Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Ìwé Ìròyìn Ṣe Lágbára Tó

Bí Ìwé Ìròyìn Ṣe Lágbára Tó

Bí Ìwé Ìròyìn Ṣe Lágbára Tó

Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní fòpin sí ètò ìṣàkóso ọba aládé nílẹ̀ Jámánì, ìjọba tiwa-n-tiwa gorí àlééfà ní ìlú Berlin. Kò pẹ́ sígbà náà táwọn Kọ́múníìsì bẹ̀rẹ̀ sí gbìyànjú àtidojú ìjọba tuntun yìí dé. Àtàwọn Kọ́múníìsì àti ìjọba ló gbà pé tí ọ̀kan nínú àwọn bá lè ráwọn oníwèé ìròyìn fà bọ abẹ́ pẹ́rẹ́n, èrò tó bá wu àwọn làwọn á máa gbìn sọ́kàn àwọn aráàlú, àwọn á sì máa darí àwọn èèyàn. Bí tọ̀tún-tòsì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí jìjàdù láti fa àwọn oníròyìn bọ̀dí nìyẹn.

LÁTI ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn làwọn ìwé ìròyìn ti ń nípa lórí àṣà àti ìṣèlú, tí wọ́n sì ń kópa ribiribi nínú ìṣòwò àti ìgbésí ayé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn. Ipa wo ni wọ́n ń kó nínú ìgbésí ayé rẹ?

Ó ṣe kedere pé lọ́dún 1605 ni wọ́n kọ́kọ́ tẹ ìwé ìròyìn lórílẹ̀-èdè Jámánì nílẹ̀ Yúróòpù. Láwọn ibì kan lónìí, ẹni mẹ́ta sí mẹ́rin lára àwọn tó ti lé lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá ló ń ka ìwé ìròyìn kan lójúmọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé láwọn orílẹ̀-èdè kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, kò lè ju ẹ̀dà kan ìwé ìròyìn ojoojúmọ́ tó wà fún àádọ́ta èèyàn láti kà, ó kéré tán, ẹni méjì á pín ìwé ìròyìn ojoojúmọ́ kan kà lórílẹ̀-èdè Norway. Lápapọ̀ ṣá, ìwé ìròyìn tó ń jáde jákèjádò ayé tó nǹkan bí ọ̀kẹ́ méjì ó dín ẹgbàá [38,000].

Gbogbo ibi nìwé ìròyìn ti ń jẹ́ kí aráàlú mọ nǹkan pàtàkì pàtàkì tó ń lọ. Kò wá mọ síbẹ̀ o. Wọ́n máa ń gbé ìsọfúnni jáde, èyí táá gbé ohun kan sọ́kàn aráàlú. Ọ̀gbẹ́ni Dieter Offenhäusser, òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ àjọ UNESCO tó wà lórílẹ̀-èdè Jámánì sọ pé: “Ìwé ìròyìn tá à ń kà lójoojúmọ́” ń nípa lórí “ìwà wa, ìṣe wa àti ohun tá a kà sí àṣà tó bójú mu.”

Àwọn òpìtàn sọ pé wọ́n ti lo ìwé ìròyìn rí láti dáná ogun, láti fọwọ́ sógun, wọ́n sì ti fi ṣètìlẹ́yìn fún ogun. Àwọn òpìtàn yìí tọ́ka sí àpẹẹrẹ ogun tí orílẹ̀-èdè Faransé àti Jámánì jà láyé Prussia lọ́dún 1870 sí ọdún 1871, èyí tí orílẹ̀-èdè Sípéènì àti Amẹ́ríkà jà lọ́dún 1898, àtèyí tí wọ́n jà ní orílẹ̀-èdè Vietnam lọ́dún 1955 sí ọdún 1975. Ọ̀pọ̀ oníṣòwò, onímọ̀ ìjìnlẹ̀, èèkàn láàárín àwọn òṣèré, àtàwọn olóṣèlú làwọn ìwé ìròyìn ti gbá wọlẹ̀ látàrí ìwà ìbàjẹ́ wọn kan tí wọ́n gbé jáde. Ìgbà kan wà táwọn oníròyìn tó máa ń tọpinpin gbé ìròyìn kan jáde láàárín ọdún 1974 sí ọdún 1976 nípa ìwà ìbàjẹ́ tí Ààrẹ ilẹ̀ Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀, Richard M. Nixon hù pa mọ́. Ìròyìn náà gbalẹ̀ débi pé ó ní láti kọ̀wé fipò sílẹ̀. Èyí fi hàn pé iyán ìwé ìròyìn ò ṣeé kó kéré nítorí pé ó lè nípa rere tàbí búburú.

Àmọ́ báwo ni ìwé ìròyìn ṣe bẹ̀rẹ̀ sí nírú agbára yìí? Báwo ni ohun tá a bá kà nínú ìwé ìròyìn ṣe ṣeé gbà gbọ́ tó? Kí ló yẹ ká ṣọ́ra fún láti lè jàǹfààní látinú ìwé ìròyìn?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Bí wọ́n ṣe ń fìwé ìròyìn dáná ogun nílùú Berlin lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní