Ayé Tí Ọrọ̀ Pín Níyà La Wà Yìí
Ayé Tí Ọrọ̀ Pín Níyà La Wà Yìí
LÁÀÁRÍN nǹkan bí ọdún 1945 sí ọdún 1989, Ogun Abẹ́lẹ̀ ṣì ń jà ràn-ìn yíká ayé, ètò ìṣèlú sì ti pín ayé sọ́nà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Orílẹ̀-èdè Olómìnira Àjùmọ̀ni Soviet, ìyẹn USSR, àtàwọn tó kó sòdí nínú ìjọba Àjùmọ̀ni ló wà nípò kìíní. Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àtàwọn orílẹ̀-èdè míì tó kó sòdí àmọ́ tí wọn kì í ṣe oníjọba Àjùmọ̀ni, gba ipò kejì. Àwọn méjèèjì yìí kì í bá ara wọn lájọṣe. Àwọn orílẹ̀-èdè tí ò sí lágbo àwọn méjèèjì, yìí ló para pọ̀ di Àwọn Orílẹ̀-Èdè Onípò Kẹta.
Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wo èdè náà, “Àwọn Orílẹ̀-Èdè Onípò Kẹta” bí èdè àbùkù, wọ́n sì fi èdè míì, ìyẹn “àwọn orílẹ̀-èdè tí ò tíì gòkè àgbà” rọ́pò rẹ̀. Kò pẹ́ tíyẹn náà fi bẹ̀rẹ̀ sí dún ìdún àbùkù létí àwọn èèyàn, ìyẹn láwọn onímọ̀ nípa ètò ìṣúnná owó fi bẹ̀rẹ̀ sí lo èdè míì, ìyẹn “àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà.” Bó ṣe di pé èdè náà ò sọ nípa ètò ìṣèlú tó yapa síra mọ́ nìyẹn o, ètò ìṣúnná owó tí kò bára dọ́gba ló kù tó ń tẹnu mọ́.
Wàyí o, nígbà tá a ti wọ ọ̀rúndún kọkànlélógún, kò tún sẹ́ni tó ń sọ̀rọ̀ nípa pé ìṣèlú ti pín ayé sọ́nà mẹ́tà mọ́. Àmọ́, ìyàtọ̀ ṣì wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà àtàwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà nítorí pé ètò ìṣúnná owó wọn dáa jura lọ, àti pé wọ́n ní ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ jura lọ. Àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ láti àwọn ilẹ̀ tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù ń ṣalábàápàdé àwọn èèyàn tí nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ ṣẹnuure fún tó sì jẹ́ pé agbára káká ni wọ́n fi ń róúnjẹ jẹ.
Nítorí náà, ìbéèrè tó yẹ ká máa béèrè ni pé: Ṣé dandan gbọ̀n ni pé kọ́wọ́ àwọn kan tẹ́nu káwọn kan sì máa ráágó, àbí ó ṣeé ṣe káwọn tó ní, ìyẹn àwọn ọlọ́rọ̀, àtàwọn tí kò ní, ìyẹn àwọn òtòṣì, lè máa jàǹfààní kan náà láwùjọ kí wọ́n sì jọ máa gbé ìgbé ayé yọ̀tọ̀mì?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
© Fọ́tò tí Qilai Shen/Panos yà