Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Dandan Ni Ká Ṣègbéyàwó Níṣulọ́kà?

Ṣé Dandan Ni Ká Ṣègbéyàwó Níṣulọ́kà?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Ṣé Dandan Ni Ká Ṣègbéyàwó Níṣulọ́kà?

“Cindy, ìyàwó àfẹ́sọ́nà mi ló kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa pé ká ṣègbéyàwó wa ní bòókẹ́lẹ́ láìsí pé tẹbí tọ̀rẹ́ mọ̀ sí i. Nígbà tá a sì sọ ọ́ lọ sọ ọ́ bọ̀, a rí i pé bá a bá ṣe é báyẹn, kò ní gba àkókò púpọ̀, kò ní ṣe wá ní wàhálà tó bẹ́ẹ̀, kò sì ní ni wá lára.”— Allen. a

TÓ O bá ti dàgbà tẹ́ni tó ń ṣègbéyàwó, tọ́rọ̀ ìfẹ́ sì ti wà láàárín ìwọ àtẹnì kan, ó lè máa wù yín pé kẹ́ ẹ ṣègbéyàwó yín ní bòókẹ́lẹ́. Àwọn nǹkan míì lè ṣẹlẹ̀ tó lè mú kí ọmọbìnrin kan bá ọkọ sá lọ kí wọ́n sì lọ ṣègbéyàwó láìsọ fáwọn òbí wọn. Àwọn ìlànà wo ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti pinnu ohun tó yẹ kó o ṣe?

Ṣé Dandan Ni Kó O Tẹ̀ Lé Àṣà Ìbílẹ̀?

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà síbi tí wọn kì í ti í ṣègbéyàwó, ó kàn jẹ́ pé bí wọ́n ṣe máa ń ṣe é níbì kan yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe máa ń ṣe é níbòmíì ni. Ọ̀rọ̀ pé ìgbéyàwó gbọ́dọ̀ bá àṣà ìbílẹ̀ wọn mu kọ́ ló ṣe pàtàkì jù fáwọn Kristẹni tó bá fẹ́ fẹ́ra wọn. (Róòmù 12:2) Dípò ìyẹn, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ fún wọn ni bí wọ́n á ṣe jẹ́ kí ìfẹ́sọ́nà àti ìgbéyàwó wọn mú ọlá bá Jèhófà Ọlọ́run.—1 Kọ́ríńtì 10:31.

Níwọ̀n bí ìgbéyàwó ti jẹ́ ìṣètò tó lọ́lá, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó ò ní fẹ́ ṣe é ní bòókẹ́lẹ́. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá fẹ́ ṣègbéyàwó, wọ́n máa ń ṣètò láti ṣayẹyẹ náà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. b Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n wá lè bẹ̀rẹ̀ ètò àwẹ̀jẹwẹ̀mu fún tẹbítọ̀rẹ́ kí wọ́n sì máa dá ara wọn lára yá. Kò pọn dandan kí irú ayẹyẹ bẹ́ẹ̀ jẹ́ gbagba dudu. A gbọ́dọ̀ gbà pé wàhálà pọ̀ nídìí ṣíṣetò ayẹyẹ ìgbéyàwó àti àwẹ̀jẹwẹ̀mu, ó sì lè náni lówó gọbọi. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó sábà máa ń ná wọn ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún owó dọ́là láti ṣètò àwẹ̀jẹwẹ̀mu ayẹyẹ ìgbéyàwó.

Láti lè dín wàhálà àti ìnáwó tó wà nídìí ẹ̀ kù, àwọn tọkọtaya kan ti yàn láti ṣègbèyàwó tí kò mú ariwo lọ́wọ́. Cindy sọ pé: “A sọ fáwọn òbí wa pé a ò ní ṣègbéyàwó níṣulọ́kà torí pé a kò fẹ́ kó jẹ́ aláriwo a ò sì fẹ́ kó ná wa lówó. Àwọn òbí mi sọ fún wa pé ọ̀rọ̀ wa yé àwọn, wọ́n sì ní kò sí ìṣòro. Wọ́n tì wá lẹ́yìn gbágbáágbá.” Àmọ́ nígbà tí Allen, ẹni tá a ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, tó jẹ́ ọkọ àfẹ́sọ́nà Cindy, sọ fáwọn òbí tiẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe fẹ́ ṣètò ìgbéyàwó wọn, àwọn òbí ẹ̀ ò fẹ́ gbà fún wọn. Allen sọ pé: “Wọ́n rò pé ẹ̀bi àwọn ni, wọ́n sọ pé ó ní láti jẹ́ torí ohun kan táwọn ò ṣe dáa la ṣe ṣerú ìpinnu yẹn. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá àti rárá.”

