Gbogbo Èèyàn Ló Yẹ Kó Ní Ibùgbé
Gbogbo Èèyàn Ló Yẹ Kó Ní Ibùgbé
“Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ láti gbé ìgbé ayé tó bójú mu nínú èyí tí òun àti ẹbí rẹ̀ yóò wà ní ìlera àti àlàáfíà, tí wọn yóò sì ní . . . ilégbèé.” —Ìkéde Kárí Ayé fún Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, Abala Kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n.
Ọ̀KỌ̀Ọ̀KAN èjèèjì làwọn alágbàro bẹ̀rẹ̀ sí kóra jọ títí tí wọ́n fi di ogunlọ́gọ̀ síbi tí wọ́n fi ṣe ibùgbé báyìí. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìdílé ló ń gbé lẹ́yìn ìlú ní àgọ́ olówó pọ́ọ́kú táwọn èèyàn ń gbé mọ́tò tí wọ́n fi ṣelé sí, irú ilé báyìí ni wọ́n ń pè ní parqueaderos. Nínú àgọ́ yẹn, kò sí àwọn ohun kòṣeémánìí bí ilé ìgbọ̀nsẹ̀, omi, àti pé bí wọ́n ṣe ń palẹ̀ ìdọ̀tí mọ́ níbẹ̀ kò bóde oní mu tàbí ká kúkú sọ pé wọn kì í palẹ̀ ìdọ̀tí mọ́. Akọ̀ròyìn kan sọ pé: “Àgọ́ náà kò bójú mu páàpáà, [àwọn lébìrà tó ń ṣiṣẹ́ oko] ló lè gbébẹ̀.”
Lọ́dún mẹ́ta sẹ́yìn nígbà táwọn aláṣẹ bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn èèyàn kúrò nírú àwọn àgọ́ yẹn, àwọn ìdílé kan lára àwọn tó ń gbébẹ̀ ta ọkọ̀ tí wọ́n ń gbé inú rẹ̀, wọ́n sì kọrí sí àárín ìlú láti lọ máa gbénú àwọn ilé àtàwọn ibi ìgbọ́kọ̀sí táwọn èèyàn ti kún fọ́fọ́. Ṣe làwọn míì kàn wulẹ̀ kó ẹ̀rù wọn tí wọ́n sì forí lé ibikíbi tí wọ́n bá ṣáà ti lè ráàyè sùn lálẹ́ tí wọ́n bá toko ìkórè dé, ìyẹn ibi tí wọ́n lè pè ní ilé wọn.
Àbó o ti ń rò pé ibì kan ní Àárín Gbùngbùn Amẹ́ríkà tàbí Gúúsù Amẹ́ríkà nibi tá à ń sọ yìí wà? Rò ó dáadáa o. Tó o bá dé tòsí ìlú kan tí wọ́n ń pè ní Mecca, lápá gúúsù ìpínlẹ̀ California,
lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wàá rí àgọ́ tá à ń sọ yìí, ọkọ̀ tó máa gbé ọ débẹ̀ láti ìlú Palm Springs tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù kò lè rìn ju wákàtí kan lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣe làwọn èèyàn ń ralé lọ bó ṣe wù wọ́n nílẹ̀ Amẹ́ríkà tó sì jẹ́ pé lọ́dún 2002, iye tó ń wọlé fún ìdílé kan, tá a bá pín in dọ́gba jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹgbàá [42,000] dọ́là, wọ́n ní ó ju mílíọ̀nù márùn-ún ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà lọ tó ṣì ń gbé nínú ilé tí kò bójú mu.
Ọ̀ràn náà burú jù báyìí lọ láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Pẹ̀lú gbogbo ètò táwọn olóṣèlú, lẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ àti lájọlájọ tó fi mọ́ àwọn ẹlẹ́sìn ń dá sílẹ̀, wàhálà ilégbèé ṣì ń lè sí i kárí ayé.
Wàhálà Tó Kárí Ayé Ni
Wọ́n ṣírò rẹ̀ pé àwọn tó ń gbé láwọn ilé akúṣẹ̀ẹ́ jákèjádò ayé ju bílíọ̀nù kan lọ. Lórílẹ̀-èdè Brazil, àwọn ògbógi tó ń ṣèwádìí nípa báwọn èèyàn ṣe máa ń ti ìlú kéékèèké ya lọ sí ìlú ńlá sọ pé ẹ̀rù ń ba àwọn pé àwọn ilé akúṣẹ̀ẹ́ lórílẹ̀-èdè náà, èyí tí wọ́n ń pè ní favelas kò ní pẹ́ “di ibi tó túbọ̀ tóbi sí i, térò á sì pọ̀ níbẹ̀ ju ìlú tó ń ṣàkóso wọn lọ.” Àwọn ìlú kan sì wà lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà wa yìí níbí tó jẹ́ pé ìdá mẹ́rin nínú márùn-ún àwọn tó ń gbébẹ̀ ló ń gbé inú ebútú tí wọ́n sì ń tọrọ yàrà lò lọ́dọ̀ àwọn míì tó ríbi gbé. Lọ́dún 2003, Ọ̀gá Àgbà àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè, Kofi Annan sọ pé: “Bí wọn kò bá wá nǹkan gidi ṣe sọ́ràn náà, tó bá fi máa di ọgbọ̀n ọdún sí àkókò tá a wà yìí, iye àwọn tó ń gbé inú ilé akúṣẹ̀ẹ́ lágbàáyé á ti di bílíọ̀nù méjì.”
