́ ọtí. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Alain dé láti ẹ̀wọ̀n nígbà kẹta látàrí àwọn ọ̀ràn tó máa ń dá lásìkò tó bá ti mutí yó, ló tó gbà pé káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa wá kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó sọ pé: “Ẹ̀kọ́ Bíbélì jẹ́ kí n túbọ̀ mọyì ìgbésí ayé ó sì jẹ́ kí n lè dúró ti ìpinnu tí mo ṣe láti má mutí
mọ́. Kì í ṣe pé mo kàn fẹ́ ṣíwọ́ mímutí nìkan ni ṣùgbọ́n mo fẹ́ máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́.”Ohun Tó O Lè Ṣe Bí Ọtí Bá Tún Ń Wù Ọ́ Mu Lẹ́yìn Tó O Ti Fi Sílẹ̀
Àwọn agbaninímọ̀ràn lórí àmujù ọtí sọ pé ó ṣe pàtàkì kí ọ̀mùtí tó fẹ́ ṣíwọ́ náà ní alámọ̀ràn rere táá máa ṣí i létí. Ọ̀pọ̀ wọn làwọn mọ̀lẹ́bí àtọ̀rẹ́ ti pa tì nítorí bí ọtí ṣe sọ wọ́n dìdàkudà. Bí wọ́n ṣe dá wà láwọn nìkan lè mú kí wọ́n soríkọ́ kódà ó lè sún wọn fọwọ́ ara wọn para wọn. Ìwé tá a mẹ́nu kàn lẹ́ẹ̀kan dábàá fáwọn tó bá ń ran ẹni tí ọtí ti jàrábà lọ́wọ́, ó ní: “Rí i pé o kò fọwọ́ líle mú ọ̀mùtí tó ò ń ràn lọ́wọ́ kódà báwọn ìwà rẹ̀ kan bá múnú bí ọ tàbí tó mú kí gbogbo ẹ̀ tojú sú ọ. Rántí pé kì í rọrùn àtifi ìwà tó bá ti mọ́ èèyàn lára sílẹ̀. Ìgbà míì wà tó máa gbọ́ràn sí ẹ lẹ́nu, ìgbà míì sì wà tí ò ní fẹ́ ṣe ohun tó o ní kó ṣe. Àwọn nǹkan tó nílò ni pé kó o máa gbà á nímọ̀ràn, kó o dúró tì í débi tí ò fi ní mu kọjá ìwọ̀n tí kò lè pa á lára tàbí kó o tiẹ̀ ṣèrànwọ́ débi tí ò fi ní mu ún mọ́ rárá àti bó o ṣe máa ràn án lọ́wọ́ tó fi máa dáwọ́ lé àwọn nǹkan kan táá lè máa ronú lé lórí ní gbogbo ìgbà.”
Hilario tó mu àmuyíràá fún nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún ṣàlàyé pé: “Báwọn ará nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ mi tí wọ́n sì bójú tó mi ló ràn mí lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo tún máa ń padà sídìí ọtí, àmọ́ kì í sú àwọn ará yẹn láti máa fún mi níṣìírí, tí wọ́n sì máa ń gbà mí nímọ̀ràn tó bọ́ sákòókò látinú Bíbélì.”
