Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Òṣì Ò Ṣe Ní Sí Mọ́

Bí Òṣì Ò Ṣe Ní Sí Mọ́

Bí Òṣì Ò Ṣe Ní Sí Mọ́

ỌGỌ́RỌ̀Ọ̀RÚN lọ́nà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn kárí ayé ló ń fojoojúmọ́ wá bọ́wọ́ àwọn á ṣe tẹ́nu, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òṣì mù wọ́n dundun. Ó ṣe kedere pé aráyé nílò ìjọba òdodo tí kò ní figbá kan bọ̀kan nínú nígbà tó bá ń kásẹ̀ ìwà ìrẹ́jẹ nílẹ̀. Irú ìjọba bẹ́ẹ̀ sì gbọ́dọ̀ lágbára tó láti ṣe gbogbo nǹkan rere tó bá fẹ́ ṣe. Ǹjẹ́ a lè máa retí pé kí aráyé gbé irú ìjọba bẹ́ẹ̀ kalẹ̀?

Ìtàn ti jẹ́ ká rí òótọ́ tó wà nídìí ìkìlọ̀ Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀.” (Sáàmù 146:3) Ǹjẹ́ o ti rí i pé ìjákulẹ̀ ló sábà máa ń já sí béèyàn bá gbọ́kàn lé ìjọba èèyàn tàbí àwọn aṣáájú ayé? Ta là bá wá sá tọ̀ lọ o?

Ká sòótọ́, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ti ń gbàdúrà pé kí ìjọba òdodo tó máa kásẹ̀ ìwà ìrẹ́jẹ nílẹ̀ dé. Bóyá ìwọ náà ti gba àdúrà àwòkọ́ṣe tí Jésù kọ́ni pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú. Fún wa lónìí oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní; kí o sì dárí àwọn gbèsè wa jì wá, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ti dárí ji àwọn ajigbèsè wa. Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.”—Mátíù 6:9-13.

Ṣé Ìjọba tá à ń gbàdúrà fún yìí gan-an la nílò? Ṣé àkóso òdodo Ìjọba náà ò ní figbá kan bọ̀kan nínú? Ṣé òun ni ìjọba tó lágbára débi pé gbogbo rere tó bá fẹ́ ṣe náà ló máa lè ṣe? Dájúdájú, òun gan-an ni! Ọlọ́run tó gbé ìjọba náà kalẹ̀, ìyẹn “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run,” jẹ́ “Ọlọ́run òdodo àti Olùgbàlà,” ó sì tún jẹ́ “olódodo nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.” (Aísáyà 45:21; Dáníẹ́lì 9:14) Bíbélì sì tún sọ nípa rẹ̀ pé: “Ojú rẹ ti mọ́ gaara jù láti rí ohun tí ó burú,” nítorí náà ó yẹ kó dá wa lójú pé ìjọba náà ò ní figbá kan bọ̀kan nínú. (Hábákúkù 1:13) Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un,” a mọ̀ pé dénúdénú ló fẹ́ olúkúlùkù àwa èèyàn tá a wà lórí ilẹ̀ ayé fẹ́re.—Ìṣe 10:34, 35; Róòmù 2:11.

Ọlọ́run Ti Gbé Ìjọba Rẹ̀ Kalẹ̀ Ó sì Ti Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Ní Pẹrẹu!

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀run ni Ìjọba Ọlọ́run yóò ti máa ṣàkóso wá, yóò máa darí bí nǹkan ṣe ń lọ sí lórí ilẹ̀ ayé níbí lọ́nà tí yóò fi máa mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Yóò fi àkóso pípé látọ̀dọ̀ Ọlọ́run rọ́pò àkóso aláìpé ti ẹ̀dá èèyàn. Ọlọ́run ṣèlérí nínú Dáníẹ́lì 2:44 pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba [ìjọba] wọ̀nyẹn, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”

Lábẹ́ ìdarí Ìjọba Ọlọ́run, ìfẹ́ Ọlọ́run á di ṣíṣe lọ́run àti lórí ilẹ̀ ayé. Ẹ wo bó ti ń fúnni níṣìírí tó láti mọ̀ pé á ṣeé ṣe fún ìjọba náà láti mú gbogbo ohun tó ń fà á tí ìka ò fi dọ́gba kúrò! Nítorí pé látẹ̀yìnwá, irú èrò bẹ́ẹ̀ ló ń mú kí ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ wà láàárín àwọn olówó àtàwọn òtòṣì. Kò tún ní sí àwọn èèyàn kéréje tó jẹ́ olówó àti ọ̀pọ̀ yanturu tó jẹ́ òtòṣì mọ́.

