Bó O Ṣe Lè Máa Tọ́jú Eyín Rẹ
Bó O Ṣe Lè Máa Tọ́jú Eyín Rẹ
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ KÁNÁDÀ
BÓ O bá dúró níwájú dígí, kí lo máa ń wò? Ó lè jẹ́ irun ẹ tàbí àwọn nǹkan míì nípa ìrísí ẹ. Ǹjẹ́ o tiẹ̀ máa ń wo bí ẹ̀rín ṣe rí lẹ́nu ẹ? Ǹjẹ́ o tiẹ̀ mọ̀ pé ó ní ipa tí eyín ń kó bó o bá ń rẹ́rìn-ín? Ó dájú pé bó o bá fẹ́ kí ẹ̀rín máa dùn mùkẹ̀mukẹ lẹ́nu ẹ, wàá fẹ́ láti máa tọ́jú eyín ẹ. Yàtọ̀ sí eyín ọyàn tó máa ń wọ́ dà nù, ṣe ni Ọlọ́run dá eyín lọ́nà táá fi báni kalẹ́. Ó yẹ kéèyàn máa fún eyín ní àkànṣe ìtọ́jú. Yàtọ̀ sí pé eyín rẹ ń mú kó o lè rún oúnjẹ lẹ́nu tó sì tún ń mú kó o lè sọ̀rọ̀ dáadáa, òun ló tún gbé ètè àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ ró, tó ń mú kí ẹnu rẹ gún régé, tó sì ń mú kí ẹ̀rín dùn lẹ́nu ẹ. Tẹ̀gàn ni ẹ̀, eyín ń mẹ́nu gún ojàre!
Báwo Lo Ṣe Lè Máa Tọ́jú Eyín Rẹ?
Bí eyín bá máa dáa, ó sinmi lórí irú oúnjẹ téèyàn bá ń jẹ. Oúnjẹ tí èròjà ẹ̀ pé máa ń ní èròjà calcium tó ń méyín gbó keke àtàwọn fítámì mélòó kan, àwọn èròjà yìí sì ń mú kí eyín hù dáadáa látinú oyún títí dìgbà téyín náà á fi gbó dáadáa. a Bó o bá ń jẹ oúnjẹ tó dáa, eyín rẹ ò ní bàjẹ́, àmọ́ ṣọ́ra fún oúnjẹ tí ṣúgà bá pọ̀ nínú ẹ̀ o! Ńṣe ló máa ń jẹ́ kí eyín tètè jẹrà. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, bí wọ́n ṣe ń kìlọ̀ gbọnmọgbọnmọ tó, pé ṣúgà máa ń jẹ́ kí eyín jẹrà, ọ̀pọ̀ lára àwọn ará Àríwá Amẹ́ríkà máa ń nìkan jẹ àpò ṣúgà kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ nǹkan bí ọgọ́ta kìlógíráàmù lọ́dọọdún! Kí ló fà á tí ṣúgà fi máa ń ba eyín jẹ́?
Oríṣi kòkòrò bakitéríà méjì kan tó ń jẹ́ “mutans streptococci àti lactobacilli,” ló máa ń fa èérí eyín. Àwọn ló máa ń dàpọ̀ mọ́ èérún oúnjẹ tó máa ń lẹ̀ mọ́ eyín. Ṣúgà loúnjẹ àwọn bakitéríà yìí, wọ́n sì máa ń pa ṣúgà náà dà di omiró tó máa ń jẹ́ kí eyín bẹ̀rẹ̀ sí jẹrà. Irú àwọn ṣúgà kan tiẹ̀ wà tí kì í pẹ́ di omiró, àwọn kan sì máa ń tètè lẹ̀ mọ́ eyín, nípa bẹ́ẹ̀ kòkòrò bakitéríà tó ń ba eyín jẹ́ á tètè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. b Béèyàn bá fọ èérí eyín kúrò tí kò mọ́, ńṣe ló máa le gbagidi, á sì di yọ̀rọ̀ tó máa wà nídìí erìgì.
