Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Kó Sínú Ewu Níbi Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì?

Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Kó Sínú Ewu Níbi Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Kó Sínú Ewu Níbi Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì?

“Mo sábà máa ń lò tó wákàtí mẹ́ta sí mẹ́rin lójúmọ́ níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Mo tiẹ̀ máa ń lò tó wákàtí mẹ́fà tàbí méje nídìí ẹ̀ nígbà míì.”—José. a

ÀWỌN ewu kan wà níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó yẹ kó o mọ̀. Ṣe ló dà bí ibikíbi táwọn tí wọn ò mọ ara wọn rí ti máa ń pàdé. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá lọ sí ìlú ńlá kan, ó bọ́gbọ́n mu kó o gbìyànjú láti dín ewú tó lè wu ẹ́ kù nípa mímọ àwọn ibi tó léwu kó o má sì ṣe débẹ̀.

Ohun tó bọ́gbọ́n mu kó o ṣe gan-an nìyẹn tó bá pọn dandan pé kó o lọ síbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Nínú ìwé ìròyìn Jí! October 8, 2005, a jíròrò ewu méjì tó wà ní ọ̀pọ̀ ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Àwọn ewu náà ni pé, o lè tibẹ̀ kó sọ́wọ́ àwọn oníṣekúṣe tó máa ń dọdẹ àwọn ọmọdé, o sì lè gbabẹ̀ di ẹlẹ̀tàn. Àwọn ewu míì wà tó tún yẹ ká gbé yẹ̀ wò.

Àmọ́ ká tó ṣèyẹn, báwo tiẹ̀ ni wọ́n ṣe ṣètò àwọn ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì?

Ó Lóhun Tí Ọ̀kọ̀ọ̀kan Wọn Wà Fún

Lábala lábala ni wọ́n ṣètò ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì kọ̀ọ̀kan, ó lóhun tí abala kọ̀ọ̀kan wọn wà fún, ó sì nírú àwọn tó máa ń fẹ́ lọ síbẹ̀. Wọ́n lè dá àwọn kan sílẹ̀ fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí irú eré ìdárayá kan tàbí eré ìgbà-ọwọ́-dilẹ̀ kan. Nítorí tàwọn tó fẹ́ máa sọ̀rọ̀ nípa ètò orí tẹlifíṣọ̀n kan ni wọ́n ṣe ṣètò àwọn míì. Àwọn abala míì sì tún wà fáwọn tí wọ́n láwọn jọ ń ṣe ẹ̀sìn.

Tó bá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́, ojúmìító lè sún ẹ dédìí àtilọ síbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì kan tí wọ́n sọ pé torí káwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí káàkiri ayé lè yan ọ̀rẹ́ tuntun ni wọ́n ṣe dá a sílẹ̀. Kò sóhun tó burú nínú kó o fẹ́ lọ́rẹ̀ẹ́ láàárín àwọn ọ̀dọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí. Àmọ́, àwọn ewu kan lúgọ de àwọn Kristẹni láwọn ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì yìí. Irú àwọn ewu wo nìyẹn ná?

O Lè Tibẹ̀ Kọ́ Ìwàkiwà

Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Tyler sọ pé: “Mo wà níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan náà pẹ̀lú àwọn kan tí mo rò pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni gbogbo wọn. Nígbà tó ṣe, àwọn kan nínú wọn bẹ̀rẹ̀ sí bẹnu àtẹ́ lu àwọn ohun tá a gbà gbọ́. Kò pẹ́ tí mo fi rí i kedere pé apẹ̀yìndà hánrán-ún ni wọ́n.” Àwọn wọ̀nyí mọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ máa kọ́ àwọn tí wọ́n pè ní onígbàgbọ́ bíi tiwọn ní ìkọ́kúkọ̀ọ́ ni.

Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, kìlọ̀ fún wa pé àwọn kan lára àwọn tó ń tẹ̀ lé òun máa yí padà wọ́n á sì dojú ìjà kọ àwọn akẹgbẹ́ wọn. (Mátíù 24:48-51; Ìṣe 20:29, 30) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lákòókò tiẹ̀ ní èké arákùnrin ó sì sọ pé wọ́n “pá kọ́lọ́ wọlé” láti ta jàǹbá fáwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni. (Gálátíà 2:4) Júúdà tó jẹ́ òǹkọ̀wé Bíbélì sọ pé wọ́n “yọ́ wọlé” láti lè “sọ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run wa di àwáwí fún ìwà àìníjàánu.” (Júúdà 4) Ó tún sọ pé wọ́n dà bí “àpáta tí ó fara sin lábẹ́ omi.”—Júúdà 12.

