Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ẹlẹ́rìí Tu Ìdílé Tí Àjálù Bá Nínú

Àwọn Ẹlẹ́rìí Tu Ìdílé Tí Àjálù Bá Nínú

Àwọn Ẹlẹ́rìí Tu Ìdílé Tí Àjálù Bá Nínú

Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Dolores Gómez, tó ń gbé ní ìlú kékeré kan létí ìlú Barcelona lórílẹ̀-èdè Sípéènì. Ẹni ọdún mẹ́rìnlélógójì ni obìnrin yìí nígbà tí dókítà rẹ̀ sọ fún un pé kinní kan ti wú sí i nínú ọpọlọ. Dókítà náà sọ fún un pé oṣù mẹ́jọ péré ló kù tó fi máa kú. Báwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni ṣe gbọ́ báyìí, ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀jò ìfẹ́ lé e lórí. Nígbà tó ku ọjọ́ mélòó kan kó kú, àwọn èèyàn ẹ̀, tí wọn kì í ṣe Ajẹ́rìí wá láti tọ̀tún tòsì orílẹ̀-èdè Sípéènì.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n bá níbẹ̀ tọ́jú wọn gan-an, wọ́n bá wọn ṣètò ilé, oúnjẹ àti ọkọ̀ táá máa gbé wọn, wọ́n sì ṣètò àwọn nǹkan míì láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Ìgbàgbọ́ Arábìnrin Dolores tó dúró sán-ún àti bó ṣe gbayì títí dọjọ́ ikú, tó fi mọ́ báwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ ṣe nífẹ̀ẹ́ àtimáa ṣàlejò, wọ àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́kàn ṣinṣin. Lẹ́tà tí wọ́n fi sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lọ́kàn wọn rèé nísàlẹ̀ yìí.

“Àwùjọ àwọn èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tí wọ́n máa ń wàásù, là ń kọ lẹ́tà yìí sí. Kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn wọ̀nyí nìkan ló ń fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn bíi tiwọn, àmọ́ ìṣe wọn tún ń fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ tó tọkàn wá. A ò sì mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, àfìgbà tí àjálù ńlá bá wa, tí àbúrò wa Loli [Dolores] bẹ̀rẹ̀ àìsàn tó gbẹ̀mí ẹ̀, la tó mọ irú èèyàn tí wọ́n jẹ́.

“Nítorí náà, gbogbo wa (àwa èèyàn Dolores tá a wá láti iyànníyàn orílẹ̀-èdè Sípéènì) tá à ń ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, là ń dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo ẹ̀yin tẹ́ ẹ dúró tì í nígbà ìdùnnú àti ìbànújẹ́ rẹ̀, nígbà ìtura àti ìrora ọkàn rẹ̀, títí tó fi dákẹ́. A ò ní fi irú ẹ̀ gbà á o.

“A tún ń fi àsìkò yìí sọ fún yín pé a ò tíì rí irú ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan tiyín yìí rí. Lóòótọ́, a ti padà délé lọ́dọ̀ àwọn ìdílé wa, tá a sì ti padà sẹ́nu iṣẹ́ wa, ṣùgbọ́n ìfẹ́ tó lágbára tá a rí nínú Loli àbúrò wa àtẹ̀yin alára ti wọ̀ wá lọ́kàn ṣinṣin débi pé ojoojúmọ́ ló ń fún wa lókun láti máa bá ìgbésí ayé wa lọ.

“Tọkàntọkàn la fi kí yín pé ó dìgbà o, ẹ kú àdúrótì wa. Kí Olúwa má kọ àtúnrí o, kí Jèhófà máa fi ire àti ayọ̀ bù kún yín.”

Ìbuwọ́lùwé látọ̀dọ̀ ìdílé àtàwọn ẹ̀gbọ́n Dolores Gómez.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Díẹ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń gbébẹ̀