Ó lè bí àwọn òbí tìẹ náà nínú tó o bá sọ pé ìgbéyàwó bòókẹ́lẹ́ lo fẹ́ ṣe, torí pé wọ́n lè fẹ́ pe ọ̀pọ̀ èrò láti wá bá wọn yọ ayọ ọjọ́ ẹ̀yẹ wọn. Ká wá ní o tiẹ̀ ń gbèrò pé o kò ní jẹ́ káwọn òbí ẹ mọ̀ kó o tó ṣègbéyàwó nítorí o mọ̀ pé wọn ò ní gbà kó o ṣègbéyàwó ńkọ́?

Ro Bó Ṣe Máa Rí Lójú Àwọn Èèyàn Rẹ

Ó lè jẹ́ pé àwọn òbí ẹ ò ní fọwọ́ sí i, torí wọ́n gbà pé o ṣì kéré sẹ́ni tó ń ṣerú ìpinnu pàtàkì yẹn. Ẹ̀rù lè máa bà wọ́n pé bó o bá ṣe ń dàgbà sí i lohun tó ń wù ẹ́ á ṣe máa yí padà àti pé o ò ní pẹ́ kábàámọ̀ pé irú ẹni yẹn lo fẹ́. Ẹ̀wẹ̀, ó lè jẹ́ pé wọ́n gbà pé o ti tó ẹni tó ń ṣègbéyàwó àmọ́ wọ́n ráwọn ohun kan tí wọ́n kà sí àléébù nínú ìwà ẹni tó o fẹ́ fẹ́. Ó sì lè jẹ́ pé torí pé ìgbàgbọ́ ẹni tó o fẹ́ fẹ́ kò pa pọ̀ mọ́ tìẹ ni wọn ò ṣe fẹ́ kó o fẹ́ ẹ.

Tó bá jẹ́ pé Kristẹni tòótọ́ làwọn òbí ẹ, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú Bíbélì ni wọ́n ti rí ohun tí wọ́n tìtorí ẹ̀ dá ẹ dúró àtiṣe ìgbéyàwó. Ẹ̀tọ́ wọn ni láti sọ ohun tó bá ń rú wọn lójú jáde. Kódà, tí wọn ò bá sọ ọ́, Jèhófà á kà á sí wọn lọ́rùn pé wọn ò bójú tó iṣẹ́ wọn dáadáa àti pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ rẹ. Fún àǹfààní ara ẹ sì ni tó o bá fetí sóhun tí wọ́n ń bá ẹ sọ.—Òwe 13:1, 24.

Àpẹẹrẹ kan rèé: Tó o bá ra aṣọ kan, ó ṣeé ṣe kó o ní kí ẹlòmíì bá ẹ wò ó bí aṣọ náà bá bá ẹ lára mu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà náà kọ́ ni wàá máa gba ohun tí wọ́n bá sọ, síbẹ̀ wàá ṣáà retí káwọn ọ̀rẹ́ ẹ tímọ́tímọ́ sọ ohun tí wọ́n ń rò nípa aṣọ náà, bóyá kò dáa lára ẹ tàbí bóyá pé o ò dáa nínú ẹ̀. Ó dájú pé wàá dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn fóhun tí wọ́n sọ, torí pé wọn ò jẹ́ kó o fowó jóná. Ṣó o wá rí i nísinsìnyí pé á dáa kó o gbọ́ ohun táwọn èèyàn ẹ ń sọ lórí ọ̀ràn ẹni tó wù ẹ́ fẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ pé o lè dá aṣọ tí kò dáa padà tàbí kó o pa á tì, ńṣe ni Jèhófà fẹ́ kí ìwọ àti ọkọ tàbí ìyàwó tó o bá fẹ́ jọ wà títí ayé ẹ. (Mátíù 19:5, 6) Tó o bá lọ fẹ́ ẹni tí ìwà ẹ̀ ò bá tìẹ mu tẹ́ ò sì bá ara yín mu nípa tẹ̀mí, gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ lohun tójú ẹ máa rí níbẹ̀ á fi kọjá ohun tójú ẹ máa rí tó o bá wọṣọ tí kò bá ẹ lára mu. Yàtọ̀ síyẹn, tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, àyọ tòótọ́ ló bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́ wẹ́rẹ́ yẹn.—Òwe 5:18; 18:22.