Ohun ayọ̀ gbáà ló jẹ́ láti mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run lókè ọ̀run ti wà ní sẹpẹ́ báyìí láti kásẹ̀ àwọn ìṣòro wọ̀nyí nílẹ̀ títí gbére! Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ayé ti jẹ́ ká rí i kedere pé lọ́dún 1914 ni Ọlọ́run gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ lókè ọ̀run. a Nítorí náà, láti nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún, ìjọba náà ti wà lẹ́nu iṣẹ́ fífi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún ayé tuntun òdodo.

Àwọn tó ti mọ̀ pé Ọlọ́run ti gbé Ìjọba náà kalẹ̀, tí wọ́n sì ń fi ìgbọràn tẹ̀lé ìtọ́ni rẹ̀ kì í ṣe ojúsàájú. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ní gbogbo orílẹ̀-èdè làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń bá iṣẹ́ ìwàásù wọn nìṣó. Yálà àwọn olùgbé orílẹ̀-èdè wọ̀nyí lọ́rọ̀ tàbí wọn kò lọ́rọ̀, wọ́n láǹfààní láti kọ́ nípa bí wọ́n ṣe lè jogún ìyè ayérayé. (Jòhánù 17:3) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi béèyàn ṣe rí já jẹ sí tàbí ipò tó wà láwùjọ pè nínú àwọn ìjọ wọn. Wọ́n kì í fún ẹnikẹ́ni láfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ nítorí ohun tó ní. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tẹ́nì kan jẹ́ ló ń mú kí wọ́n fọ̀wọ̀ fún un. Ọwọ́ téèyàn fi mú ìjọsìn Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì lójú wọn ju ọrọ̀ tara lọ.

Ṣé wàá fẹ́ láti mọ bó o ṣe lè gbé lábẹ́ ìṣàkóso òdodo yìí? O ò ṣe kúkú bẹ̀rẹ̀ sí ṣèwádìí látòní lọ. Kọ́ bó o ṣe lè máa fojú sọ́nà fún bí wàá ṣe máa láyọ̀ nígbà tó o bá ń gbé nínú ayé tí ọrọ̀ kò pín níyà.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Yálà A Jẹ́ Olówó Tàbí Òtòṣì, Ará Ni Gbogbo Wa

◼ Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Yúróòpù àti nílẹ̀ Éṣíà ni ò róúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé. Àwọn Ẹlẹ́rìí látàwọn orílẹ̀-èdè míì kó ọ̀pọ̀ aṣọ àti oúnjẹ ránṣẹ́ sáwọn Ẹlẹ́rìí bíi tiwọn nílẹ̀ Yúróòpù, lórílẹ̀-èdè Philippines àti lórílẹ̀-èdè Japan. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Amẹ́ríkà àti Kánádà dáwó jọ láti ra àwọn ohun àfiṣèrànwọ́, wọ́n sì kó wọn ránṣẹ́ sí orílẹ̀-èdè Austria, Belgium, Czechoslovakia (tó ti di orílẹ̀-èdè Czech àti Slovakia báyìí), ilẹ̀ Faransé, Finland, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Gíríìsì, Holland, Hungary, Ítálì, Jámánì, Poland àti Romania.

[Àwọn àwòrán]

Amẹ́ríkà

Switzerland

Jámánì

◼ Láìpẹ́ yìí, nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1994, àgbájọ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni láti ilẹ̀ Yúróòpù tara ṣàṣà lọ ran àwọn Kristẹni bíi tiwọn lọ́kùnrin àti lóbìnrin lọ́wọ́ ní Áfíríkà. Wọ́n ṣètò àwọn àgọ́ fáwọn olùwá-ibi-ìsádi láti orílẹ̀-èdè Rwanda, wọ́n sì tún ṣètò ibi tí wọ́n á ti máa fún wọn ní ìtọ́jú ìṣègùn. Wọ́n tún kó òbítíbitì aṣọ wíwọ̀, aṣọ ìbora, oúnjẹ àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ránṣẹ́ láti ṣèrànwọ́ fáwọn olùwá-ibi-ìsádi tó lé ní ẹgbẹ̀rún méje [7,000]. Á fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìgbà mẹ́ta tí èyí fi tayọ iye gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Rwanda nígbà yẹn.

