Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Wà Nídìí Wàhálà Àìrílégbé?

Kí Ló Wà Nídìí Wàhálà Àìrílégbé?

Kí Ló Wà Nídìí Wàhálà Àìrílégbé?

ETÍ ìlú ńlá kan nílẹ̀ Áfíríkà, ni abilékọ kan, ẹni ọdún mẹ́rìndínlógójì, tó ń jẹ́ Josephine àtàwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́ta ń gbé. Ọmọ ọdún mẹ́fà ni èyí tó kéré jù nínú àwọn ọmọ rẹ̀, èyí tó dàgbà jù sì jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá. Kòròfo ike ló ń ṣà kiri, ó sì máa ń tà á fún ilé iṣẹ́ tó ń fi àlòkù ike ṣe ike tuntun, tó wà ní tòsí ibẹ̀, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tiẹ̀ nìyẹn. Owó tó ń rí lórí iṣẹ́ àṣekúdórógbó yìí kò tó dọ́là méjì owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà lóòjọ́. Ní ìlú tó ń gbé yìí, owó yẹn kò tó owó tóun àtàwọn ọmọ ẹ̀ á fi jẹun, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé á tó rán wọn nílé ìwé.

Tó bá sì ti parí iṣẹ́ ọjọ́ kan á padà síbi tó pè ní ilé, àbí, nígbà tí kò rí ibòmíì gbé. Ilé alámọ̀ ni ilé ọ̀hún, igi tẹ́ẹ́rẹ́ ni wọ́n sì fi ṣe òpó igun ilé náà. Páànù yíya tó ti dógùn-ún, tó sì ti fẹ́ẹ̀ ṣí, pẹ̀lú èéjá irin jánganjàngan àti òrùlé onírọ́bà ni wọ́n fi ṣe òrùlé. Wọ́n kó òkúta, pákó àti oríṣiríṣi àlòkù irin lé orí òrùlé kí atẹ́gùn líle má bàa gbé e lọ. Àpò ìdọ̀họ ló fi sí ẹnu ọ̀nà bí ilẹ̀kùn, òun náà ló sì fi sí ojú wíńdò. Báwo lèyí á ṣe dáàbò bò wọ́n tójú ọjọ́ bá ṣọwọ́ òdì, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ tìgbà táwọn jàgùdà bá dé?

Kódà, ibi tí obìnrin yìí pè nílé yẹn kì í ṣe tiẹ̀ gan-an. Ojoojúmọ́ lẹ̀rù ń ba òun àtàwọn ọmọ ẹ̀ pé wọ́n lè lé àwọn kúrò níbẹ̀. Ó ṣe tán, títì tó wà létí ibẹ̀ tí wọ́n fẹ́ fẹ̀ sẹ́yìn máa gba orí ilẹ̀ tí ilé náà wà kọjá. Ó ṣeni láàánú pé káàkiri ayé ni irú nǹkan báyìí wà.

Ilé Gbẹ̀mígbẹ̀mí

Ọ̀gbẹ́ni Robin Shell, ọ̀kan lára àwọn ọ̀gá àgbà tó ń bójú tó ètò kan tó wà fún ìrànlọ́wọ́ lórí ilégbèé kárí ayé, sọ pé: “Nírú ilé táwọn tálákà bá ń gbé báyìí, ojú máa ń ti àwọn ọmọ láti sọ pé ilé àwọn nìyẹn, . . . ṣe ni àìsàn á máa dá gbogbo ilé gúnlẹ̀, bákan náà, . . . wọn ò mọ ìgbà táwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tàbí àwọn onílẹ̀ máa wá wó [ilé] náà dànù.”

Tí ìdílé bá ń gbé nírú ipò yìí, ńṣe lẹ̀rù máa ń ba àwọn òbí nípa ìlera àti ààbò àwọn ọmọ wọn. Dípò kí iṣẹ́ ọwọ́ wọn tó láti pèsè fún ìdílé wọn, ibi tó jásí ni pé èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò wọn ni wọ́n fi ń là kàkà láti lè bójú tó àwọn nǹkan táwọn ọmọ wọn nílò, bí oúnjẹ, ìsinmi àti ilégbèé.

