Ibi Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì—Kí Ló Wà Níbẹ̀ Tó Ṣì Yẹ Kí N Mọ̀?
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Ibi Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì—Kí Ló Wà Níbẹ̀ Tó Ṣì Yẹ Kí N Mọ̀?
“Bó tilẹ̀ jẹ́ pé onítìjú èèyàn ni mí, síbẹ̀, tí mo bá dé ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ó máa ń rọrùn fún mi láti bá àwọn èèyàn tí mi ò lè bá sọ̀rọ̀ lójúkojú sọ̀rọ̀. Wọn ò kúkú ní mọ irú ẹni tí mo jẹ́.”—Peter. a
“Ní ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ẹ̀rù ò ní bà ẹ́ láti sọ gbogbo ohun tó o bá fẹ́ sọ.”—Abigail.
OHUN tó ń jẹ́ ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni “àwọn ibi” téèyàn ti lè bá ẹlòmíì fọ̀rọ̀ wérọ̀ nípa títẹ ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ síra lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Èrò lè pọ̀ níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì kan náà tí wọ́n á máa kọ̀wé ránṣẹ́ síra wọn tí wọ́n á sì máa ka èsì ara wọn lójú ẹsẹ̀.
Àwọn ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó máa ń wu àwọn ọ̀dọ́ jù láti lọ. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọ̀dọ́ káàkiri àgbáyé ló máa ń rọ́ lọ síbẹ̀ lójoojúmọ́ kí wọ́n lè sọ èrò ọkàn wọn jáde lórí onírúurú ọ̀ràn. Àwọn ilé ìwé kan ti ń lò ó báyìí láti ráàyè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ní orílẹ̀-èdè míì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan nílẹ̀ Amẹ́ríkà ti lọ síbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì láti lè bá àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn láti ilẹ̀ Sípéènì àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tàbí láti ibòmíì sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ, olùkọ́ wọn sì máa ń mójú tó wọn. Kódà, àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ kan lè bá onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ, oníṣègùn tàbí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ míì fọ̀rọ̀ wérọ̀ nípa iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ wọn.
Ṣùgbọ́n kì í ṣe ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ ló ń gbé ọ̀pọ̀ àwọn míì lọ síbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì o. Tó o bá ní láti lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ewu wo ló yẹ kó o ṣọ́ra fún?
Àwọn Oníṣekúṣe Máa Ń Dọdẹ Àwọn Ọmọdé Níbẹ̀
Abigail sọ pé: “Mò ń báwọn èèyàn fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́jọ́ kan lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni ọkùnrin kan bá bi mí bóyá mo mọ àwọn ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kankan. Ó fẹ́ bá wọn lò pọ̀. Ó lóun á fún wọn lówó bí wọ́n bá lè gbà kóun bá wọn sùn.”
Ohun tí Abigail rí yìí kò ṣàjèjì. Ìṣòro àwọn abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe pọ̀ gan-an lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì débi táwọn ìjọba fi ní ìlànà lórí bá a ṣe lè dáàbò bo àwọn ọ̀dọ́. Bí àpẹẹrẹ, àtẹ̀jáde kan láti ilé iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ìyẹn Federal Bureau of Investigation, kìlọ̀ nípa àwọn kan tó máa ń tètè dá ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ sílẹ̀ tí wọ́n á sì máa fi gbogbo ẹnu sọ ọ́ níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Àtẹ̀jáde náà tún kìlọ̀ nípa àwọn tí wọ́n “máa ń dọ́gbọ́n tan àwọn tí wọ́n fẹ́ mú. Ìyẹn àwọn tí wọ́n á máa ṣe bíi pé ire ẹni tí wọ́n ń bá sọ̀rọ̀ ló jẹ wọ́n lógún, wọ́n á fi ìfẹ́ hàn sí wọn, wọ́n á máa ṣe bí onínúure, kódà wọ́n tiẹ̀ lè ra ẹ̀bùn fún wọn.”
