Àwọn Ọ̀dọ́ Nílò Alábàárò
Àwọn Ọ̀dọ́ Nílò Alábàárò
GBOGBO abiyamọ tó mọyì ọmọ ló gbà pé àwọn ọmọ tí wọ́n bá ṣì ń fà ní tẹ̀tẹ́ máa ń yinwọ́ bí wọ́n bá rí àbójútó tó dáa. Bí wọ́n bá sì ń wá ẹni gbé wọn mọ́ra, wọ́n máa ń fẹ́ rá lọ sọ́dọ̀ òbí kó lè gbé wọn lésẹ̀. Àmọ́, Dókítà Barbara Staggers tó jẹ́ olùdarí ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ tó ti bàlágà, ìyẹn Children’s Hospital and Research Center ní Oakland, California, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé táwọn ọmọ bá ti bàlágà, ó ṣeé ṣe kí wọ́n máà fẹ́ láti bá àwọn òbí ṣe nǹkan pọ̀. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àkókò yìí gan-an ni wọ́n nílò àbójútó òbí jù lọ. Kí nìdí tọ́ràn fi rí bẹ́ẹ̀?
Béèyàn bá ti kúrò lọ́mọdé, á túbọ̀ máa ní àkókò láti ṣe ohun tó wù ú, láìsí ẹni táá yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò. Dókítà Staggers sì sọ pé ọ̀kan lára ewu ńlá tó dojú kọ àwọn ọmọ tí kò tíì pé ogún ọdún nìyẹn. Ó tiẹ̀ sọ nínú ìwé ìròyìn Toronto Star pé: “Ìgbà ìbàlágà jẹ́ àkókò táwọn ọmọ máa ń mọ irú ẹni táwọn jẹ́ àti báwọn ṣe lè bẹ́gbẹ́ mu. Tá a bá tún wá ro ti bí wọ́n ṣe máa ń fẹ́ láti dán ohun tó lè pa wọ́n lára wò àti ipa táwọn ojúgbà wọn máa ń ní lórí wọn, a ó rí i pé àkókò tó léwu gan-an ni wọ́n wà.” Ìgbà ìbàlágà tún pín sí ìpele ìpele, ṣùgbọ́n tọjọ́ orí kọ́ là ń wí o. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí Dókítà Staggers ṣe sọ, “ọ̀ràn tó ní í ṣe pẹ̀lú ìṣesí àwọn [ọ̀dọ́langba] ni. Ó tún kan bí ohun tí wọ́n ń gbọ́ ṣe ń yé wọn sí àti ohun tó ń wù wọ́n láti dáwọ́ lé.” Ní ìpele àkọ́kọ́ ìgbà ìbàlágà, àwọn ọmọ kì í sábà rí tẹlòmíì rò, wọ́n á máa ronú ṣáá nípa ara wọn tó ń yí padà, wọ́n á sì máa fi ìwàǹwára ṣe nǹkan. Ní ìpele kejì ìgbà ìbàlágà, wọ́n á máa fẹ́ láti dán onírúurú nǹkan wò, bó bá sì di ìpele kẹta, wọ́n á máa dá tara wọn ṣe.
Òótọ́ ni pé ọdún olóyinmọmọ làwọn ìgbà téèyàn ò bá tíì pọ́mọ ogún ọdún, àmọ́ ó tún lè jẹ́ àkókò táwọn nǹkan máa ń tojú sú àwọn òbí àtàwọn ọmọ. Dókítà Staggers, tó ti wà lẹ́nu ìtọ́jú àwọn ọ̀dọ́langba fún ohun tó lé lógún ọdún, sọ pé èyí tó pọ̀ jù nínú wọn “nílò alábàárò, ìyẹn ni àgbàlagbà kan tó lè máa bójú tó wọn.” Báwo ni wọ́n ṣe lè rí irú alábàárò bẹ́ẹ̀?
Ẹ máa bá wọn sọ̀rọ̀! Ẹ̀yin òbí, ẹ máa gbọ́ tàwọn ọmọ yín, kẹ́ ẹ sì máa tipa bẹ́ẹ̀ fi dá wọn lójú pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ yín lógún. Kí wọ́n bàa lè rí i pé ọ̀rọ̀ àwọn ká yín lára, ẹ máa bi wọ́n láwọn ìbéèrè táá máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fi oókan kún eéjì bí wọ́n ṣe ń ronú síwá sẹ́yìn, kí wọ́n sì lè mọ ibi tí ìpinnu èyíkéyìí tí wọ́n bá ṣe máa já sí. Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìwúrí fún wọn nípa ibi ti ìpinnu tó tọ́ máa ń já sí. Ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ ìwà tó yẹ kí ọmọlúwàbí máa hù.
Báwọn òbí bá ń ronú bíi tọ̀pọ̀ èèyàn, táwọn náà sì gbà pé àwọn ọmọdé gbọ́dọ̀ mọ ọ̀ràn ara wọn bójú tó, ìyẹn lè mú káwọn ọmọkọ́mọ tí ò níwà rere tètè kó ìkókúkòó ràn wọ́n. (Òwe 13:20) Lọ́nà mìíràn ẹ̀wẹ̀, àwọn òbí tó bá ń fi ìtọ́ni Bíbélì sílò á kọ́wọ́ ti àwọn ọmọ wọn ní gbogbo ọ̀nà kí wọ́n bàa lè kẹ́sẹ járí nígbà ìbàlágà wọn, kí wọ́n sì mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ bí wọ́n bá dàgbà tán. Nítorí náà, ẹ̀yin òbí gbọ́dọ̀ mọ bẹ́ ẹ ó ṣe “tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀.”—Òwe 22:6.
Ẹ lè rí àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò nípa béèyàn ṣe lè máa bá àwọn ọmọ tí ò tíì pé ogun ọdún sọ̀rọ̀ pọ̀ àti béèyàn ṣe lè máa dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. a Ìwé náà tún fún ìyá, bàbá àtàwọn ọmọ ní ìmọ̀ràn tó bá Ìwé Mímọ́ mu.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́.