Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Béèyàn Bá Ṣe Láǹfààní Láti Yàn Tó Ni Ìtẹ́lọ́rùn Á Ṣe Jìnnà Sí I Tó?

Ṣé Béèyàn Bá Ṣe Láǹfààní Láti Yàn Tó Ni Ìtẹ́lọ́rùn Á Ṣe Jìnnà Sí I Tó?

Ṣé Béèyàn Bá Ṣe Láǹfààní Láti Yàn Tó Ni Ìtẹ́lọ́rùn Á Ṣe Jìnnà Sí I Tó?

ÀPILẸ̀KỌ kan nínú ìwé ìròyìn Scientific American sọ pé àwọn èèyàn tó wà nílẹ̀ Amẹ́ríkà ní “àǹfààní láti yan ohun púpọ̀ lóríṣiríṣi ọ̀nà ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.” Òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn tó bá dọ̀ràn kí wọ́n yan irú ọjà tí wọ́n fẹ́ rà, irú iṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ gbé fún èèyàn láti ṣe, irú ibi tí wọ́n fẹ́ wáṣẹ́ sí àti irú ẹni tí wọ́n á fẹ́ máa bá rìn. Téèyàn bá fojú inú wò ó, èèyàn lè retí pé ṣe ló yẹ kí ìgbésí ayé máa tù wọ́n lára bí wọ́n ṣe láǹfààní tó pọ̀ láti yan ohun tó wù wọ́n. Àmọ́, ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé ìyọnu nìyẹn ń kó wọn sí. Kí ló wá fà á o?

Àpilẹ̀kọ náà sọ pé ojú téèyàn bá fi wo ohun tó yàn láá sọ bó ṣe máa láyọ̀ sí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò tí wọ́n á sì ṣe wàhálà tó pọ̀ níbi tí wọ́n ti ń yẹ ọjà tí wọ́n fẹ́ rà wò kí wọ́n lè yan èyí tó dàá jù. Wọ́n á wá máa yẹ ohun tí wọ́n kọ sí ẹ̀yìn ọrùn àwọn aṣọ náà wò, wọ́n á máa wo èyí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé tí wọ́n á sì máa fi ohun tí wọ́n rà wé èyí táwọn ẹlòmíì rà. Báwọn míì bá fẹ́ ra ọjà, èyí tó bá “ṣáà ti dáa” ti tẹ́ wọn lọ́rùn, kódà kéyìí tó dáa jù bẹ́ẹ̀ lọ tiẹ̀ wà. Irú àwọn bẹ́ẹ̀ á wulẹ̀ sinmi agbaja nígbà tí wọ́n bá ti rí i pé ohun táwọn rí ti bá ohun táwọn nílò mu.

A lè rí i pé bí oríṣiríṣi bá ṣe kúnlẹ̀ tó ni ìpinnu ṣíṣe á ṣe nira tó fáwọn tó bá ń wá èyí tó dára jù. Ìwé ìròyìn Scientific American sọ pé nígbà tí wọ́n bá wá pinnu ohun tí wọ́n á rà tán wàyí, “á di pé kí wọ́n tún máa banú jẹ́ torí pé wọ́n ti rí irú míì tí wọn ì bá ti yẹ̀ wò ká ní wọ́n ráàyè ni.” Ní àbárèbábọ̀, irú àwọn bẹ́ẹ̀ “kì í sábàá ní ìtẹ́lọ́rùn láyé wọn, wọn kì í láyọ̀ púpọ̀, wọn kì í ronú pé ohun tó dáa ń bọ̀, àwọn sì ni àárẹ̀ ọkàn máa ń mú jù.” Kí la wá lè rí fà yọ nínú èyí? Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “A lè rí i pé lára ohun tó ń fà á tí ọ̀pọ̀ èèyàn láwùjọ òde òní ò fi láyọ̀ ni pé wọ́n ní oríṣiríṣi nǹkan tí wọ́n lè yàn.”

Àmọ́, àwọn tó ṣe ìwádìí náà sọ pé èèyàn lè dín ìnira tó wà nínú yíyan ohun tó wu èèyàn kù. Bíi báwo?

● A lè yàn láti dín onírúurú nǹkan tá a ó máa yẹ̀ wò kù tí kì í bá ṣe pé ó pọn dandan. Bí àpẹẹrẹ, pinnu pé ìwọ̀nba ni iye ṣọ́ọ̀bù tó o máa yà tó o bá fẹ́ ra aṣọ.

● Fara mọ́ èyí tó bá ti bá ohun tó o nílò mu dípò kó o máa wá èyí tó ‘dáa jù,’ tó o lè máà rí láéláé. Kó o sì gbàgbé nípa ẹ̀.

● Mọ̀ọ́mọ̀ gbọ́kàn kúrò lára èyí tó o kọ̀ tó ò yàn, má ṣe máa ronú lórí ibi tó dà bíi pé ó dáa sí. Fi kọ́ ara rẹ láti máa ronú lórí àǹfààní tó wà nínú ohun tó o yàn.

● Àṣamọ̀ ọ̀rọ̀ kan ni pé: “Ẹní bá ti fọkàn sí ohun tó pọ̀ jù, ìjákulẹ̀ láá bá pàdé.” Àmọ́ ìmọ̀ràn tó mọ́gbọ́n dání ni fẹ́ni tó bá fẹ́ gbádùn ìgbésí ayé ẹ̀.

[Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]

Orísun ìsọfúnni: Ìwé ìròyìn Scientific American