Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àìrílégbé Ti Di Ìṣòro Tó Kárí Ayé

Àìrílégbé Ti Di Ìṣòro Tó Kárí Ayé

Àìrílégbé Ti Di Ìṣòro Tó Kárí Ayé

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ POLAND

“ÀWỌN olóòórùn, ọ̀bùn ṣìọ̀ṣìọ̀, wọn ò ní gá, wọn ò ní go, wọn ò lárá, wọ́n ò sì léèyàn!” Ẹ ò rí i pé àpèjúwe tó kani láyà lèyí jẹ́, síbẹ̀ àwọn olùyọ̀ọ̀da ara ẹni tó ń ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n kọ́ fáwọn tí kò nílé lórí nílùú Czestochowa, lórílẹ̀-èdè Poland sọ pé ojú táwọn èèyàn fi ń wo àwọn tí kò nílé lórí nìyẹn.

Bí ìròyìn kan nínú ìwé ìròyìn The Economist ṣe sọ lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn, ibi àbákọjá tó ń rùn fùn-ùn lápá ìsàlẹ̀ àwọn òpópónà ìlú Ulaanbaatar, lórílẹ̀-èdè Mongolia, ni ọ̀pọ̀ lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọmọ asùnta tó wà níbẹ̀ ń gbé. Àwọn ibi àbákọjá náà ló lọ já síbi kòtò omi ìgbọ̀nsẹ̀ tàbí ibi tí ooru táwọn aráàlú fi ń múlé gbóná ti ń wá. Ìwé ìròyìn náà tún wá fi kún un pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè múni ta kìjí béèyàn bá kọ́kọ́ gbọ́ nípa àwọn ọmọ tí kò nílé lórí yìí, ọ̀pọ̀ àwọn ará Mongolia ló ń sọ pé ohun tó fà á tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀ “ni pé àwọn èèyàn ti yọ̀lẹ kọjá kí wọ́n lè tọ́jú àwọn ọmọ wọn.”

Láwọn apá ibòmíì nínú ayé, ìpakúpa làwọn fijilanté tágbára ń gùn, tí wọ́n máa ń pa ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá fura sí, ń pa àwọn ọmọ asùnta. Kí nìdí? Àtẹ̀jáde kan tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gbé jáde ṣàlàyé pé: “Nílẹ̀ Látìn Amẹ́ríkà, ọ̀pọ̀ àwọn tó wà nídìí ètò ìdájọ́, àwọn ọlọ́pàá, àjọ akọ̀ròyìn, àwọn oníṣòwò, àtàwọn aráàlú gbà pé ewu gbáà làwọn ọmọ ajẹ̀gboro jẹ́ láwùjọ táwọn èèyàn ti jẹ́ ọ̀làjú.” Àtẹ̀jáde náà tún sọ síwájú sí i pé: “Ó kéré tán, ọmọ ajẹ̀gboro-dàgbà mẹ́ta ni ìròyìn sọ pé wọ́n ń pa lójúmọ́ ní ìpínlẹ̀ Rio de Janeiro, lórílẹ̀-èdè Brazil.”

Àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n kọ́ fáwọn tí kò nílé lórí nílùú Czestochowa ní ìkànnì kan lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Wọ́n sọ níbẹ̀ pé àwọn tí kò rílé gbé “máa ń mú ká bẹ̀rù, kí ọkàn wa má sì balẹ̀. . . , àmọ́ ẹ̀dá ẹlẹ́ran ara tí ebi ń pa bíi tiwa làwọn náà. Irú wọn pọ̀, wọn ò sì lágbòójúlé kankan.” Wọ́n tún wá fi kún un pé: “A nírètí pé . . . a óò ráwọn èèyàn táá dìde ìrànlọ́wọ́.” Kí tiẹ̀ lohun tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ lé lórí gan-an, báwo ni ìṣòro náà sì ṣe pọ̀ tó?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 2, 3]

Àwọn ọmọ aláìrílégbé kan wà tí wọ́n ń gbé nínú ihò tó gba abẹ́ ilẹ̀ kọjá yìí

[Credit Line]

Jacob Ehrbahn/Morgenavisen Jyllands-Posten