◼ Lọ́dún méjì lẹ́yìn náà, ìyẹn lọ́dún 1996, ogun bẹ́ sílẹ̀ ní ẹkùn ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Kóńgò. Wọ́n ba irúgbìn jẹ́, àwọn èèyàn jí oúnjẹ tó wà nípamọ́ kó, wọ́n sì dí àwọn ọ̀nà tí oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì lè bá wọlé. Ọ̀pọ̀ ò lè rí jẹ ju oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan lóòjọ́, ìyẹn sì ń fa àìjẹunrekánú àti àrùn. Kíá làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílẹ̀ Yúróòpù dìde ìrànwọ́. Àwọn dókítà wà lára àwọn Ẹlẹ́rìí tó lọ ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọ́n sì fi ọkọ̀ òfuurufú kó owó àti oògùn dání. Nígbà tó fi máa di oṣù June, lọ́dún 1997, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nílẹ̀ Belgium, Faransé àti Switzerland ti fi ọ̀pọ̀ nǹkan ránṣẹ́. Oògùn tí wọ́n kó ránṣẹ́ tẹ̀wọ̀n tó àpò sìmẹ́ǹtì mẹ́wàá, àwọn bisikí tó ní èròjà protein tí wọ́n kó ránṣẹ́ tó ẹ̀kún ọkọ̀ akóyọyọ méjì, oúnjẹ tí wọ́n kó ránṣẹ́ fẹ́rẹ̀ẹ́ kún ọkọ̀ akóyọyọ mẹ́rin, aṣọ tí wọ́n kó ránṣẹ́ sì kún ọkọ̀ akóyọyọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Wọ́n tún kó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lé lẹ́gbàásàn-án [18,500] bàtà àti ẹgbẹ̀rún aṣọ ìbora ránṣẹ́, gbogbo rẹ̀ sì kú sí nǹkan bíi mílíọ̀nù kan dọ́là.

◼ Yàtọ̀ sí pípèsè ohun táwọn èèyàn nílò nípa tara fún wọn, ó máa ń wu àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jù láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Ìyẹn ló fà á tí wọ́n fi máa ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba gẹ́gẹ́ bí ibi tí wọ́n á ti máa kóra jọ láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. A rí ìròyìn gbọ́lọ́dún 1997 pé: “Nítorí ìrànlọ́wọ́ tá a rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn ará wa láti àwọn orílẹ̀-èdè míì, [Watch Tower] Society ti bá wa kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba okòó-lé-nírínwó ó dín méje [413], wọ́n sì bá wa tún òjì-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́tàlá [727] ṣe láàárín oṣù mẹ́rin péré, ní orílẹ̀-èdè márùndínlọ́gọ́rin.” Ìròyìn tá a gbọ́ lọ́dún 2003 sọ pé: “Orílẹ̀-èdè Romania jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Yúróòpù tó ń jàǹfààní ètò tó wà nílẹ̀ fún kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sáwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan ò ti fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ṣọ̀mù, wọ́n sì ti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́rìnlélọ́gọ́fà [124] síbẹ̀ láti oṣù July, ọdún 2000. Àwọn ará Ukraine ní ọ̀nà pàtó tí wọ́n gbà ń kọ́ èyí tó pọ̀ jù lára àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Ọ̀nà yẹn ni wọ́n gbà kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba mọ́kànlélọ́gọ́ta lọ́dún 2001, wọ́n sì kọ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́rin sí i lọ́dún 2002. Nítorí ìrànwọ́ owó tí wọ́n ń rí látinú Owó Àkànlò fún Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, ọgọ́rọ̀ọ̀rún Gbọ̀ngàn Ìjọba ni wọ́n ti kọ́ sí àwọn orílẹ̀-èdè Bulgaria, Croatia, Macedonia, Moldova, Rọ́ṣíà àti Serbia òun Montenegro báyìí.”

[Àwọn àwòrán]

Romania

Croatia

Bulgaria

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Olùyọ̀ǹda ara ẹni kan tó ń tọ́jú àwọn ọmọ méjì tí wọ́n jẹ́ aláìlóbìí níbi táwọn olùwá ibi ìsádi wà

[Credit Line]

© Fọ́tò tí Liba Taylor/Panos yà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù ìhìn rere tó ń fúnni ní ìrètí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ìjọba Ọlọ́run á fòpin sí ìṣẹ́