Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Ìròyìn Ṣe Ń Dé Etígbọ̀ọ́ Aráyé

Bí Ìròyìn Ṣe Ń Dé Etígbọ̀ọ́ Aráyé

Bí Ìròyìn Ṣe Ń Dé Etígbọ̀ọ́ Aráyé

NÍ NǸKAN bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn, Lúùkù tó máa ń ròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ sọ pé: “Gbogbo ará Áténì àtàwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí ń ṣàtìpó níbẹ̀ kì í lo àkókò tí ọwọ́ wọ́n dilẹ̀ fún nǹkan mìíràn bí kò ṣe fún sísọ ohun kan tàbí fífetísí ohun tí ó jẹ́ tuntun.” (Ìṣe 17:21) Ní ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn, nígbà tí ìjọba orílẹ̀-èdè Róòmù rí i pé àwọn èèyàn máa ń fẹ́ gbọ́ ìròyìn nípa ọ̀rọ̀ tó ń lọ, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí pàtẹ ìwé ìròyìn ojoojúmọ́, tí wọ́n pè ní Acta Diurna, sáwọn ibi táwọn èèyàn máa ń pé jọ sí.

Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún keje, àwọn ará Ṣáínà ti bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìwé ìròyìn àkọ́kọ́, èyí tí wọ́n pè ní Dibao (Pao) jáde. Nílẹ̀ Yúróòpù, níbi tọ́pọ̀ èèyàn ò ti mọ̀wé kà nígbà yẹn, àwọn òpìtàn tó ń rìnrìn-àjò máa ń gbé ìròyìn ogun, àjálù, ìwà ọ̀daràn àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ míì káàkiri. Nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fọwọ́ kọ̀wé ìròyìn, wọ́n tún ń fi igi gbígbẹ́ yàwòrán àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sínú bébà tí wọ́n tẹ ìròyìn sí, wọ́n á sì wá máa tà wọ́n láàárín ọjà àti láwọn ibi ìpàtẹ ọjà.

Nígbà tó yá, àwọn onílé ìtajà bẹ̀rẹ̀ sí fi ìròyìn nípa àwọn nǹkan pàtàkì pàtàkì tó ń ṣẹlẹ̀ kún lẹ́tà tí wọ́n ń kọ sáwọn oníṣòwò. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ àwọn ìròyìn yìí sínú bébà tó ṣeé pín kiri.

Bí Wọ́n Ṣe Bẹ̀rẹ̀ sí Tẹ̀wé Ìròyìn

Níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1600 sí 1699, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tẹ ìwé ìròyìn méjì jáde déédéé nílẹ̀ Jámánì. Ọdún 1605 ni wọ́n kọ́kọ́ tẹ èyí tí wọ́n pè ní Relation (tó máa ń sọ ìròyìn); wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ èyí tí wọ́n pè ní Avisa Relation oder Zeitung (tó ń fi ìròyìn ṣíni létí) ní ìlú Wolfenbüttel, lọ́dún 1609. Ìwé ìròyìn ojoojúmọ́ tó kọ́kọ́ jáde nílẹ̀ Yúróòpù ni Einkommende Zeitungen (Àjáàbalẹ̀ Ìròyìn), èyí tó jáde nílùú Leipzig, lórílẹ̀-èdè Jámánì lọ́dún 1650.

Olójú ewé mẹ́rin ni ìwé ìròyìn ojoojúmọ́ tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ ní ìlú Leipzig, kò sì ju ohun téèyàn lè kì bàpò lọ. Irú wá ògìrì wá ìròyìn ni wọ́n kó jọ sínú ẹ̀. Kò wọ́n púpọ̀ láti ra ẹ̀dà kan ìwé ìròyìn yìí, ṣùgbọ́n owó téèyàn á fi san àsansílẹ̀ ọdún kan á tó owó oṣù òṣìṣẹ́ tó ń gbowó tó tówó lóṣù kan gbáko. Síbẹ̀, ṣe làwọn èèyàn ń fẹ́ ìwé ìròyìn ṣáá. Nílẹ̀ Jámánì nìkan, nígbà tó fi máa di ọdún 1700, ó ti di ìwé ìròyìn àádọ́ta sí ọgọ́ta tó ń jáde látìgbàdégbà, ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún èèyàn ló sì ń kà wọ́n.

Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, wọ́n máa ń rí ìròyìn gbọ́ látinú àwọn lẹ́tà tó ń gbé ìròyìn ní ṣókí, látinú àwọn ìwé ìròyìn míì, látọ̀dọ̀ àwọn apínlẹ́tà tí wọ́n máa ń fi ìròyìn ránṣẹ́ sí, táwọn yẹn á sì ṣe àdàkọ rẹ̀ tàbí látinú ìròyìn àtẹnudẹ́nu táwọn oníròyìn bá hú gbọ́ láàárín ìgboro. Àmọ́ nígbà tó di pé àwọn tó ń tẹ ìwé ìròyìn ti pọ̀ lóríṣiríṣi, àwọn olóòtú ìwé ìròyìn bẹ̀rẹ̀ sí ta ọgbọ́n tí wọ́n á fi mú kí ìròyìn wọn pọ̀ sí i, àti ọ̀nà táá fi túbọ̀ sunwọ̀n sí i. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gba àwọn olóòtú ìròyìn tó mọṣẹ́ dunjú. Nígbà tó sì ti di pé ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ tó ń tẹ ìwé ìròyìn jáde kò lè máa ráwọn ìròyìn tó ń lọ lókèèrè gbé jáde, tí wọ́n ò sí láwọn oníròyìn tó pọ̀ tó, tàwọn èèyàn sì ń fẹ́ máa gbọ́ ohun tó ń lọ, wọ́n bá kúkú dá àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde sílẹ̀ táwọn iléeṣẹ́ ìròyìn á lè máa sanwó fún kí wọ́n fi lè máa rí ìròyìn gbà.

Àwọn Irin Iṣẹ́ Pàtàkì Tó Mú Kí Ìtẹ̀síwájú Dé Bá Títẹ Ìwé Ìròyìn

Ì bá tí ṣeé ṣe fẹ́nikẹ́ni láti máa ṣiṣẹ́ ní iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn tí kì í bá ṣe tàwọn irin iṣẹ́ pàtàkì tí wọ́n ṣe, pàápàá ọgbọ́n tí Johannes Gutenberg dá láti máa fi ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tí àwọn lẹ́tà rẹ̀ ṣeé tún tò tẹ̀wé. Wọ́n tún ṣàwọn nǹkan míì tó mú kí títẹ ìwé ìròyìn rọrùn kó sì dínwó. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1860, ẹ̀rọ ìtẹ̀wé alátẹ̀yípo mú kó ṣeé ṣe láti máa tẹ̀wé sórí bébà tí wọ́n ká ságbàá dípò ègé bébà. Kò pẹ́ sígbà náà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lo ẹ̀rọ ìtẹ̀wé Linotype láti fi to ọ̀rọ̀ tí wọ́n fẹ́ tẹ̀ sórí ìwé. Nígbà tó sì di ẹ̀yìn ọdún 1950, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi kọ̀ǹpútà to ọ̀rọ̀ bí wọ́n á ṣe fẹ́ kó rí nígbà tí wọ́n bá tẹ̀ ẹ́, èyí sì dín ìnáwó àti iṣẹ́ tí wọ́n ń fọwọ́ ṣe kù.