Lóòótọ́, ó lè jẹ́ pé ìmọtara-ẹni nìkan ló ń mú káwọn òbí kan má gbà kí ọmọ wọn ṣègbéyàwó bó ṣe wù ú. Àpẹẹrẹ irú ìyẹn ni tàwọn tó fẹ́ máa darí ọmọ wọn títí ayé ẹ̀. Àmọ́ ṣá, kó o tó sọ pé tara àwọn òbí ẹ nìkan ni wọ́n ń rò tí wàá sì yọ́ lọ ṣègbéyàwó, o ò ṣe ronú wò lórí ìdì tí wọn ò fi gbà?

Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Ṣọ́ra

Òótọ́ pọ́ńbélé ni pé bó o bá ṣe ń dàgbà sí lohun tó ń wù ẹ́ á ṣe máa yí padà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nígbà tí mo jẹ́ ìkókó, mo máa ń sọ̀rọ̀ bí ìkókó, ronú bí ìkókó, gbèrò bí ìkókó; ṣùgbọ́n nísinsìnyí tí mo ti wá di ọkùnrin, mo ti fi òpin sí àwọn ìwà ìkókó.” (1 Kọ́ríńtì 13:11) Bákan náà, àwọn ìwà tó wù ẹ́ lára ẹlòmíì lónìí nígbà tó o ṣì wà lọ́dọ̀ọ́ lè yàtọ̀ sí èyí tó máa wù ẹ́ nígbà tó o bá dàgbà sí i. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì ṣe dá a lábàá pé kó o dúró tí wàá fi “ré kọjá ìgbà ìtànná òdòdó èwe,” ìyẹn àwọn ọdún tí ìbálòpọ̀ máa ń wu èèyàn jù lọ, kó o tó ṣe ìpinnu tó lágbára bíi yíyan ẹni tó o máa fẹ́.—1 Kọ́ríńtì 7:36.

Táwọn òbí ẹ bá sọ pé àwọn rí àléèbù ẹni tó o fẹ́ fẹ́ ńkọ́? Ìrírí tí wọ́n ti ní nígbèésí ayé lè ti kọ́ agbára ìwòye wọn dáadáa ju tìẹ lọ láti fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. (Hébérù 5:14) Nítorí náà, wọ́n lè ráwọn àbùkù ńlá kan lára olólùfẹ́ ẹ tí ìwọ ò sì rí i. Ìwọ wo ìlànà tó wà nínú ohun tí ọlọgbọ́n ọkùnrin náà, Sólómọ́nì kọ pé: “Ẹnì kìíní nínú ẹjọ́ rẹ̀ jẹ́ olódodo; ọmọnìkejì rẹ̀ wọlé wá, dájúdájú, ó sì yẹ̀ ẹ́ wò látòkè délẹ̀.” (Òwe 18:17) Bákan náà, olólùfẹ́ rẹ ti lè mú kó o gbà gbọ́ pé kò sẹ́lòmíì tó bá ẹ mu tó òun. Àmọ́ ṣá, lẹ́yìn táwọn òbí ẹ ti “yẹ̀ ẹ́ wò látòkè délẹ̀,” wọ́n lè fi àwọn nǹkan kan tó yẹ kó o yẹ̀ wò dáadáa hàn ẹ́.

Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè rán ẹ létí láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ pé ohun tí Bíbélì sọ ni pé káwọn Kristẹni tòótọ́ ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 7:39) O lè yarí pé o mọ àwọn míì tí wọ́n fẹ́ ẹni tí kì í ṣe Kristẹni bíi tiwọn síbẹ̀ táwọn méjèèjì ń fayọ̀ sin Jèhófà báyìí. Ó máa ń ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ lóòótọ́ o. Àmọ́, irú wọn ò tó nǹkan lára àwọn tọ́ràn yíwọ́ fún. Tó o bá lọ fẹ́ ẹni tí kì í ṣe onígbàgbọ́ bíi tìẹ, àìdáa àkọ́kọ́ tó o ṣe ni pé o ò ka àwọn ìlànà Jèhófà kún, ekejì sì ni pé o ti fi ara rẹ sínú ewu tẹ̀mí.—2 Kọ́ríńtì 6:14. c

