Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bó O Ṣe Lè Jàǹfààní Nínú Ìwé Ìròyìn

Bó O Ṣe Lè Jàǹfààní Nínú Ìwé Ìròyìn

Bó O Ṣe Lè Jàǹfààní Nínú Ìwé Ìròyìn

“Ọ̀dẹ̀ lẹ́ni tí kò bá tíì ka ìwé ìròyìn rí; baba ọ̀dẹ̀ sì lẹni tó bá wá ń gba ohun tó kà nínú ìwé ìròyìn gbọ́ torí pé ó rí i nínú ìwé ìròyìn.” —August von Schlözer, òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Jámánì kan tó jẹ́ akọ̀ròyìn lápá ìparí ọ̀rúndún kejìdínlógún, ló sọ bẹ́ẹ̀.

WỌ́N ṣèwádìí kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti nílẹ̀ Faransé nínú èyí tí wọ́n ti bi ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn léèrè nípa bí wọ́n ṣe gbẹ́kẹ̀ lé àwọn iléeṣẹ́ àti àjọ mẹ́tàlá kan tó. Ìgbẹ́kẹ̀lé tí wọ́n láwọn ní nínú àwọn oníròyìn ló kéré jù, kódà wọ́n láwọn fọkàn tán àwọn olóṣèlú àtàwọn oníṣòwò aládàá-ńlá ju àwọn oníròyìn lọ. Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó ń ka ìwé ìròyìn ló ṣì ń sọ pé àwọn gba ohun táwọn ń kà nínú ìwé ìròyìn gbọ́. Àmọ́ ìwádìí tí ilé iṣẹ́ ìwádìí Pew Research Center ṣe fi hàn pé iye àwọn tó gba ohun tí wọ́n ń kà nínú ìwé ìròyìn gbọ́ ti dín kù.

Ọ̀pọ̀ ìgbà la ò lè dá àwọn tó ń ṣiyèméjì yìí lẹ́bi, pàápàá tó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tó kan orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń tẹ ìwé ìròyìn ọ̀hún ló sọ̀rọ̀ lé lórí. Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ tọ́rọ̀ bá ti dà bẹ́ẹ̀? Òótọ́ sábà máa ń kùtà ni. Arthur Ponsonby, àgbà òṣèlú kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láàárín ọdún 1901 sí ọdún 2000 sọ pé: “Táwọn aláṣẹ bá ti fẹ́ ṣe nǹkan pàtàkì kan, Òótọ́ ni wọ́n á kọ́kọ́ gbá sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.”

Ká tiẹ̀ ní kò sí nǹkan pàtó kan táwọn aláṣẹ ń bò mọ́lẹ̀, ó ṣì bọ́gbọ́n mu kó o mojú ìròyìn tí wàá máa gbà gbọ́. Òwe kan nínú Bíbélì sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Òwe 14:15) Tó o bá wojú ilẹ̀ dáadáa kó o tó yan ìwé ìròyìn tí wàá kà, o lè máa rí ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ìròyìn tó o nílò gbọ́.

Ìdí Tí Ìròyìn Fi Ṣe Pàtàkì

Lónìí, ohun tá à ń rí gbọ́ nínú ìròyìn ṣe pàtàkì torí ó ń jẹ́ ká lè máa mọ àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé. Ó sì ṣe pàtàkì pé ká máa mọ̀ ọ́n. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ nínú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí ni wòlíì tó tíì tóbi jù lọ láyé, ìyẹn Jésù Kristi ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bi í nípa òpin ètò nǹkan ìsinsìnyí, ó sọ pé àwọn nǹkan tá a fi máa mọ àkókò òpin ni pé ogun á máa jà, ìwà àìlófin á máa pọ̀ sí i, oúnjẹ ò ní tó, àjàkálẹ̀ àrùn á wà, ilẹ̀ á máa ri, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ míì á sì máa wáyé.—Mátíù 24:3-14; Lúùkù 21:7-11.

Bíbélì tún sọ pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín.” Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn fi kún un pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí, àwọn ènìyàn yóò jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó,” àti “aṣàìgbọràn sí òbí.” Wọ́n á jẹ́ “aláìní ìfẹ́ni àdánidá,” wọ́n á sì tún jẹ́ “aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.”—2 Tímótì 3:1-5.

Kò sí àníàní pé ìwọ náà ti ń rí i bí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yìí ṣe ń ní ìmúṣẹ ládùúgbò rẹ. Àwọn nǹkan tó sì ń ṣẹlẹ̀ káàkiri ayé, bí wọ́n ṣe ń kọ wọ́n sínú ìwé ìròyìn ń jẹ́ ká rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì náà ti ń ṣẹ bó ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́. Ṣé ohun tíyẹn ń sọ ni pé a lè gba gbogbo ohun tá a bá kà nínú ìwé ìròyìn gbọ́? Rárá o, kódà ohun táwọn tó ń ṣiṣẹ́ lórí kíkọ ìwé ìròyìn gan-an ń sọ fi hàn pé ó yẹ kéèyàn ṣọ́ra.

