A Rí Ọwọ́ Agbára Ọlọ́run Lára Wa
A Rí Ọwọ́ Agbára Ọlọ́run Lára Wa
GẸ́GẸ́ BÍ ESTHER GAITÁN ṢE SỌ Ọ́
“Ọwọ́ wa ti tẹ ìyá yín o. Ẹ má sì ṣòpò lọ pé ọlọ́pàá. Ẹ ṣáà máa retí ìgbà tá a máa fóònù yín ní ìdájí ọlá.”
NÍ ỌJỌ́ Tuesday kan lọ́dún tó kọjá làwọn gbọ́mọgbọ́mọ fóònù àbúrò mi obìnrin, tí wọ́n sì sọ báyìí fún un nípa ìyá wa, Esther. Èmi àtọkọ mi, Alfredo ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a ti lọ ṣèpàdé ni mo gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn. Nígbà tá a fi máa dé ilé àwọn òbí mi ní ìlú Mexico City, àwọn ìbátan wa ti wà níbẹ̀. Ṣe ni àbúrò mi obìnrin àtèyí ọkùnrin ń wa ẹkún mu, orí ẹkún náà sì làwọn tẹ̀gbọ́n tàbúrò ìyá wa lóbìnrin wa.
Bàbá mi àti bùrọ̀dá mi ti ba ti òwò lọ sí ìrìn-àjò. Lẹ́yìn tá a ti bá wọn sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù, gbogbo wa fẹnu kò pé ó máa dáa ká sọ fáwọn ọlọ́pàá. Orí àdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Jèhófà la wà ní gbogbo òru ọjọ́ tó kan gógó yẹn. A mọ̀ ọ́n lára pé Jèhófà ń fún wa ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.”—2 Kọ́ríńtì 4:7.
Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn gbọ́mọgbọ́mọ náà sì pè wá lórí tẹlifóònù láàárọ̀ ọjọ́ kejì, èmi ni mo dá a lóhùn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù ń bà mí gan-an, mo rí i pé ohùn pẹ̀lẹ́ ni mo fi bá a sọ̀rọ̀. Ó lóhun fẹ́ bá bàbá mi sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n mo sọ fún un pé bàbá mi ti lọ sí ìdálẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni yẹn bá sọ fún mi pé àwọn á dúró dìgbà tí bàbá mi bá dé káwọn tó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ nípa ohun táwọn máa gbà káwọn tó fi màmá mi sílẹ̀. Ó kìlọ̀ fún mi pé bá ò bá sanwó gọbọi táwọn bá ní ká san, àwọn á pa màámi.
Lọ́jọ́ kẹta, èmi náà ni mo tún bá gbọ́mọgbọ́mọ náà sọ̀rọ̀ lórí fóònù. Nígbà tó rí i pé ìbẹ̀rù ò sí nínú ohùn tí mo fi ń bá òun sọ̀rọ̀ pẹ̀lú gbogbo
ìhàlẹ̀ rẹ̀, ó sọ pé: “Ṣó o rò pé ọ̀rọ̀ kékeré ló wà ńlẹ̀ yìí ni?”Mo dá a lóhùn pé: “Mo mọ̀ kẹ̀. Ṣe bí màmá mi lẹ gbé. Àmọ́, Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, a sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún pé Ọlọ́run wa yóò ràn wá lọ́wọ́. Bíbélì sì ti jẹ́ ká mọ bí a ó ṣe máa fara da àwọn ìṣòro tó wà ní àkókò líle tá à ń gbé yìí.”
Ó fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Bẹ́ẹ̀ ni. Èmi náà mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ohun tí ìyá yín ń nu ẹnu mọ́ náà nìyẹn. Ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run rẹ̀, ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀ lórí ẹ̀yin aráalé ẹ̀.” Bá a ṣe mọ̀ pé ìgbàgbọ́ màmá wa ṣì dúró ṣinṣin nìyẹn, èyí sì fún wa lókun.
Ohun Tó Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Fara Dà Á
Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni bẹ̀rẹ̀ sí ké sí wa lórí tẹlifóònù, àwọn míì nínú wọn ń fi káàdì ránṣẹ́ nígbà táwọn míì ń tẹ lẹ́tà ìkíní ránṣẹ́ látorí fóònù alágbèéká tàbí látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì. A ò tìtorí èyí pa ìpàdé jẹ a sì ń bá ìjọ lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Kíka Bíbélì àtàwọn ìwé tó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lójoojúmọ́ tún ń tù wá nínú. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, àdúrà gbígbà jẹ́ ká rí “àlàáfíà Ọlọ́run” gbà.—Fílípì 4:6, 7.
Ọ̀kan lára àwọn ọlọ́pàá tá a lọ pè wá sọ pé: “Ọdún kẹsàn-án mi rèé lẹ́nu iṣẹ́ yìí, mo ti máa ń rí àwọn ìdílé tí wàhálà bá, àmọ́ tiyín yàtọ̀. Pẹ̀sẹ̀ lọkàn yín balẹ̀. Ó dá mi lójú pé Ọlọ́run tẹ́ ẹ̀ ń sìn ló fi yín lọ́kàn balẹ̀.”