Téèyàn bá ń wo ọ̀ràn ọ̀hún látòkèèrè, ó rọrùn láti tètè sọ pé ó yẹ káwọn tálákà lè rí nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà, tí wọ́n bá dá a bí ọgbọ́n lọ́tùn-ún lósì. Àmọ́ ká kàn máa sọ pé kí wọ́n máa fọwọ́ ara wọn tún ìwà ara wọn ṣe nìkan ò tó láti mú kí ìgbésí ayé wọn gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Àwọn nǹkan míì tó lágbára wà nídìí wàhálà àìrílégbé tó kọjá agbára tẹ́nì kọ̀ọ̀kan lè sà. Àwọn olùṣèwádìí sọ pé àwọn nǹkan tó sábà máa ń fa wàhálà yìí jù ni èrò tó ń pọ̀ sí i, báwọn ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń ti ìlú kékeré ya lọ sí ìlú ńlá, àjálù, rògbòdìyàn òṣèlú àti òṣì tó ń bá wọn fínra. Ṣe làwọn ìṣòro márààrún yìí dà bí ìka márùn-ún tó fún mọ́ nǹkan pinpin, wọ́n ti fẹ́ yọ ilé ayé lẹ́mìí àwọn tálákà.

Èrò Tó Ń Pọ̀ Jù

Wọ́n ti fojú bù ú pé lọ́dọọdún iye èèyàn tó yẹ ká máa wálé fún tó mílíọ̀nù méjìdínláàádọ́ta sí ọgọ́rin, láfikún sí iye ilé tó wà tẹ́lẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àjọ tí ń pèsè owó láti bójú tó bérò ṣe ń pọ̀ sí i lágbàáyé lábẹ́ àsíá àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-èdè ṣe sọ, iye èèyàn tó wà láyé lé ní bílíọ̀nù mẹ́fà àti mílíọ̀nù kan lọ́dún 2001, wọ́n sì sọ pé tó bá fi máa di ọdún 2050, èrò tó wà láyé á ti tó nǹkan bíi bílíọ̀nù méje ó lé mílíọ̀nù mẹ́sàn-án sí bílíọ̀nù mẹ́wàá ó lé mílíọ̀nù mẹ́sàn-án. Èyí tó muni lómi níbẹ̀ ni pé tó bá jẹ́ pé ọgọ́rùn-ún èèyàn làwọn èèyàn tó wà ní orílẹ̀-èdè fi máa pọ̀ sí i ní ogún ọdún sí àkókò tá a wà yìí, méjìndínlọ́gọ́rùn-ún lára wọn ló máa wáyé láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Ìṣirò yìí fi hàn pé ìṣòro ńlá lọ̀ràn ilé gbígbé. Ohun tó tún wá mú kí wàhálà ọ̀hún pọ̀ sí i ni bó ṣe jẹ́ pé àwọn ìlú tó ti kún ya tẹ́lẹ̀ làwọn èèyàn tún ń ya lọ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.

Yíya Táwọn Èèyàn Ń Ya Lọ Sáwọn Ìlú Ńlá

Àwọn ìlú pàtàkì kọ̀ọ̀kan wà bíi New York, London àti Tokyo táwọn èèyàn sábà máa ń kà sí ibi tó ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà. Látàrí èyí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn látàwọn ìlú kéékèèké ló ń rọ́ lọ sí ‘àwọn ibi tí ilẹ̀ ti lọ́ràá’ yìí, ohun tí wọ́n sì sábà máa ń torí ẹ̀ lọ jù ni torí àtikàwé tàbí kí wọ́n wáṣẹ́ lọ síbẹ̀.

