Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bópẹ́bóyá—Gbogbo Èèyàn á Nílé Gidi Lórí!

Bópẹ́bóyá—Gbogbo Èèyàn á Nílé Gidi Lórí!

Bópẹ́bóyá—Gbogbo Èèyàn á Nílé Gidi Lórí!

ÀJỌ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-èdè ní abúlé ẹlẹ́wà kan tó fẹ̀ tó hẹ́kítà mẹ́rìndínlọ́gọ́ta tàbí ogóje sarè sí tòsí ìlú Nairobi lórílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà. Abúlé yìí, tó ń jẹ́ Gigiri, tí wọ́n mọ odi yí po, ni oríléeṣẹ́ àjọ tó ń ṣètò ilégbèé lábẹ́ àsíá Àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-èdè wà. Wọ́n dá abúlé yìí sílẹ̀ láti fi hàn pé àjọ àgbáyé yìí múra tán láti yanjú ìṣòro ilégbèé jákèjádò ayé. Téèyàn bá gba Ọ̀nà Ọgbà Gigiri, tó wà ní abúlé náà kọjá, èèyàn á rí ẹ̀rí pé táráyé bá pawọ́ pọ̀ tí wọ́n sì náwó sí i dáadáa, wọ́n á ṣe bẹbẹ lórí ọ̀rọ̀ ilégbèé. Ilẹ̀ kan tí kò sẹ́ni tó lè lò ó ló wà níbí tẹ́lẹ̀, òun ni wọ́n ti sọ di ibi ìgbafẹ́ tó rí rèǹtèrente táwọn òṣìṣẹ́ àtàwọn àlejò lè rìnrìn àjò lọ láti máa gbafẹ́.

Àmọ́ o, ní bí ibùsọ̀ mélòó kan síbẹ̀ yẹn, ilé kan wà níbẹ̀ tó jẹ́ ilé àwọn tálákà, tí kò tíì pẹ́ tí wọ́n dá a sílẹ̀, síbẹ̀ ṣe ló ń gbòòrò sí i ṣáá. Ẹní bá débẹ̀ á rí i pé wàhálà ńlá gbáà tó ṣòroó yanjú ni ọ̀rọ̀ àìrílégbé. Àwọn ilé ebútú tí wọ́n fi amọ̀, igi àti páànù kọ́ yìí tóbi tó mítà mẹ́rin tàbí ogójì ẹsẹ̀ bàtà níbùú lóòró. Ṣe lọ̀nà tó gbabẹ̀ kọjá ń rùn fùn-ùn nítorí omi ìdọ̀tí. Àwọn tó ń gbé níbẹ̀ ń san tó ìlọ́po márùn-ún iye táwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ń san lórí omi. Láàárín ogún ọdún sí ogójì ọdún lọjọ́ orí àwọn bí ọ̀kẹ́ méjì èèyàn tó ń gbébẹ̀ wà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn wọ̀nyí kì í ṣọ̀lẹ o, wọn kì í sì í ṣe alápámáṣiṣẹ́. Kódà, iṣẹ́ ni wọ́n wá lọ sí tòsí ìlú Nairobi yẹn.

Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, ibì kan tó mọ́ tónítóní tí àyíká rẹ̀ rí rèǹtèrente, tó sì fani mọ́ra létí ibi tá à ń sọ yìí gan-an làwọn aṣáájú ayé kóra wọn jọ sí láti máa jíròrò bí ọjọ́ iwájú ṣe máa rí fún tọkùnrin tobìnrin, tọmọdé tàgbà tó wà nínú ìṣẹ́ tí wọ́n ń gbé lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àgbà àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-èdè ṣe sọ, òótọ́ kan tó ń jáni ní tànmọ́-ọ̀n níbẹ̀ ni pé “aráyé ní ọrọ̀, ọgbọ́n àti agbára” tí wọ́n á fi yanjú ìṣòro àwọn tó ń gbé inú ebútú. Kí ló wá yẹ kí wọ́n ṣe tí wọn ò tíì ṣe? Ọ̀gbẹ́ni Annan sọ pé: “Mo nírètí pé . . . gbogbo àwọn tọ́ràn kàn [á lè] borí ìwà ọ̀dájú wọn, táwọn olóṣèlú á sì ní ìfẹ́ láti ran àwọn èèyàn bíi tiwọn lọ́wọ́, torí pé ohun tí kò jẹ́ káwọn tálákà tẹ̀ síwájú nìyẹn.”