Àmọ́ ṣá, àwọn tó ń gbé nírú ilé báyìí nìkan la tíì rí lókè yìí o, a ò tíì rí ìṣòro tí gbígbé nírú ilé bẹ́ẹ̀ ń kó bá àwọn mẹ̀kúnnù tó ń gbé láyé o. Gẹ́gẹ́ bí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ṣe sọ, ó ju ìlàjì èèyàn tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà tí wọn kò rí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà ṣe ìmọ́tótó ilé wọn, ó sì tó ìdá mẹ́ta tí kò rí omi tó mọ́ lò. Yàtọ̀ síyẹn, ìdá mẹ́rin àwọn tó ń gbé láyé ni kò rílé gidi gbé, ìdá márùn-ún ni kò jàǹfààní ètò ìlera tó bójú mu. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, ọ̀pọ̀ èèyàn láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà ni kò lè jẹ́ kí ajá tàbí ẹran ọ̀sìn wọn míì wà nírú ipò yẹn.
Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn
Kò sẹ́ni tí kò gbà pé gbogbo èèyàn ló nílò ibi tó bójú mu tó lè máa forí ara ẹ̀ pamọ́ sí. Ìkéde Kárí Ayé fún Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, tí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè fọwọ́ sí lọ́dún 1948 kéde pé ẹ̀tọ́ mùtúmùwà ni láti gbé ìgbé ayé tó bójú mu nínú èyí tó ti yẹ kó ní ilégbèé tó tẹ́ ẹ lọ́rùn. Òótọ́ ni, gbogbo èèyàn ló yẹ kó ní ilé tó dáa.
Láìpẹ́ yìí, lọ́dún 1996, àwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan fọwọ́ sí àbá kan tó wá di UN’s Habitat Agenda, ìyẹn àbá fún ìjíròrò lórí ibùgbé tí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ṣe. Ìwé yìí ṣàlàyé àwọn apá ibi tó yẹ kí wọ́n ti jára mọ́ nǹkan tí wọ́n ń ṣe kí wọ́n bàa lè pèsè ilé fún gbogbo èèyàn. Lẹ́yìn náà, ní January 1, ọdún 2002, àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-èdè gùn lé àbá yìí síwájú sí i nípa sísọ ọ́ di ọ̀kan lára àwọn ètò tí àjọ náà gbé kalẹ̀.
Ibi tọ́rọ̀ ọ̀hún pakasọ sí ni pé àwọn kan nínú àwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ jù lọ lágbàáyé tún ti bẹ̀rẹ̀ sí ronú lórí bí wọ́n á ṣe lọ kọ́lé sínú òṣùpá, wọ́n sì ń wá bí wọ́n á ṣe lọ yẹ inú pílánẹ́ẹ̀tì tó ń jẹ́ Mars wò. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn tó ń pọ̀ sí i tí wọ́n tálákà jù lórílẹ̀-èdè wọn ni ò ríbi tó dáa gbé nílé ayé ńbí. Báwo ni wàhálà ọ̀rọ̀ ilégbèé yìí ṣe kàn ọ́? Ṣé ìrètí kankan wà pé lọ́jọ́ kan kálukú á ní ibi tó dẹ̀ ẹ́ lọ́rùn láti fi ṣe ibùgbé?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]
Níbi táwọn orílẹ̀-èdè kan ti ń wọ́nà láti lọ kọ́lé sínú òṣùpá, la ti rí ọ̀pọ̀ ọmọ orílẹ̀-èdè wọn tí kò ríbi tó bójú mu gbé láyé ńbí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ní ìlú ńlá kan, àwọn tó ń gbé inú àgọ́ jẹ̀kúrẹdí kan lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àbọ̀, ìyà omi àti ibi tí wọ́n lè kẹ́gbin sí ń jẹ fòóò sí wọn lára
[Credit Line]
© Tim Dirven/Panos Pictures
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
ÀRÍWÁ AMẸ́RÍKÀ