Bí àpẹẹrẹ, ọrọ̀ ajé ilẹ̀ Ṣáínà ń yára búrẹ́kẹ́ dáadáa. Ìròyìn kan sọ pé látàrí èyí, kó tó tó àádọ́ta ọdún sí àkókò tá a wà yìí, ilé aládàáni tí wọ́n á nílò níbẹ̀ láwọn ìlú ńláńlá nìkan á ju igba mílíọ̀nù lọ. Iye yìí ju ìlọ́po méjì iye ilé aládàáni tó wà ní gbogbo orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́wọ́lọ́wọ́. Irú ètò wo ni wọ́n fẹ́ gbé kalẹ̀ tí wọ́n fi lè kọ́ adúrú ilé tó tó báyìí ná?

Báńkì Àgbáyé sọ pé: “Lọ́dọọdún, láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ó tó nǹkan bíi mílíọ̀nù méjìlá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ìdílé tó lọ ń dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń gbé láwọn ìlú ńláńlá, àwọn wọ̀nyí sì nílò ibi tó dáa tó sì máa gbà wọ́n.” Nígbà tí kò sì ti sí ilé tó tó láti gbà wọ́n, ó di dandan fáwọn tálákà yìí láti forí wọn pamọ́ síbikíbi tí wọ́n bá ráàyè sí, ibi tẹ́nì kankan kì í fẹ́ gbé sì ni wọ́n sábà máa ń rí.

Àjálù Àtàwọn Rògbòdìyàn Òṣèlú

Ìṣẹ́ ti fipá mú ọ̀pọ̀ èèyàn láti máa gbé láwọn ibi tí omíyalé àti ilẹ̀ ríri ti lè wáyé àti ibi tí pọ̀tọ̀pọ́tọ̀ ti lè ya lù wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fojú bù ú pé ní ìlú Caracas, Venezuela, ó lé ní ìlàjì mílíọ̀nù èèyàn “tó ń tọrọ ilé gbé ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè níbi tí ilẹ̀ orí òkè ti sábà máa ń ya wálẹ̀.” Ó sì ṣeé ṣe kó o rántí gáàsì tó kàn dédé bú jáde ní ilé iṣẹ́ kan ní ìlú Bhopal lórílẹ̀-èdè Íńdíà lọ́dún 1984. Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá [2,500] èèyàn ló bá a rìn, nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn míì sì fara pa yánnayànna. Kí ló dé tó pààyàn tó bẹ́ẹ̀ yẹn? Pàtàkì ohun tó fà á ni bó ṣe jẹ́ pé àgọ́ àwọn tálákà tó wà nítòsí ibẹ̀ ti fi mítà márùn-ún tàbí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún wọ inú ilẹ̀ iléeṣẹ́ náà.

Rògbòdìyàn òṣèlú, irú bí ogun abẹ́lé, wà lára ohun tó ń pa kún ìṣòro ilé gbígbé. Ìròyìn kan tí ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn kan gbé jáde lọ́dún 2002 fi hàn pé á tó mílíọ̀nù kan ààbọ̀ èèyàn tó ń gbé lábúlé tí rògbòdìyàn tó ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Turkey láàárín ọdún 1984 sí 1999 lé kúrò nílé wọn. Ọ̀pọ̀ wọn ló di túláàsì fún láti lọ máa gbé ibikíbi tí wọ́n bá lè rí gbé. Lọ́pọ̀ ìgbà ló sì máa ń jẹ́ pé níbi táwọn ẹbí tàbí aládùúgbò wọn ti fún mọ́ra gádígádí nínú àgọ́ ahẹrẹpẹ, ilé mèrẹ́ǹtì, ahéré oko tàbí ibi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé lọ́wọ́ ni wọ́n máa ń ráàyè sí. Ìròyìn sọ pé àwọn ìdílé kan kóra jọ sí ibùjẹ ẹran, wọn ò sì dín ní èèyàn mẹ́tàlá ní yàrá kan ṣoṣo, ṣáláńgá kan ṣoṣo ni gbogbo wọn ń kìdìí bọ̀, ẹ̀rọ kan ṣoṣo ló sì wà níbẹ̀ níbi tí gbogbo wọn ti ń pọnmi. Ọ̀kan lára àwọn tó ń gbé níbẹ̀ sọ pé: “Irú ìgbésí ayé báyìí ti sú wa o jàre. A wá ń gbé inú ilé tí wọ́n kọ́ fáwọn ẹranko.”