Kí eyín má bàa dípẹtà, kí bakitéríà tó ń ba eyín jẹ́ sì má lọ wọ abẹ́ eyín, ó ṣe kókó kéèyàn máa tọ́jú eyín déédéé. Nítorí náà, èèyàn gbọ́dọ̀ máa fọnu lójoojúmọ́ kí eyín èèyàn má bàa jẹrà. Ẹ̀ka tí wọ́n ti ń kọ́ nípa eyín àti iṣẹ́ abẹ ẹnu ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Columbia University sọ pé: “Ní àfikún sí kéèyàn máa lo fọ́nrán okùn ìfọyín [lílo búrọ́ọ̀ṣì] ni ohun kan ṣoṣo tó ṣe pàtàkì jù lọ tó o lè ṣe láti mú kí eyín ẹ
lágbára káwọn iṣan tó gbé eyín ró má sì bà jẹ́.” Ọ̀nà tó dáa téèyàn lè gbà máa lo búrọ́ọ̀ṣì tàbí fọ́nrán okùn ìfọyín wà nínú àwòrán tó wà lójú ewé yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e. Oníṣègùn eyín lè dábàá àwọn ohun èlò míì fún ọ, ó sì lè kọ́ ọ láwọn ọgbọ́n míì tó o fi lè máa tọ́jú eyín rẹ dáadáa, kó lè máa buyì kún ẹ̀rín ẹ.Bí omiró ò bá yé rogún sídìí eyín, ó lè mú àwọn èròjà tó ń jẹ́ kí eyín lágbára dín kù tàbí kó tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí jẹ eyín. Ṣùgbọ́n ojoojúmọ́ ni èròjà yẹn tún ń kóra jọ padà. Báwo? Ẹ̀rí ti fi hàn pé èròjà fluoride tó wà nínú ọṣẹ ìfọnu máa ń gbogun ti ohun tó ń mú kí eyín bá jẹ̀ nípa dídá èròjà tó yẹ padà sí ẹnu. Ó wá já sí pé, bí kòkòrò tó ń ba eyín jẹ́ ṣe ń ṣe tiẹ̀ ni èròjà fluoride náà ń rí i pé òun fi èròjà tí ò ní jẹ́ kí eyín bá jẹ̀ rọ́pò. Àṣé òótọ́ ni pé eyín lè tọ́jú ara ẹ̀!
Bó O Ṣe Lè Múra Àtilọ Rí Oníṣègùn Eyín
Nínú ìwádìí káàkiri kan tí wọ́n ti ní káwọn èèyàn sọ àwọn ohun tó máa ń bà wọ́n lẹ́rù, bá a bá yọwọ́ ká báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ní gbangba, lílọ sọ́dọ̀ oníṣègùn eyín làwọn èèyàn sọ pé ó máa ń ba àwọn lẹ́rù jù. Ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ ọ̀hún le tó ni? Láwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù, àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n lè yára fi gbẹ́ eyín àtàwọn ìpara àti egbòogi tí kì í jẹ́ kéèyàn jẹ̀rora ti mú kó ṣeé ṣe fáwọn oníṣègùn eyín láti ṣe ọ̀pọ̀ lára iṣẹ́ wọn téèyàn ò sì ní fi bẹ́ẹ̀ mọ ìrora. Bó o bá mọ àwọn nǹkan tí wọ́n á ṣe bí wọ́n bá ń tọ́jú rẹ, ìyẹn tún lè dín ìbẹ̀rù rẹ kù.
Bó o bá lọ sí ilé ìtọ́jú eyín, ó lè jẹ́ pé fọyínfọyín tí wọ́n ń pè ní hygienist láá bá ọ fi egbòogi fọ eyín rẹ. Nígbà tó bá ń fọ eyín náà lọ́wọ́ ló máa fọ yọ̀rọ̀ àti èérí eyín kúrò níbi kọ́lọ́fín eyín tí búrọ́ọ̀ṣì àti fọ́nrán okùn ìfọyín ò lè dé. Lẹ́yìn náà ni wọ́n á mú kí eyín dán kí èérí má bàa gbára jọ síbẹ̀, kí wọ́n sì tún lè fọ àbàwọ́n tó lè tàbùkù sí ẹ̀rín kúrò níbẹ̀.
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé èròjà fluoride kì í jẹ́ kí eyín tètè jẹrà, àwọn tó ń tọ́jú eyín máa ń fi pa eyín àwọn ọmọdé, tàbí kí wọ́n fi fọ̀ ọ́, wọ́n sì tún lè fi mú un dán. Èròjà yìí tún máa ń wà nínú omi táwọn ará ìlú ń mu ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè, èyí tó pọ̀ sì sábà máa ń wà nínú ọṣẹ ìfọyín kí eyín má bàa bà jẹ́.
Kí Ni Iṣẹ́ Táwọn Dókítà Eyín Ń Ṣe?