Ìwé tí ilé iṣẹ́ tá à ń sọ yìí fi síta ṣàlàyé ọgbọ́n táwọn ẹlẹ́tàn yìí máa ń dá, ó ní: “Wọ́n máa ń tẹ́tí sílẹ̀ káwọn ọmọdé lè sọ ìṣòro wọn fún wọn, wọ́n á sì máa káàánú wọn. Wọ́n máa ń mọ àwọn orin, eré àtàwọn nǹkan míì tọ́mọdé fẹ́ràn, èyí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé. Àwọn wọ̀nyí á máa wọlé sáwọn ọmọdé
lára díẹ̀díẹ̀ nípa dídọ́gbọ́n mú ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ wọ inú ìjíròrò wọn wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́.”Kì í ṣàwọn àgbààgbà oníṣekúṣe nìkan ló máa ń wà nídìí ìwà ibi yìí. Ó tún yẹ kó o mọ̀ pé àwọn ọ̀dọ́ kan wà tí wọn ò mọ ìlànà Bíbélì tàbí tí wọn ò fẹ́ tẹ̀ lé e. Wo ohun tójú ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Cody rí. Ó ń bá àwọn ọ̀dọ́ míì fọ̀rọ̀ wérọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì lọ́jọ́ kan nígbà tí ọmọbìnrin kan ní kó jẹ́ káwọn lọ síbi táwọn ti lè máa fọ̀rọ̀ wérọ̀ tí ẹlòmíì ò ti ní mọ ohun táwọn ń sọ. Ló bá béèrè ohun kan tó jẹ mọ́ ìbálòpọ̀. Ọpẹ́lọpẹ́ pé Cody lo ìkóra-ẹni-níjàánu, bó ṣe fòpin sí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ náà nìyẹn.
Nítorí bí Ẹlẹ́dàá ṣe dá wa, ọkàn èèyàn lè máa lọ síbi ìbálòpọ̀, ìyẹn sì lè mú kó nira fún ẹ púpọ̀ láti ṣe bí Cody ṣe ṣe. Peter, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan jẹ́wọ́ pé: Mo rò pé ìkóra-ẹni-níjàánu tí mo ní pọ̀ tó láti mú kí n lè fòpin sí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan tó bá ti ń lọ síbi ìbálòpọ̀ ni. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń jẹ́ pé n kì í lè dá a dúró, témi náà á sì máa dá sí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ lórí ìbálòpọ̀. Ojú ara mi sì máa ń tì mí bí mo bá ti ṣe bẹ́ẹ̀ tán.. Àmọ́, o lè máa rò ó pé: ‘Tí mi ò bá sọ bí mo ṣe jẹ́ níbi tí mo ti ń fọ̀rọ̀ wérọ̀, ewu wo ló wá wà nínú kí n máa sọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?’
Ṣó Léwu Láti Máa Sọ̀rọ̀ Ìbálòpọ̀ Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?
Bíbélì ò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ lórí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀. (Òwe 5:18, 19) A mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ sábà máa ń wá séèyàn lọ́kàn gan-an, pàápàá nígbà tó bá ṣì wà lọ́dọ̀ọ́. Nítorí náà, kò burú tó o bá ń sọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀. Ó yẹ kó o mọ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè pàtàkì tó ń jẹ ọ́ lọ́kàn nípa rẹ̀. b Àmọ́, ọ̀nà tó o bá gbà wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè nípa ìbálòpọ̀ wà lára ohun tó máa sọ bí ìgbésí ayé rẹ ṣe máa láyọ̀ tó ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú.
Tó o bá sọ pé orí Íńtánẹ́ẹ̀tì lo ti fẹ́ lọ jíròrò ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀, kódà kó jẹ́ pẹ̀lú àwọn tó pera wọn ní ọ̀rẹ́ ẹ, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́kùnrin kan tí Bíbélì sọ̀rọ̀ rẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ. Ọ̀dọ́kùnrin yìí fẹ́ wádìí ohun tí kò yé e, ó rin gbéregbère dé etí ilé obìnrin aṣẹ́wó kan báyìí. Ṣe ni obìnrin yìí kọ́kọ́ ń bá a sọ̀rọ̀ o. Àmọ́, nígbà tó ti wá mú kí ara ọmọkùnrin yìí gbóná, ọ̀ràn yẹn ò mọ síbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ mọ́. “Lójijì, ó ń tọ obìnrin náà lẹ́yìn, bí akọ màlúù tí ń bọ̀ àní fún ìfikúpa, . . . gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ti ń ṣe kánkán sínú pańpẹ́.”—Òwe 7:22, 23.