Ǹjẹ́ ìrètí yìí lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ bí? Kí ló lè mú káwọn olóṣèlú káàkiri àgbáyé àti lórílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan pa ìmọtara-ẹni-nìkan tì kí wọ́n sì fìmọ̀ ṣọ̀kan láti wá ojútùú sí ìṣòro gbogbo àwọn tíyà ń jẹ? Ẹnì kan wà tó ní ọrọ̀, ọgbọ́n àti agbára láti lè yanjú wàhálà ilégbèé tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́. Èyí tó tún wá ṣe pàtàkì jù ni pé ó láàánú ó sì pinnu láti ṣe nǹkan kan lórí ẹ̀ láìpẹ́. Kódà, ìjọba rẹ̀ ti ní ètò tó kún rẹ́rẹ́ tó máa fi yanjú gbogbo ìṣòro ilégbèé tó wà lágbàáyé pátápátá.

Ètò Ìkọ́lé Tuntun

Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run sọ ohun tó máa ṣe sínú Bíbélì. Ó ṣèlérí pé: “Èmi yóò dá ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun.” (Aísáyà 65:17) Ìyàtọ̀ tó kàmàmà ni èyí yóò mú wá o. Ìjọba “ọ̀run” tuntun yìí yóò ṣe ohun tí ìjọba èèyàn kankan kò lè ṣe láéláé. Ìjọba Ọlọ́run, tàbí ìṣàkóso rẹ̀, yóò mú ìlera àti ààbò tó dájú wá fún gbogbo àwọn tó bá wà nínú ayé tuntun, yóò sì sọ gbogbo wọn di èèyàn pàtàkì. Jèhófà ti sọ fún Aísáyà ṣáájú pé “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” òun á kó àwọn tó máa jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ayé tuntun yìí jọ. (Aísáyà 2:1-4) Èyí fi hàn pé ìyàtọ̀ náà kù sí dẹ̀dẹ̀.—Mátíù 24:3-14; 2 Tímótì 3:1-5.

Ó tiẹ̀ dáa tó jẹ́ pé, nínú àwọn ẹsẹ tó kù ní orí karùndínláàádọ́rin ìwé Aísáyà, Ọlọ́run sọ ní pàtó bó ṣe máa pèsè ibùgbé tó máa wà pẹ́ títí fún kálukú wa. Ó ní: “Wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn.” Bákan náà, “Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé.” (Aísáyà 65:21, 22) Rò ó wò ná, pé ìwọ náà á nílé tó dáa lórí, tí wàá máa gbé ní àyíká tó mọ́ tónítóní níbi tó láàbò nínú Párádísè àgbàyanu! Ta ni kò ní fẹ́ kóun wà nírú ipò yẹn? Àmọ́, báwo ni ìlérí Ọlọ́run yìí ṣe lè dá ọ lójú?

Ìlérí Tó O Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé

Nígbà tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá Ádámù àti Éfà, kò pa wọ́n tì sí ilẹ̀ àpatì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi wọ́n sínú ọgbà kan ní Édẹ́nì, ọgbà Ẹlẹ́wà kan tó mọ́ tónítóní tó ni omi àti oúnjẹ tó pọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:8-15) Jèhófà sọ fún Ádámù pé kó fi ọmọ “kún ilẹ̀ ayé,” kì í ṣe kérò pọ̀ jù níbẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ohun tó wà lọ́kàn Ọlọ́run látìbẹ̀rẹ̀ ni pé kí gbogbo nǹkan wà létòlétò fáwọn èèyàn, kí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan, kí wọ́n sì máa gbádùn nǹkan rere lọ́pọ̀ yanturu.