Ohun Tójú Ń Rí Kí Wọ́n Tó Kó Òkodoro Ìròyìn Jọ

Gbogbo èèyàn pátá, tó fi mọ́ àwọn ògbógi tó mọṣẹ́ dunjú tí wọ́n sì ń finnú kan ṣiṣẹ́, ló máa ń ṣàṣìṣe. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Ariel Hart kọ̀wé sínú ìwé ìròyìn Columbia Journalism Review pé: “Láti ọdún mẹ́ta tí mo ti ń bá ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ yẹ bí ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé ìròyìn ṣe jẹ́ òtítọ́ tó wò, kò tíì sí ìròyìn kan tí mo yẹ̀ wò tí kò ní àṣìṣe kankan, ì báà jẹ́ ìròyìn tó pọ̀ tó ojú ìwé márùn-ún tàbí tí kò ju ìpínrọ̀ méjì péré lọ.” Ó mẹ́nu ba àwọn àṣìṣe tí wọ́n sábà máa ń ṣe, ó ní “déètì ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn lè fi bí ọdún kan yàtọ̀; àkọsílẹ̀ tí wọ́n lọ wò lè ti pẹ́; wọ́n lè ṣi sípẹ́lì ọ̀rọ̀; ìròyìn náà sì lè jẹ́, ‘wọ́n ní, wọ́n pé’ kan tó ti tàn kálẹ̀, àmọ́ tí kì í ṣòótọ́.”

Ìṣòro làwọn ìròyìn tí orísun wọn ṣòro gbà gbọ́ jẹ́ fáwọn oníròyìn. Nígbà míì, àwọn kan á máa fún àwọn oníròyìn ní fàbú. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1999, ọgbẹ́ni olódù kan lọ gbé ìròyìn èké fáwọn oníròyìn nípa ibi ìgbafẹ́ kan táwọn èèyàn á ti máa fi oríṣiríṣi nǹkan ṣeré. Ó sọ pé wọ́n fẹ́ ṣe ibi ìgbafẹ́ yìí bí itẹ́ òkú, ó sì fi àdírẹ́sì ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ti iléeṣẹ́ tó máa bá wọn kọ́ ibi ìgbáfẹ́ náà, ṣe arúmọjẹ sínú ìròyìn ọ̀hún. Ó fi nọ́ńbà tẹlifóònù téèyàn fi lè bá wọn sọ̀rọ̀ ní ilé iṣẹ́ náà síbẹ̀, léyí tó sì jẹ́ pé téèyàn bá pe ibẹ̀, ẹlẹ̀tàn kan wà níbẹ̀ tó máa ṣe bí agbẹnusọ iléeṣẹ́ náà. Agbárí tó lò yẹn jẹ iléeṣẹ́ Associated Press tó máa ń fi ìròyìn ránṣẹ́ nípa títẹ wáyà sáwọn oníròyìn, bó ṣe di pé ọ̀pọ̀ ìwé ìròyìn nílẹ̀ Amẹ́ríkà gbé ìròyìn èké náà jáde nìyẹn. Àwọn kan sọ pé téèyàn bá fẹ́ gbé ìròyìn fàbú jáde tó sì fẹ́ kó jẹ àwọn èèyàn dáadáa, kó wá “ìròyìn kàyééfì kan, kó tún wá yàwòrán kan tó pabanbarì tó ṣeé gbà gbọ́ síbẹ̀.”

Kódà àwọn akọ̀rọ̀yìn tó fẹ́ sọ bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an kì í rí òkodoro òtítọ́ gbé jáde nígbà míì. Akọ̀ròyìn kan nílẹ̀ Poland sọ pé: “Iṣẹ́ tó ń léni léré niṣẹ́ àwọn oníròyìn. Ńṣe làwọn ìwé ìròyìn ń lé ara wọn dórí àtẹ. Olúkúlùkù ló ń fẹ́ kó jẹ́ òun láá kọ́kọ́ gbé ìròyìn kan síta. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nínú wa fẹ́ wádìí jinlẹ̀ lórí àpilẹ̀kọ kan ká tó gbé e jáde, a kì í lè ṣe bẹ́ẹ̀.”