Ṣó o rí i pé àti Pọ́ọ̀lù àti Júúdà ló sọ báwọn apẹ̀yìndà ṣe sábà máa ń yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ṣiṣẹ́ ibi wọn. Àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì yìí sọ pé ṣe làwọn apẹ̀yìndà náà “pá kọ́lọ́ wọlé,” tàbí pé wọ́n “yọ́ wọlé” kí wọ́n bàa lè kọ́ àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni ní ìwàkiwà. Lónìí, ibì kan tírú àwọn oníbàjẹ́ bẹ́ẹ̀ lè fara pamọ́ sí láti ṣiṣẹ́ ibi wọn ni ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Àfi bí àwọn àpáta tó fara sin lábẹ́ omi, àwọn èké Kristẹni yìí á fi ohun tó wà nínú wọn pa mọ́, wọ́n á wá máa ṣojú ayé bíi pé ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí ló jẹ àwọn lógún. Ṣùgbọ́n ọgbọ́n tí wọ́n fẹ́ fi mú kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ àwọn tí kò bá fura rì ni wọ́n ń ta.—1 Tímótì 1:19, 20.

Ìwé ìròyìn yìí àtàwọn ìwé mìí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tẹ̀ máa ń kìlọ̀ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ nípa ewu yìí. b Nítorí náà, tó o bá pàdé ẹnì kan níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tí wọ́n sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n ṣe é fún; tírú ẹni bẹ́ẹ̀ kì í bá ṣe apẹ̀yìndà, á jẹ́ ẹni tí kò tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì tó ti wà lórí ọ̀ràn yìí. Ká sòótọ́ ṣé wàá fẹ́ mú àwọn tó mọ̀ọ́mọ̀ kọ etí ikún sí ìmọ̀ràn Bíbélì lọ́rẹ̀ẹ́?—Òwe 3:5, 6; 15:5.

Ó Lè Sọ Ẹ́ Di Anìkànjẹ̀

Apá ibòmíì tó tún yẹ kó o wò lórí ọ̀ràn ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni ti iye àkókò tó máa ń gbà. José, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, sọ pé: “Nígbà míì, ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì máa ń gbà mí lọ́kàn débi tí màá fi gbàgbé láti jẹun.”

Ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì lè má máa gbà ẹ́ lọ́kàn tó ti José o. Síbẹ̀, kó o tó lè ráàyè tí wàá máa lò níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, o ní láti ra àkókò látinú àkókò tó yẹ kó o lò fáwọn nǹkan míì. Ohun tó sì ṣeé ṣe kí ìyẹn kọ́kọ́ pa lára lè máà jẹ́ iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ tàbí iṣẹ́ ilé rẹ. Ohun tó ṣeé ṣe kó kọ́kọ́ pa lára ni ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn aráalé rẹ. Adrian tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Sípéènì sọ pé: “Bá a bá ṣe ń jẹun tán báyìí mo ti gba ìdí Íńtánẹ́ẹ̀tì lọ, ó di pé kí n lọ pàdé àwọn kan níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ti kó sí mi lórí débi pé mo fẹ́rẹ̀ẹ́ lè má máa bá àwọn aráalé sọ̀rọ̀ mọ́.”

Tó o bá ń lo àkókò púpọ̀ níbi tó o ti ń fọ̀rọ̀ wérọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìwọ náà lè bẹ̀rẹ̀ sí ya ara rẹ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn tó ṣe pàtàkì sí ẹ jù lọ. Ìkìlọ̀ Bíbélì tó bá ọ̀rọ̀ yẹn mu rèé: “Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa wá ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan; gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ ni yóò ta kété sí.” (Òwe 18:1) Bóyá làwọn àjèjì tó ò ń bá pàdé níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì lè rọ̀ ẹ́ láti máa tẹ̀ lé ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ tó wà nínú Bíbélì. Ohun tó ṣeé ṣe kí wọ́n máa gbà ẹ́ níyànjú ẹ̀ ni pé kó o máa wá tara ẹ nìkan kó o sì pa ìlànà ìwà Kristẹni tì.

Lóòótọ́, ará nǹkan tó lè mú kó máa wù ẹ́ láti máa fọ̀rọ̀ wérọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni pé ó lè rọrùn fún ẹ láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ju bó ṣe rọrùn láti bá àwọn ará ilé ẹ sọ̀rọ̀ lọ. Ó lè dà bíi pé àwọn tó o bá pàdé níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì fẹ́ gbọ́ èrò rẹ lórí àwọn ọ̀ràn kan tí wọ́n sì lè sọ èrò tiwọn náà láìfi nǹkan kan bò. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ó lè dà bíi pé ọwọ́ àwọn aráalé ẹ dí kọjá kí wọ́n máa ráàyè gbọ́ ohun tó wà lọ́kàn ẹ, tí wọn kì í sì í fẹ́ fi gbogbo ẹnu sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn.