Ńṣe ni ìdálẹ́kọ̀ọ́ túbọ̀ ń gorí ìdálẹ́kọ̀ọ́ fáwọn dókítà eyín lórí bí wọ́n á ṣe máa dènà omiró tó máa
ń ba èròjà inú eyín jẹ́. Bó o bá ń lo nǹkan sí ohun tó ń jẹ eyín kó tó di ńlá, lọ́pọ̀ ìgbà, èérí eyín ò ní lè máa wà nídìí eyín rẹ. Nítorí náà, bó o bá ń tètè kíyè sí ìdọ̀tí tó há sáàárín eyín, tó o sì ń bójú tó o lásìkò, àtilọ sọ́dọ̀ olùtọ́jú eyín kò ní máa bà ọ́ lẹ́rù.Àmọ́, bí omiró tó wá látara èérún oúnjẹ bá wà bẹ́ẹ̀ láìfọ̀ ọ́ kúrò, ńṣe ni eyín á bẹ̀rẹ̀ sí jẹrà. Bí wọn ò bá tètè wá nǹkan ṣe sí i, eyín lè dáhò. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ kéèyàn máa tọ́jú eyín. Bí eyín ò bá tíì jẹrà kan iṣan àárín eyín, wọ́n sábà máa ń fi èròjà kan báyìí dí ojú ihò náà, kí eyín tó ti ń bà jẹ́ lè padà sípò.
Olùtọ́jú eyín tún máa ń lo ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń gbẹ́ eyín láti fọ ojú ihò náà, á sì tún fi gbẹ́ ibi tó máa fi èròjà tí wọ́n fi ń dí ihò eyín sí. Lẹ́yìn náà ló máa da èròjà tí wọ́n fi ń dí ihò eyín sínú ihò náà. Èròjà amalgam tí wọ́n fi ń dí ihò eyín máa ń tètè gbẹ, bó bá wá gbẹ tán, wọ́n á fi ẹ̀rọ ṣe é sí bátànì tí wọ́n fẹ́. Àmọ́, èròjà olóje míì wà tí wọ́n ń lò tó jẹ́ pé iná kan báyìí ni wọ́n fi ń gbẹ òun ní tiẹ̀. Bí wọn ò bá tètè dí eyín tó dáhò, tó fi jẹrà kan iṣan àárín eyín, ó lè di dandan pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tọ́jú ẹsẹ̀ eyín, ìyẹn apá tó wọlé sínú erìgì, tàbí kí wọ́n kúkú yọ eyín náà kúrò. Bí wọ́n bá yàn láti tọ́jú ẹsẹ̀ eyín, kò tún ní pọn dandan pé kí wọ́n yọ eyín kúrò, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé irú ìtọ́jú yìí máa ń béèrè pé kí wọ́n rọ èròjà egbòogi sí ẹsẹ̀ eyín kí wọ́n sì dí ibi tó ń jẹrà náà pa. Bí eyín bá ti wá bà jẹ́ gan-an, wọ́n lè fi nǹkan bò ó, wọ́n lè fi irin so eyín náà mọ́ òmíràn, tàbí kí wọ́n fi eyín àtọwọ́dá pààrọ̀ eyín. c
Ìdí Tí Ìtọ́jú Eyín Fi Ṣe Pàtàkì
Bóyá ẹ̀rù àtilọ sọ́dọ̀ oníṣègùn eyín ṣì ń bà ọ́. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, sọ bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára rẹ fún oníṣègùn tó ń bá ọ tọ́jú eyín. Kó tó bẹ̀rẹ̀ sí tọ́jú eyín rẹ, ẹ jọ fohùn ṣọ̀kan lórí ohun tó o máa ṣe bó bá ti ń dùn ọ́. (Ó lè jẹ́ pé kó o nawọ́ sókè.) Sọ pé kó ṣàlàyé bó ṣe máa tọ́jú ẹ ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé. Bó o bá jẹ́ abiyamọ, o tún lè mú àwọn ọmọ rẹ lọ́kàn le bọ́ràn bá dọ̀ràn ìtọ́jú eyín, tí o kì í bá sọ̀rọ̀ ìtọ́jú eyín láìdáa. Tún rí i pé o kì í dẹ́rù bà wọ́n pé ilé ìtọ́jú eyín lo máa gbé wọn lọ bí wọ́n bá ṣe ohun tí kò tọ́.
Dókítà Daniel Kandelman, ọ̀jọ̀gbọ́n ní ẹ̀ka ìtọ́jú eyín nílé ẹ̀kọ́ gíga University of Montreal, sọ pé: “Bó bá jẹ ti ká tọ́jú eyín ni, èèyàn lè ṣàṣeyọrí tó gbámúṣé bí èyí: kéèyàn dáàbò bo eyín, kí eyín wà bí Ọlọ́run ṣe dá a, síbẹ̀ kó fani mọ́ra, kéèyàn sì máa fi rẹ́rìn-ín mùkẹ̀mukẹ títí dọjọ́ alẹ́.” Ìtọ́jú eyín ṣe pàtàkì o!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí eyín bá hù bó ṣe yẹ, ẹ̀rí ló jẹ́ pé ìyá ń jẹ irú oúnjẹ tó yẹ kó jẹ nígbà tó wà nínú oyún ọmọ náà àti pé kò tún fi oúnjẹ tó lè mú kí eyín hù bó ṣe yẹ du ọmọ náà nígbà tó wà lọ́mọ ọwọ́, lákòókò tí eyín máa ń kọ́kọ́ yọ látinú erìgì. Eyín á ti gbó nígbà tí ọmọ bá fi máa pé ogún ọdún tàbí kó lé díẹ̀.