Àwọn Kan Ń Fẹ́ Kí Oníròyìn Kọ Ohun Tó Wu Àwọn

Ìwé Freedom of the Press 2003—A Global Survey of Media Independence, tó ń ṣèwádìí nípa báwọn oníròyìn ṣe lómìnira tó sọ pé nínú igba ó dín méje orílẹ̀-èdè, márùndínlọ́gọ́fà nínú wọn làwọn oníròyìn kò ti ní òmìnira tó pọ̀ tó tàbí tí wọn ò tiẹ̀ ní in rárá. Àmọ́, àwọn èèyàn lè dọ́gbọ́n fi irọ́ díẹ̀ lú okodoro ìròyìn láwọn orílẹ̀-èdè táwọn oníròyìn ti lómìnira.

Nígbà míì, wọn ò ní jẹ́ káwọn oníròyìn kan gbọ́ nípa àwọn nǹkan pàtàkì tó bá ń lọ, tó sì jẹ́ pé àwọn oníròyìn tó bá lè tó ìwé ara wọn ni wọ́n á máa fún láàyè láti fọ̀rọ̀ wá àwọn lẹ́nu wò, àwọn làwọn olóṣèlú á máa ní kí wọ́n tẹ̀ lé àwọn lọ sí ìrìn-àjò. Owó táwọn oníròyìn ń pa látọ̀dọ̀ àwọn tó ń ṣe ìkéde nínú ìwé ìròyìn wọn lè mú kí wọ́n gbàbọ̀dè. Oníròyìn kan lórílẹ̀-èdè Poland sọ pé: “Ẹni tó ń ṣe ìkéde nínú ìwé ìròyìn kan lè sọ pé òun ò ní gbé ìkéde olówó tabua dé ọ̀dọ̀ wọn mọ́ tí olóòtú ìwé ìròyìn náà bá gbé ohun tí kò dáa jáde nípa òun.” Ẹnì kan tó wà lára àwọn tó máa ń ka ìwé ìròyìn orílẹ̀-èdè Japan kan kí wọ́n tó lọ tẹ̀ ẹ́ sì kìlọ̀ pé, “Fi sọ́kàn pé ó ṣòro kéèyàn tó lè rí ìròyìn tí kò ní àbùmọ́ àti àyọkúrò gbé jáde.”

Ó ṣeé ṣe kó o béèrè pé, ‘Tó bá wá jẹ́ pé adúrú ìṣòro yìí làwọn oníwèé ìròyìn tó gbà á bí iṣẹ́ ń dojú kọ kí wọ́n tó lè gbé ìròyìn tó ṣeé gbà gbọ́ jáde, báwo lẹ́ni tó fẹ́ kà á ṣe máa mọ èyí tó yẹ kóun gbà gbọ́?’

Ó Ṣe Pàtàkì Pé Kó O Mọ Ohun Tó Ò Ń Ṣe

A ti rí i kedere pé ìfòyemọ̀ ṣe pàtàkì. Olórí ìdílé kan látijọ́, Jóòbù, béèrè pé: “Etí kò ha ń dán ọ̀rọ̀ wò bí òkè ẹnu ti ń tọ́ oúnjẹ wò?” (Jóòbù 12:11) Ẹni tó bá ka ìwé ìròyìn kan ní láti wò ó dáadáa kó lè dá a lójú pé ìròyìn náà jọ òótọ́. Ó bọ́gbọ́n mu fún un pé kó dán ohun tó ń kà wò kó sì rí i pé òótọ́ ibẹ̀ lòun á gbà gbọ́. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi ní ọ̀rúndún kìíní kọ̀wé láti ṣe sàdáńkátà fáwọn kan tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù, àmọ́ tí wọ́n tún lọ wo ibi tó ti mú ọ̀rọ̀ náà wá láti lè rí i pé òótọ́ ló ń kọ́ àwọn.—Ìṣe 17:11; 1 Tẹsalóníkà 5:21.

Bákan náà, ẹnì kan tó ń ka ìwé ìròyìn yẹ kó bi ara rẹ̀ pé: Irú èèyàn wo lẹni tó kọ ìròyìn yìí? Àwọn nǹkan wo ló kórìíra? Ṣé bá a bá wá a lọ wá a bọ̀, ṣé bẹ́ẹ̀ la máa bá àwọn nǹkan tó kọ sínú àpilẹ̀kọ náà? Ṣé ẹnì kan wà tá fẹ́ fi irọ́ bo òtítọ́ lójú? Ó bọ́gbọ́n mu fẹ́ni tó ń kàwé ìròyìn kó wádìí lọ́nà bíi mélòó kan kó fi lè mọ bí ìròyìn náà ṣe jóòótọ́ tó. Ó lè bá àwọn ẹlòmíì sọ̀rọ̀ nípa ohun tó kà. Òwe inú Bíbélì kan sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.”—Òwe 13:20.