Kó tó dìgbà yẹn, ìròyìn ti bẹ̀rẹ̀ sí tàn kálẹ̀ kíákíá ju ti tẹ́lẹ̀ lọ nítorí pé àwọn èèyàn nílé lóko ti bẹ̀rẹ̀ sí tẹ wáyà láàárín ọdún 1840 sí ọdún 1849, ẹ̀rọ ìtẹ̀wé táwọn akọ̀wé ń lò ti dọ́wọ́ àwọn èèyàn láàárín ọdún 1870 sí ọdún1879, tẹlifóònù sì ti dé sọ́wọ́ ìgbà kan náà. Àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà tẹ̀wé ìròyìn, wọ́n ń fi ìsọfúnni ránṣẹ́ látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì, wọ́n ń lo ẹ̀rọ tó ń ṣàdàkọ ìwé, kódà àwọn tọ́rọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ lójú wọn ṣì tó àràádọ́ta ọ̀kẹ́ láyé. Kì í pẹ́ mọ́ báyìí táwọn oníròyìn fi ń débi tí ìṣẹ̀lẹ̀ kan bá ti ṣẹlẹ̀, torí pé wọ́n lè wọ ọkọ̀ ojú irin, torí ilẹ̀ tàbí tojú òfuurufú. Nítorí pé ọkọ̀ tó yára sì ti wà báyìí, ṣe ló túbọ̀ ń rọrùn láti máa pín ìwé ìròyìn káàkiri.

Kí Làwọn Nǹkan Tí Wọ́n Máa Ń Gbé Jáde Nínú Ìwé Ìròyìn?

Ní ọ̀pọ̀ ibi, láyé tó ti lu jára yìí, àtirí ìròyìn tó máa kún inú ìwé ìròyìn kì í ṣe ìṣòro. Àwọn olóòtú ìwé ìròyìn, Frankfurter Allgemeine Zeitung sọ pé: “Ìṣòro tó wà níbẹ̀ ni bí wọ́n ṣe máa yan èyí tí wọ́n máa gbé jáde nínú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìròyìn tó ń rọ́ wọlé.” Àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde lórílẹ̀-èdè Jámánì máa ń gbé tó ẹgbàá ìròyìn jáde lójúmọ́. Àwọn oníròyìn, aṣojú iléeṣẹ́ ìròyìn, akàròyìn, àtàwọn míì náa máa ń da ìròyìn púpọ̀ sí i bo àwọn olóòtú ìwé ìròyìn.

Ìdá méjì nínú mẹ́ta ìròyìn ọ̀hún ló jẹ́ ìkéde, ìyẹn àwọn bí àtẹ̀jáde tí wọ́n fi sọwọ́ sáwọn oníròyìn, ìròyìn nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí wọ́n ti ń retí bí àríyá, eré ìdárayá àtàwọn àpéjọ. Àwọn olóòtú ìròyìn gbọ́dọ̀ mọ ohun táwọn tó ń ra ìwé ìròyìn wọn fẹ́ kí wọ́n bàa lè mọ àwọn ohun tí wọ́n á fẹ́ gbọ́ nípa ẹ̀, léyìí tó lè jẹ́ ìròyìn nípa ìkórè, àjọ̀dún, àtàwọn ayẹyẹ.

Ara nǹkan tó sábà máa ń wà nínú ìwé ìròyìn ni abala eré ìdárayá, àkàrẹ́rìn-ín, abala ibi tí wọ́n ti ń fọ̀rọ̀ òṣèlú ṣẹ̀fẹ̀ àti èrò olóòtú. Àwọn abala tó tún lè mú káwọn èèyàn ronú táá sì dùn mọ́ wọn ni kókó inú ìwé ìròyìn, àwọn ìròyìn láti ilẹ̀ òkèèrè àti fífi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn èèyàn jàǹkàn jàǹkàn àtàwọn ògbógi lórí àwọn ọ̀ràn táwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí.