b Àwọn Dókítà eyín ti rí i pé èròjà ṣúgà kan wà tó ń jẹ́ xylitol. Wọ́n ní èròjà yìí dáa gan-an láti fi dènà àwọn bakitéríà burúkú kan báyìí tó ń ba eyín jẹ́. Èròjà yìí wà nínú àwọn ṣingọ́ọ̀mù kan.
c Bó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa eyín àtọwọ́dá, wo àpilẹ̀kọ náà “Iwọ Ha Nilo Eyín Àtọwọ́dá Bí?” nínú Jí! February 22, 1993, ojú ìwé 18 sí 20.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Bó O Ṣe Lè Máa Fi Búrọ́ọ̀ṣì Fọ Eyín Rẹ
Onírúurú ọ̀nà lèèyàn lè gbà fi búrọ́ọ̀ṣì fọyín. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ kan rèé—ọṣẹ ìfọyín kíún ni kó o tẹ̀ sórí búrọ́ọ̀ṣì. Èròjà tó lè ha nǹkan ni wọ́n fi ṣe ọṣẹ ìfọyín, “ohun tó fi lágbára ju èròjà tó pilẹ̀ eyín lọ á fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po ọgọ́rùn-ún mélòó kan.”
1 Jẹ́ kí búrọ́ọ̀ṣì gbórí lé ibi tí eyín àti erìgì ti pàdé. Rọra fọ eyín òkè láti ibi erìgì wá sísàlẹ̀, sì fọ eyín ìsàlẹ̀ láti ibi erìgì lọ sókè. Rí i dájú pé o fọ eyín tinú tòde.
2 Jẹ́ kí búrọ́ọ̀ṣì rọra máa lọ síwá sẹ́yìn bó o bá ń fọ eyín.
3 Bó o bá fẹ́ fọ inú eyín iwájú, ki búrọ́ọ̀ṣì rẹ bọ ibẹ̀, kó o sì jẹ́ kí búrọ́ọ̀ṣì rẹ ṣe bí ẹní nàró gan-n-gan. Kó o wá fọ apá òkè láti ibi erìgì wá sísàlẹ̀, kó o sì fọ apá ìsàlẹ̀ láti ibi erìgì lọ sókè.
4 Jẹ́ kí búrọ́ọ̀ṣì máa lọ síwá sẹ́yìn bó o bá ń fọ orí ahọ́n àti àjà ẹnu rẹ.
[Credit Line]
Ìpele 1 sí 4: Pẹ̀lú ìyọ̀ọ̀da www.OralB.com
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Bó O Ṣe Lè Lo Fọ́nrán Okùn Ìfọyín
Àwọn oníṣègùn eyín dábàá pé kéèyàn máa lo fọ́nrán okùn ìfọyín lójoojúmọ́ kéèyàn sì máa fọ eyín ní gbogbo ìgbà lẹ́yìn oúnjẹ.
1 Lọ́ fọ́nrán okùn ìfọyín mọ́ orí ìka àárín tó wà lọ́wọ́ méjèèjì títí táá fi ṣẹ́ ku díẹ̀ láàárín.
2 Fi àtàǹpàkò ọwọ́ kan àti ìka ìlábẹ̀ ọwọ́ kejì fa fọ́nrán okùn ìfọyín náà le tantan. Fa fọ́nrán okùn ìfọyín náà síwá sẹ́yìn, kó o lè tẹ̀ ẹ́ bọ àárín eyín.
3 Máa tẹ fọ́nrán okùn ìfọyín náà síwá sẹ́yìn kó lè máa fọ ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún àti ẹ̀gbẹ́ òsì àárín eyín tó o bá kì í bọ̀. Ṣọ́ra torí erìgì rẹ o, má ṣe tẹ fọ́nrán okùn ìfọyín mọ́ erìgì, má sì ṣe fi gbo ó lọ gbo ó bọ̀.
[Àwọn Credit Line]
Ibi tá a ti rí ìsọfúnni: Ìwé amọ̀nà látọ̀dọ̀ ẹ̀ka tó ń bójú tó ìtọ́jú eyín ní Columbia University
Ìpele 1 sí 3: Pẹ̀lú ìyọ̀ọ̀da www.OralB.com