Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Olówó àti Òtòṣì

Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Olówó àti Òtòṣì

Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Olówó àti Òtòṣì

ORÚKỌ yòówù ká lò láti fìyàtọ̀ sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà, tí wọ́n ní ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ tó pọ̀, tí ètò ìṣúnná owó wọn dáa, ń gbé ní yọ̀tọ̀mì, nígbà tó sì jẹ́ pé ọwọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí kò fi bẹ́ẹ̀ nílé iṣẹ́ ẹ̀rọ kì í tẹ́nu torí pé ètò ìṣúnná owó tiwọn kò dáa tó. Ó wá dà bí ẹni pé inú ayé kan náà kọ́ ni wọ́n jọ ń gbé.

Kódà gan-an, láàárín orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo, èèyàn lè ráwọn tó lówó àtàwọn tó tòṣì. Ìwọ ṣáà ronú nípa àwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù, tá a sọ̀rọ̀ wọn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí. Bí àwọn olówó ṣe wà níbẹ̀ náà làwọn òtòṣì wà níbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, nǹkan bí ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá lára owó tó ń wọlé sí orílẹ̀-èdè náà ló ń kọjá sápò ìdílé kan lára ìdílé mẹ́wàá tó lọ́rọ̀ jù lọ. Àwọn ìdílé tí kò lọ́rọ̀ wá ń kọ́ o? Àfi kí méjì nínú mẹ́wàá irú ìdílé bẹ́ẹ̀ yáa fara mọ́ ìdá márùn-ún péré lára ìdá ọgọ́rùn-ún owó tó ń wọlé sórílẹ̀-èdè náà. Ó lè jẹ́ pé bí nǹkan ṣe rí lórílẹ̀-èdè tíwọ náà ń gbé nìyí, tàbí kó wulẹ̀ fara jọ ọ́, pàápàá bó bá jẹ́ pé àwọn mẹ̀kúnnù ò pọ̀ níbẹ̀. Àmọ́, àwọn ìjọba tó ń ṣàkóso láwọn orílẹ̀-èdè táwọn mẹ̀kúnnù ti ṣe bí ẹní pọ̀ pàápàá ò tíì lè fòpin sí ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn olówó àtàwọn òtòṣì, títí di bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí.

Ọ̀kan Ò Sàn Jùkan Lọ

Kò sí ìkankan nínú àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà àtàwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà tó lè fọwọ́ sọ̀yà pé bó ṣe yẹ kí nǹkan rí ló ṣe rí fáwọn yìí. Ìwọ ronú ná nípa ibi tí bàtà ti ń ta àwọn tó ń gbé lórílẹ̀-èdè tó tòṣì lẹ́sẹ̀. Àwọn aláìsàn kì í fi bẹ́ẹ̀ rí ìtọ́jú. Láwọn orílẹ̀-èdè mẹ́sàn-án tó lọ́rọ̀ jù lọ, tá a mẹ́nu kàn nínú àpótí tó wà lójú ìwé yìí, dókítà kan ló wà ní sẹpẹ́ fáwọn aráàlú tí wọ́n jẹ́ òjìlénígba ó lé méjì [242] sí òjìlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó dín kan [539]. Àmọ́ dókítà ò pọ̀ tóyẹn láwọn orílẹ̀-èdè méjìdínlógún tí wọ́n tòṣì jù lọ, torí pé dókítà kan ṣoṣo ló wà fún aláìsàn tó tó ọ̀gbọ̀kàndínlógún ó dín mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún [3,707] sí ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínláàádọ́ta ó lé méjìdínláàádọ́fà [49,118]. Nítorí náà, èèyàn lè rí ìdí táwọn tó ń gbé lórílẹ̀-èdè tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù fi máa ń pẹ́ tó ọdún mẹ́tàléláàádọ́rin tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ láyé, nígbà tó jẹ́ pé léyìí tó ju ìdajì lọ láwọn orílẹ̀-èdè tó tòṣì jù lọ, àwọn èèyàn kì í sábàá lò tó àádọ́ta ọdún láyé.

Láwọn orílẹ̀-èdè tí kò lọ́rọ̀, àyè ilé ìwé kì í tún fi bẹ́ẹ̀ yọ, èyí sì sábà máa ń mú káwọn ọmọdé di akóbàtà fẹ́gbẹ́. Àìrelé ẹ̀kọ́ yìí sì hàn lára iye àwọn tó mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Nínú méje lára àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́sàn-án tó lọ́rọ̀ jù lọ, gbogbo èèyàn ló mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà (láwọn orílẹ̀-èdè méjì yòókù, àwọn tí kò mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà kò ju mẹ́ta sí mẹ́rin nínú ìdá ọgọ́rùn-ún). Àwọn orílẹ̀-èdè méjìdínlógún tó tòṣì jù lọ wá ń kọ́ o? Iye tó tíì ga jù lọ lára àwọn tó mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà jẹ́ nǹkan bí ìpín mọ́kànlélọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún, iye tó rẹlẹ̀ jù lọ sì jẹ́ ìpín mẹ́rìndínlógún nínú ọgọ́rùn-ún. Àmọ́, àwọn tó mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà nínú mẹ́wàá lára àwọn orílẹ̀-èdè náà kò tó ìdajì.

Àwọn tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ náà ò ṣaláì ní ibi tí bàtà ti ń ta àwọn náà lẹ́sẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ń gbé lórílẹ̀-èdè tó tòṣì lè máà róúnjẹ jẹ tó, ìṣòro àwọn tó ń gbé níbi tí oúnjẹ ti pọ̀ yamùrá ni pé wọ́n máa ń jẹ àjẹyíràá, oúnjẹ ọ̀hún náà ló sì ń fa àwọn ìṣòro tó ń pa wọ́n. Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa oúnjẹ, Food Fight, sọ pé “àjẹjù àti àmujù ti wá gbapò báyìí lọ́wọ́ àìróúnjẹ tó dáa jẹ, bá a bá ń sọ̀rọ̀ ìṣòro oúnjẹ tó ga jù lọ lágbàáyé.” Ìwé ìròyìn The Atlantic Monthly sọ pé: “Ó ti tó nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́sàn-án ará Amẹ́ríkà báyìí tí wọ́n ‘sanra rọ̀pọ̀tọ̀rọpọtọ,’ ìyẹn ni pé kìlógíráàmù márùndínláàádọ́ta, èyí tó wúwo tó àpò símẹ́ǹtì kan, tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n fi tẹ̀wọ̀n ju bó ṣe yẹ lọ. Àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ títẹ̀wọ̀n jù sì ń fa ikú àìtọ́jọ́ fún nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùndínlógún [300,000] èèyàn lọ́dọọdún lórílẹ̀-èdè yìí.” Àpilẹ̀kọ kan náà dọ́gbọ́n sọ pé “ó lè máà pẹ́ tí sísanra jọ̀kọ̀tọ̀ á fi di ìṣòro tó ń yọ aráyé lẹ́nu jù lọ, ìṣòro náà á sì pọ̀ ju àdánù tí ebi àtàwọn àrùn tí ń ranni ń fà.” a

Lóòótọ́ làwọn tó ń gbé lórílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ máa ń gbé ìgbé ayé ìdẹ̀rùn, àmọ́ lọ́wọ́ kan náà, wọ́n tún lè máa wo ohun ìní bí ohun tó ṣe pàtàkì ju àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ìyẹn lè mú kí wọ́n máa wá bí wọ́n á ṣe ní nǹkan dípò kí wọ́n máa wá bí wọ́n á ṣe máa gbé ìgbé ayé rere. Wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí fi iṣẹ́ tẹ́nì kan ń ṣe, owó oṣù rẹ̀, tàbí ohun ìní rẹ̀ díwọ̀n bó ti ṣe pàtàkì tó, dípò kí wọ́n mọrírì ìmọ̀ tó ní, ọgbọ́n rẹ̀, àwọn ohun tó lè ṣe, tàbí àwọn ànímọ́ rere tó ní.