Àmọ́ nígbà tó yá nígbà ayé Nóà, ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ipá àti ìṣekúṣe débi pé “ilẹ̀ ayé sì wá bàjẹ́ ní ojú Ọlọ́run tòótọ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:11, 12) Ǹjẹ́ Ọlọ́run ṣe bí ẹni tí kò rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn bí? Rárá o. Lójú ẹsẹ̀ ló wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ náà. Nítorí orúkọ rẹ̀ àti nítorí Nóà olódodo àtàwọn ọmọ rẹ̀, ó fọ ilẹ̀ ayé mọ́ tónítóní nípasẹ̀ Ìkún Omi tó kárí ayé. Nítorí náà, nígbà tí Nóà àtàwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀ kalẹ̀ látinú áàkì náà sínú ilé wọn tuntun, ìyẹn ilé ayé, Jèhófà tún sọ fún wọn pé kí wọ́n máa tàn káàkiri, ‘kí wọ́n di púpọ̀, kí wọ́n kún ilẹ̀ ayé.’—Jẹ́nẹ́sísì 9:1.

Kódà nígbà tó ṣe, Ọlọ́run fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ tó ṣèlérí fún Ábúráhámù babańlá wọn. Bíbélì pe Ilẹ̀ Ìlérí yẹn ní “ilẹ̀ kan tí ó dára tí ó sì . . . ń ṣàn fún wàrà àti oyin.” (Ẹ́kísódù 3:8) Nítorí àìgbọràn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n fi ogójì ọdún rìn káàkiri nínú aginjù láìní ibi pàtó tí wọ́n lè pè ní ilé. Síbẹ̀, nítorí pé Ọlọ́run ti sọ ọ́, ó pàpà fún wọn ní ilẹ̀ tí wọ́n á máa gbé. Ìtàn náà tí Ọlọ́run mí sí sọ pé: “Jèhófà fún wọn ní ìsinmi yí ká. . . Kò sí ìlérí kan tí ó kùnà nínú gbogbo ìlérí dáradára tí Jèhófà ti ṣe fún ilé Ísírẹ́lì; gbogbo rẹ̀ ni ó ṣe.”—Jóṣúà 21:43-45.

Ilé Rèé Nígbẹ̀yìngbẹ́yín!

Látàrí ohun tá a ti jíròrò yìí, ó ṣe kedere pé ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà ní Aísáyà orí karùndínláàádọ́rin kì í ṣe ìlérí tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá gbogbo nǹkan, ó dájú pé ó ní agbára láti ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ ní ṣíṣe kó fi lè fọ ilẹ̀ ayé mọ́ kó sì mú kí ohun tó ní lọ́kàn látìbẹ̀rẹ̀ ṣẹ. (Aísáyà 40:26, 28; 55:10, 11) Pẹ̀lúpẹ̀lù, Bíbélì fi dá wa lójú pé ó fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Sáàmù 72:12, 13) Ó ti ṣètò láti mú kí ilé tó bójú mu wà fáwọn olódodo nígbà kan rí, kò sì tún ní pẹ́ ṣe irú rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.

Kódà, nígbà tí Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi wá sílé ayé, ó dìídì kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé ‘kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe láyé bíi ti ọ̀run.’ (Mátíù 6:10) Nígbà kan báyìí, ó fi hàn pé ayé yóò di Párádísè. (Lúùkù 23:43) Ronú ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ná. Kò ní sí ilé ebútú mọ́, kò ní sáwọn tó ń tọrọ ilé gbé mọ́, kò ní sí asùnta bẹ́ẹ̀ ni kò ní sẹ́ni táá máa bẹ̀rù pé wọ́n máa lé òun níbi tóun ń gbé. Àkókó alárinrin nìyẹn á mà jẹ́ o! Lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, gbogbo èèyàn pátá ló máa nílé lórí!

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

IRÚ ILÉ TÍ WỌ́N Ń KỌ́ NÍ ÍSÍRẸ́LÌ ÀTIJỌ́

Ẹ̀rí wà pé, bíi tàwọn ará Kénáánì, tó wà ṣáájú wọn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ràn àtimáa fi òkúta kọ́lé. Àwọn ilé yìí máa ń lágbára ju ara wọn lọ, wọ́n sì lè dáàbò bo èèyàn lọ́wọ́ àwọn jàgùdà jura wọn lọ. (Aísáyà 9:10; Ámósì 5:11) Ṣùgbọ́n láwọn ibi tí ilẹ̀ ti tẹ́ pẹrẹsẹ, amọ̀ tí wọ́n sá lóòrùn tàbí tí wọ́n sun ni wọ́n fi máa ń mọ búlọ́ọ̀kù. Àwọn búlọ́ọ̀kù yìí ni wọn á wá fi mọ ògiri ilé náà. Ṣe ni ọ̀pọ̀ òrùlé wọn máa ń tẹ́ pẹrẹsẹ, òrùlé míì sì máa ń ní ìyẹ̀wù. Ọ̀pọ̀ ilé ló máa ń ní ààrò ní àgbàlá wọn, wọ́n sì máa ń ní kànga tàbí ìkùdu nígbà míì.—2 Sámúẹ́lì 17:18.

