Ṣé Bíbélì Kọ́ni Pé Àwọn Ọkùnrin Sàn Ju Àwọn Obìnrin lọ?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ṣé Bíbélì Kọ́ni Pé Àwọn Ọkùnrin Sàn Ju Àwọn Obìnrin lọ?
TERTULLIAN, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ní ọ̀rúndún kẹta, ti fìgbà kan rí fi àwọn obìnrin wé “ẹnu bodè ẹ̀mí èṣù.” Àwọn míì ti fi Bíbélì ṣàlàyé pé àwọn obìnrin ò ṣe pàtàkì tó àwọn ọkùnrin. Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi lérò pé Bíbélì kọ́ni pé àwọn ọkùnrin sàn ju àwọn obìnrin lọ.
Elizabeth Cady Stanton, tó jẹ́ ajìjàgbara fún ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, tiẹ̀ sọ èrò tiẹ̀ pé “Bíbélì àti Ṣọ́ọ̀ṣì ni òkúta ìdìgbòlù títóbi jù lọ tí ò jẹ́ káwọn obìnrin lómìnira.” Ó sì tún sọ nígbà kan nípa àwọn ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì pé: “Yàtọ̀ sáwọn ìwé yìí o, mi ò mọ ìwé míì tó kọ́ni pé ká máa tẹ àwọn obìnrin lórí ba ká sì máa tẹ̀ wọ́n mẹ́rẹ̀.”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lónìí, àwọn èèyàn kan lè máa ronú lọ́nà tó ṣàjèjì báyìí, ọ̀pọ̀ ṣì gbàgbọ́ pé àwọn apá ibì kan wà nínú Bíbélì tó sọ pé àwọn ọkùnrin sàn ju àwọn obìnrin lọ. Ṣó tọ́ kéèyàn ronú pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn?
Ohun Tí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù Sọ Nípa Àwọn Obìnrin
“Ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ sì ni ìfàsí-ọkàn rẹ yóò máa wà, òun yóò sì jọba lé ọ lórí.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:16) Àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ ka ọ̀rọ̀ yìí sí ìdájọ́ tí Ọlọ́run mú wá sórí Éfà, wọ́n sì tún kà á sí ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé Ọlọ́run fọwọ́ sí títẹ obìnrin lórí ba. Àmọ́ ṣá o, ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ̀ yìí kì í ṣe ohun tó fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ sí wọn nígbà tó dá wọn, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ àtúbọ̀tán ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá àti kíkọ̀ tí wọ́n kọ̀ láti gba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ. Àìpé ẹ̀dá ló mú káwọn èèyàn máa fìyà jẹ àwọn obìnrin, Ọlọ́run ò fẹ́ bẹ́ẹ̀ rárá. Àṣà ìbílẹ̀ tàwọn kan tiẹ̀ ni pé káwọn ọkọ máa jẹ gaba lé àwọn aya wọn lórí, èyí sì sábà máa ń jẹ́ lọ́nà rírorò. Ṣùgbọ́n bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí ọ̀ràn rí kọ́ nìyẹn.
Ó ṣe tán, àti Ádámù àti Éfà ni Ọlọ́run dá ní àwòrán ara rẹ̀. Bákan náà, àṣẹ kan náà ni Ọlọ́run pa fún àwọn méjèèjì pé kí wọ́n di púpọ̀, kí wọ́n kún ilẹ̀ ayé, kí wọ́n sì ṣèkáwọ́ rẹ̀. Ṣe ni Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n jùmọ̀ máa ṣe àwọn nǹkan. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28) Ó ṣe kedere nígbà yẹn pé kò sẹ́ni tó ń fìwà òǹrorò jẹ gaba lé ara wọn lórí nínú àwọn méjèèjì. Jẹ́nẹ́sísì 1:31 tiẹ̀ sọ pé: “Ọlọ́run rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an ni.”
Láwọn ìgbà míì, àkọsílẹ̀ Bíbélì kì í sọ èrò Ọlọ́run nípa ọ̀ràn kan. Ó wulẹ̀ lè jẹ́ pé ńṣe ni Bíbélì sọ ọ́ gẹ́gẹ́ bí ìtàn. Nígbà tí Bíbélì sọ ìtàn nípa bí Lọ́ọ̀tì ṣe fa àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ lé àwọn ará Sódómù lọ́wọ́, kò ṣàlàyé bóyá òun tó dáa ló ṣe kò sì mẹ́nu kàn án bóyá inú Ọlọ́run dùn sí i pé kó ṣe bẹ́ẹ̀. a—Jẹ́nẹ́sísì 19:6-8.
Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, Ọlọ́run kórìíra gbogbo onírúurú ìyànjẹ àti ìjẹniníyà. (Ẹ́kísódù 22:22; Diutarónómì 27:19; Aísáyà 10:1, 2) Òfin Mósè sọ pé ìfipábánilòpọ̀ àti iṣẹ́ aṣẹ́wó ò dáa. (Léfítíkù 19:29; Diutarónómì 22:23-29) Ó ka panṣágà léèwọ̀, tọkùnrin tobìnrin tó bá sì jọ ṣe é ni ikú tọ́ sí. (Léfítíkù 20:10) Kàkà kí Bíbélì kọ́ni pé àwọn ọkùnrin sàn ju àwọn obìnrin lọ, Òfin gbé wọn ga, ó sì dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ ìkóninífà tó wọ́pọ̀ gan-an láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. Wọ́n máa ń buyì àti ọ̀wọ̀ ńlá fún Júù obìnrin tó bá dáńgájíá bí ìyàwó ilé. (Òwe 31:10, 28-30) Ẹ̀bi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni, pé wọn ò tẹ̀lé òfin Ọlọ́run tó ní kéèyàn máa fọ̀wọ̀ wọ àwọn obìnrin, kì í ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Diutarónómì 32:5) Ní àbárèbábọ̀, Ọlọ́run dá orílẹ̀-èdè náà lẹ́jọ́, ó sì fìyà jẹ wọ́n nítorí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ṣègbọràn sí i.
Ṣé Báwọn Obìnrin Ṣe Ń Tẹrí Ba Fi Hàn Pé Àwọn Ọkùnrin Sàn Jù Wọ́n Lọ?
Kí nǹkan tó lè máa lọ geerege nínú ẹgbẹ́ àwùjọ èyíkéyìí, nǹkan gbọ́dọ̀ wà létòlétò. Èyí béèrè pé kí àṣẹ wà táwọn èèyàn á máa tẹ̀ lé. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbogbo nǹkan á rí rúdurùdu ni. Ó ṣe tán, “Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run rúdurùdu, bí kò ṣe ti àlàáfíà.”—1 Kọ́ríńtì 14:33.
Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń ṣàlàyé ètò ipò orí nínú ìdílé, ó sọ pé: “Orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi; ẹ̀wẹ̀, orí obìnrin ni ọkùnrin; ẹ̀wẹ̀, orí Kristi ni Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 11:3) Bá a bá yọwọ́ Ọlọ́run, kò sí ẹlòmíì tí ò lẹ́ni tó gbọ́dọ̀ máa tẹrí ba fún. Ṣé a wá lè tìtorí pé Jésù ní olórí ká wá sọ pé ńṣe ni Ọlọ́run kò kà á kún? Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Ti pé Ìwé Mímọ́ sọ pé káwọn ọkùnrin máa darí bí nǹkan ṣe ń lọ sí nínú ìjọ àti nínú ìdílé ò wá túmọ̀ sí pé àwọn ọkùnrin sàn ju àwọn obìnrin lọ. Kí nǹkan lè máa lọ geerege nínú ìdílé àti nínú ìjọ, àfi kí olúkúlùkù obìnrin àti ọkùnrin máa fi ìfẹ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ ṣe ipa tiwọn.—Éfésù 5:21-25, 28, 29, 33.
Gbogbo ìgbà ni Jésù máa ń fọ̀wọ̀ wọ obìnrin. Ó kọ̀ láti tẹ̀ lé àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àti ìlànà a-jura-wa-lọ táwọn Farisí fi ń kọ́ni. Ó báwọn Júù tó jẹ́ obìnrin sọ̀rọ̀. (Mátíù 15:22-28; Jòhánù 4:7-9) Ó kọ́ àwọn obìnrin lẹ́kọ̀ọ́. (Lúùkù 10:38-42) Kò jẹ́ káwọn obìnrin dẹni àpatì. (Máàkù 10:11, 12) Ó tiẹ̀ fẹ́ẹ̀ jẹ́ pé pabanbarì ohun tí Jésù ṣe nígbà tó wà láyé ni pé ó yọ̀ọ̀da káwọn obìnrin wà lára àwọn tó yàn ní ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. (Lúùkù 8:1-3) Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó fi gbogbo ànímọ́ Ọlọ́run sílò lọ́nà pípé, Jésù fi hàn pé bákan náà ni tọkùnrin tobìnrin ṣe rí níwájú Ọlọ́run. Kódà, láàárín àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, àti ọkùnrin àti obìnrin ló rí ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́ gbà. (Ìṣe 2:1-4, 17, 18) Ní tàwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n ní ìrètí láti jẹ́ ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Kristi, a ò ní fojú ọkùnrin tàbí obìnrin wo ẹnikẹ́ni nínú wọn mọ́ gbàrà tí wọ́n bá ti jí dìde sókè ọ̀run. (Gálátíà 3:28) Jèhófà, Ẹni tó ni Bíbélì kò sọ pé àwọn ọkùnrin sàn ju àwọn obìnrin lọ.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Jésù ò dà bí ọ̀pọ̀ àwọn tó wà láyé lákòókò rẹ̀, ó fọ̀wọ̀ wọ àwọn obìnrin