Àmọ́, bi ara rẹ pé: ‘Ṣé àwọn tí mò ń bá sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì mọ irú ẹni tí mo jẹ́? Ṣé ọ̀rọ̀ ìgbésí ayé mi jẹ wọ́n lógún lóòótọ́?’ Kò sí bí ohun tó ń jẹ ọ́ lọ́kàn àti okun tẹ̀mí ẹ ṣe lè ká wọn lára tó tàwọn aráalé ẹ. Táwọn òbí ẹ bá ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, wọ́n á máa wá bí wọ́n ṣe lè máa bá ẹ fọ̀rọ̀ wérọ̀. (Éfésù 6:4) Tó o bá ń fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ àti ohun tó ń ṣe ẹ́ fún wọn, bí wọ́n ṣe máa ṣe á yà ẹ́ lẹ́nu, torí wàá rí i pé wọ́n fẹ́ ọ fẹ́re kọjá bó o ṣe rò.—Lúùkù 11:11-13.

Bó Ò Ṣe Ní Kó Séwu Níbẹ̀

Àwọn nǹkan tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ lè gbé ẹ lọ síbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ ara iṣẹ́ ilé ìwé. c Tó bá rí bẹ́ẹ̀, láti má ṣe jẹ́ kí ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì dẹkùn mú ẹ, àwọn nǹkan tó o lè ṣe nìwọ̀nyí.

Àkọ́kọ́, má ṣe lo kọ̀ǹpútà tó o lè gbabẹ̀ dórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ní kọ̀rọ̀ yàrá ẹ. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣe lo máa dà bí ẹni tó ń rìn gbéregbère ní òpópónà tó ṣókùnkùn ní ìlú kan tí o kò dé rí, wàá rí i pé wàhálà lò ń kọ̀wé sí yẹn. Dípò ìyẹn, gbé kọ̀ǹpútà náà sí ojútáyé níbi táwọn míì ti lè máa rẹ́ni tó bá ń lò ó.

Ìkejì, jẹ́ kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ máa wáyé dáadáa láàárín ìwọ àtàwọn òbí ẹ nípa sísọ àwọn ìkànnì tó o lọ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì kó o sì ṣàlàyé ohun tó gbé ẹ débi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì kan. Bákan náà, dá gbèdéke lé àkókò tó o fẹ́ lò nídìí kọ̀ǹpútà kó o sì dúró ti ìpinnu rẹ.

Ìkẹta, jẹ́ kí kọ̀ǹpútà rẹ ní ohun táá máa dènà ohun táwọn tó lè fẹ́ fi ìbálòpọ̀ dà ẹ́ láàmú bá fi ránṣẹ́, bí irú èyí táá máa dá ohun tí kò yẹ kó wọ orí kọ̀ǹpútà rẹ látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì dúró. Tẹ́nì kan bá fi ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ lọ̀ ẹ́ látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì, sọ fáwọn òbí ẹ tàbí tíṣà ẹ lójú ẹsẹ̀. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, bí àgbàlagbà kan tó mọ̀ ẹ́ lọ́mọdé bá ń fi ohun tó ń mú èrò ìbálòpọ̀ wá lọ̀ ẹ́ tàbí tó ń fi àwọn àwòrán tàbí ọ̀rọ̀ míì tó jẹ́ ti oníṣekúṣe ránṣẹ́ sí ẹ, ọ̀ràn ló dá. Wọ́n máa ń fẹjọ́ irú wọn sun àwọn ọlọ́pàá ni.

Yàtọ̀ síyẹn, láé, o ò gbọ́dọ̀ fún ẹni tó o pàdé níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ní orúkọ ẹ, àdírẹ́sì ẹ, orúkọ ilé ìwé tó ò ń lọ, tàbí nọ́ńbà tẹlifóònù ẹ. O ò sì gbọ́dọ̀ gbà rárá pé kí ìwọ àtẹni tó o bá mọ̀ níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì pàdé lójúkojú!

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ti kọjá báyìí tí Sólómọ́nì Ọba ti kọ ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n yìí sílẹ̀, síbẹ̀, ọ̀rọ̀ náà ṣì bá ọ̀ràn ewu tó wà níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì mu. Òun ni pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.”—Òwe 22:3.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

b Wo Jí! December 8, 2004, ojú ìwé 16 sí 19.

c Wo Jí! April 8, 2000, ojú ìwé 24.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ó bọ́gbọ́n mu pé kó o sọ ibi tó o fẹ́ lọ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì fáwọn òbí ẹ