Ọrọ Ajé Tó Dorí Kodò

Èyí tó gbẹ̀yìn nínú àwọn ìṣòro náà ni ti ọrọ̀ ajé tó dorí kodò fáwọn aláìní, kò sí bá a ṣe fẹ́ sọ̀rọ̀ ilégbèé tá ò ní sọ̀rọ̀ nípa èyí. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn Báńkí Àgbáyé tá a mẹ́nu bà lẹ́ẹ̀kan yẹn ṣe sọ, lọ́dún 1998 nìkan, ọ̀ọ́dúnrún àti ọgbọ̀n mílíọ̀nù èèyàn lára àwọn tó ń gbé àwọn ìlú ńlá tó wà làwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ló jẹ́ tálákà, wọn ò sì retí pé bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, nǹkan lè yí padà. Ṣé àwọn èèyàn tí ò rówó ra àwọn nǹkan kòṣeémáàní bí oúnjẹ àti aṣọ ló máa rówó rẹ́ǹtì ilé tó bójú mu tàbí kí wọ́n rówó kọ́lé?

Èlé orí ẹ̀yáwó àti ọ̀wọ́n gógó ọjà ti mú kó di àbá lásán fún ọ̀pọ̀ ìdílé láti rí owó yá ní báńkì. Owó iná àtàwọn owó míì téèyàn ń san sì ti mú kó ṣòro láti rọwọ́ họrí. Láwọn orílẹ̀-èdè míì, àtijẹ àtimu nira gan-an torí pé, ìdá márùn-ún wọn ni kò níṣẹ́ lọ́wọ́.

Èyí àtàwọn ìṣòro míì ló mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn káàkiri ayé gba kámú láti gbé ibikíbi tí wọ́n bá rí. Àwọn èèyàn kan ń gbé nínú òkú bọ́ọ̀sì, nínú àpótí gbàràmù onírin tí wọ́n fi ń kẹ́rù ránṣẹ́ àti inú ilé páálí. Àwọn míì ń gbé lábẹ́ àtẹ̀gùn, nínú ilé oníke, àti ilé tí wọ́n fi àjákù pákó kọ́. Kódà, àwọn ibi tí wọ́n fi ṣe iléeṣẹ́ rí gan-an ti di ilé fáwọn kan.

Kí Ni Wọ́n Ń Ṣe Láti Yanjú Ẹ̀ O?

Ọ̀pọ̀ èèyàn, lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, lẹ́lẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ àtàwọn ìjọba ń ṣe gudugudu méje láti wawọ́ wàhálà yìí. Bí àpẹẹrẹ, oríṣiríṣi àjọ ni wọ́n ti gbé kalẹ̀ lórílẹ̀-èdè Japan láti bá wọn kọ́lé olówó pọ́ọ́kú. Látàrí ètò ilé kíkọ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1994 lórílẹ̀-èdè South Africa, ó ti ju mílíọ̀nù kan ilé oníyàrá-mẹ́rin tí wọ́n ti kọ́. Lórílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà, ohun tí wọ́n ní lọ́kàn nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ ìkọ́lé tó kọjá agbára wọn yìí ni pé kí wọ́n máa kọ́ ọ̀kẹ́ méje àbọ̀ ilé aládàáni sáwọn ìlú ńlá kí wọ́n sì máa kọ́ ìlọ́po méjì sáwọn ìlú kéékèèké, lọ́dọọdún. Àwọn orílẹ̀-èdè míì, bíi Madagascar ti sa gbogbo agbára wọn láti mọ ọgbọ́n tí wọ́n á fi máa kọ́lé olówó pọ́ọ́kú.