La bá fi Jí! ti January 8, 2000 tó sọ nípa ìdí tá a fi lè pe ọ̀ràn jíjí èèyàn gbé ní ìṣòro kárí ayé hàn án, lẹ́yìn táwa náà ti tún un kà. Ó kà á ó sì lóhun fẹ́ sí i, ó fi kún un pé òun fẹ́ mọ̀ sí i nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tá a ti ń sọ ọ̀rọ̀ náà lọ sọ ọ́ bọ̀, àwọn gbọ́mọgbọ́mọ náà fi màmá mi sílẹ̀. Nǹkan kan ò ṣe é, àfi ti pé inú yàrá kékeré kan ni wọ́n fi òun nìkan sí, tí wọ́n kó ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí i lẹ́sẹ̀. Síbẹ̀, wọ́n fi ọ̀wọ̀ rẹ̀ wọ̀ ọ́, wọ́n sì ń fún un lóògùn tó máa ń lò sí àìsàn ìtọ̀ ṣúgà rẹ̀ àti ìfúnpá rẹ̀ tó máa ń ga.
Màámi sọ bó ṣe ń ṣe é lọ́hùn-ún tí kò fi bara jẹ́. Ó ní: “Nígbà tí gbogbo ẹ̀ kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, ẹ̀rù bà mí gan-an; àmọ́ mo bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí Jèhófà, kò sì jẹ́ kí n sọ̀rètí nù. Kò ṣe mí bíi pé èmi nìkan ló wà nínú yàrá tí wọ́n fi mí sí. Mo wá rí i bí Jèhófà ṣe jẹ́ Ọlọ́run tó wà fún mi lọ́jọ́kọ́jọ́ tó; kò pa mí tì rárá. Mo gbàdúrà pé kó ràn mí lọ́wọ́ láti lo èso tẹ̀mí rẹ̀, kó sì jẹ́ kí n ní àníkún sùúrù.
“Ọpẹ́lọpẹ́ pé Ọlọ́run ràn mí lọ́wọ́, mi ò ké, ojora ò sì mú mi. Ní gbogbo ọjọ́ tí mo lò lọ́dọ̀ wọn, ṣe ni mò ń rántí ẹsẹ Bíbélì tí mo mọ̀ lórí, mo sì ń kọ àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run sókè ketekete. Nígbà míì màá máa ronú bíi pé mo wà nípàdé, á sì dà bíi pé a jọ ń ṣe é ni. Nínú ọkàn mi, màá máa ṣe bí ẹni pé mò ń wàásù fáwọn èèyàn tí mo sì ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Gbogbo ohun tí mo ń fọkàn rò rèé tí gbogbo ọjọ́ tí mo lò níbẹ̀ ò fi pẹ́ lójú mi.
“Kódà mo ráàyè wàásù nípa ohun tí mo gbà gbọ́ fáwọn tó jí mi gbé. Ní gbogbo ìgbà tí ọ̀kan nínú wọn bá gbé oúnjẹ wá fún mi, mo máa ń wàásù fún un bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fi aṣọ dì mí lójú. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí mo sọ fún gbọ́mọgbọ́mọ náà pé Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àkókò tá à ń gbé yìí á le koko, mo sì mọ̀ pé wọ́n á nílò owó gan-an ni. Mo sọ pé Jèhófà Ọlọ́run ní agbára tó ju gbogbo agbára lọ ṣùgbọ́n kì í ṣì í lò. Mo wá bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n má ṣi agbára wọn lò lórí mi, kàkà bẹ́ẹ̀, kí wọ́n ṣe mí jẹ́jẹ́.
“Gbọ́mọgbọ́mọ yẹn gbọ́ ọ̀rọ̀ mi ó sì sọ pé kí n má bẹ̀rù, ó láwọn ò ní ṣe mí léṣe. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó dúró tì mí lákòókò tó le koko yẹn, mo sì ti pinnu pé mi ò ní fi iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà [iṣẹ́ alákòókò-kíkún] tí mò ń ṣe yìí sílẹ̀ láé.”
Kò sí àníàní pé àdánwò yìí ti mú kí màámi, àti gbogbo wa náà túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Inú wa dún kọjá sísọ pé màmá wa tún padà wálé láyọ̀. Ìtùnú ló jẹ́ fún wa pé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run irú ìwà pálapàla báwọ̀nyí ò ní sí mọ́. Ní báyìí ná nínú ìdílé wa, a lè jẹ́rìí sí òótọ́ tó wà nínú ọ̀rọ̀ ìwé Sáàmù nínú Bíbélì pé: “Ọ̀pọ̀ ni ìyọnu àjálù olódodo, ṣùgbọ́n Jèhófà ń dá a nídè nínú gbogbo wọn.”—Sáàmù 34:19.