Àìrílégbé—Kí Lọ̀nà Àbáyọ?
Àìrílégbé—Kí Lọ̀nà Àbáyọ?
“ẸNÍ fúnni lẹ́ja jẹ foúnjẹ ọjọ́ kan bọ́ni; àmọ́ ẹni kọ́ni lẹ́ja pípa ló bọ́ni títí ayé.” Àṣàyàn ọ̀rọ̀ yìí lọmọ ìyá òwe míì tó sọ pé: “Gbà mu, kò tán ibà.” Bá a bá fún èèyàn lóhun tó ń fẹ́ lójú ẹsẹ̀, díẹ̀ nìyẹn tán lára ìṣòro onítọ̀hún. Ó tiẹ̀ sàn jù ká ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ bí wọ́n ṣe lè dá yanjú ìṣòro àti bọ́wọ́ wọn ṣe lè tẹ ohun tí wọ́n ṣaláìní. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló yẹ kó kọ́ béèyàn ṣe lè gbádùn ayé wọn tàbí bí wọ́n ṣe lè yí ojú tí wọ́n fi ń wo nǹkan àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbé ìgbé ayé wọn padà.
Ó dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lójú pé ọ̀nà tó dáa jù lọ tá a lè gbà ran àwọn aláìrílégbé lọ́wọ́ ni pé ká kọ́ wọn ní ọ̀nà tó dára jù lọ láti máa gbé ìgbé ayé wọn. Èyí túmọ̀ sí pé kí wọ́n fi ìmọ̀ràn tó dára jù lọ tí wọ́n lè rí sílò, ìyẹn ìmọ̀ràn tí Ẹlẹ́dàá fúnni. Àbí ta ló tọ́ kó fúnni nírú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀? Ìmọ̀ràn rẹ̀ ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kòòré ọ̀pọ̀ ìṣòro tó ń fa àìrílégbé. Ó tún ń ran àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ní ìṣòro àìrílégbé lọ́wọ́ láti borí ẹ̀. Ohun kan ni pé kíka Bíbélì fúnra rẹ̀ ò kásẹ̀
gbogbo ìṣòro tá à ń dojú kọ nílẹ̀. Àmọ́, Bíbélì lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ṣíwọ́ àwọn àṣàkaṣà tó ń gbọ́nni lówó lọ, láti padà dẹni tó ka ara wọn kún, kí wọ́n sì dẹni tó ń gbé ìgbé ayé ọmọlúwàbí.Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti di aláìnílélórí látàrí lílò tí wọ́n ń lo àwọn nǹkan tó ń di bárakú síni lára, híhùwà ọ̀daràn, ìṣòro ìṣúnná owó, tàbí ìdílé tó pínyà. Bíbélì fúnni láwọn ìmọ̀ràn tó múná dóko lórí àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí. Fífi irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ sílò ti ran àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lọ́wọ́ báyìí láti yí ojú tí wọ́n fi ń wo ìgbé ayé wọn padà, àní ó tiẹ̀ ti yí irú ẹni táwọn fúnra wọn jẹ́ padà pátápátá, sí rere. A mọ̀ pé fífi àwọn ìmọ̀ràn inú Ìwé Mímọ́ sílò nìkan lè má lè yanjú àwọn ìṣòro tó jẹ mọ́ àìrílégbé. Ní báyìí ná, àwọn ìjábá, àìlera ara, ipò òṣì tó ń gbilẹ̀, sísọ oògùn àti ọtí di bárakú, àtàwọn ìṣòro míì bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ ṣì jẹ́ àwọn ìṣòro táá máa béèrè pé kéèyàn ṣèrànwọ́ nírú àwọn ọ̀nà mìíràn kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran olúkúlùkù èèyàn tí irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ ń bá fínra lọ́wọ́, a mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá aráyé nìkan ló lè yanjú àwọn ìṣòro náà títí láé fáàbàdà. Ṣó máa yanjú àwọn ìṣòro náà ṣá?