Wàhálà Tó Dé Bá Ìwé Ìròyìn

Lọ́dún 2002, ìwé ìròyìn Die Zeit ròyìn pé: “Àwọn ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn tó wà lórílẹ̀-èdè Jámánì ń dojú kọ ìṣòro ìṣúnná owó tí wọn ò tíì rírú ẹ̀ rí látọjọ́ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀.” Ilé iṣẹ́ àwọn oníròyìn lórílẹ̀-èdè Switzerland, ìyẹn Swiss Press Association náà sì ròyìn pé ọdún 2004 ni iye ìwé ìròyìn tí wọ́n tẹ̀ jákèjádò orílẹ̀-èdè náà tíì dín kù jù lọ látọdún mẹ́wàá sẹ́yìn. Ṣé àwọn èèyàn ò ra ìwé ìròyìn mọ́ ni?

Ìdí kan tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé ètò ọrọ̀ ajé dorí kodò lágbàáyé, èyí sì mú kí iye ìpolowó ọjà dín kù, ibi ìpolowó ọjà sì lọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn ti máa ń rí ìdá méjì nínú mẹ́ta owó tó ń wọlé fún wọn. Láàárín ọdún 2000 sí 2004, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì ìpolówó ọjà táwọn èèyàn ń ṣe nínú ìwé ìròyìn U.S. Wall Street Journal tí wọn ò gbé débẹ̀ mọ́. Ṣé ìpolówó ọjà á tún bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i nínú ìwé ìròyìn tí ètò ọrọ̀ ajé bá padà rú gágá? Àwọn ìpolówó tá a lè pè ní ìkéde fún ilé títà, iṣẹ́, àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ló ti di èyí tí wọn ò gbé lọ sínú ìwé ìròyìn mọ́ àfi orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Lóde oní, rédíò, tẹlifíṣọ̀n àti Íńtánẹ́ẹ̀tì ti ń gbé ìròyìn tó jẹ́ pé ìwé ìròyìn nìkan ló ń gbé e tẹ́lẹ̀.

Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, àwọn èèyàn ṣì ń fẹ́ máa gbọ́ ìròyìn lójú méjèèjì. Ọ̀jọ̀gbọ́n Axel Zerdick tó máa ń kọ̀wé fáwọn agbéròyìnjáde lórí ẹ̀kọ́ nípa ètò ìṣúnná sọ nínú ìwé ìròyìn kan tí wọ́n ń tẹ̀ nílùú Frankfurt lórílẹ̀-èdè Jámánì pé: “Wàhálà náà ò ṣòro tó bí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn oníròyìn ṣe ń rò ó sí.” Olóòtú àgbà fún iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn ojoojúmọ́ tó máa ń jáde ládùúgbò kan nílẹ̀ Jámánì sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀, ó ní: “[Ìwé ìròyìn] wa tó ń jáde lápá ibì kan ṣì ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ sí i ni.”

Ká tiẹ̀ gbà pé kò sí orísun ìròyìn míì tó lè ṣe bẹbẹ bí ìwé ìròyìn nínú ká sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ohun tó ń lọ àti káwọn èèyàn kà á tán kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n kà, àwọn ìbéèrè kan ṣì wà bíi, Ṣé gbogbo ohun tí wọ́n bá sọ lórí ọ̀ràn tó ń lọ ṣeé gbà gbọ́? Báwo lo ṣe lè jàǹfààní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nínú ìwé ìròyìn tó o bá kà?

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

IṢẸ́ ŃLÁ NI IṢẸ́ AKỌ̀RÒYÌN

Èèyàn lè fẹ́ máa jowú àwọn oníròyìn. Àgbà oníròyìn kan nílẹ̀ Faransé sọ pé: “Iyì ló máa ń jẹ́ fún oníròyìn tó bá rí orúkọ rẹ̀ nídìí ìròyìn tó kọ.” Síbẹ̀, iṣẹ́ akọ̀ròyìn láwọn ìdààmú tiẹ̀. Ìdààmú ni fún akọ̀ròyìn kan tí akọ̀ròyìn míì bá gbé ìròyìn tó ń kọ lọ́wọ́ jáde, tàbí tẹ́ni tó fẹ́ fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò bá ní kò sáàyè, tàbí tó ń dúró de àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ń retí pé kó ṣẹlẹ̀ àmọ́ tí ò ṣẹlẹ̀.