Bó o bá ń sapá láti yé mutí, má gbàgbé pé ó ṣì lè máa dá ọ lọ́rùn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan o, ṣe lo gbọ́dọ̀ kàyẹn sí ara ohun tó máa ṣẹlẹ̀ kó o lè bọ́ nígbèkùn ọtí àmuyíràá. Pé kò lè ṣeé fi sílẹ̀ yẹn, irọ́ ni! Ohun tó mú kó o tún padà sídìí ẹ̀ yẹn ni kó o gbìyànjú láti mọ̀, kó o lè mọ bí wàá ṣe máa ṣọ́ra tírú ẹ̀ ò fi ní ṣẹlẹ̀ mọ́. Ṣàkíyèsí ohun tó kọ́kọ́ máa ń ṣẹlẹ̀ tó fi máa ń di pé ọtí tún ń dá ọ lọ́rùn. Ṣé kì í ṣe àárẹ̀ ọkàn, ìbànújẹ́, ìṣòro dídáwà, àríyànjiyàn, ìnira, wíwà ní òde tàbí àwọn ibòmíì táwọn èèyàn ti ń mutí ló ń fà á? Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀, ṣé wàá kúkú yàgò fáwọn nǹkan yẹn! Ọdún méjì ló gba Jerzy kó tó o lè ṣíwọ́ mímutí pátápátá, ó ní: “Mo máa ń kíyè sí àsìkò tí ọtí máa ń dá mi lọ́rùn kí n lè mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi ṣáájú àkókò náà tó fi di pé ọtí ń dá mi lọ́rùn. Lẹ́yìn tí mo ti mọ̀ ọ́n, n kì í jẹ́ kí nǹkan yẹn ṣẹlẹ̀ kí ọtí má bàa máa wù mí mu. N kì í sì í sún mọ́ tòsí ibi táwọn èèyàn bá ti ń mutí. N kì í jẹ ohunkóhun tó bá ní ọtí líle nínú kódà n kì í lo ìpara èyíkéyìí tàbí àwọn oògùn tó bá ní ọtí líle nínú. Bákan náà, n kì í wo ìpolówó ọtí líle èyíkéyìí.” Àwọn kan sọ pé gbígbà táwọn gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó fáwọn ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” ló jẹ́ káwọn lè gbé èrò nípa ọtí mímu kúrò lọ́kàn.—2 Kọ́ríńtì 4:7; Fílípì 4:6, 7.
O Lè Jàjàbọ́!
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í yá bọ̀rọ̀ láti ṣíwọ́ mímutí pátápátá, síbẹ̀ èèyàn ṣì lè bọ́ nínú okùn ọtí àmuyíràá. Gbogbo àwọn tá a dárúkọ wọn nínú àpilẹ̀kọ yìí ni wọ́n ti yé mutí. Wọ́n lálàáfíà, wọ́n sì ń jàǹfààní tó wà nínú kí ọ̀ọ̀dẹ̀ èèyàn tòrò, kí iṣẹ́ sì tún wà lọ́wọ́. Alain sọ pé, “Mo ti bọ́ lọ́wọ́ ọtí.” Konstantin náà ṣàlàyé pé: “Jèhófà tí mo mọ̀ ló kó ìdílé mi yọ. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá mọ ibi tí ayé mi dorí kọ báyìí ni. Ọtí kọ́ ló ń fún mi láyọ̀.” Víctor ni tiẹ̀ sọ pé: “Mo wá dẹni ara mi. Àwọn èèyàn padà bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú èèyàn gidi wò mí.”
Kò sẹ́ni tí kò lè jàjàbọ́ kódà kó jẹ́ pé ṣe lẹni yẹn ti fẹ́ kàgbákò jàǹbá látàrí ìmukúmu ọtí, bóyá ṣe ni ìṣòro kan ń bá a fà á látàrí àmujù ọtí tàbí kẹ̀, kó jẹ́ pé ṣe ni ọtí ti di bárakú fún un. Bó o bá rí i pé ọtí ti ń wọ̀ ẹ́ lẹ́wù, yáa tètè ṣíwọ́ ọtí mímu o. Ìyẹn ló lè pé ìwọ àtàwọn tó fẹ́ràn ẹ.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
b Ọ̀pọ̀ ibi téèyàn ti lè gba ìtọ́jú, ọsibítù àtàwọn ètò tó ń mú kéèyàn kọ́fẹ padà ló wà tó lè ṣèrànwọ́. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò sọ pé ìtọ́jú ìṣègùn kan pàtó ló dáa jù o. Èèyàn sì gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kó má lọ di pé á bẹ̀rẹ̀ sí lọ́wọ́ sáwọn nǹkan tó máa lòdì sí ìlànà Ìwé Mímọ́. Lẹ́yìn gbígbé gbogbo ohun tó yẹ yẹ̀ wò, kálukú ló máa pinnu irú ìtọ́jú ìṣègùn tóun máa yàn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Lákọ̀ọ́kọ́, ẹni náà gbọ́dọ̀ gbà pé ìṣòro ni àmujù ọtí jẹ́ fóun
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Ọ̀pọ̀ ló nílò àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n tó lè ṣíwọ́ mímutí pátápátá
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Àdúrà lè ràn ọ́ lọ́wọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
O lè gbara ẹ lọ́wọ́ ọtí mímu!