Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
(Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí. Wàá rí àwọn ìdáhùn níbi tí a tẹ̀ ẹ́ sí lójú ìwé 18. Bó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ìdáhùn yìí, wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀.)
1. Ní Góṣénì, nítorí ibẹ̀ jẹ́ pápá ìjẹko tó dára jù lọ ní Íjíbítì. Àgbẹ̀ ẹlẹ́ran ọ̀sìn ni ìdílé Jékọ́bù
2. Ìkórìíra
3. Gbígbé ọwọ́ rẹ̀ sókè láti búra
4. Àgbébọ̀ adìyẹ tó ń kó àwọn òròmọdìyẹ rẹ̀ jọpọ̀ lábẹ́ àwọn ìyẹ́ apá rẹ̀
5. Sẹ́ẹ́tì
6. Àwọn olórí àlùfáà àtàwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì
7. Láti wá “gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́”
8. “Kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni”
9. Lẹ́yìn tó ti mú kí oorun àsùnwọra kun Ádámù, Ó mú ọ̀kan nínú egungun ìhà rẹ̀ ó sì fi ṣe obìnrin kan
10. Látinú “gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn àti orílẹ̀-èdè”
11. Yahweh
12. Ó kùnà láti sọ Jèhófà di mímọ́ lójú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí Jèhófà pèsè omi lọ́nà ìyanu nínú aginjù
13. Ó díbọ́n bí asínwín, ọba Gátì sì ní kí wọ́n jẹ́ kó máa lọ nítorí tí ó kà á sí ayírí tí kò lè ṣe wọ́n ní jàǹbá kan
14. Kò gbọ́dọ̀ ní ẹ̀sùn lọ́rùn, kò gbọ́dọ̀ jẹ́ aṣetinú-ẹni, kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ní ìtẹ̀sí fún ìrunú, kò gbọ́dọ̀ jẹ́ aláriwo ọ̀mùtípara, kò gbọ́dọ̀ jẹ́ aluni, kò gbọ́dọ̀ jẹ́ oníwọra fún èrè àbòsí
15. Ó gbé àṣẹ ìtọ́ni kan jáde pé, láti inú ibi ìṣúra ọba ni a ó ti pèsè ìnáwó, pé kí wọ́n dá àwọn ohun èlò wúrà àti fàdákà tí Nebukadinésárì kó jáde wá sí Bábílónì padà
16. Àwọn òbí gbọ́dọ̀ wà lójúfò láti lè máa lo gbogbo àyè tó bá ṣí sílẹ̀ láti gbin òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sínú ọkàn àwọn ọmọ wọn, ì báà jẹ́ lásìkò tí wọ́n ṣètò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí láwọn àkókò míì
17. Wọ́n fi tipátipá gbéṣẹ́ fún un láti gbé òpó igi oró Jésù nílẹ̀
18. “Ètè wọn” ni wọ́n fi ń bọlá fún Ọlọ́run, síbẹ̀ ọkàn-àyà wọn “jìnnà réré” sí i
19. Ó sọ omi di ọtí wáìnì níbi àsè ìgbéyàwó ní Kánà
Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. Apá ibo ni Fáráò sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa gbé nílẹ̀ Íjíbítì, kí sì nìdí tí ibẹ̀ fi dáa gan-an? (Jẹ́nẹ́sísì 47:3-6)
2. Kí ló lè fa asọ̀? (Òwe 10:12)
3. Kí ni Jèhófà sọ pé òun ṣe káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè ka ìlérí òun sí ẹ̀jẹ́ mímọ́ àti èyí tó ṣeé gbọ́kàn lé? (Ìsíkíẹ́lì 36:7)
4. Àpèjúwe wo ni Jésù lò láti fi ṣàlàyé bó ṣe sapá tó láti kó àwọn elétí kunkun olùgbé Jerúsálẹ́mù jọ pọ̀? (Mátíù 23:37)
5. Ọmọ Ádámù àti Éfà wo ni baba ńlá Jésù? (Lúùkù 3:38)
6. Àwọn wo gan-an ló wà nídìí ọ̀tẹ̀ tí wọ́n dì láti fi pa Jésù? (Mátíù 26:3)
7. Bí Jòhánù ṣe sọ, ìkésíni wo ló wà fún mùtúmùwà tí “òùngbẹ” òdodo ń “gbẹ”? (Ìṣípayá 22:17)
8. Bí ẹnikẹ́ni bá ro pé òun ṣaláìní ọgbọ́n, kí ló gbọ́dọ̀ ṣe, kí sì nìdí? (Jákọ́bù 1:5)
9. Kí ni Jèhófà ṣe láti lè fún Ádámù ní ìyàwó? (Jẹ́nẹ́sísì 2:22)
10. Ibo láwọn ọba àti àlùfáà tó máa bá Jésù ṣàkóso ayé ti máa jáde wá? (Ìṣípayá 5:9)
11. Ọ̀nà mìíràn wo la lè gbà pe orúkọ Ọlọ́run? (Ẹ́kísódù 6:3, àkíyèsí ìsàlẹ̀ ìwé, NW)
12. Kí ló fà á tí Jèhófà ò fi jẹ́ kí Mósè wọ Ilẹ̀ Ìlérí? (Númérì 20:10-12)
13. Kí ni Dáfídì ṣe kó bàa lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn Filísínì ní Gátì? (1 Sámúẹ́lì 21:12-14)
14. Àwọn nǹkan tí ò dáa wo ni kò yẹ ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ di alábòójútó nínú ìjọ Kristẹni? (Títù 1:7)
15. Ọ̀nà wo ni Dáríúsì ara Mídíà gbà kópa nínú títún tẹ́ńpìlì Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù kọ́? (Ẹ́sírà 6:5-8)
16. Báwo láwọn òbí tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ọmọ wọn ní òfin Jèhófà, nígbà wo ló sì yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀? (Diutarónómì 6:6, 7)
17. Báwo ni ti Símónì ara Kírénè ṣe wọ̀ ọ́ nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣekú pa Jésù? (Mátíù 27:32)
18. Ìwà àgàbàgebè wo làwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí ń hù tó mú kí Jésù fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwé Aísáyà lásìkò tó ń dẹ́bi fún wọn? (Mátíù 15:8)
19. Iṣẹ́ ìyanu wo ni Jésù kọ́kọ́ ṣe, ibo ló sì ti ṣe é? (Jòhánù 2:1-11)