Wọ́n ti dá ọ̀pọ̀ àjọ kalẹ̀ káàkiri àgbáyé, irú bí àjọ tó ń ṣètò ilégbèé lábẹ́ àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-èdè, láti lè fi hàn pé aráyé ń wá ọ̀nà “láti dín àwọn ìṣòro tó ń jẹ yọ látàrí yíya táwọn èèyàn ń ya lọ sáwọ́n ìlú ńlá kù, tábí kí wọ́n tiẹ̀ dènà wọn.” Àwọn iléeṣẹ́ aládàáni tí wọn ò tìtorí èrè dá sílẹ̀ àtàwọn iléeṣẹ́ tí kì í ṣe tìjọba pẹ̀lú ń gbìyànjú ìrànlọ́wọ́ tiwọn. Iléeṣẹ́ kan tí kì í ṣe tìjọba ti ran àwọn tó ju ọ̀kẹ́ méje ààbọ̀ [150,000] ìdílé lọ́wọ́ láti rọ́nà kúro nínú ipò tí kò bójú mu tí wọ́n ń gbé. Wọ́n fojú bù ú pé tó bá fi máa di ọdún 2005, iléeṣẹ́ yìí á ti ran àwọn tó ju mílíọ̀nù kan lọ́wọ́ láti rí ilé tó mọ níwọ̀n, tó bójú mu tí kò sì wọ́nwó.

Ọ̀pọ̀ nínú àwọn iléeṣẹ́ yìí ló ti jágbọ́n ohun tí wọ́n á máa kọ́ àwọn tó ń gbé nínú ilé tí kò bójú mu kí wọ́n bàa lè mọ bí wọ́n á ṣe máa gbádùn ìgbésí ayé wọn ní ìwọ̀nba tó bá ṣeé ṣe tó, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ kọ́ wọn lọ́nà tí ìgbésí ayé wọn fi lè sunwọ̀n díẹ̀ sí i. Ó dájú pé tíwọ náà bá dẹni tó nílò ìrànlọ́wọ́ wọn, o lè jàǹfààní lára àwọn ètò tí wọ́n gbé kalẹ̀ yẹn. Ọ̀pọ̀ nǹkan míì tún wà tó o lè ṣe láti ran ara rẹ lọ́wọ́.—Wo àpótí náà, “Bí Ilé Ẹ Bá Ṣe Rí Lara Ẹ Á Ṣe Le Tó,” tó wà lójú ìwé 17.

Láìka ti pé bóyá o lè mú kí ìgbésí ayé rẹ sunwọ̀n sí i tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ sí, kò sí ìrètí tó dájú tó bẹ́ẹ̀ pé ẹ̀dá èèyàn kan tàbí àjọ kan téèyàn dá sílẹ̀ wà tó lè gba aráyé lọ́wọ́ ìṣòro márààrún tó ń fa wàhálà yìí. Àgbáríjọ àwọn orílè-èdè ti rí i pé ṣe ni ọ̀rọ̀ yíyanjú ìṣòro ètò ọrọ̀ ajé àti pípèsè ohun tọ́mọ èèyan nílò túbọ̀ ń kọjá agbára àwọn. Lọ́dọọdún àràádọ́ta ọmọ ni wọ́n ń bí sínú ìṣẹ́ tó túbọ̀ ń ṣẹ́ àwọn èèyàn yìí. Ǹjẹ́ ìrètí tó dájú kan wà pé wàhálà àìrílégbé yìí máa dópin?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]

“BÍ ILÉ Ẹ BÁ ṢE RÍ LARA Ẹ Á ṢE LE TÓ”

Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣe sọ, béèyàn bá máa ní ìlera tó dáa, ó yẹ kí ilé tó ń gbé ní àwọn ohun tá a sọ sísàlẹ̀ yìí:

◼ Òrùlé tó dáa tí kò ní jẹ́ kí òjò máa wọlé

◼ Ògiri tó dáa tó lè dáàbò bo èèyàn nígbà tí ojú ọjọ́ bá ṣọwọ́ òdì àti ilẹ̀kùn tí kò ní jẹ́ káwọn ẹranko ráàyè máa wọlé