Bí Ọlọ́run Ṣe Fẹ́ Kí Nǹkan Rí ní Ìpilẹ̀ṣẹ̀
Ìdí wà tá a fi lè gbà gbọ́ pé ìṣòro àìrílégbé máa tó dópin. Kí nìdí? Gbé èyí yẹ̀ wò: Jèhófà Ọlọ́run pèsè ibùgbé tó dáa fún tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́. Ọlọ́run fi wọ́n sínú párádísè, níbi tí wọ́n ti ní gbogbo ohun tí wọ́n fẹ́ ní ànító àti àníṣẹ́kù. Ká sọ pé wọ́n ti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ẹlẹ́dàá wọn ni, wọn ì bá ti mú kí Párádísè yẹn gbòòrò dé gbogbo ilẹ̀ ayé. Àwọn àtọmọdọ́mọ wọn ì bá ti ní ànító àti àníṣẹ́kù àti ilé tó túni lára. Ì bá ti ṣeé ṣe fún olúkúlùkù ẹ̀dá tó ń gbé láyé láti gbára lé ìfẹ́ àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ọmọlàkejì wọn. Bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí nǹkan rí ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ nìyẹn. Kò sì tí ì yí èrò rẹ̀ padà.—Sáàmù 37:9-11, 29.
Síwájú sí i, ó dájú pé ohunkóhun tí Ọlọ́run bá fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ ló máa ṣẹlẹ̀. (Aísáyà 55:10, 11) Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àkókò kan ń bọ̀ tí olúkúlùkù á ní ilé tirẹ̀ àti ọ̀pọ̀ yanturu nǹkan tara. A mọ̀ pé kí ìyẹn tó lè ṣeé ṣe, àyípadà gbọ́dọ̀ dé bá àwùjọ ẹ̀dá èèyàn wa yìí látòkèdélẹ̀. Àfi bí Ọlọ́run bá sì lọ́wọ́ sí ọ̀ràn àwa ẹ̀dá ni irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ tó lè wáyé. Ohun tí Jésù ní lọ́kàn gan-an nìyẹn nígbà tó ń sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:9, 10.
Lábẹ́ ìṣàkóso òdodo ti Ìjọba Ọlọ́run, aráyé onígbọràn á rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tó ń múni lọ́kàn yọ̀ yìí pé: “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn . . . Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ. . . . Iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.” (Aísáyà 65:21, 22) Láìdéènà pẹnu, kò ní sí aláìrílégbé kankan.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sapá láti fún àwọn èèyàn ní ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí tó jẹ́ kòṣeémánìí fún wọn ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Wọ́n tún máa ń fìfẹ́ ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́, wọ́n sì máa ń gba tiwọn rò bí Jésù ti ṣe. (Mátíù 22:36-39) Ti pé ọ̀ràn àwọn ẹlòmíì máa ń jẹ wọ́n lógún náà ló ń mú kí wọ́n máa ran àwọn tí ìjábá ti mú kí wọ́n pàdánù ilé wọn lọ́wọ́. a
Ká sòótọ́ tó wà níbẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé kò ṣeé ṣe láti ran gbogbo èèyàn lọ́wọ́. Jacek, tó wá láti orílẹ̀-èdè Poland, tó ń gbé nínú ilé tí wọ́n kọ́ fún àwọn aláìrílégbé, ló sọ ọ̀rọ̀ tò tẹ́ lé e yìí nípa àwọn aláìrílégbé: “Àwọn kan ya oníjàgídíjàgan tàbí kí oògùn olóró tiẹ̀ máa pa wọ́n bí ọtí. Àwọn míì kórìíra ká máa jíròrò ọ̀ràn ẹ̀sìn, nítorí èrò wọn
ni pé Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀ràn àwọn. Àmọ́, àwọn kan wà tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kan lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Jacek fúnra rẹ̀. Ó ti bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i nípa ohun tí Bíbélì fi kọ́ni ní ti gidi.Ọkùnrin aláìrílégbé míì tó fìfẹ́ hàn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Roman, tó ní àrùn éèdì, tó sì ń gbé lójú pópó títí fi di ẹnu àìpẹ́ yìí. Ó níràn ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sì sọ pé: “Nígbà tí mo kọ́kọ́ dé Ibùdó Àwọn Afẹ́dàáfẹ́re tó ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ yìí, mi ò mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣèpàdé nítòsí ibẹ̀. Kò sì pẹ́ tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí bá mi jíròrò lójú pópó níbẹ̀, tí wọ́n sì ṣàlàyé fún mi pé Ọlọ́run máa ń tẹ́tí sí àdúrà àwọn èèyàn tí kò nílé lórí. Wọ́n tún ní kí n wá sí ọ̀kan nínú àwọn ìpàdé àwọn.”—Sáàmù 72:12, 13.