Akọ̀ròyìn kan tó máa ń kọ ìwé ìròyìn lórílẹ̀-èdè Poland sọ ìṣòro míì pé, “A ò mọ̀gbà tó yẹ ká wà lákòókò ìsinmi tàbí ìgbà tó yẹ ká ṣiṣẹ́.” Obìnrin yìí fi kún un pé: “Nígbà míì, a kì í rí àkókò lò fọ́rọ̀ ara wa, bí iṣẹ́ ṣe máa ń yọjú lọ́tùn-ún lósì sì máa ń ṣàkóbá fún ìdílé wa.” Ẹnì kan tó ti jẹ́ oníròyìn tẹ́lẹ̀ rí nílẹ̀ Soviet Union àtijọ́ sọ èyí tá a lè pè ní olórí ìdààmú wọn, ó ní, “Màá ṣiṣẹ́ kára nígbà míì, lórí ìròyìn kan, àmọ́ nígbẹ̀yìngbẹ́yín wọn ò ní gbé ìròyìn ọ̀hún jáde.”

Akọ̀ròyìn eré ìdárayá kan ní ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn tó tóbi jù lọ ní orílẹ̀-èdè Netherlands sọ pé: “Wọ́n máa ń sọ fún mi nígbà míì pé òye mi ò kún tó lórí ohun tí mò ń sọ. Kódà a rí àwọn òǹkàwé wa tó ń bínú sí mi, àní nígbà tórí àwọn èèyàn tiẹ̀ gbóná lórí ọ̀ràn eré ìdárayá láwọn ìgbà kan, wọ́n láwọn á pa mí.” Torí náà kí ló ń mú káwọn oníròyìn máa ṣiṣẹ́ ọ̀hún lọ?

Ó lè jẹ́ owó gbẹ̀mù táwọn kan nínú wọn ń gbà ló fà á, àmọ́ kì í ṣe gbogbo wọn ló tìtorí owó dúró sídìí iṣẹ́ náà. Akọ̀ròyìn kan tó ń kọ̀wé fún ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn kan nílẹ̀ Faransé sọ pé òun kàn dìídì nífẹ̀ẹ́ sí ìwé kíkọ ni. Akọ̀ròyìn kan nílẹ̀ Mẹ́síkò sọ pé: “Ó kéré tán, o ṣáà ń kọ nǹkan kan táwọn èèyàn á rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ẹ̀.” Nílẹ̀ Japan sì rèé, olóòtú àgbà kan níléeṣẹ́ ìwé ìròyìn ojoojúmọ́ tó tóbi ṣìkejì láyé sọ pé: “Mo máa ń láyọ̀ bí mo bá rí i pé mo ti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ tí mo sì rí i pé òdodo lékè.”

Àmọ́ ṣá o, akọ̀ròyìn nìkan kọ́ ló ń lọ́wọ́ sí ìwé ìròyìn tó ń jáde o. Àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn kan wà tí wọ́n ní olóòtú, akàwéṣàtúnṣe, ẹni tó ń yẹ òótọ́ inú ìwé ìròyìn wò, ẹni tó ń tọ́jú àkọsílẹ̀, tó fi mọ́ àwọn míì tó ti ṣiṣẹ́ kára lórí ìwé ìròyìn náà kó tó lè dé ọwọ́ rẹ àmọ́ tí orúkọ wọn ò jáde nínú rẹ̀.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Ìwé ìròyìn ayé àtijọ́ kan nílẹ̀ Jámánì àti ibì kan tí wọ́n ń pàtẹ ìwé ìròyìn sí lóde òní

[Credit Line]

Àwọn ìwé ìròyìn tó kọ́kọ́ ń jáde nílẹ̀ Jámánì: Bibliothek für Kunst - und Antiquitäten-Sammler, Ìdìpọ̀ kọkànlélógún, Flugblatt und Zeitung, 1922