◼ Ó yẹ kí nẹ́ẹ̀tì wà lójú wíńdò àti lẹ́nu ọ̀nà káwọn kòkòrò, pàápàá ẹ̀fọn, má bàa ráàyè wọlé

◼ Ó yẹ kí agboòrùn wà yí ilé po kí oòrùn má bàa máa ta sára ògiri ilé tààràtà, pàápàá nígbà tí ojú ọjọ́ bá gbóná

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

ÀWỌN ILÉ TÍ WỌ́N Ń KỌ́ NÍLẸ̀ ÁFÍRÍKÀ LÁTIJỌ́

Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, irú ilé àtijọ́ tí wọ́n ń kọ́ nílẹ̀ Áfíríkà wà káàkiri. Wọ́n máa ń tóbi jura lọ, bí igun tí wọ́n ní ṣe rí sì yàtọ̀ síra. Àwọn ẹ̀yà kan, bí ẹ̀yà Kikuyu àti Luo, lórílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà nífẹ̀ẹ́ sáwọn ilé ológiri róbótó tí òrùlé wọn dà bí òkòtó. Àwọn míì, bí ẹ̀yà Masai tí wọ́n wà lórílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà àti Tanzania máa ń kọ́ ilé tó dà bí onígun mẹ́rin. Láwọn àgbègbè etíkun ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà, àwọn ilé kan wà tí wọ́n fi ewé ṣe òrùlé wọn tí òrùlé náà á sì gùn débi tá a fi máa kanlẹ̀ táá sì dà bí ilé oyin.

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lára ohun tí wọ́n fi ń kọ́ irú àwọn ilé báyìí ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó, kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìṣòro àìrílégbé láwọn ibẹ̀ yẹn. Ṣebí ẹnu kí wọ́n po yẹ̀pẹ̀ àti omi pọ̀ ni, amọ̀ tí wọ́n á fi mọlé ti délẹ̀ nìyẹn. Inú igbó tó sì wà nítòsí ni wọ́n ti máa rí igi, koríko, esùsú, àti ewé ọparun. Ìdí rèé tó fi jẹ́ pé kò sí bí ìdílé kan ṣe lówó tó tàbí kó kúṣẹ̀ẹ́ tó, wọ́n á ní ilé ara wọn.

Àmọ́ ṣá, irú àwọn ilé báyìí ní àwọn àbùkù tiwọn o. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn nǹkan tó lè jóná ni wọ́n fi kọ́ wọn, ilé ọ̀hún lè tètè gbiná. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀daràn kan lè tètè ráàyè wọnú ilé, tó bá kàn ti lu ihò sára ògiri alámọ̀. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé níbi púpọ̀ lónìí, irú ilé àtijọ́ tí wọ́n ń kọ́ nílẹ̀ Áfíríkà yìí ti ń pòórá díẹ̀díẹ̀, wọ́n sì ti ń fàwọn ilé tó lágbára jù bẹ́ẹ̀ lọ rọ́pò wọn.

[Àwọn Credit Line]

Orísun ìsọfúnni: Ìwé African Traditional Architecture

Àwọn ahéré: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda iléeṣẹ́ Bomas of Kenya Ltd – Ibùdó Ọ̀rọ̀ Àṣà, Eré Ìnàjú àti Ìpàdé Àpérò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

YÚRÓÒPÙ

[Credit Line]

© Tim Dirven/Panos Pictures

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

ÁFÍRÍKÀ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

GÚÚSÙ AMẸ́RÍKÀ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

GÚÚSÙ AMẸ́RÍKÀ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

ÉṢÍÀ

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 16]

© Àwòrán tí Teun Voeten/Panos àti J.R. Ripper/BrazilPhotos yà

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 17]

Àwòrán JORGE UZON/AFP/Getty Images; © Àwòrán tí Frits Meyst/Panos yà