Ìwé ìròyìn orílẹ̀-èdè Jámánì kan tó máa ń jáde lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tí wọ́n ń pè ní Focus, gbé àpilẹ̀kọ kan jáde tó sọ pé béèyàn ò bá walé ayé máyà, á mú kéèyàn láyọ̀, àkọlé àpilẹ̀kọ náà béèrè pé: “Bó Bá Jẹ́ Pé Nǹkan Tó O Ní Ò Tó Báyìí Ńkọ́?” Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọmọ Ilẹ̀ Yúróòpù àti Amẹ́ríkà ń ní búrùjí àti ọrọ̀ ṣáá báyìí, ayọ̀ tí wọ́n ní nísinsìnyí kò ju èyí tí wọ́n ní lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn. . . . Bí ẹnikẹ́ni bá gbẹ́kẹ̀ lé dúkìá, àfàìmọ̀ kó máa jẹ́ pé àìláyọ̀ náà ni gbogbo ẹ̀ máa já sí.”

Ṣé Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Olówó àti Òtòṣì Lè Kúrò?

Ẹ̀rí ti wá fi hàn kedere pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àti olówó àti òtòṣì ló lè róhun mú yangàn, síbẹ̀ àwọn méjèèjì náà ló ní ibi tí wọ́n kù sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ owó àti dúkìá lè máà ká àwọn òtòṣì lára, àwọn ọlọ́rọ̀ lè máa walé ayé máyà. Ì bá má dára o, ká ní àtolówó àti òtòṣì lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lọ́dọ̀ ara wọn! Àmọ́, ṣé a lè gbà lóòótọ́ pé ìyàtọ̀ tó wà láàárín olówó àti òtòṣì lè kúrò?

Bá a bá fojú ẹ̀dá wò ó, ó lè ṣeni bíi pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó dáa ni bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ ó lè jọ ohun tó kọjá agbára ẹ̀dá láti ṣe. Ohun tá a rí nínú ìtàn sì fi hàn pé irú èrò bẹ́ẹ̀ tọ̀nà. Síbẹ̀, ọ̀ràn náà ò kọjá àtúnṣe. Bóyá ńṣe lo gbójú fo ọ̀nà tó mọ́gbọ́n dání jù lọ láti mú ìṣòro náà kúrò. Ọ̀nà wo nìyẹn?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Jí! November 8, 2004, ojú ìwé 3 sí 12.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

“Ó lè máà pẹ́ tí sísanra jọ̀kọ̀tọ̀ á fi di ìṣòro tó ń yọ aráyé lẹ́nu jù lọ, ìṣòro náà á sì pọ̀ ju àdánù tí ebi àtàwọn àrùn tí ń ranni ń fà.”— The Atlantic Monthly

[Graph tó wà ní ojú ìwé 5]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

A to orúkọ orílẹ̀-èdè Báwọn Ọkùnrin Ṣe Ń Àwọn Tó Mọ̀ọ́kọ Mọ̀ọ́kà

lọ́nà a, b, d Pẹ́ Tó Láyé (ọdún) (ìpín nínú ọgọ́rùn-ún)

 

Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà 74.4 95.5

Mẹ́sàn-án Tó Belgium 75.1 100

Lọ́rọ̀ Jù Lọ Denmark 74.9 100

Iceland 78.4 100

Japan 78.4 100

Kánádà 76.4 96.6

Luxembourg 74.9 100

Norway 76.5 100

Switzerland 77.7 100

Orílẹ̀-Èdè Benin 50.4 37.5

Méjìdínlógún Burkina Faso 43 23

Tó Tòṣì Jù Lọ Burundi 42.5 48.1

Etiópíà 47.3 38.7

Guinea-bissau 45.1 36.8

Kóńgò 49 80.7

Madagascar 53.8 80.2

Màláwì 37.6 60.3

Málì 44.7 40.3

Mòsáńbíìkì 38.9 43.8

Nàìjíríà 50.9 64.1

Niger 42.3 15.7

Rwanda 45.3 67

Sierra Leone 40.3 36.3

Ṣáàdì 47 53.6

Tanzania 43.3 75.2

Yemen 59.2 46.4

Zambia 35.3 78

[Credit Line]

Orísun ìsọfúnni: Ìwé 2005 Britannica Book of the Year.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]

© Fọ́tò tí Mark Henley/Panos yà