Bí ìwọ náà bá ń sọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, o lè di ẹni tó ń fẹ́ díẹ̀ sí i láti tẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Philip sọ pé: “Mò ń bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni àwòrán ìṣekúṣe kan bá dédé yọ lójú kọ̀ǹpútà mi. Ẹni tí mò ń bá sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ló fi ránṣẹ́ sí mi.” Tó bá ti lè wá sí ọ lọ́kàn pẹ́rẹ́n láti rí i dáadáa, ó lè di pé kó o tún fẹ́ wò ó díẹ̀ sí i, irú bíi kó o fẹ́ lọ síbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tí wọ́n ní kí ọmọdé máà dé. c Àwọn tó ti di bárakú fún láti máa wo àwòrán oníhòòhò máa ń ṣèṣekúṣe ni bópẹ́bóyá, wọ́n sì máa ń jìyà ẹ̀.—Gálátíà 6:7, 8.
Àwọn tó fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ lórí d Sólómọ́nì Ọba bá ọmọ rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ pàtàkì kan kó má bàa kó sọ́wọ́ àwọn tó lè tàn án sínú ìbálòpọ̀, ó sọ pé: “Jẹ́ kí ọ̀nà rẹ jìnnà réré sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, má sì sún mọ́ ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀, kí ìwọ má bàa fi iyì rẹ fún àwọn ẹlòmíràn, . . . kí àwọn àjèjì má bàa fi agbára rẹ tẹ́ ara wọn lọ́rùn.” (Òwe 5:8-10) A lè sọ ìlànà tó wà nínú ìmọ̀ràn yìí lọ́nà míì báyìí pé: Má ṣe sún mọ́ àwọn ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀, kó o má bàa fi iyì ẹ fáwọn àjèjì kan tí wọ́n kàn fẹ́ jìfà ẹ láti tẹ́ ara wọn lọ́rùn.
Íńtánẹ́ẹ̀tì kò nífẹ̀ẹ́ ẹ dénú o. Àwọn àjèjì yìí fẹ́ dọ́gbọ́n tàn ẹ́ sínú ìjíròrò nípa ìṣekúṣe ni, tó bá sì ṣeé ṣe kí wọ́n fa ìwọ náà sínú ẹ̀, láti lè tẹ́ ìfẹ́ tara wọn lọ́rùn.“Àwọn Tí Ń Fi Ohun Tí Wọ́n Jẹ́ Pa Mọ́”
Àmọ́, ìwọ lè sọ pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ lo fẹ́ lọ máa sọ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ó lè jẹ́ pé ohun tó ń ṣe Peter àti Abigail, tá a sọ̀rọ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan ló ń ṣe ẹ́, ìyẹn ni pé bóyá o rò pé ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì lo ti lè sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ tẹ́nikẹ́ni ò ní mọ̀ ẹ́, tójú ò sì ní tì ẹ́. e Síbẹ̀, ewu míì ṣì tún wà tó yẹ kó o ṣọ́ra fún.
Torí pé ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ò mọ̀ ẹ́, ó ṣeé ṣe kó o máà fẹ́ sọ òótọ́. Abigail sọ pé: “Màá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, tó bá wá yá, màá ṣe bíi pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ yẹn bá mi lára mu.” Bíi ti Abigail, ìwọ náà lè fẹ́ máa hùwà bí ẹlòmíì láti lè bá àwọn tẹ́ ẹ jọ ń fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ lákòókò yẹn mu. O lè máa sọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ tàbí kó o fara mọ́ èrò wọn torí pé o fẹ́ lọ́rẹ̀ẹ́ tuntun. Ohun míì tún ni pé o lè rí i pé á rọrùn fún ẹ níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì láti sọ èrò rẹ àtohun tó wà lọ́kàn ẹ, èyí tó o rò pé àwọn òbí ẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ kò ní fara mọ́. Ọ̀kan ò lè má ṣèkan nínú méjèèjì, nínú kó o máa tan àwọn òbí àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ tàbí kó o máa tan àwọn tó ò ń bá pàdé lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Tó o bá lọ ń díbọ́n ṣe bí irú ẹlòmíì lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ńṣe lò ń tan àwọn tó o bá pàdé níbẹ̀. Tó bá sì jẹ́ pé o ò finú han àwọn ará ilé ẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ, ṣe lò ń tan àwọn náà.