Ohun Tí Kò Yẹ Kó O Torí Ẹ̀ Ṣègbéyàwó

Àwọn ọ̀dọ́ kan ti bá ọkọ sá lọ tí wọ́n sì lọ ṣègbéyàwó ní bòókẹ́lẹ́ nítorí pé wọ́n ṣèṣekúṣe tí wọ́n sì rò pé táwọn bá fẹ́ ẹni táwọn jọ ṣe é, ẹ̀rí ọkàn àwọn á jẹ́ káwọn gbádùn. Wọ́n sì lè rò pé táwọn bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè bo àtubọ̀tán ẹ̀ṣẹ̀ àwọn mọ́lẹ̀, irú bí oyún àìròtẹ́lẹ̀.

Tó o bá fẹ́ fi ìgbéyàwó bo ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀, ṣe lo wulẹ̀ ń dá kún àṣìṣe tó o ṣe. Sólómọ́nì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bo àwọn ìrélànàkọjá rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò kẹ́sẹ járí, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ni a ó fi àánú hàn sí.” (Òwe 28:13) Bàbá àti ìyà Sólómọ́nì, ìyẹn Dáfídì àti Bátí-ṣébà rí i pé ìwà òmùgọ̀ ni pé kéèyàn máa gbìyànjú láti bo ìṣekúṣe tó ṣe mọ́lẹ̀. (2 Sámúẹ́lì 11:2-12:25) Dípò tí wàá fi máa fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ pa mọ́, lọ bá àwọn òbí ẹ àtàwọn alàgbà ìjọ rẹ sọ ọ́. Ó gba pé kó o máyà le o, àmọ́ jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà á dárí jì ẹ́ tó o bá ronú pìwà dà. (Aísáyà 1:18) Tí ẹ̀rí ọkàn rẹ bá sì ti wá padà mọ́ báyìí, o wá lè ronú ní àrògún kó o tó ṣèpinnu lórí ọ̀ràn ìgbéyàwó.

Má Ṣe Ohun Tó Máa Mú Kó O Ki Ìka Àbámọ̀ Bọnu

Nígbà tí Allen tún ronú nípa ìgbà tó fẹ́yàwó, ó sọ pé: “Ìpinnu wa láti má ṣe ṣègbéyàwó aláriwo dín wa ní wàhálà kù. Ohun kan ṣoṣo tí mo kábàámọ̀ níbẹ̀ ni pé mi ò jẹ́ káwọn èèyàn mi lóye ìdí tá a fi ṣèpinnu yẹn.”

Lóòótọ́, ọwọ́ tọkùnrin tobìnrin èyíkéyìí tí wọ́n bá ti dàgbà tó láti gbéyàwó ló wà yálà wọ́n á ṣègbéyàwó níṣulọ́kà tàbí wọn ò ní ṣe é bẹ́ẹ̀. Àmọ́, bí ìwọ bá fẹ́ ṣe ìpinnu èyíkéyìí lórí ìgbéyàwó, máà kánjú ṣe é o, bá àwọn èèyàn ẹ sọ ọ́ kó kúnná, kó o sì ‘ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ rẹ.’ Èyí á dín ohun tó lè mú kó o kábàámọ̀ kù.—Òwe 14:15.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

b Àwọn ibi ìjọsìn yìí bójú mu láti lò fún ayẹyẹ ìgbéyàwó àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣe ni wọ́n á rọra ṣe é ráńpẹ́, wọ́n sì máa ń jíròrò àwọn ìlànà Bíbélì ní ṣókí, èyí táwọn tọkọtaya náà lè fi ṣe ìpìlẹ̀ rere fún ìgbéyàwó wọn. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, a kì í díye lé àwọn tó bá fẹ́ ṣègbéyàwó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.

c Ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àlàyè lórí kókó yìí wà nínú Ilé Ìṣọ́ July 1, 2004, ojú ìwé 30 sí 31, àti November 1, 1989, ojú ìwé 18 sí 22.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Tó o bá fẹ́ ṣèpinnu lórí ọ̀ràn ìgbéyàwó, bá àwọn èèyàn rẹ sọ ọ́