Síbẹ̀, má retí pé gbogbo ẹ̀ á pé pérépéré. Gẹ́gẹ́ bá a ti ṣe rí i, oríṣiríṣi nǹkan ni kò ní jẹ́ káwọn oníwèé ìròyìn lè kọ ohun tí kò lábùlà. Síbẹ̀, wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa ohun tó ń lọ nínú ayé. Ó sì ṣe pàtàkì pé kó o máa mọ ohun tó ń lọ torí pé nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa àkókò tá à ń gbé yìí, ó ní: “Ẹ wà lójúfò.” (Máàkù 13:33) Ìwé ìròyìn tó o bá ń kà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa wà lójúfò, bó tilẹ̀ jẹ́ pé o gbọ́dọ̀ mọ̀ pé gbogbo ẹ̀ náà kọ́ lo lè gbà gbọ́.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

BÁWỌN ONÍRÒYÌN BÁ PỌ̀N SỌ́NÀ KAN

Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó máa ń jẹ́ káwọn oníròyìn gbé ìròyìn tí kò péye jáde ni pé wọ́n máa ń kánjú kọ ìròyìn wọn ni tàbí kó jẹ́ pé orí eré ni wọ́n ti rí ìròyìn yẹn gbà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú kan làwọn tó kọ irú ìròyìn bẹ́ẹ̀ ní, síbẹ̀ ìròyìn wọn lè yára tan irọ́ ńláńlá kálẹ̀. Àmọ́ nígbà míì, àwọn kan máa ń mọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ tan àwọn èèyàn jẹ, irú rẹ̀ ni ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìṣàkóso Násì ní orílẹ̀-èdè Jámánì nígbà tí wọ́n ń purọ́ mọ́ àwọn ẹ̀ya kan àtàwọn ẹ̀sìn kan.

Wo irọ́ kan tí kò bò wọ́n lẹ́yìn ẹsẹ̀ tí wọ́n pa láìpẹ́ yìí nígbà tí wọ́n ń ṣe ẹjọ́ lórí ọ̀ràn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn nílùú Moscow lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Ìwé ìròyìn The Globe and Mail tí wọ́n ń tẹ̀ nílùú Toronto lórílẹ̀-èdè Kánádà sọ pé: “Nígbà táwọn ọmọbìnrin mẹ́ta kan fọwọ́ ara wọn pa ara wọn ní ìlú Moscow, ojú ẹsẹ̀ làwọn oníwèé ìròyìn tó wà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti ń sọ pé ọmọlẹ́yìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn ọmọbìnrin yẹn máa jẹ́.”

Ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kejì, ọdún 1999, ìyẹn ọjọ́ tí ilé ẹjọ́ ìjọba padà bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ lórí bí wọ́n ṣe máa fòfin de iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìlú Moscow, ni wọ́n gbé irú àwọn ìròyìn yẹn jáde. Geoffrey York tó jẹ́ aṣojú ìwé ìròyìn The Globe and Mail, èyí tí wọ́n ń tẹ̀ ní ìlú Moscow, nílẹ̀ Rọ́ṣíà ròyìn pé: “Àwọn ọlọ́pàá wá sọ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé, kò sí nǹkan tó kan àwọn ọmọbìnrin yẹn kan ọ̀ràn ẹ̀sìn kankan. Àmọ́ nígbà táwọn ọlọ́pàá fi máa gbé ìròyìn náà jáde, ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n kan nílùú Moscow ti bẹ̀rẹ̀ sí lọgun àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sọ pé bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Adolf Hitler nígbà ìṣàkóso Násì ní Jámánì, bó tilẹ̀ pé ẹ̀rí jaburata wà nínú ìtàn pé ẹgbàágbèje àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló kú sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ táwọn Násì ti ń pààyàn díẹ̀díẹ̀.”

Látàrí èyí, lójú àwọn aráàlú táwọn ìwé ìròyìn yìí ti purọ́ fún, tẹ́rù sì ti ń bà, ẹgbẹ́ òkùnkùn tó ń para wọn tàbí àwọn alábàáṣiṣẹ́ àwọn Násì ni wọ́n ka àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Jésù Kristi ti sàsọtẹ́lẹ̀ ọ̀pọ̀ nǹkan tá à ń rí nínú ìwé ìròyìn báyìí

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Àwọn ìròyìn tá à ń rí nínú ìwé ìròyìn fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń ṣẹ

[Credit Line]

FAO photo/B. Imevbore

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbóríyìn fún àwọn tó yẹ ibi tó ti rí ẹ̀kọ́ tó fi ń kọ́ wọn wò, ó sì bọ́gbọ́n mu pé káwa náa máa ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá gbọ́ ìròyìn kan tó jọ wá lójú