Báwo ni ohun tó gbọ́ ṣe ràn án lọ́wọ́? “Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé mo lè máa gbé títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé àti pé mo ṣeyebíye lójú Ọlọ́run. Ní báyìí táwọn ọ̀rẹ́ tó ń gba tẹni rò ti yí mi ká, mi ò ro ti ìṣòro tó bá mi mọ́ mo sì bẹ̀rẹ̀ sí yí ìwà mi padà. Nítorí pé mo nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, mi ò mu sìgá mọ́, mo sì ṣèlérí fún Ọlọ́run nínú àdúrà pé màá máa rìn ní ipa ọ̀nà òdodo.”
Roman tẹ̀ síwájú dáadáa nípa tẹ̀mí, kò sì pẹ́ tó fi ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìrànlọ́wọ́ tó rí gbà lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí bíi tiẹ̀ yìí àti látọ̀dọ̀ àwọn aláṣẹ mú kó ṣeé ṣe fún un láti máa gbé nínú ilé tó bójú mu. Roman bú sí ayọ̀, ó sọ pé: “Ńṣe ni ayọ̀ kún inú mi fọ́fọ́ bí ilé ataare. Mo ti sún mọ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ ẹni tó jẹ́ káyé mi padà nítumọ̀. Ó fi ìdílé tó jíire níbi táwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin wà jíǹkí mi, mo sì tún dẹni tó nílé lórí!”
Ọjọ́ Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dára Fáwọn Aláìrílégbé
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sapá láti fi ara wọn sípò àwọn aládùúgbò wọn, tó fi mọ́ àwọn aláìrílégbé. Wọ́n máa ń fẹ́ láti fi òtítọ́ Bíbélì nípa ọjọ́ ọ̀la tó sàn jù kọ́ àwọn èèyàn, òtítọ́ tó lè yí ìgbésí ayé padà báyìí.—Jòhánù 8:32
Bíbélì sọ pé: “Èyí tí a ṣe ní wíwọ́ ni a kò lè mú tọ́.” (Oníwàásù 1:15) Àmọ́ ṣá o, bó ti wù kí ohun táwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni àtàwọn aláṣẹ yìí ní lọ́kàn dára tó, àwọn ìṣòro ìgbé ayé ẹ̀dá tó ti ta gbòǹgbò, bí àìrílégbé àti òṣì ṣòro mú kúrò pátápátá. Àmọ́ Bíbélì fi dá wa lójú pé láìpẹ́, lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run, gbogbo èèyàn onígbọràn yóò gbádùn àtimáa gbé lábẹ́ ipò pípé.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àwọn àpẹẹrẹ èyí nínú Jí! January 8, 1993 (Gẹ̀ẹ́sì), ojú ìwé 14 sí 21; Jí! October 22, 2001 (Gẹ̀ẹ́sì), ojú ìwé 23 sí 27; àti Jí! August 8, 2003, ojú ìwé 22 sí 27.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ìyá kan láti orílẹ̀-èdè Sòmálíà tó mú káàdì tí wọ́n fi ń tò fún oúnjẹ dání ní ibùdó àwọn olùwá-ibi-ìsádi kan
[Credit Line]
© Fọ́tò tí Trygve Bolstad/Panos Pictures yà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó yẹ káwọn aláìrílégbé ní àgbọ́kànlé pé ọjọ́ iwájú á dáa
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Kò ní sí aláìrílégbé kankan lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run