Ọ̀pọ̀ ìlànà lórí ilé kíkọ́ ló wà nínú Òfin Mósè. Ààbò ẹ̀mí lohun tó ṣe pàtàkì jù nínú rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ní láti ṣe ìgbátí yí òrùlé wọn ká kó má bàa di pé èèyàn já bọ́ láti ibẹ̀. Òfin kẹwàá kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n má ṣe ṣojúkòkòrò ilé ẹlòmíràn. Ẹnikẹ́ni tó bá ní láti ta ilé rẹ̀ ṣì ní ẹ̀tọ́, títí dìgbà kan, láti tún un rà padà.—Ẹ́kísódù 20:17; Léfítíkù 25:29-33; Diutarónómì 22:8.

Nílẹ̀ Ísírẹ́lì, wọ́n tún máa ń lo ilé wọn gẹ́gẹ́ bí ibi tí wọ́n ti lè fáwọn ọmọ wọn ní ìtọ́ni tẹ̀mí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fáwọn Bàbá pé kí wọ́n máa kọ́ àwọn ọmọ wọn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nígbà tí wọ́n bá jókòó ní ilé wọn, ó sì ní kí wọ́n mú gbogbo ohun tó bá jẹ mọ́ ìbọ̀rìṣà kúrò nínú ilé wọn.—Diutarónómì 6:6, 7; 7:26.

[Àwòrán]

Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, wọ́n máa ń bójú tó àwọn nǹkan tẹ̀mí nínú ilé, irú bíi ṣíṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

ÀWỌN ILÉ ÌGBÀ LÁÉLÁÉ

Bíbélì kò sọ ohunkóhun nípa irú ilé tí Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́ gbé. Àmọ́, Jẹ́nẹ́sísì 4:17 sọ pé Kéènì “dáwọ́ lé títẹ ìlú ńlá kan dó, ó sì fi orúkọ ọmọkùnrin rẹ̀ Énọ́kù pe ìlú ńlá náà.” Tá a bá fojú tòde òní wo ilé náà, bóyá ló lè ju abúlé kan tí wọ́n mọ odi yí ká lọ. Àkọsílẹ̀ yẹn ò sọ irú ilé tí wọ́n kọ́ sínú ìlú náà. Bóyá gbogbo abúlé náà kò ju ibi tí Kéènì, ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ ń gbé.

Inú àgọ́ ni wọ́n sábà máa ń gbé nígbà láéláé. Àtọmọdọ́mọ Kéènì kan tó ń jẹ́ Jábálì ni Bíbélì pè ní “olùpilẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí ń gbé inú àgọ́ tí wọ́n sì ní ohun ọ̀sìn.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:20) Ó ṣe kedere pé á rọrùn láti pàgọ́ àti láti máa gbé e káàkiri, béèyàn bá ṣe ń ṣí kiri.

Nígbà tó yá, tí ọ̀làjú bẹ́rẹ̀ sí dé, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn ìlú tó ní oríṣiríṣi ilé aláràbarà. Bí àpẹẹrẹ, ní ìlú Úrì, níbi tí Ábúrámù babańlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé, àwọn àwókù nǹkan àtijọ́ táwọn èèyàn rí níbẹ̀ fẹ̀rí hàn pé àwọn tó gbé níbẹ̀ látijọ́ gbádùn ògiri tí wọ́n rẹ́ tí wọ́n sì kùn lẹ́fun, àwọn ilé náà sì ní tó yàrá mẹ́tàlá tàbí mẹ́rìnlá. Irú ilé báwọ̀nyí ti ní láti wọ àwọn ará ìgbàanì lójú gan-an ni.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]

Ọlọ́run ṣèlérí láti pèsè ilé fáwọn olódodo