Bó tilẹ̀ jẹ pé kò tíì pẹ́ púpọ̀ tí ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì dóde, látijọ́ táláyé ti dáyé ló ti wà lọ́kàn ọmọ èèyàn láti máa parọ́ kí wọ́n sì máa yọ́ òjé fáwọn ẹlòmíì. Bíbélì fi hàn pé ẹni náà tó kọ́kọ́ parọ́, ìyẹn Sátánì Èṣù ló pilẹ̀ ọgbọ́n táwọn kan nínú àwọn tó ń lọ síbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ń lò. Títí tó fi parọ́ ẹ̀ àkọ́kọ́ kò jẹ́ kí wọ́n mọ bóun ṣe jẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5; Ìṣípayá 12:9, 10) Tó o bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Dáfídì Ọba, o ò ní jẹ́ kí wọ́n rí ẹ tàn jẹ. Ó kọ̀wé pé: “Èmi kò bá àwọn tí kì í sọ òtítọ́ jókòó; àwọn tí ń fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́ ni èmi kì í sì í bá wọlé.”—Sáàmù 26:4.
Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, àwọn ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì kan lè wúlò fún ẹ. Síbẹ̀, àwọn ọ̀dọ́ tó bá fẹ́ kí inú Jèhófà dùn sáwọn gbọ́dọ̀ ṣọ́ra gidigidi lórí lílo ohun ìbánisọ̀rọ̀ ìgbàlódé yìí. Tó bá pọn dandan fún ẹ láti lọ síbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, bóyá nírú ìgbà tó bá jẹ mọ́ iṣẹ́ ilé ìwé, ní káwọn òbí ẹ tàbí àgbàlagbà míì jókòó tì ẹ́. Àpilẹ̀kọ kan tó ń bọ̀ lọ́nà yóò sọ ìdí méjì míì tó fi yẹ kó o ṣọ́ra nígbà tó o bá ń wọlé síbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ó tún máa sọ bó o ṣe lè ṣe tàwọn ìṣòro tó lè ti ibẹ̀ yọjú, ká tiẹ̀ ní ò ń ṣọ́ra nípa bó o ṣe ń lò ó.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
b Nínú ìwé náà, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, a lè ráwọn àmọ̀ràn Bíbélì tó mọ́yán lórí tó lè ranni lọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀ràn bí ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó, ìdánìkanhùwà ìbálòpọ̀ àti irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀.
c Àwọn ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì kan wà tí wọ́n ní káwọn ọmọ tí kò bá tíì pé ọjọ́ orí kan pàtó máà dé. Ìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn ohun tí wọ́n ń jíròrò àtàwọn àwòrán tí wọ́n máa ń fi ránṣẹ́ síra níbẹ̀ máa ń mú kí ìṣekúṣe wu èèyàn. Àmọ́, ìwádìí fi hàn pé àwọn ọ̀dọ́ tọ́jọ́ orí wọn ò ju mẹ́sàn-án péré lọ máa ń purọ́ ọjọ́ orí wọn láti lè ráàyè wọ ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó jẹ́ tàwọn àgbàlagbà yìí.
d Níwọ̀n bí kò ti sí bó o ṣe lè mọ ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, onítọ̀hún lè díbọ́n bíi pé òun kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ó lè jẹ́ pé irọ́ ló ń pa.
e Ìwé kan tó ń fún àwọn òbí ní àbá nípa ààbò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn A Parent’s Guide to Internet Safety, dábàá pé káwọn tó bá ń lọ síbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì má sọ orúkọ wọn, àdírẹ́sì wọn, tàbí nọ́ńbà tẹlifóònù wọn fáwọn àjèjì tí wọ́n bá bá pàdé lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
Ìjíròrò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì léwu